Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
JUNE 4-10
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁÀKÙ 15-16
“Àsọtẹ́lẹ̀ Ṣẹ sí Jésù Lára”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 15:24, 29
pín ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀: Ìtàn tó wà nínú Jo 19:23, 24 ṣe àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé kan tí kò sí nínú ìwé Mátíù, Máàkù àti Lúùkù: Ó ṣe kedere pé àwọn ọmọ ogun Róòmù ṣẹ́ kèké lórí ẹ̀wù àwọ̀lékè àti àwọ̀tẹ́lẹ̀ Jésù; àwọn ọmọ ogun náà pín ẹ̀wù àwọ̀lékè Jésù sí “apá mẹ́rin, apá kan fún ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan”; wọ̀n ò fẹ́ pín ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀, torí náà wọ́n ṣẹ́ kèké lórí rẹ̀; èyí sì mú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Sm 22:18 ṣẹ pé wọ́n máa ṣẹ́ kèké lé aṣọ Mèsáyà. Ó ṣe kedere pé àṣà àwọn tó ń pa àwọn ọ̀daràn ni pé kí wọ́n gba aṣọ àwọn ọ̀daràn tí wọ́n fẹ́ pa, torí náà wọ́n á gba aṣọ àti àwọn ohun ìní wọn kí wọ́n tó pa wọ́n, èyí á mú kí wọ́n túbọ̀ kó ìtìjú bá àwọn ọ̀daràn náà.
wọ́n á mi orí wọn síwá sẹ́yìn: Wọ́n sábà máa ń sọ̀rọ̀ tí wọ́n bá mi orí wọn síwá sẹ́yìn láti fi hàn pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ sí ohun kan, láti fi pẹ̀gàn tàbí láti fini ṣẹ̀sín. Àwọn tó ń kọjá lọ tipa bẹ́ẹ̀ mú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Sm 22:7 ṣẹ.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 15:43
Jósẹ́fù: Irú ẹni tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere jẹ́ hàn nínú àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé tí wọ́n ṣe nípa Jósẹ́fù. Mátíù tó jẹ́ agbowó orí sọ pé ó jẹ́ “ọkùnrin ọlọ́rọ̀”; Máàkù tó dìídì kọ ìwé rẹ̀ nítorí àwọn ará Róòmù sọ pé ó jẹ́ “mẹ́ńbà kan tí ó ní ìsì rere nínú Àjọ Ìgbìmọ̀” tó sì ń retí Ìjọba Ọlọ́run; Lúùkù, tó jẹ́ oníṣègùn tó sì lójú àánú sọ pé ó jẹ́ “ọkùnrin rere àti olódodo” tí kò fara mọ́ ohun tí Ìgbìmọ̀ fẹ́ ṣe fún Jésù; Jòhánù nìkan ló sọ pé ó jẹ́ “ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ṣùgbọ́n ọ̀kan tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀ nítorí ìbẹ̀rù rẹ̀ fún àwọn Júù.”—Mt 27:57-60; Mk 15:43-46; Lk 23:50-53; Jo 19:38-42.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 15:25
wákàtí kẹta: Ìyẹn jẹ́, nǹkan bí aago mẹ́sàn-án àárọ̀ [9:00 a.m]. Àwọn kan máa ń sọ pé ohun tí ẹsẹ yìí sọ kó dọ́gba pẹ̀lú ohun tí Jo 19:14-16 sọ, pé “ó jẹ́ nǹkan bí wákàtí kẹfà” nígbà tí Pílátù fa Jésù lé àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti lọ pa á. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò sọ ohun tó fa ìyàtọ̀ yìí lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, díẹ̀ rèé lára ohun tó yẹ ká ronú lé lórí: Àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ láwọn àkókò tí Jésù lò kẹ́yìn láyé, àwọn àkókò tí wọ́n sọ sì bára mu. Àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sọ pé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbà ọkùnrin ṣe ìpàdé ní òwúrọ̀, wọ́n sì ní kí wọ́n mú Jésù lọ sọ́dọ̀ Pọ́ńtíù Pílátù tó jẹ́ Gómìnà Róòmù. (Mt 27:1, 2; Mk 15:1; Lk 22:66–23:1; Jo 18:28) Mátíù, Máàkù àti Lúùkù ròyìn pé, nígbà tí Jésù ti wà lórí òpó igi oró, òkùnkùn kan ṣú bo gbogbo ilẹ̀ náà láti “wákàtí kẹfà . . . títí di wákàtí kẹsàn-án.” (Mt 27:45, 46; Mk 15:33, 34; Lk 23:44) Ohun kan tó ṣeé ṣe kó fa ìyàtọ̀ nínú