Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
APRIL 2-8
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÀTÍÙ 26
“Ìyàtọ̀ àti Ìjọra Tó Wà Láàárín Ìrékọjá àti Ìrántí Ikú Kristi”
nwtsty àwòrán àti fídíò
Oúnjẹ Ìrékọjá
Àwọn ohun tí wọ́n máa ń jẹ nígbà Ìrékọjá ni: ẹran àgùntàn tí wọ́n yan (wọn ò gbọ́dọ̀ fọ́ ìkankan lára egungun rẹ̀) (1); àkàrà aláìwú (2); àti ewébẹ̀ kíkorò (3). (Ẹk 12:5, 8; Nu 9:11) Ìwé Míṣínà sọ pé ó ṣeé ṣe kí lettuce, chicory, pepperwort, endive, tàbí dandelion, wà lára ewébẹ̀ kíkorò tí wọ́n máa ń jẹ. Èyí máa rán wọn létí bí wọ́n ṣe fi wọ́n ṣe ẹrú lọ́nà kíkorò nílẹ̀ Íjíbítì. Jésù lo àkàrà aláìwú láti ṣàpẹẹrẹ ara rẹ̀ tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan. (Mt 26:26) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sì pe Jésù ní “Kristi ìrékọjá wa.” (1Kọ 5:7) Nígbà tó fi máa di ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, wáìnì ti (4) wà lára ohun tí wọ́n máa ń lò nígbà oúnjẹ Ìrékọjá. Jésù lo wáìnì láti ṣàpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, èyí tí wọ́n máa ta sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ.—Mt 26:27, 28.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 26:26
túmọ̀ sí: Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà e·stinʹ (tó túmọ̀ sí “ni”) tí wọ́n lò níbí sábà máa ń ní ìtumọ̀ bíi “tọ́ka sí; ṣàpẹẹrẹ; dúró fún; túmọ̀ sí.” Ìtumọ̀ yìí ṣe kedere sí àwọn àpọ́sítélì, torí pé ní àkókò yẹn Jésù fúnra rẹ̀ tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan wà níwájú wọn, bí búrẹ́dì tí kò ní ìwúkàrà tí wọ́n fẹ́ jẹ náà ṣe wà níwájú wọn. Torí náà, búrẹ́dì yẹn kò lè jẹ́ ara Jésù gangan. Ó gba àfiyèsí pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí kan náà ni wọ́n lò ní Mt 12:7, ọ̀pọ̀ àwọn tó túmọ̀ Bíbélì sì túmọ̀ rẹ̀ sí “ìtumọ̀.”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 26:28
ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú: Ẹbọ tí Jésù fi ara rẹ̀ rú ló fìdí májẹ̀mú tuntun tó wà láàárín Jèhófà àtàwọn ẹni àmì òróró múlẹ̀. (Heb 8:10) Níbí yìí, Jésù lo ọ̀rọ̀ kan náà tí Mósè lò nígbà tó ṣe alárinà májẹ̀mú Òfin tí wọ́n sì fìdí májẹ̀mú náà múlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lórí Òkè Sínáì. (Ẹk 24:8; Heb 9:19-21) Bí ẹ̀jẹ̀ màlúù àti ewúrẹ́ ṣe fìdí májẹ̀mú òfin múlẹ̀ láàárín Ọlọ́run àti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀jẹ̀ Jésù ṣe fìdí májẹ̀mú tuntun tí Jèhófà máa bá Ísírẹ́lì tẹ̀mí dá múlẹ̀. Ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni májẹ̀mú náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.—Heb 9:14, 15.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 26:17
