ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwbr19 September ojú ìwé 1-8
  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka Sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka Sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé—2019
  • Ìsọ̀rí
  • SEPTEMBER 2-8
  • SEPTEMBER 9-15
  • SEPTEMBER 16-22
  • SEPTEMBER 23-29
  • SEPTEMBER 30–OCTOBER 6
Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé—2019
mwbr19 September ojú ìwé 1-8

Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka Sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni

SEPTEMBER 2-8

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | HÉBÉRÙ 7-8

“Àlùfáà Títí Láé Ní Ọ̀nà Ti Melikisédékì”

it-2 366

Melikisédékì

Ọba Sálẹ́mù àtijọ́ tó tún jẹ́ “àlùfáà Ọlọ́run Gíga Jù Lọ,” ìyẹn Jèhófà. (Jẹ 14:18, 22) Òun ni àlùfáà àkọ́kọ́ tí Bíbélì mẹ́nu kàn; ó dé orí ipò yìí láàárín àkókò kan kó tó di ọdún 1933 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Bó ṣe jẹ́ pé Melikisédékì ni ọba Sálẹ́mù, tó túmọ̀ sí “Àlàáfíà,” àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe Melikisédékì ní “Ọba Àlàáfíà,” àti pé orúkọ náà Melikisédékì túmọ̀ sí “Ọba Òdodo.” (Heb 7:1, 2) Ìlú Sálẹ́mù àtijọ́ ló wà ní agbègbè tí wọ́n pa dà kọ́ ìlú Jerúsálẹ́mù sí, wọ́n sì fi orúkọ náà kún orúkọ tí wọ́n sọ ìlú Jerúsálẹ́mù. Láwọn ìgbà míì, wọ́n máa ń pe Jerúsálẹ́mù ní “Sálẹ́mù.”—Sm 76:2.

Lẹ́yìn tí Ábúrámù (Ábúráhámù) ṣẹ́gun Kedoláómà àtàwọn ọba tó wà pẹ̀lú rẹ̀, ó wá sí Àfonífojì Ṣáfè tàbí “Àfonífojì Ọba.” Níbẹ̀, Melikisédékì “gbé búrẹ́dì àti wáìnì jáde wá,” ó sì súre fún Ábúráhámù pé: “Kí Ọlọ́run Gíga Jù Lọ, Ẹni tó dá ọ̀run àti ayé bù kún Ábúrámù; Ìyìn yẹ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ, Ẹni tó mú kí ọwọ́ rẹ tẹ àwọn tó ń ni ọ́ lára!” Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù fún Melikisédékì ní “ìdá mẹ́wàá gbogbo” àwọn “ẹrù ogun tó dáa jù” tó kó bọ̀ lẹ́yìn tó ṣẹ́gun àwọn ọba náà.—Jẹ 14:17-20; Heb 7:4.

it-2 367 ¶4

Melikisédékì

Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé Melikisédékì ‘kò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́, kò sì ní òpin ìwàláàyè’?

Pọ́ọ̀lù sọ ohun kan tó gbàfiyèsí nípa Melikisédékì, ó ní: “Bó ṣe jẹ́ pé kò ní bàbá, kò ní ìyá, kò ní ìran, kò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́, kò sì ní òpin ìwàláàyè, àmọ́ tí a ṣe é bí Ọmọ Ọlọ́run, ó jẹ́ àlùfáà títí láé.” (Heb 7:3) Bíi ti gbogbo èèyàn, ẹnì kan ló bí Melikisédékì, ó sì kú nígbà tó yá. Àmọ́, Bíbélì ò sọ orúkọ bàbá àti ìyá rẹ̀ fún wa, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sọ ìlà ìdílé tó ti wá tàbí àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀, kódà Ìwé Mímọ́ ò sọ ìgbà tí wọ́n bí i àti ìgbà tó kú. Torí náà, ó bá a mu wẹ́kú bí Bíbélì ṣe fi Melikisédékì ṣàpẹẹrẹ Jésù Kristi tó máa jẹ́ Àlùfáà Àgbà títí láé. Bákan náà, bó ṣe jẹ́ pé Bíbélì ò sọ ẹni tó jẹ́ àlùfáà ṣáájú Melikisédékì àti ẹni tó di àlùfáà lẹ́yìn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àlùfáà àgbà tó dà bíi Jésù tó wà ṣáájú rẹ̀, Bíbélì sì tún fi hàn pé kò sí èyí tó máa wà lẹ́yìn rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlà ìdílé Ọba Dáfídì tó jẹ́ ti ẹ̀yà Júdà ni wọ́n ti bí Jésù, kò sí baba ńlá Jésù tó fìgbà kan rí jẹ́ àlùfáà àgbà. Torí náà, kì í ṣe ìlà ìdílé tó ti wá ló mú kó jẹ́ ọba, kó sì tún jẹ́ àlùfáà lẹ́sẹ̀ kan náà. Jèhófà ló búra fún un tó sì gbé e sáwọn ipò méjèèjì yìí.