àkókò tí àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ pé wọ́n pa Jésù ni: Nínà tí wọ́n na Jésù, àwọn kan sì ka èyí sí ara àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó bá ikú rẹ̀ rìn. Nígbà míì ọ̀daràn kan lè kú mọ́ wọn lọ́wọ́ níbi tí wọ́n ti ń nà án ní ìnàkunà. Ní ti Jésù, nínà yẹn burú gan-an débi pé ẹlòmíì ló bá a gbé opó igi oró rẹ̀ dé ibi tí wọ́n ti fẹ́ pa á, lẹ́yìn tí òun fúnra rẹ̀ ti rù ú fúngbà díẹ̀. (Lk 23:26; Jo 19:17) Tó bá jẹ́ pé ìgbà tí wọ́n na Jésù làwọn kan ti bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìṣẹ̀lẹ̀ tó bá ikú rẹ̀ rìn, á jẹ́ pé àkókò díẹ̀ ti máa kọjá kó tó wá di pé wọn kan Jésù mọ igi oró. Ìtàn tó wà ní Mt 27:26 àti Mk 15:15 ti ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn. Wọ́n mẹ́nu kan nínà tí wọ́n na Jésù àti bí wọ́n ṣe pa á lórí igi oró pa pọ̀. Torí náà, èrò tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó kọ Ìwé Ìhìn Rere ni ló máa pinnu àkókò tí wọ́n gbà pé wọ́n pa Jésù, èyí sì lè mú kí àkókò tí wọ́n sọ yàtọ̀ síra. Èyí jẹ́ ká rí ìdí tó fi ya Pílátù lẹ́nu nígbà tó gbọ́ pé kò pẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n kan Jésù mọ́gi ló kú. (Mk 15:44) Láfikún sí i, àwọn tó kọ Bíbélì sábà máa ń pín ọ̀sán kan sí mẹ́rin tí ọ̀kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ wákàtí mẹ́ta, bẹ́ẹ̀ náà sì ni wọ́n ṣe máa ń pín òru. Bí wọ́n ṣe ń pín ọjọ́ yìí jẹ́ ká rí ìdí tí Bíbélì fi máa ń sọ̀rọ̀ nípa wákàtí kẹta, kẹfà àti kẹsàn ọjọ́, èyí tí wọ́n máa ń kà látìgbà tí ọ̀yẹ̀ bá ti là ní nǹkan bí aago mẹ́fà ìdájí [6:00 a.m.] (Mt 20:1-5; Jo 4:6; Iṣe 2:15; 3:1; 10:3, 9, 30) Bákan náà, kò tíì sí aago láyé ìgbà yẹn táwọn èèyàn á fi mọ iye aago tó lù gangan, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi sábà máa ń lo “nǹkan bí” láti sọ àkókò, bó ṣe wà ní Jo 19:14. (Mt 27:46; Lk 23:44; Jo 4:6; Iṣe 10:3, 9) Lákòótán: Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àkókò tí wọ́n na Jésù, tí wọ́n sì kàn án mọ́gi ni Máàkù sọ pa pọ̀, tí Jòhánù sì sọ àkókò tí wọ́n kàn án mọ́gi nìkan. Ó sì tún ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe làwọn méjèèjì kó àkókò tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé pa pọ̀ sáàárín wákàtí mẹ́ta tó sún mọ́ra, Jòhánù sì lo “nǹkan bí” nígbà tó ń sọ àkókò tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé. Àwọn ohun tá a sọ yìí ló ṣeé ṣe kó fa àkókò tó yàtọ̀ nínú àwọn ìtàn náà. Paríparí rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí Máàkù kọ ìtàn yìí ni Jòhánù ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ ìtàn tiẹ̀ tó dà bíi pé àkókò tó mẹ́nu bà yàtọ̀ sí ti Máàkù, síbẹ̀ ó hàn pé Jòhánù kò da ìtàn tí Máàkù sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kọ.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mk 16:8
nítorí wọ́n ń bẹ̀rù: Ẹsẹ kẹjọ ni ìwé Ìhìn Rere Máàkù parí sí, bó ṣe wà nínú ìwé àfọwọ́kọ tó pẹ́ jù lọ tó wà báyìí nìyẹn. Àwọn kan ronú pé ọ̀rọ̀ tí Máàkù sọ kò lè ṣàdédé parí lójijì bẹ́ẹ̀. Àmọ́, èrò táwọn kan ní yìí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀, torí pé Máàkù kì í lo ọ̀rọ̀ púpọ̀ tó bá ń kọ̀wé. Bákan náà, Jerome àti Eusebius tí wọ́n jẹ́ ọ̀mọ̀wé tó gbáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin sọ pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ gangan láti parí ẹsẹ yẹn ni “nítorí wọ́n ń bẹ̀rù.”