Ní ọjọ́ kìíní àkàrà aláìwú: Nísàn 15 ni wọ́n máa ń bẹ̀rẹ̀ Àjọyọ̀ Àkàrà Aláìwú, ìyẹn ọjọ́ kejì Ìrékọjá (Nísàn 14), wọ́n sì máa ń ṣe é fún ọjọ́ méje. (Wo ìwé Àfikún Ìsọfúnni Apá 19.) Àmọ́ ní àkókò Jésù, Ìrékọjá àti àjọyọ̀ yìí ti wọnú ara wọn débí pé ọjọ́ mẹ́jọ ni wọ́n fi ń ṣe é, bẹ̀rẹ̀ láti Nísàn 14, ìdí nìyẹn tí wọ́n tún fi ń pè é ní “Àjọyọ̀ Àkàrà Aláìwú.” (Lk 22:1) Àyíká ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé, gbólóhùn náà “Ní ọjọ́ kìíní àkàrà aláìwú” tún lè túmọ̀ sí “Ní ọjọ́ tó ṣáájú.” (Fi wé Jo 1:15, 30, ẹsẹ Bíbélì yìí túmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà “àkọ́kọ́” [proʹtos] sí “ṣáájú” nínú ọ̀rọ̀ kan tó fara jọ ọ́, ẹsẹ yẹn kà pé, “nítorí pé ó wà ṣáájú [proʹtos] mi.”) Torí náà, àṣà àwọn Gíríìkì àtàwọn Júù ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bi í ní ìbéèrè yìí ní Nísàn 13. Ní ọ̀sán Nísàn 13, àwọn ọmọ ẹ̀yìn múra sílẹ̀ fún Ìrékọjá, èyí tí wọ́n ṣe ayẹyẹ rẹ̀ “lẹ́yìn tí alẹ́ ti lẹ́” ní ìbẹ̀rẹ̀ Nísàn 14.—Mk 14:16, 17.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 26:39
jẹ́ kí ife yìí ré mi kọjá: Nínú Bíbélì, “ife” sábà máa ń ṣàpẹẹrẹ ìfẹ́ Ọlọ́run tàbí “ohun tí wọ́n yàn” fún ẹnì kan. (Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 20:22.) Wọ́n fẹ̀sùn kan Jésù pé ó jẹ́ asọ̀rọ̀ òdì àti ẹni tó ń dìtẹ̀ sí ìjọba, wọ́n sì dájọ́ ikú fún un, kò sí àní-àní pé ẹ̀gàn tí ikú rẹ̀ yìí máa mú bá orúkọ Ọlọ́run ló kó ẹ̀dùn ọkàn bá a, èyí ló mú kó gbàdúrà pé kí “ife” yìí ré òun kọjá.
Bíbélì Kíkà
APRIL 9-15
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 27-28
“Ẹ Lọ Sọ Àwọn Ènìyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn—Kí Nìdí, Níbo àti Báwo?”
‘Ẹ Lọ, Kí ẹ Sì Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn’
4 Jésù ní ọlá àṣẹ lórí ìjọ rẹ̀, àtọdún 1914 ló sì ti ní ọlá àṣẹ lórí Ìjọba tuntun tí Ọlọ́run fìdí rẹ̀ múlẹ̀. (Kólósè 1:13; Ìṣípayá 11:15) Òun ni olú-áńgẹ́lì, ipò tó wà yìí sì jẹ́ kó ní àṣẹ lórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run tó jẹ́ ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì. (1 Tẹsalóníkà 4:16; 1 Pétérù 3:22; Ìṣípayá 19:14-16) Bàbá rẹ̀ ti fún un láṣẹ láti sọ “gbogbo ìjọba àti gbogbo ọlá àṣẹ àti agbára” tó bá lòdì sí ìlànà òdodo di asán. (1 Kọ́ríńtì 15:24-26; Éfésù 1:20-23) Ọlá àṣẹ tí Jésù ní kò mọ sórí àwọn tó wà láàyè nìkan o. Òun tún ni “onídàájọ́ alààyè àti òkú” ó sì ní agbára tí Ọlọ́run fún un láti jí àwọn tó ti sùn nínú ikú dìde. (Ìṣe 10:42; Jòhánù 5:26-28) Ó dájú pé àṣẹ tí Ẹni tá a fún ní ọlá àṣẹ gíga bẹ́ẹ̀ bá pa ni a ní láti kà sí ohun tó ṣe pàtàkì gan-an. Nítorí náà, tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ àti tinútinú la fi ń ṣègbọràn sí àṣẹ tí Kristi pa pé ká ‘lọ sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.’