it-2 366

Melikisédékì

Àpẹẹrẹ Bí Kristi Ṣe Jẹ́ Àlùfáà Àgbà. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa Mèsáyà, Jèhófà búra fún ẹni tí Dáfídì pè ní “Olúwa,” ó ní: “Ìwọ jẹ́ àlùfáà títí láé ní ọ̀nà ti Melikisédékì!” (Sm 110:1, 4) Ọ̀rọ̀ inú sáàmù yìí ló mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà pé Mèsáyà náà máa jẹ́ ọba àti àlùfáà. Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Hébérù, ó jẹ́ kó ṣe kedere pé Jésù lẹni tí àsọtẹ́lẹ̀ náà ń tọ́ka sí. Ó sọ pé: “Jésù, ẹni tó ti di àlùfáà àgbà ní ọ̀nà ti Melikisédékì títí láé.”—Heb 6:20; 5:10; wo MÁJÈMÚ.

Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

w00 8/15 14 ¶11

Àwọn Ẹbọ Tí Inú Ọlọ́run Dùn Sí

11 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Olúkúlùkù àlùfáà àgbà ni a yàn sípò láti fi àwọn ẹ̀bùn àti ohun ẹbọ rúbọ.” (Hébérù 8:3) Ṣàkíyèsí pé ọ̀nà méjì ni Pọ́ọ̀lù pín àwọn ẹbọ tí àlùfáà àgbà Ísírẹ́lì ìgbàanì ń rú sí, èyíinì ni, “àwọn ẹ̀bùn” àti “ohun ẹbọ,” tàbí “àwọn ohun ẹbọ . . . fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀.” (Hébérù 5:1) Àwọn èèyàn sábà máa ń fúnni lẹ́bùn láti fi ìfẹ́ àti ìmọrírì hàn, àti láti sọ àwọn èèyàn dọ̀rẹ́, tàbí láti fi wá ojú rere, tàbí láti lè rí ìtẹ́wọ́gbà. (Jẹ́nẹ́sísì 32:20; Òwe 18:16) Bákan náà, ọ̀pọ̀ ọrẹ ẹbọ tí Òfin là kalẹ̀ ni a lè kà sí “ẹ̀bùn” fún Ọlọ́run, láti fi rí ìtẹ́wọ́gbà àti ojú rere rẹ̀. Ríré Òfin kọjá ń béèrè fún ìsanpadà, wọ́n sì máa ń rú “àwọn ohun ẹbọ . . . fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀,” láti fi ṣètùtù. Ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì, àgàgà àwọn ìwé náà, Ẹ́kísódù, Léfítíkù, àti Númérì, ṣe àlàyé rẹpẹtẹ nípa onírúurú ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè máà rọrùn rárá láti kó gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa rẹ̀ ságbárí, ká sì máa rántí wọn, síbẹ̀síbẹ̀, á dára kí á pe àfiyèsí sí àwọn kókó pàtàkì kan nípa oríṣiríṣi ẹbọ tó wà.

it-1 523 ¶5

Májẹ̀mú

Báwo ni májẹ̀mú Òfin ṣe di “èyí tí kò wúlò mọ́”?