Àwọn ìwé àfọwọ́kọ míì wà lédè Gíríìkì àtàwọn èdè míì tó fi ìparí gígùn tàbí ìparí kúkúrú sí ibi tí ẹsẹ 8 parí sí. Ìparí gígùn (tó ní ẹsẹ méjìlá 12 tí wọ́n fi kún un) wà nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ bíi Codex Alexandrinus, Codex Ephraemi Syri rescriptus, àti Codex Bezae Cantabrigiensis, gbogbo wọn sì ni wọ́n ṣe ní ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-un Sànmánì Kristẹni. Ó tún wà nínú Bíbélì Látìn Vulgate, Curetonian Syriac, àti Syriac Peshitta. Àmọ́ ṣá o, kò sí nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ méjì lédè Gíríìkì tí wọ́n ṣe ní ọgọ́rùn-un ọdún kẹrin, ìyẹn Codex Sinaiticus àti Codex Vaticanus, tàbí nínú Codex Sinaiticus Syriacus ti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin àti ìkarùn-ún tàbí nínú ìwé àfọwọ́kọ Sahidic Coptic ti Máàkù tí wọ́n ṣe ní ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún. Lọ́nà kan náà, ẹsẹ 8 ni ìwé àfọwọ́kọ Máàkù tó pẹ́ jù ní èdè Armenian àti Georgian parí sí.
Àwọn ìwé àfọwọ́kọ kan lédè Gíríìkì tí wọ́n ṣe lẹ́yìn náà àtàwọn míì tí wọ́n túmọ̀ sí èdè míì ní ìparí kúkúrú nínú (gbólóhùn mélòó kan ló wà nínú rẹ̀). Ìwé Codex Regius tí wọ́n ṣe ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ Sànmánì Kristẹni ní ìparí méjèèjì, àmọ́ ìparí kúkúrú ni wọ́n fi ṣáájú. Ó fi ọ̀rọ̀ kan bẹ̀rẹ̀ ìparí kọ̀ọ̀kan tó ṣàlàyé pé ìparí kúkúrú àti ìparí gígùn tí àwọn fi kún un wà nínú àwọn ìwé míì, àmọ́ kò dájú pé ìkankan nínú wọn ṣe é gbára lé.
ÌPARÍ KÚKÚRÚ
Ìparí kúkúrú tó wà lẹ́yìn Mk 16:8 kò sí lára Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí. Ó kà báyìí:
Ṣùgbọ́n gbogbo ohun tí a ti pa láṣẹ ni wọ́n ṣèròyìn ní ṣókí fún àwọn tí wọ́n yí Pétérù ká. Síwájú sí i, lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jésù fúnra rẹ̀ rán ìpòkìkí mímọ́ àti aláìlè-díbàjẹ́ ti ìgbàlà àìnípẹ̀kun jáde nípasẹ̀ wọn láti ìlà-oòrùn sí ìwọ̀-oòrùn.
ÌPARÍ GÍGÙN
Ìparí gígùn tó wà lẹ́yìn Mk 16:8 kò sí lára Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí. Ó kà báyìí:
9 Lẹ́yìn tí ó dìde ní kùtùkùtù ní ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, ó kọ́kọ́ fara han Màríà Magidalénì, lára ẹni tí ó ti lé ẹ̀mí èṣù méje jáde. 10 Ó lọ, ó sì ròyìn fún àwọn tí wọ́n ti wà pẹ̀lú rẹ̀, bí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀, tí wọ́n sì ń sunkún. 11 Ṣùgbọ́n, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ó ti yè àti pé ó ti rí i, wọn kò gbà gbọ́. 12 Jù bẹ́ẹ̀ lọ, lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ó fara hàn ní ìrísí mìíràn fún méjì lára wọn tí wọ́n jọ ń rìn lọ, bí wọ́n ti ń lọ sí ìgbèríko; 13 wọ́n sì padà wá, wọ́n sì ròyìn fún àwọn yòókù. Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gba àwọn wọ̀nyí gbọ́. 14 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn náà, ó fara han àwọn mọ́kànlá náà fúnra wọn bí wọ́n ti rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì, ó sì gan àìnígbàgbọ́ àti líle-ọkàn wọn, nítorí pé wọn kò gba àwọn wọnnì gbọ́, tí wọ́n rí i nísinsìnyí tí a ti gbé e dìde kúrò nínú òkú. 15 Ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ lọ sínú gbogbo ayé, kí ẹ sì wàásù ìhìn rere fún gbogbo ìṣẹ̀dá. 16 Ẹni tí ó bá gbà gbọ́, tí a sì batisí ni a ó gbà là, ṣùgbọ́n ẹni tí kò bá gbà gbọ́ ni a óò dá lẹ́bi. 17 Síwájú sí i, àmì wọ̀nyí yóò máa bá àwọn tí wọ́n gbà gbọ́ rìn: Nípa lílo orúkọ mi, wọn yóò lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, wọn yóò máa fi ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀, 18 wọn yóò sì fi ọwọ́ wọn gbé ejò, bí wọ́n bá sì mu ohunkóhun tí ń ṣekú pani, kì yóò ṣe wọ́n lọ́ṣẹ́ rárá. Wọn yóò gbé ọwọ́ wọn lé àwọn aláìsàn, àwọn wọ̀nyí yóò sì sàn.”