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 28:19
sọ àwọn ènìyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn: A lè túmọ̀ ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì náà ma·the·teuʹo sí “kọ́ni” láti lè sọ àwọn èèyàn di ọmọlẹ́yìn. (Fi wé bí wọ́n ṣe lò ó ní Mt 13:52, wọ́n túmọ̀ rẹ̀ sí “kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́” nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn.) Ọ̀rọ̀ ìṣe náà “batisí wọn” àti “kọ́ wọn” jẹ́ ká mọ ohun tí àṣẹ náà láti “sọ àwọn ènìyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn” ní nínú.
àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè: Tá a bá túmọ̀ rẹ̀ ní olówuuru, ohun tó máa túmọ̀ sí ni “gbogbo orílẹ̀-èdè,” àmọ́ àyíká ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé gbólóhùn náà ń tọ́ka sí èèyàn kọ̀ọ̀kàn nínú gbogbo orílẹ̀-èdè. Ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ “wọn” tí wọ́n lò níbi tó ti sọ pé batisí wọn ń tọ́ka sí àwọn èèyàn, kì í ṣe “orílẹ̀-èdè” lápapọ̀. Àṣẹ tuntun ni àṣẹ tí Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n wàásù fún “àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè.” Kí Jésù tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, Ìwé Mímọ́ fi hàn pé àwọn Kèfèrí tó wá sin Jèhófà nìkan làwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè gbà sí orílẹ̀-èdè wọn. (1Ọb 8:41-43) Àmọ́, Jésù lo àṣẹ yìí láti sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kì í ṣe àwọn Júù nìkan ni wọ́n máa wàásù fún, kàkà bẹ́ẹ̀, ó tẹnu mọ́ ọ pé iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn gbọ́dọ̀ kárí ayé.—Mt 10:1, 5-7; Iṣi 7:9; wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 24:14.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 28:20
ẹ máa kọ́ wọn: Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n túmọ̀ sí “kọ́ni” gba pé kéèyàn fúnni ní ìtọ́ni, kó ṣàlàyé ọ̀rọ̀, kó fìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀, kó sì fi ẹ̀rí tì í lẹ́yìn. (Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 3:1; 4:23.) Àṣe tí Jésù pa fún wa pé ká máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí òun pa láṣẹ mọ́ jẹ́ ohun tí a ó máa ṣe láìdáwọ́ dúró. Èyí gba pé ká kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ Jésù, bí wọ́n ṣe máa fi ẹ̀kọ́ náà sílò àti bí wọ́n ṣe máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.—Jo 13:17; Ef 4:21; 1Pe 2:21.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 27:51
ìkélé: Aṣọ ọ̀ṣọ́ tó rẹwà yìí ni wọ́n fi pín Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú tẹ́ńpìlì. Àṣà àwọn Júù àtijọ́ fi hàn pé aṣọ ìkélé yìí tóbi ó sì wúwo gan-an. Gígùn rẹ̀ jẹ́ ọgọ́ta ẹsẹ̀ bàtà [60 ft], fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n ẹsẹ̀ bàtà (30 ft), ó sì nípọn tó íǹṣì méjì àti ẹ̀sún mẹ́sàn-án (2.9 in.). Bí Jèhófà ṣe fa aṣọ ìkélé yìí ya sí méjì fi hàn pé ó bínú gidigidi sí àwọn tó pa ọmọ rẹ̀, ó sì tún fi hàn pé ọ̀nà ti ṣí sílẹ̀ fún àwọn tó máa lọ sí ọ̀run.—Heb 10:19, 20.
ibùjọsìn: Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà na·osʹ tí wọ́n lò níbí ń tọ́ka sí ilé ńlá kan tó ní ibì kan tí wọ́n pè ní Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 28:7
sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé a ti gbé e dìde: Àwọn obìnrin yìí ni wọ́n kọ́kọ́ sọ fún pé Jésù ti jí dìde, àmọ́ kì í ṣèyẹn nìkan, àwọn tún ni wọ́n rán pé kí wọ́n lọ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù. (Mt 28:2, 5, 7) Àṣà àwọn Júù tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu kò fàyè gba àwọn obìnrin láti wá ṣe ẹlẹ́rìí ní ilé ẹjọ́. Àmọ́ àwọn ańgẹ́lì Jèhófà buyì kún àwọn obìnrin yìí nígbà tí wọ́n fún wọn ní iṣẹ́ tó ń fúnni láyọ̀ yìí.