Májẹ̀mú Òfin di “èyí tí kò wúlò mọ́” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nígbà tí Jèhófà kéde nípasẹ̀ wòlíì Jeremáyà pé òun máa bá orílẹ̀-èdè náà dá májẹ̀mú tuntun kan. (Jer 31:31-34; Heb 8:13) Májẹ̀mú Òfin kásẹ̀ nílẹ̀ lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni nígbà tí Kristi kú lórí òpó igi oró (Kol 2:14), tí májẹ̀mú tuntun sì wá rọ́pò rẹ̀.—Heb 7:12; 9:15; Iṣe 2:1-4.

it-1 524 ¶3-5

Májẹ̀mú Tuntun

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún keje Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ wòlíì Jeremáyà pé òun máa bá orílẹ̀ èdè Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú tuntun kan tó máa yàtọ̀ sí Májẹ̀mú Òfin táwọn èèyàn náà ò pa mọ́. (Jer 31:31-34) Ní alẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀, Jésù Kristi dá ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ olóòótọ́ ní Nísàn 14 ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ó wá ṣàlàyé fún wọn pé májẹ̀mú tuntun máa bẹ̀rẹ̀ iṣé lẹ́yìn ikú ìrúbọ òun. (Lk 22:20) Àádọ́ta (50) ọjọ́ lẹ́yìn tí Jésù jíǹde àti ọjọ́ kẹwàá lẹ́yìn tó pa dà sọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀ lọ́run, Jèhófà fún Jésù lágbára láti tú ẹ̀mí mímọ́ jáde sára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà tí gbogbo wọn wà nínú yàrá òkè kan ní Jerúsálẹ́mù.—Iṣe 2:1-4, 17, 33; 2Kọ 3:6, 8, 9; Heb 2:3, 4.

Àwọn tí wọ́n wà nínú májẹ̀mú tuntun yìí ni Jèhófà àti “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” ìyẹn àwọn tí Jèhófà fẹ̀mí yàn, tí wọ́n wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, tí wọ́n sì para pọ̀ di ìjọ tàbí ara rẹ̀. (Heb 8:10; 12:22-24; Ga 6:15, 16; 3:26-28; Ro 2:28, 29) Ẹ̀jẹ̀ Jésù (ìyẹn ẹ̀mí rẹ̀ tó fi rúbọ gẹ́gẹ́ bí èèyàn) ló mú kí májẹ̀mú yìí ṣeé ṣe. Jésù gbé ìtóye ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà lẹ́yìn tó pa dà sọ́run. (Mt 26:28) Tí Ọlọ́run bá yan ẹni kan láti lọ sọ́run (Heb 3:1), ṣe ni Ọlọ́run ń mú ẹni náà wọ inú májẹ̀mú Rẹ̀ nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Kristi. (Sm 50:5; Heb 9:14, 15, 26) Jésù Kristi ni Alárinà májẹ̀mú tuntun yìí (Heb 8:6; 9:15) òun sì ni apá àkọ́kọ́ lára ọmọ Ábúráhámù. (Ga 3:16) Torí pé Jésù ni alárinà májẹ̀mú tuntun yìí, ó mú kó ṣeé ṣe fáwọn míì láti di apá kejì lára ọmọ Ábúráhámù náà (Heb 2:16; Ga 3:29) nígbà tí wọ́n bá rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. Jèhófà sì máa tipa bẹ́ẹ̀ kà wọ́n sí olódodo.—Ro 5:1, 2; 8:33; Heb 10:16, 17.

Àwọn tí Jèhófà fẹ̀mí yàn, ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi máa di àlùfáà tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Àlùfáà Àgbà, àwọn ló sì para pọ̀ di “ẹgbẹ́ àlùfáà aládé.” (1Pe 2:9; Ifi 5:9, 10; 20:6) Àwọn yìí ń ṣiṣẹ́ àlùfáà, ìyẹn “iṣẹ́ fún àwọn èèyàn” (Flp 2:17), Bíbélì sì pè wọ́n ní “òjíṣẹ́ májẹ̀mú tuntun kan.” (2Kọ 3:6) Àwọn tá a fẹ̀mí yàn yìí gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ipasẹ̀ Jésù pẹ́kípẹ́kí, wọ́n sì gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú; ẹ̀yìn ìyẹn ni Jèhófà máa sọ wọ́n di ìjọba àwọn àlùfáà, wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ nípìn-ín nínú àwọn ohun ti ọ̀run, Jèhófà á wá san wọ́n lẹ́san pẹ̀lú àìkú àti àìdíbàjẹ́, wọ́n á sì di àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run. (1Pe 2:21; Ro 6:3, 4; 1Kọ 15:53; 1Pe 1:4; 2Pe 1:4) Ohun tí májẹ̀mú yìí wà fún ni pé kó kó àwọn èèyàn jọ fún orúkọ Jèhófà, kí wọ́n lè di apá kan lára “ọmọ” Ábúráhámù. (Iṣe 15:14) Àwọn yìí máa di “aya” Kristi, àwọn sì ni Kristi mú wọnú májẹ̀mú ìjọba, kí wọ́n lè ṣàkóso pẹ̀lú Rẹ̀. (Jo 3:29; 2Kọ 11:2; Ifi 21:9; Lk 22:29; Ifi 1:4-6; 5:9, 10; 20:6) Májẹ̀mú tuntun yìí á máa báṣẹ́ lọ títí gbogbo àwọn tó jẹ́ “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” fi máa jíǹde sí ọ̀run, tí wọ́n á sì gba àìkú. Títí láé là á máa jàǹfààní májẹ̀mú tuntun, ìdí nìyẹn tí Bíbélì ṣe pè é ní “májẹ̀mú àìnípẹ̀kun.”—Heb 13:20.