19 Nítorí bẹ́ẹ̀, lẹ́yìn tí Jésù Olúwa ti bá wọn sọ̀rọ̀, a gbé e lọ sókè sí ọ̀run, ó sì jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. 20 Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, wọ́n jáde lọ, wọ́n sì wàásù níbi gbogbo, nígbà tí Olúwa ń bá wọn ṣiṣẹ́, tí ó sì kín ìhìn-iṣẹ́ náà lẹ́yìn nípasẹ̀ àwọn àmì tí ń bá wọn rìn.
Bíbélì Kíkà
JUNE 11-17
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÚÙKÙ 1
“Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Màríà”
“Wò Ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà!”
12 Kódà títí di òní, ọ̀pọ̀ àwọn tó ní ìgbàgbọ́ ló mọ̀ nípa ìdáhùn rẹ̀ tó fi hàn pé ó níwà ìrẹ̀lẹ̀ àti pé ó fẹ́ láti ṣègbọràn. Ó sọ fún Gébúrẹ́lì pé: “Wò ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà! Kí ó ṣẹlẹ̀ sí mi ní ìbámu pẹ̀lú ìpolongo rẹ.” (Lúùkù 1:38) Ipò ẹrúbìnrin ló rẹlẹ̀ jù lọ láàárín àwọn ìránṣẹ́ inú ilé, ọ̀gá rẹ̀ ló sì máa ń pinnu bó ṣe máa lo ìgbésí ayé rẹ̀. Màríà náà gbà pé Jèhófà tó jẹ́ Ọ̀gá òun ló yẹ kó máa darí ìgbésí ayé òun. Ó mọ̀ pé mìmì kan ò lè mi òun lọ́dọ̀ Jèhófà, torí pé kì í fi àwọn tó bá jẹ́ adúróṣinṣin sílẹ̀. Ó tún dá a lójú pé Jèhófà máa ràn án lọ́wọ́ tó bá ṣe gbogbo nǹkan tó lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ tó gba ìsapá yìí.—Sm. 18:25.
“Wò Ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà!”
15 Màríà náà wá sọ̀rọ̀, Ọlọ́run sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà nínú Bíbélì. (Ka Lúùkù 1:46-55.) Èyí ló gùn jù nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí Màríà sọ nínú Bíbélì, ó sì jẹ́ ká mọ púpọ̀ nípa irú ẹni tó jẹ́. Ó fi hàn pé Màríà moore, ó sì ní ẹ̀mí ìmọrírì. Èyí hàn nínú bó ṣe ń yin Jèhófà pé ó fún òun ní àǹfààní láti di ìyá Mèsáyà. Ó fi bí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó hàn nígbà tó ń sọ bí Jèhófà ṣe ń rẹ àwọn agbéraga àti alágbára sílẹ̀ tó sì ń ran àwọn ẹni rírẹlẹ̀ àti tálákà tó ń fẹ́ láti sìn ín lọ́wọ́. Ó tún fi bí ìmọ̀ rẹ̀ ṣe pọ̀ tó hàn. Àwọn kan díwọ̀n rẹ̀ pé ó lé ní ìgbà ogún tó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù!