Bíbélì Kíkà
APRIL 16-22
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁÀKÙ 1-2
“A Dárí Àwọn Ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ Jì”
jy 67 ¶3-5
“A Dárí Àwọn Ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ Jì”
Nígbà tí Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nínú yàrá kan táwọn èrò kún fọ́fọ́, àwọn ọkùnrin mẹ́rin kan gbé ọkùnrin kan tó yarọ wá. Wọ́n fẹ́ kí Jésù wo ọ̀rẹ́ wọn yìí sàn. Àmọ́, torí àwọn èrò tó wà níbẹ̀, wọn ò lè “gbé e tààràtà wá bá Jésù.” (Máàkù 2:4) Wo bó ṣe máa ká wọn lára tó. Ni wọ́n bá gun òkè ilé náà lọ, wọ́n sì dá ihò sí i. Wọ́n wá sọ àkéte tí ọkùnrin tó yarọ náà wà kalẹ̀ sínú ilé náà.
Ṣé Jésù bínú sí wọn fún ohun tí wọ́n ṣe yìí? Rárá o! Ìgbàgbọ́ wọn wú Jésù lórí gan-an, ó sì sọ fún ọkùnrin arọ náà pé: “A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì.” (Mátíù 9:2) Àmọ́ ṣe Jésù lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini lóòótọ́? Àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí bínú gan-an, wọ́n sì ń ronú pé: “Èé ṣe tí ọkùnrin yìí fi ń sọ̀rọ̀ lọ́nà yìí? Ó ń sọ̀rọ̀ òdì. Ta ni ó lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini bí kò ṣe ẹnì kan, Ọlọ́run?”—Máàkù 2:7.
Torí pé Jésù mọ ohun tí wọ́n ń rò lọ́kàn, ó wá bi wọ́n pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń gbèrò nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn-àyà yín? Èwo ni ó rọrùn jù, láti sọ fún alárùn ẹ̀gbà náà pé, ‘A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì,’ tàbí láti sọ pé, ‘Dìde, sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn’?” (Máàkù 2:8, 9) Torí pé Jésù máa tó fi ara rẹ̀ rúbọ láìpẹ́, ó ṣeé ṣe fún un láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin náà jì í.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 2:9
Èwo ni ó rọrùn jù: Ó rọrùn fún ẹnì kan láti sọ pé òun lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kò sí àmì kankan tó lè fi hàn bóyá lóòótọ́ ló lè ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ bí Jésù ṣe sọ fún ọkùnrin yẹn pé, Dìde . . . kí o sì máa rìn, mú kó ṣe kedere sí gbogbo èèyàn pé Jésù lágbára láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini lóòótọ́. Ìtàn yìí àti ohun tó wà nínú ìwé Ais 33:24 fi hàn pé ẹ̀ṣẹ̀ ló ń jẹ́ ká máa ṣàìsàn.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 1:11
ohùn kan sì wá láti inú àwọsánmà: Èyí ni àkọ́kọ́ lára ìgbà mẹ́ta tí àwọn ìwé Ìhìn Rere ròyìn pé Jèhófà bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ní tààràtà.—Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 9:7; Jo 12:28.