it-1 1113 ¶4-5

Àlùfáà Àgbà

Bí Melikisédékì Ṣe Jẹ́ Àlùfáà. Melikisédékì ni àlùfáà àkọ́kọ́ tí Bíbélì mẹ́nu kàn, ó sì pè é ní “àlùfáà Ọlọ́run Gíga Jù Lọ,” ó tún pè é ní ọba Sálẹ́mù (Jerúsálẹ́mù). Ìgbà tí Ábúráhámù ń pa dà bọ̀ lẹ́yìn tó ṣẹ́gun àwọn ọba mẹ́ta tó lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Ọba Kedoláómà ti Élámù ló pàdé Melikisédékì tó jẹ́ ọba àti àlùfáà yìí. Ábúráhámù gbà pé Ọlọ́run ló fi Melikisédékì sí ipò tó wà, ìdí nìyẹn tí Ábúráhámù fi fún un ní ìdá mẹ́wàá ohun tó kó bọ̀ láti ogun, tó sì tún jẹ́ kí Melikisédékì súre fún òun. Bíbélì ò sọ ìlà ìdílé tí Melikisédékì ti wá, ẹni tó bí i àti bó ṣe kú. Torí náà kò sẹ́ni tó ṣáájú rẹ̀, kò sì sẹ́ni tó jẹ lẹ́yìn rẹ̀.—Jẹ 14:17-24; wo MELIKISÉDÉKÌ.

Bí Jésù Kristi Ṣe Jẹ́ Àlùfáà Àgbà. Ìwé Hébérù jẹ́ kó ṣe kedere pé àtìgbà tí Jésù Kristi ti pa dà sí ọ̀run ló ti di “àlùfáà àgbà ní ọ̀nà ti Melikisédékì títí láé.” (Heb 6:20; 7:17, 21) Kó lè hàn kedere pé ipò Kristi gẹ́gẹ́ bí àlùfáà ga ju ti Áárónì lọ, ẹni tó kọ Bíbélì yẹn sọ pé ọba ni Melikisédékì, Ọlọ́run Ẹni Gíga Jù Lọ sì fi í sípò àlùfáà, kì í ṣe pé ó jogún rẹ̀. Bákan náà, ìlà ìdílé Dáfídì tó jẹ́ ẹ̀yà Júdà ni Kristi Jésù ti wá, kì í ṣe ẹ̀yà Léfì, torí náà, Jésù di Àlùfáà Àgbà kì í ṣe torí pé ó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Áárónì, bí kò ṣe pé Ọlọ́run ló fi í sípò yẹn bíi ti Melikisédékì. (Heb 5:10) Sáàmù 110:4 sọ pé: “Jèhófà ti búra (kò ní yí ìpinnu rẹ̀ pa dà): ‘Ìwọ jẹ́ àlùfáà títí láé ní ọ̀nà ti Melikisédékì!’ ” Láfikún sí ìlérí yìí tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù máa di Ọba àti Àlùfáà, Jésù tún lẹ́tọ̀ọ́ láti di Ọba tórí pé àtọmọdọ́mọ Dáfídì ni. Kódà, òun ni ọba tí Bíbélì tọ́ka sí nínú májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Dáfídì dá. (2Sa 7:11-16) Fún ìdí yìí, Jésù máa jẹ́ Ọba àti Àlùfáà bíi ti Melikisédékì.