16 Ó ṣe kedere pé Màríà máa ń ṣàṣàrò lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lórí gan-an. Síbẹ̀, ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó gbé ohun tó sọ karí Ìwé Mímọ́ dípò kó máa sọ èrò ti ara rẹ̀. Ọjọ́ kan ń bọ̀ tí ọmọ tó lóyún rẹ̀ sínú náà máa fi irú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ hàn. Ó máa sọ fáwọn èèyàn pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.” (Jòh. 7:16) Ó yẹ kí àwa náà bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ èmi náà ní irú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Àbí èrò ti ara mi ni mo fi ń kọ́ àwọn èèyàn?’ Ohun tó tọ́ ni Màríà ṣe ní tirẹ̀.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 1:69
ìwo ìgbàlà kan: Tàbí “olùgbàlà tó lágbára.” Nínú Bíbélì, ìwo ẹran sábà máa ń ṣàpẹẹrẹ agbára, ṣẹ́gun àti ìṣẹ́gun. (1Sa 2:1; Sm 75:4, 5, 10; 148:14.) Bákàn náà, Bíbélì tún fi ìwo ṣàpẹẹrẹ àwọn alákòóso àti ilẹ̀ ọba tó ń ṣàkóso, yálà ó jẹ́ rere tàbí búburú. Ó sì fi bí wọ́n ṣe ń ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè míì wé fífi ìwo taari àwọn èèyàn. (Diu 33:17; Da 7:24; 8:2-10, 20-24) Nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, ọ̀rọ̀ náà “ìwo ìgbàlà kan” ń tọ́ka sí Mèsáyà pé ó ní agbára láti gbani là, ìyẹn olùgbàlà tó lágbára.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 1:76
ìwọ yóò lọ ṣáájú níwájú Jèhófà: Jòhánù oníbatisí máa lọ “ṣáájú níwájú Jèhófà” ní ti pé ó máa wá ṣáájú Jésù, tó máa ṣojú fún Baba rẹ̀ tó sì máa wá ní orúkọ Baba rẹ̀.—Jo 5:43; 8:29; wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jèhófà ní ẹsẹ yìí.
Bíbélì Kíkà
JUNE 18-24
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÚÙKÙ 2-3
“Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ṣé Àjọṣe Yín Pẹ̀lú Jèhófà Túbọ̀ Ń Lágbára Sí I?”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 2:41
ó jẹ́ àṣà àwọn òbí rẹ̀: Òfin kò fi dandan lé e fún àwọn obìnrin láti lọ sí àjọyọ̀ Ìrékọjá. Síbẹ̀, Màríà ti sọ ọ́ dàṣà láti máa tẹ̀ lé Jósẹ́fù lọ sí Jerúsálẹ́mù fún àjọyọ̀ lẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́dún. (Ẹk 23:17; 34:23) Lọ́dọọdún, wọ́n máa ń rin ìrìn àjò tó jìnnà tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] kìlómítà, àlọ àtàbọ̀ pẹ̀lú ìdílé wọn tó ń tóbi sí i.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 2:46, 47
ó sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè: Ohun tí àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù ṣe nígbà tó ń bi wọ́n ní ìbéèrè fi hàn pé àwọn ìbéèrè Jésù kì í ṣe ti ọmọdé kan tó kàn ń fẹ́ tọpinpin ọ̀rọ̀. (Lk 2:47) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “bi wọ́n ní ìbéèrè” lè tọ́ka sí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ èèyàn nílé ẹjọ́, tó sì lè gba pé kí wọ́n da ìbéèrè bo èèyàn lórí ohun tó ti sọ tẹ́lẹ̀. (Mt 27:11; Mk 14:60, 61; 15:2, 4; Iṣe 5:27) Àwọn òpìtàn sọ pé ó jẹ́ àṣà àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó jẹ́ òléwájú láti tẹsẹ̀ dúró ní tẹ́ńpìlì lẹ́yìn àjọyọ̀ kí wọ́n lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ láwọn ibi àbáwọlé tó ní àyè fífẹ̀. Àwọn èèyàn lè jókòó síbi ẹsẹ̀ àwọn ọkùnrin yẹn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, kí wọ́n sì bi wọ́n ní ìbéèrè.