Ìwọ ni Ọmọ mi: Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù torí pé ẹ̀dá ẹ̀mí ni. (Jo 3:16) “Ọmọ Ọlọ́run” ni látìgbà tí wọ́n ti bí i gẹ́gẹ́ bí èèyàn sórí ilẹ̀ ayé, bí Ádámù ẹni pípé ṣe jẹ́. (Lk 1:35; 3:38) Àmọ́, ó bọ́gbọ́n mu ká gbà pé ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ níbí yìí kọjá pé ó kàn fẹ́ fi hàn pé ọmọ òun ni Jésù. Nípasẹ̀ ìkéde yìí àti bó ṣe tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ jáde sorí Jésù, Ọlọ́run fi hàn gbangba pé ọkùnrin náà, Jésù jẹ́ Ọmọ tí òun fi ẹ̀mí yàn. Ó tipa bẹ́ẹ̀ di ‘ẹni tí a tún bí’ tó sì ní ìrètí láti pa dà sí ọ̀run, Ọlọ́run sì fi ẹ̀mí yàn án láti di Ọba àti Àlùfáà Àgbà Rẹ̀.—Fi wé Jo 3:3-6; 6:51; Lk 1:31-33; Heb 2:17; 5:1, 4-10; 7:1-3.
mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́: Tàbí “Inú mi dùn sí ẹ; ọmọ àmúyangàn ló jẹ́ fún mi.” Ọ̀rọ̀ yìí kan náà ni wọ́n lò nínú Mt 12:18, èyí tí wọ́n fa yọ̀ látinú Ais 42:1 nípa Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí tàbí Kristi. Bí Ọlọ́run ṣe tú ẹ̀mí rẹ̀ sórí Jésù àti ìkéde tó ṣe nípa Ọmọ rẹ̀ yìí jẹ́ àmì tó fi hàn gbangba pé Jésù ni Mèsáyà tó ṣèlérí.—Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 3:17; 12:18.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 2:28
Olúwa . . . sábáàtì: Jésù lo ọ̀rọ̀ yìí fún ara rẹ̀ (Mt 12:8; Lk 6:5), kó lè fi hàn pé òun lágbára lórí sábáàtì láti ṣe iṣẹ́ tí Baba rẹ̀ ọ̀run rán an. (Fi wé Jo 5:19; 10:37, 38.) Ọjọ́ Sábáàtì ni Jésù ṣe ọ̀pọ̀ lára iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, tó fi mọ́ wíwo àwọn aláìsàn sàn. (Lk 13:10-13; Jo 5:5-9; 9:1-14) Èyí ṣàpẹẹrẹ irú ìtura tó máa mú wá bá àwa èèyàn nígbà Ìṣàkóso rẹ̀, tó máa dà bí ìsinmi ọjọ́ sábáàtì.—Heb 10:1.
Bíbélì Kíkà
APRIL 23-29
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁÀKÙ 3-4
“Jésù Ṣe Ìwòsàn ní Ọjọ́ Sábáàtì”
jy 78 ¶1-2
Kí Ló Bá Òfin Mu Lọ́jọ́ Sábáàtì?
Lọ́jọ́ Sábáàtì míì, Jésù lọ sí sínágọ́gù kan, tó ṣeé ṣe kó wà nílùú Gálílì. Ibẹ̀ ló ti rí ọkùnrin kan ti ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ rọ. (Lúùkù 6:6) Àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí ń ṣọ́ Jésù lójú méjèèjì. Kí nìdí? Wọ́n fi ohun tó wà lọ́kàn wọn hàn nígbà tí wọ́n béèrè pé: “Ó ha bófin mu láti ṣe ìwòsàn ní sábáàtì bí?”—Mátíù 12:10.
Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù gbà pé ìgbà tí ẹ̀mí ẹnì kan bá wà nínú ewu nìkan ni wọ́n tó lè ṣe ìwòsàn fún un lọ́jọ́ Sábáàtì. Torí náà, bí àpẹẹrẹ, kò bófin mu rárá kéèyàn tó egungun tó kán tàbí kí wọ́n tọ́jú ẹni tó fi ibì kan rọ́, torí pé èyí kò la ẹ̀mí lọ. Ó ṣe kedere pé kì í ṣe àánú ọkùnrin tó ń jìyà yìí ló ń ṣe àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí tí wọ́n fi ń béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ Jésù. Ńṣe ni wọ́n kàn ń wá ẹ̀sùn sí Jésù lẹ́sẹ̀, kí wọ́n lè pa á.
jy 78 ¶3
Kí Ló Bá Òfin Mu Lọ́jọ́ Sábáàtì?