Bíbélì Kíkà

SEPTEMBER 9-15

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | HÉBÉRÙ 9-10

“Òjìji Àwọn Nǹkan Rere Tó Ń Bọ̀”

it-1 862 ¶1

Ìdáríjì

Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ pé, tẹ́nì kan bá dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run tàbí tó ṣẹ ọmọnìkejì rẹ̀, á kọ́kọ́ tọrọ àforíjì, kí wọ́n tó lè dárí jì í. Lẹ́yìn náà, Òfin sọ pé kó fi ẹ̀jẹ̀ ẹran rúbọ sí Jèhófà. (Le 5:5–6:7) Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé: “Àní bí Òfin ṣe sọ, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo nǹkan ni wọ́n ń fi ẹ̀jẹ̀ wẹ̀ mọ́, ìdáríjì kankan ò sì lè wáyé àfi tí a bá tú ẹ̀jẹ̀ jáde.” (Heb 9:22) Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé ẹ̀jẹ̀ ẹran ò lè fọ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, kò sì lè mú kẹ́nì kan ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. (Heb 10:1-4; 9:9, 13, 14) Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, májẹ̀mú tuntun máa ń jẹ́ ká rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà ní kíkún nípasẹ̀ ìràpadà tí Jésù Kristi san. (Jer 31:33, 34; Mt 26:28; 1Kọ 11:25; Ef 1:7) Kódà nígbà tí Jésù wà láyé, ó jẹ́ kó ṣe kedere pé òun lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn jì wọ́n, nígbà tó wo ọkùnrin kan tó ní àrùn rọpárọsẹ̀ sàn.—Mt 9:2-7.

cf 183 ¶4

“Máa Bá A Lọ ní Títọ̀ Mí Lẹ́yìn”

4 Ìwé Mímọ́ ò sọ nǹkan kan fún wa nípa ìgbà tí Jésù dé ọ̀run, kò sọ bí wọ́n ṣe kí i káàbọ̀, kò sì sọ bí ayọ̀ náà ṣe pọ̀ tó nígbà tóun àti Bàbá rẹ̀ tún padà wà pa pọ̀. Ṣùgbọ́n tipẹ́tipẹ́ ni Bíbélì ti sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ sígbà tí Jésù bá padà sọ́run. Wàá rántí pé ó ju ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ táwọn Júù ti ń ṣe àjọyọ̀ mímọ́. Ní ọjọ́ kan lọ́dọọdún, àlùfáà àgbà máa ń lọ sínú ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú tẹ́ńpìlì láti wọ́n ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n fi ṣèrúbọ ní Ọjọ́ Ètùtù síwájú àpótí ẹ̀rí. Mèsáyà ni àlùfáà àgbà dúró fún ní ọjọ́ yẹn. Nígbà tí Jésù padà sọ́run, ó ṣe ohun tí àjọyọ̀ yẹn túmọ̀ sí ní ti gidi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé. Ó bọ́ síwájú ìtẹ́ Jèhófà ọlọ́lá ńlá lọ́run, ìyẹn ibi mímọ́ jù lọ ní gbogbo ayé àtọ̀run, ó sì fi ìtóye ẹbọ ìràpadà tó rú lé Bàbá rẹ̀ lọ́wọ́. (Hébérù 9:11, 12, 24) Ǹjẹ́ Jèhófà gbà á lọ́wọ́ rẹ̀?