wọ́n ń ṣe kàyéfì léraléra: Irú ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì tí wọ́n lò fún “kàyéfì” lè túmọ̀ sí kí nǹkan máa yani lẹ́nu léraléra.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 2:51, 52
bá a lọ ní fífi ara rẹ̀ sábẹ́ wọn: Tàbí “ó ń bá a lọ ní títẹríba; ó ń bá a lọ ní jíjẹ́ onígbọràn.” Bí wọ́n ṣe lo ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì náà “bá a lọ” fi hàn pé lẹ́yìn tí Jésù ti fi hàn pé òun ní ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí èyí sì ya àwọn olùkọ́ lẹ́nu gan-an, Jésù bá àwọn òbí rẹ̀ pa dà sílé, ó sì ń tẹrí ba fún wọn. Bí Jésù ṣe ń gbọ́ràn sáwọn òbí rẹ̀ lẹ́nu gba àfiyèsí ju tàwọn ọmọ míì lọ; ó jẹ́ ọ̀nà kan tó gbà tẹ̀ lé gbogbo ohun tí Òfin Mósè pa láṣẹ láìkù síbì kan.—Ẹk 20:12; Ga 4:4.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 2:14
àti lórí ilẹ̀ ayé àlàáfíà láàárín àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà: Àwọn ìwé àfọwọ́kọ kan ní àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe é túmọ̀ sí “àti lórí ilẹ̀ ayé àlàáfíà, fún àwọn èèyàn,” ohun tó sì wà nínú àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan nìyẹn. Àmọ́ àwọn ìwé àfọwọ́kọ kan wà tó ṣètìlẹ́yìn fún bá a ṣe túmọ̀ rẹ̀ nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lọ́nà tó lágbára gan-an. Ọ̀rọ̀ tí àwọn ańgẹ́lì kéde yìí kò tọ́ka sí inú rere tí Ọlọ́run fi hàn sí gbogbo èèyàn láìka ti ìwà àti ìṣe wọn sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń tọ́ka sí àwọn to máa rí ojúure Ọlọ́run torí pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ tòótọ́ nínú rẹ̀ tí wọ́n sì di ọmọlẹ́yìn Ọmọ rẹ̀.—Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà nínú ẹsẹ yìí.
àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà: “Ìtẹ́wọ́gbà” táwọn ańgẹ́lì yìí tọ́ka sí kì í ṣe látọ̀dọ̀ èèyàn, àmọ́ ó jẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà eu·do·kiʹa tún lè túmọ̀ sí “ojúure; ìdùnnú rere; ìfọwọ́sí.” Wọ́n lo àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe tó jọ eu·do·keʹo nínú Mt 3:17; Mk 1:11; àti Lk 3:22 (wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 3:17; Mk 1:11), níbi tí Ọlọ́run ti bá Ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tó ṣe ìrìbọmi. Ọ̀nà tí wọ́n gbà lò ó níbẹ̀ túmọ̀ sí, “láti fọwọ́ sí; kí inú ẹni dùn sí; kó fojú rere hàn sí; ní inú dídùn sí.” Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí wọ́n gbà lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn, ọ̀rọ̀ náà “àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà” (an·throʹpois eu·do·kiʹas) ń tọ́ka sí àwọn èèyàn tó rí ojúure Ọlọ́run àti ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀, ó tún lè túmọ̀ sí “àwọn èèyàn tó fọwọ́ sí; àwọn èèyàn tí inú rẹ̀ dùn sí.” Fún ìdí yìí, ọ̀rọ̀ táwọn ańgẹ́lì náà sọ ń tọ́ka sí bí Ọlọ́run ṣe tẹ́wọ́ gba kìkì àwọn tó ṣe ohun tó fẹ́ nípa lílo ìgbàgbọ́ tòótọ́ nínú rẹ̀ tí wọ́n sì di ọmọlẹ́yìn Ọmọ rẹ̀, kì í ṣe pé ó tẹ́wọ́ gba gbogbo èèyàn lápapọ̀. Láwọn ibì kan, wọ́n túmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà eu·do·kiʹa sí ìfẹ́ rere ọkàn èèyàn, ìyẹn ni pé kéèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ohun kan (Ro 10:1; Flp 1:15), àmọ́ ohun tí wọ́n sábà máa ń lò ó fún jù ni kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà tàbí kí Ọlọ́run dunnú sí tàbí kí Ọlọ́run fọwọ́ sí (Mt 11:26; Lk 10:21; Ef 1:5, 9; Flp 2:13; 2Tẹ 1:11). Nínú Bíbélì Septuagint ní Sm 51:18 [50:20, LXX], wọ́n túmọ̀ rẹ̀ sí “ìfẹ́ rere” Ọlọ́run.
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ta ni bàbá Jósẹ́fù?
Jósẹ́fù tó jẹ́ káfíńtà nílùú Násárétì ni bàbá tó gba Jésù tọ́. Àmọ́, ta ni bàbá Jósẹ́fù? Ìlà ìdílé Jésù, bó ṣe wà nínú ìwé Ìhìn Rere Mátíù fi hàn pé Jékọ́bù ni bàbá Jósẹ́fù, ṣùgbọ́n Lúùkù sọ pé Jósẹ́fù jẹ́ “ọmọkùnrin Hélì.” Kí ló fa ìyàtọ̀ yìí?—Lúùkù 3:23; Mátíù 1:16.
