ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb18 June ojú ìwé 8
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣàṣeyọrí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣàṣeyọrí
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀yin Òbí—ẹ Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Tìfẹ́tìfẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Jẹ́ Aláyọ̀?—Apá Kejì
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Gbígbé Ìdílé Tó Dúró Sán-ún Nípa Tẹ̀mí Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
mwb18 June ojú ìwé 8
Jósẹ́fù àti Màríà ń kọ́ Jésù àtàwọn ọmọ wọn tó kù lásìkò tí wọ́n ń jẹun pa pọ̀

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣàṣeyọrí

Ó máa ń wu àwọn òbí tó níbẹ̀rù Ọlọ́run láti rí bí àwọn ọmọ wọn ṣe ń fi tọkàntọkàn sin Jèhófà. Àwọn òbí lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti sin Jèhófà tí wọ́n bá gbin ẹ̀kọ́ Bíbélì sínú ọkàn wọn láti kékeré. (Di 6:7; Owe 22:6) Ǹjẹ́ ó gba pé kí àwọn òbí yááfì àwọn nǹkan kan? Bẹ́ẹ̀ ni! Àmọ́ èrè tí wọ́n máa rí tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.​—3Jo 4. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ làwọn òbí lè kọ́ lára Jósẹ́fù àti Màríà. Ó ‘jẹ́ àṣà wọn láti máa lọ sí Jerúsálẹ́mù láti ọdún dé ọdún fún àjọyọ̀ ìrékọjá,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gba ọ̀pọ̀ ìsapá àti ìnáwó. (Lk 2:41) Ó ṣe kedere pé ipò kìíní ni Jósẹ́fù àti Màríà fi àjọṣe ìdílé wọn pẹ̀lú Jèhófà sí. Bákan náà, ó yẹ kí àwọn òbí lóde òní máa lo gbogbo àǹfààní tí wọ́n bá ní láti darí àwọn ọmọ wọn sí ojú ọ̀nà tó yẹ nípa ọ̀rọ̀ ẹnu àti àpẹẹrẹ wọn.​—Sm 127:​3-5.

ǸJẸ́ O MỌ̀?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ìdílé tí wọ́n ti ń sin Jèhófà ni wọ́n ti tọ́ Jésù àti àwọn iyèkan rẹ̀ dàgbà, síbẹ̀ wọn kò gbà á gbọ́, àfìgbà tó kú. (Jo 7:5; Iṣe 1:14) Nígbà tó yá, méjì lára wọn, ìyẹn Jákọ́bù àti Júúdà, kọ àwọn ìwé Bíbélì tó ń jẹ́ orúkọ wọn.

WO FÍDÍÒ NÁÀ WỌ́N GBÁ ÀǸFÀÀNÍ TÓ ṢÍ SÍLẸ̀ MÚ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Báwo ni Jon àti Sharon Schiller ṣe fi Ìjọba Ọlọ́run sí ipò kìíní bí wọ́n ṣe ń tọ́ àwọn ọmọ wọn?

  • Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn òbí bá àwọn ọmọ wọn wí ní ìbámu pẹ̀lú ipò àti ohun tí ọmọ kọ̀ọ̀kan nílò?

  • Báwo làwọn òbí ṣe lè múra ọkàn àwọn ọmọ wọn sílẹ̀ láti kojú ìdánwò ìgbàgbọ́?

  • Èwo lára àwọn ohun tí ètò Jèhófà ṣe lẹ ti lò láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà?

Ìdílé Schiller

Máa fi ìjọsìn Jèhófà sípò kìíní nínú ìdílé rẹ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́