it-2 602-603

Ìjẹ́pípé

Bí Òfin Mósè ṣe pé. Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípasẹ̀ Mósè sọ bí wọ́n ṣe ṣètò iṣẹ́ àwọn àlùfáà àti bí wọ́n á ṣe máa fi ẹran rúbọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Ọlọ́run tó gbé òfin yẹn kalẹ̀, síbẹ̀ òfin náà, àwọn àlùfáà àti ẹran tí wọ́n fi ń rúbọ kò sọ àwọn tó wà lábẹ́ Òfin yẹn di pípé gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ. (Heb 7:11, 19; 10:1) Dípò kí Òfin yẹn gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, ńṣe ló túbọ̀ mú kó ṣe kedere pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n. (Ro 3:20; 7:7-13) Kò sí àní-àní pé ètò yìí ṣàṣeparí ohun tí Ọlọ́run torí rẹ̀ gbé e kalẹ̀; torí pé Òfin yẹn ṣiṣẹ́ bí “olùkọ́” tó ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi, ó sì jẹ́ “òjìji àwọn nǹkan rere tó ń bọ̀.” (Ga 3:19-25; Heb 10:1) Torí náà, nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa “ohun tí Òfin kò lè ṣe torí pé ẹran ara kò jẹ́ kó lágbára” (Ro 8:3), ohun tó ní lọ́kàn ni pé àlùfáà àgbà (ẹni tí Òfin yàn ṣe àlùfáà láti máa rúbọ, kó sì gbé ẹ̀jẹ̀ ẹran wọ Ibi Mímọ́ Jùlọ ní Ọjọ́ Ètùtù) ò lè “gba àwọn tó ń tipasẹ̀ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run là pátápátá” bó ṣe wà nínú Hébérù 7:11, 18-28. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé báwọn àlùfáà ṣe ń rúbọ máa ń jẹ́ káwọn èèyàn náà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run, àmọ́ ìyẹn ò gbà wọ́n sílẹ̀ pátápátá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí kókó yìí nígbà tó sọ pé ẹ̀jẹ̀ ẹran tí wọ́n fi rúbọ lọ́jọ́ ètùtù “kò lè sọ àwọn tó ń wá sí tòsí di pípé,” ìyẹn ni pé, kò lè mú kí wọ́n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. (Heb 10:1-4; fi wé Heb 9:9.) Torí náà, kò ṣeé ṣe fún àlùfáà àgbà láti pèsè ìràpadà tó máa gba àwọn èèyàn sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Ìràpadà tí Jésù san àti iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà nìkan ló mú kí èyí ṣeé ṣe.—Heb 9:14; 10:12-22.

Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

w92 3/1 31 ¶4-6

Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe

Pọọlu mẹnu kan an pe iku kan ni a nilo lati fẹsẹ awọn majẹmu mulẹ laaarin Ọlọrun ati eniyan. Majẹmu Ofin jẹ́ apẹẹrẹ kan. Mose ni alárinà rẹ̀, ẹni naa ti yoo mu iṣọkan yii wá laaarin Ọlọrun ati Isirẹli nipa ti ara. Mose tipa bayii kó ipa pataki kan oun sì ni eniyan naa ti o ba awọn ọmọ Isirẹli lò nigba ti wọn ń wá sinu majẹmu naa. Mose ni a lè tipa bayii wò gẹgẹ bi olùdámájẹ̀mú eniyan ti majẹmu Ofin ti o pilẹṣẹ lọdọ Jehofa. Ṣugbọn Mose ha nilati ta ẹ̀jẹ̀ iwalaaye rẹ̀ silẹ fun majẹmu Ofin naa ki o tó wà lẹnu iṣẹ bi? Bẹẹkọ. Kaka bẹẹ awọn ẹran ni a fi rubọ, ẹ̀jẹ̀ wọn dipo ẹ̀jẹ̀ Mose.—Heberu 9:18-22.

Ki ni nipa majẹmu titun laaarin Jehofa ati orilẹ-ede Isirẹli tẹmi? Jesu Kristi ní ipa ologo ti olùṣalárinà, Alárinà naa laaarin Jehofa ati Isirẹli tẹmi. Bi o tilẹ jẹ pe Jehofa pilẹ majẹmu yii, ó sinmi lori Jesu Kristi. Yatọ si jíjẹ́ Alárinà rẹ̀, Jesu ní awọn ibalo taarata ninu ẹran ara pẹlu awọn wọnni ti a o kọkọ gbà wọnu majẹmu yii. (Luuku 22:20, 28, 29) Ju bẹẹ lọ, ó tootun lati pese ẹbọ ti a nilo lati fẹsẹ majẹmu naa mulẹ. Ẹbọ yii kii wulẹ ṣe ti awọn ẹran ṣugbọn ti iwalaaye eniyan pípé kan. Nitori naa Pọọlu lè tọka si Kristi gẹgẹ bi olùdámájẹ̀mú eniyan ti majẹmu titun. Lẹhin ti “Kristi wọle lọ . . . si ọrun funraarẹ, lati farahan nisinsinyi niwaju Ọlọrun funraarẹ alara fun wa,” majẹmu titun naa di eyi ti o fẹsẹmulẹ.—Heberu 9:12-14, 24.