Àmọ́, Jésù náà mọ èrò òdì tó wà lọ́kàn wọn. Ó mọ̀ pé wọ́n ti ki àṣejù bọ ohun tó túmọ̀ sí láti má ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ sábáàtì, èrò wọn yìí kò sì bá Ìwé Mímọ́ mu. (Ẹ́kísódù 20:8-10) Kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ nìyí táwọn èèyàn máa fẹ̀sùn kàn án torí pé ó ń ṣe iṣẹ́ rere. Torí náà, Jésù wá kúkú ṣe ohun tó máa mú kí wọ́n sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn jáde nígbà tó sọ fún ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ náà pé: “Dìde, kí o sì wá sí àárín.”—Máàkù 3:3.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 3:5
pẹ̀lú ìkannú, nítorí tí ó ní ẹ̀dùn-ọkàn gidigidi: Máàkù nìkan ló ṣe àkọsílẹ̀ bí ó ṣe ká Jésù lára tó nígbà tó rí bí ìrònú ọkàn àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà yẹn kò ṣe mọ́gbọ́n dání. (Mt 12:13; Lk 6:10) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Pétérù ló ṣe àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ yìí nípa bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára Jésù, torí pé òun náà máa ń mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára.—Wo “Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Máàkù.”
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 3:29
ọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́: Ọ̀rọ̀ òdì jẹ́ ọ̀rọ̀ ìbanijẹ́, ọ̀rọ̀ tó ń ṣèpalára tàbí ọ̀rọ̀ àbùkù sí Ọlọ́run tàbí sí ohun mímọ́. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni ẹ̀mí mímọ́ ti wá, téèyàn bá mọ̀ọ́mọ̀ ta kò ó tàbí tí kò gbà kó darí òun, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ lẹni náà ń sọ̀rọ̀ òdì sí. Bí Mt 12:24, 28 àti Mk 3:22 ṣe fi hàn, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn rí i pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló jẹ́ kí Jésù ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe; síbẹ̀, wọ́n sọ pé Sátánì Èṣù ló fún un lágbára.
ó jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ àìnípẹ̀kun: Ó jọ pé èyí ń tọ́ka sí ẹ̀ṣẹ̀ tí àbájáde ẹ̀ máa wà títí láé; kò sí ìrúbọ tó lè bo irú ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀.—Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́ nínú ẹsẹ yìí àti àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 12:31, tó jẹ́ ibòmíì tí Jésù ti sọ ọ̀rọ̀ yìí.
Ǹjẹ́ O “Mòye Ìtúmọ̀ Ìwé Mímọ́”?
6 Kí ni a lè rí kọ́ nínú àpèjúwe yìí? Ohun àkọ́kọ́ ni pé, a gbọ́dọ̀ gbà pé àwa kọ́ la máa mú kí ẹni tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Tí a bá mọ èyí, a ò ní máa fipá mú ẹni tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pé kó ṣèrìbọmi. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la máa ṣe gbogbo ohun tí a bá lè ṣe láti ran ẹni náà lọ́wọ́, àá sì gbà pé ọwọ́ rẹ̀ ló kù sí láti pinnu bóyá ó máa ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ìfẹ́ tí ẹnì kan ní fún Ọlọ́run ló yẹ kó mú kó wù ú láti ya ara rẹ̀ sí mímọ́. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, inú Jèhófà kò ní dùn sí irú ìyàsímímọ́ bẹ́ẹ̀.—Sm. 51:12; 54:6; 110:3.