Àkọsílẹ̀ Mátíù kà pé: “Jékọ́bù bí Jósẹ́fù.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò níbí jẹ́ ká mọ̀ pé Jékọ́bù ni bàbá tó bí Jósẹ́fù. Torí náà, Mátíù to ìlà ìdílé Jósẹ́fù, ìyẹn ìlà ìdílé Dáfídì ọba. Ìlà ìdílé yìí ní í ṣe pẹ̀lú àwọn tí ọba tọ́ sí, èyí fi hàn pé ọba tọ́ sí Jésù tí Jósẹ́fù gbà ṣọmọ.
Lọ́wọ́ kejì, àkọsílẹ̀ Lúùkù pé Jósẹ́fù ní “ọmọkùnrin Hélì.” Ọ̀rọ̀ náà, “ọmọkùnrin,” tún lè túmọ̀ sí “ọkọ ọmọ.” Ohun tó fara jọ èyí wà nínú Lúùkù 3:27, níbi tó ti pe Ṣéálítíẹ́lì ní “ọmọkùnrin Nẹ́rì,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jekonáyà ni bàbá rẹ̀. (1 Kíróníkà 3:17; Mátíù 1:12) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Ṣéálítíẹ́lì fẹ́ ọmọbìnrin Nẹ́rì tí a kò dárúkọ, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ di ọkọ ọmọ Nẹ́rì. Irú ọ̀nà yìí ni Jósẹ́fù gbà jẹ́ “ọmọkùnrin” Hélì, torí pé ó fẹ́ Màríà tó jẹ́ ọmọ Hélì. Torí náà, Lúùkù to ìlà ìdílé Jésù “lọ́nà ti ẹran ara,” nípasẹ̀ Màríà tó jẹ́ ìyá rẹ̀. (Róòmù 1:3) Bíbélì tipa bẹ́ẹ̀ sọ ìlà ìdílé méjì tí Jésù ti wá.
Bíbélì Kíkà
JUNE 25–JULY 1
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÚÙKÙ 4-5
“Kọ Ìdẹwò Bí I Ti Jésù”
Máa Ronú Nípa Irú Ẹni Tó Yẹ Kó O Jẹ́
8 Ọgbọ́n kan náà yìí ni Sátánì lò nígbà tó ń dẹ Jésù wò ní aginjù. Lẹ́yìn tí Jésù ti gbààwẹ̀ fún ogójì [40] ọ̀sán àti ogójì òru, Sátánì mọ̀ pé ebi á ti máa pa á, torí náà ó fẹ́ fi oúnjẹ tàn án. Sátánì sọ pé, “Bí ìwọ bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, sọ fún òkúta yìí kí ó di ìṣù búrẹ́dì.” (Lúùkù 4:1-3) Ohun méjì ni Jésù lè ṣe: Ó lè pinnu pé òun kò ní torí àtijẹun kóun wá lo agbára tí òun ní láti ṣe iṣẹ́ ìyanu, ó sì lè pinnu pé òun máa lo agbára náà. Jésù mọ̀ pé òun kò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìyanu torí pé ó fẹ́ tẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn. Lóòótọ́ ni ebi ń pa á, àmọ́ kò ní torí àtijẹun kó wá ba àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Jésù da Sátánì lóhùn pé, “A kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ènìyàn kò gbọ́dọ̀ tipa oúnjẹ nìkan ṣoṣo wà láàyè.’ ”—Lúùkù 4:4.
Máa Ronú Nípa Irú Ẹni Tó Yẹ Kó O Jẹ́
10 Báwo ni Sátánì ṣe fi ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú dán Jésù wò? ‘Ó fi gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé tí à ń gbé han Jésù ní ìṣẹ́jú akàn.’ Èṣù sì wí fún un pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ yìí àti ògo wọn ni èmi yóò fi fún ọ.” (Lúùkù 4:5, 6) Kì í ṣe pé Jésù fi ojú rẹ̀ rí gbogbo ìjọba ayé yìí ní ìṣẹ́jú akàn o. Àmọ́, ńṣe ni Sátánì fi ògo ìjọba ayé yìí hàn án nínú ìran, èrò rẹ̀ sì ni pé àwọn nǹkan yẹn máa fa Jésù lọ́kàn mọ́ra. Ó wá sọ fún Jésù pé: “Bí o bá jọ́sìn níwájú mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, gbogbo rẹ̀ ni yóò jẹ́ tìrẹ.” (Lúùkù 4:7) Jésù kò gbà láé kí Sátánì sọ òun dìdàkudà. Kíá ló fún un lésì pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.’ ”—Lúùkù 4:8.