Ni sisọrọ nipa Mose ati Jesu gẹgẹ bi awọn eniyan olùdámájẹ̀mú, kii ṣe pe Pọọlu ń damọran pe eyikeyii ninu wọn ti pilẹ awọn majẹmu ọtọọtọ naa, eyi ti a dá nipasẹ Ọlọrun nitootọ. Kaka bẹẹ, awọn eniyan mejeeji wọnni lọwọ jinlẹjinlẹ ninu mimu awọn majẹmu kọọkan ṣẹ gẹgẹ bi alárinà. Ati ninu ọran kọọkan, iku kan ni a nilo—awọn ẹran dipo Mose, ti Jesu sì fi ẹ̀jẹ̀ iwalaaye tirẹ̀ rubọ fun awọn wọnni ti wọn wà ninu majẹmu titun.

it-1 249-250

Ìrìbọmi

Àkọsílẹ̀ Lúùkù jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù gbàdúrà nígbà tó ń ṣèrìbọmi. (Lk 3:21) Bákan náà, ẹni tó kọ lẹ́tà sáwọn Hébérù jẹ́ ká mọ̀ pé nígbà tí Jésù “dé sí ayé” (kì í ṣe nígbà tá a bí i tí kò lè kàwé tàbí sọ̀rọ̀ yìí, ṣùgbọ́n ó jẹ́ nígbà tó ṣèrìbọmi tó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀) ó sọ ohun tó wà nínú Sáàmù 40:6-8 (LXX): “Ẹbọ àti ọrẹ kọ́ ni ohun tí o fẹ́, àmọ́ ìwọ pèsè ara kan fún mi. . . . Wò ó! Mo ti dé (a ti kọ ọ́ nípa mi sínú àkájọ ìwé) láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.” (Heb 10:5-9) Àárín àwọn Júù tí Ọlọ́run ti bá dá májẹ̀mú Òfin la bí Jésù náà sí. (Ẹk 19:5-8; Ga 4:4) Fún ìdí yìí, òótọ́ pọ́ńbélé ibẹ̀ ni pé kó tiẹ̀ tó di pé Jésù lọ bá Jòhánù kó lè ṣèrìbọmi, ni ó ti wà nínú májẹ̀mú pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run. Ohun tí Jésù sì ṣe yìí ṣe pàtàkì ju ohun tí Òfin béèrè lọ. Jésù jẹ́ kí Bàbá òun Jèhófà mọ̀ pé òun máa ṣe “ìfẹ́” rẹ̀, ó sì fi ẹ̀rí èyí hàn bó ṣe “pèsè” ara rẹ̀ fún ìrúbọ, tí ohun tó ṣe yẹn sì wọ́gi lé bí wọ́n ṣe máa ń fi ẹranko rúbọ bó ṣe wà nínú Òfin. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nípasẹ̀ “ìfẹ́” yìí, a ti fi ara Jésù Kristi tó fi rúbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé sọ wá di mímọ́.” (Heb 10:10) Ìfẹ́ Jèhófà tún ni pé kí Jésù ṣe nǹkan kan torí Ìjọba Ọlọ́run, Jésù sì ṣe nǹkan náà. (Lk 4:43; 17:20, 21) Jèhófà tẹ́wọ́ gba ohun tí Ọmọ rẹ̀ ṣe, ó sì tì í lẹ́yìn, kódà ó fi ẹ̀mí mímọ́ yàn-án, ó ní: “Ìwọ ni Ọmọ mi, àyànfẹ́; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.”—Mk 1:9-11; Lk 3:21-23; Mt 3:13-17.

Bíbélì Kíkà

SEPTEMBER 16-22

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | HÉBÉRÙ 11

“Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Ní Ìgbàgbọ́?”