7 Ìkejì, tí a bá lóye ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wà nínú àpèjúwe yìí, a ò ní rẹ̀wẹ̀sì tí a kò bá tí ì rí i kí ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ṣe ìyípadà. Ó gba pé ká ṣe sùúrù. (Ják. 5:7, 8) Tí a bá ti ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́, síbẹ̀ tí kò yí pa dà, ká gbà pé kì í ṣe torí pé a jẹ́ aláìṣòótọ́ ni kò ṣe so èso. Àwọn tó bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tí wọ́n sì ṣe tán láti ṣe ìyípadà ni Jèhófà máa ń jẹ́ kí irúgbìn òtítọ́ dàgbà nínú wọn. (Mát. 13:23) Torí náà, a ò gbọ́dọ̀ fi bí iye àwọn èèyàn tó ń ṣèrìbọmi ṣe pọ̀ tó díwọ̀n àṣeyọrí wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ó kúkú ṣe tán, ìyẹn kọ́ ni Jèhófà fi ń díwọ̀n àṣeyọrí tá a ṣe lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà mọrírì gbogbo ohun tí à ń ṣe tọkàntọkàn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láìka irú ọwọ́ táwọn èèyàn fi mú òtítọ́ sí.—Ka Lúùkù 10:17-20; 1 Kọ́ríńtì 3:8.
8 Ìkẹta, a kì í sábà rí àwọn ìyípadà tẹ́nì kan ń ṣe nínú ọkàn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan tó jẹ́ míṣọ́nnárì ń kọ́ tọkọtaya kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, lọ́jọ́ kan tọkọtaya náà sọ fún míṣọ́nnárì yìí pé àwọn fẹ́ di akéde tí kò tíì ṣe ìrìbọmi. Arákùnrin yìí sọ fún tọkọtaya náà pé kí wọ́n tó lè tóótun láti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, wọ́n gbọ́dọ̀ fi sìgá mímu sílẹ̀. Ó ya arákùnrin yìí lẹ́nu nígbà tí tọkọtaya náà sọ pé àwọn ti jáwọ́ nínú àṣà yìí láti nǹkan bí oṣù mélòó kan sẹ́yìn. Kí nìdí tí wọ́n fi jáwọ́? Wọ́n ti wá mọ̀ pé táwọn bá tiẹ̀ ń mu sìgá níbi téèyàn ò ti ní rí àwọn, Jèhófà ń rí àwọn, wọ́n sì mọ̀ pé Jèhófà kórìíra ìwà àgàbàgebè. Torí náà, àwọn méjèèjì pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe, yálà láti máa mu sìgá níṣojú míṣọ́nnárì tó ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ tàbí kí wọ́n jáwọ́ pátápátá. Àmọ́, torí pé tọkọtaya yìí ti wá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n ṣe ìpinnu tí ó tọ́. Òtítọ́ ti ń jinlẹ̀ nínú àwọn tọkọtaya náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé míṣọ́nnárì yìí ò rí ìyípadà ti wọ́n ti ṣe lọ́kàn wọn.
Bíbélì Kíkà
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Kí Ẹni Tí Ó Ní Etí Láti Fetí Sílẹ̀, Fetí Sílẹ̀”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 4:9
Kí ẹni tí ó ní etí láti fetí sílẹ̀, fetí sílẹ̀: Kí Jésù tó sọ àpèjúwe nípa afúnrúgbìn, ó ní: “Ẹ fetí sílẹ̀.” (Mk 4:3) Ọ̀rọ̀ yìí kan náà ló tún fi parí àpèjúwe yẹn láti fi tẹnu mọ́ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ fara balẹ̀ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó fún wọn. A tún lè rí irú ọ̀rọ̀ ìyànjú yìí nínú Mt 11:15; 13:9, 43; Mk 4:23; Lk 8:8; 14:35; Iṣi 2:7, 11, 17, 29; 3:6, 13, 22; 13:9.