nwtsty fídíò àti àwòrán
Odi Orí Òrùlé Tẹ́ńpìlì
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Sátánì dìídì mú Jésù dúró “lórí odi orí òrùlé” tẹ́ńpìlì [tàbí “ibi tó ga jù”], ó sì sọ fún un pé kó bẹ́ sílẹ̀, àmọ́ a ò mọ ibi tó ṣeé ṣe kí Jésù dúró sí gangan. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé gbólóhùn náà “tẹ́ńpìlì” lè tọ́ka sí gbogbo tẹ́ńpìlì náà àti àyíká rẹ̀, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé apá gúúsù tẹ́ńpìlì náà níbi tó ti dojú kọ ìlà oòrùn (1) ni Jésù dúró sí. Ó sì lè jẹ́ pé apá ibòmíì lára tẹ́ńpìlì náà ló dúró sí. Ibi yòówù kéèyàn ti ṣubú látorí tẹ́ńpìlì náà, ẹni náà máa kú ni, àyàfi tí Jèhófà bá yọ ọ́.
Máa Ronú Nípa Irú Ẹni Tó Yẹ Kó O Jẹ́
12 Jésù ní tiẹ̀ kò dà bí Éfà. Àpẹẹrẹ àtàtà ni Jésù jẹ́ tó bá dọ̀rọ̀ kéèyàn lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀! Sátánì lo ọgbọ́n míì láti tan Jésù, àmọ́ Jésù ò gbà kí Sátánì mú òun ṣe àṣehàn. Ó mọ̀ pé ńṣe nìyẹn máa túmọ̀ sí pé òun ń dán Ọlọ́run wò. Kò sí àní-àní pé ìwà ìgbéraga nìyẹn máa jẹ́! Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù dá Sátánì lóhùn lọ́nà tó ṣe kedere tó sì ṣe tààràtà pé: “A sọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà Ọlọ́run rẹ wò.’ ”—Ka Lúùkù 4:9-12.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 4:17
àkájọ ìwé wòlíì Aísáyà: Àpapọ̀ abala tí wọ́n fi ṣe ìwé Aísáyà tó wà lára Àkájọ Òkun Òkú jẹ́ mẹ́tàdínlógún [17], ó gùn tó ẹsẹ̀ bàtà mẹ́rìnlélógún [24], ó sì ní òpó ìlà mẹ́rìnléláàádọ́ta [54]. Ó ṣeé ṣe kí àkájọ ìwé tí wọ́n lò ní sínágọ́gù tó wà ní Násárétì gùn tó báyìí. Ó ní láti jẹ́ pé ńṣe ni Jésù fara balẹ̀ wá ibi tó fẹ́ kà nínú àkájọ ìwé náà, torí pé àkájọ ìwé tó wà nígbà yẹn kò ní orí àti ẹsẹ. Àmọ́ bó ṣe rí ibi tí àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn wà jẹ́ ẹ̀rí pé ó mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 4:25
fún ọdún mẹ́ta àti oṣù mẹ́fà: Bó ṣe wà ní 1Ọb 18:1, lẹ́yìn “ọdún kẹta” wòlíì Èlíjà kéde pé òjò máa rọ̀. Àwọn kan sọ pé ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ta ko ìtàn tó wà ní Àwọn Ọba Kìíní. Àmọ́, Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù kò sọ pé ọ̀dá náà kò pé ọdún mẹ́ta. Ó ṣe kedere pé ohun tí gbólóhùn náà “ní ọdún kẹta” ń tọ́ka sí ni àkókò kan tó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Èlíjà kọ́kọ́ kéde fún Áhábù pé òjò kò ní rọ̀. (1Ọb 17:1) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àkókò ẹ̀ẹ̀rùn tó máa ń gùn tó nǹkan bí oṣù mẹ́fà ti bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Èlíjà ṣe ìkéde yìí, kó sì wá jẹ́ pé àsìkò ẹ̀ẹ̀rùn yẹn gùn ju bó ṣe yẹ lọ. Síwájú sí i, kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí Èlíjà pa dà wá sọ́dọ̀ Áhábù “ní ọdún kẹta” ni òjò ti bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀, àmọ́ ó jẹ́ lẹ́yìn tí Èlíjà gbàdúrà fún iná láti ọ̀run lórí Òkè Kámẹ́lì. (1Ọb 18:18-45) Torí náà, ọ̀rọ̀ Jésù tó wà ní ẹsẹ yìí àti irú rẹ̀ tí Jákọ́bù ọmọ ìyá Jésù sọ nínú Jak 5:17 dọ́gba pẹ̀lú ìtàn tó wà nínú 1Ọb 18:1.
Bíbélì Kíkà