APRIL 30–MAY 6
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁÀKÙ 5-6
“Jésù Ní Agbára Láti Jí Àwọn Èèyàn Wa Tó Kú Dìde”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 5:39
kò tíì kú, ṣùgbọ́n ó ń sùn ni: Nínú Bíbélì, wọ́n sábà máa ń sọ pé ńṣe ni ẹni tó kú ń sùn. (Sm 13:3; Jo 11:11-14; Iṣe 7:60; 1Kọ 7:39; 15:51; 1Tẹ 4:13) Jésù máa jí ọmọbìnrin náà dìde, ó ṣeé ṣe kó sọ̀rọ̀ yìí láti fi han àwọn èèyàn náà pé bá a ṣe lè jí ẹni tó sùn wọra, bẹ́ẹ̀ náà làwọn tó ti kú ṣe lè pa dà jíǹde. Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run “tí ń sọ òkú di ààyè, tí ó sì ń pe àwọn ohun tí kò sí bí ẹni pé wọ́n wà” ni Jésù ti rí agbára tó fi jí ọmọ náà dìde.—Ro 4:17.
jy 118 ¶6
Ọmọdébìnrin Kan Jíǹde!
Tí Jésù bá ti wo aláìsàn kan sàn, ó sábà máa ń sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe sọ fáwọn èèyàn ohun tí òun ṣe fún wọn, ohun tó sì tún sọ fáwọn òbí ọmọbìnrin yìí náà nìyẹn. Àmọ́, inú ẹni kì í dùn ká fi pa mọ́, àwọn òbí ọmọ náà àtàwọn míì tan ọ̀rọ̀ náà kálẹ̀ “dé gbogbo ẹkùn ilẹ̀ yẹn.” (Mátíù 9:26) Ṣé ìwọ náà ò ní fayọ̀ ròyìn ẹ̀ kiri tó bá jẹ́ pé ọ̀rẹ́ rẹ ló jí dìde? Èyí ni àjíǹde kejì tí Jésù ṣe tí wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 5:19
ròyìn fún wọn: Jésù máa ń sọ fáwọn èèyàn tẹ́lẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe polongo iṣẹ́ ìyanu tí òun ṣe (Mk 1:44; 3:12; 7:36), àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí ó sọ fún ọkùnrin náà pé kó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fáwọn ìbátan rẹ̀. Èyí lè jẹ́ torí pé wọ́n ti ní kí Jésù kúrò ní àgbègbè yẹn, kò sì ní lè ráyè jẹ́rìí fún àwọn ará ìlú yẹn fúnra rẹ̀; ó sì tún máa bomi paná àhesọ ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn á máa sọ kiri nípa agbo ẹlẹ́dẹ̀ tó kó sínú òkun.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 6:11
ẹ gbọn ìdọ̀tí tí ó wà lábẹ́ ẹsẹ̀ yín dànù: Èyí fi hàn pé àwọn ọmọlẹ́yìn náà ti yọ ara wọn nínú ìdájọ́ tí Ọlọ́run máa ṣe fáwọn èèyàn náà. Irú ọ̀rọ̀ yìí náà wà ní Mt 10:14; Lk 9:5. Máàkù àti Lúùkù fi gbólóhùn náà fún ẹ̀rí lòdì sí wọn kún ọ̀rọ̀ yìí. Pọ́ọ̀lù àti Bánábà fi ìtọ́ni yìí sílò nígbà tí wọ́n wà ní ìlú Písídíà ti Áńtíókù (Iṣe 13:51), nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì ṣe ohun tó jọ èyí nílùú Kọ́ríńtì nígbà tó gbọn ẹ̀wù rẹ̀, ó fi ọ̀rọ̀ kan kún un láti ṣàlàyé ohun tó ṣe, pé: “Kí ẹ̀jẹ̀ yín wà ní orí ẹ̀yin fúnra yín. Ọrùn mi mọ́.” (Iṣe 18:6) Àṣà yìí lè má ṣàjèjì sí àwọn ọmọlẹ́yìn; àwọn Júù tó jẹ́ onítara ẹ̀sìn tó máa ń rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè àwọn Kèfèrí máa ń gbọn ekuru tí wọ́n kà sí aláìmọ́ kúrò nínú bàtà wọn kí wọ́n tó wọ ìpínlẹ̀ àwọn Júù. Àmọ́, ọ̀tọ̀ ni ohun tí Jésù ní lọ́kàn nígbà tó fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni yìí.
Bíbélì Kíkà