w16.10 27 ¶6

Máa Lo Ìgbàgbọ́ Nínú Àwọn Ìlérí Jèhófà

6 Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ nínú Hébérù 11:1. (Kà á.) Ó jẹ́ ká mọ̀ pé orí ohun méjì tí a kò lè fojú rí ni ìgbàgbọ́ dá lé: (1) “Ohun tí a ń retí.” Lára rẹ̀ ni àwọn ohun tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú àmọ́ tí kò tíì ṣẹlẹ̀, bí ìgbà tí Ọlọ́run máa fòpin sí ìwà búburú, táá sì sọ ayé di Párádísè. (2) “Àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” Nínú ẹsẹ yìí, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ìfihàn gbangba-gbàǹgbà” túmọ̀ sí “àwọn ẹ̀rí tó dáni lójú” pé àwọn ohun tá ò lè fojú rí wà lóòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, a gbà pé Jèhófà Ọlọ́run, Jésù Kristi àtàwọn áńgẹ́lì wà, bẹ́ẹ̀ náà la sì gbà pé Ìjọba Ọlọ́run wà lẹ́nu iṣẹ́. (Héb. 11:3) Báwo la ṣe lè fi hàn pé ohun tá à ń retí ṣì wà lọ́kàn wa digbí àti pé a gba ohun tí Bíbélì sọ gbọ́ bá ò tiẹ̀ rí àwọn nǹkan ọ̀hún? Kì í ṣe pé ká kàn sọ pé a nígbàgbọ́, àmọ́ ó tún gbọ́dọ̀ hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa.

w13 11/1 11 ¶2-5

“Olùsẹ̀san fún Àwọn Tí Ń Fi Taratara Wá A”

Kí la lè ṣe láti wu Jèhófà? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wù ú dáadáa.” Kíyè sí pé, Pọ́ọ̀lù kò sọ pé ó nira láti wu Ọlọ́run láìsí ìgbàgbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wu Ọlọ́run. Ká sòótọ́, kòṣeémáàní ni ìgbàgbọ́ jẹ́ fún gbogbo ẹni tó bá fẹ́ máa ṣe ohun tó wu Ọlọ́run.

Irú ìgbàgbọ́ wo ló yẹ ká ní tí a bá fẹ́ máa ṣe ohun tó wu Jèhófà? Ìgbàgbọ́ wa nínú Ọlọ́run gbọ́dọ̀ fi ohun méjì hàn. Àkọ́kọ́, a ‘gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó wà.’ Kò sí bí a ṣe lè ṣe ohun tó wu Ọlọ́run tí a kò bá gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà. Ojúlówó ìgbàgbọ́ ju pé ká kàn gbà pé Ọlọ́run wà. Ó ṣe tán, àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbà pé Jèhófà wà. (Jákọ́bù 2:19) Ó yẹ kí ìgbàgbọ́ tí a ní nínú Ọlọ́run hàn nínú ìgbésí ayé wa, ìyẹn ni pé, àwọn ohun tá bá ń ṣe lójoojúmọ́ gbọ́dọ̀ máa fi hàn pé lóòótọ́ la gbà pé Ọlọ́run wà.—Jákọ́bù 2:20, 26.

Ìkejì, a “gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé” Ọlọ́run “ni olùsẹ̀san.” Ó máa ń dá ẹni tó ní ojúlówó ìgbàgbọ́ lójú pé gbogbo ìsapá òun láti máa ṣe ohun tó wu Ọlọ́run kò ní já sí asán. (1 Kọ́ríńtì 15:58) Kò sí bá a ṣe lè ṣe ohun tó wu Jèhófà tí kò bá dá wa lójú pé ó lágbára láti san èrè fún wa àti pé ó wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Jákọ́bù 1:17; 1 Pétérù 5:7) Ẹni tó bá sọ pé Ọlọ́run kò bìkítà nípa wa tàbí pé abara-moore jẹ ni tàbí pé kò lawọ́, kò tíì mọ Ọlọ́run.

Àwọn wo ni Jèhófà máa san èrè fún? Pọ́ọ̀lù sọ pé yóò san èrè fún “àwọn tí ń fi taratara wá a.” Ìwé kan táwọn atúmọ̀ Bíbélì máa ń ṣèwádìí nínú rẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “fi taratara wá a” kò túmọ̀ sí pé ká “jáde lọ wá nǹkan,” àmọ́, ohun tó túmọ̀ sí ni pé ká wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run, ká sì “jọ́sìn rẹ̀.” Ìwé ìwádìí míì sọ pé ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì yìí túmọ̀ sí ohun tá a fi gbogbo ara ṣe àti ohun tá a dìídì ṣe tọkàntọkàn. Ní ti gidi, Jèhófà máa ń san èrè fún àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn mú kí wọ́n máa fi ìfẹ́ àtọkànwá àti ìtara sìn ín.—Mátíù 22:37.

w16.10 23 ¶10-11

Bó O Ṣe Lè Mú Kó Túbọ̀ Dá Ẹ Lójú Pé Ìlérí Ọlọ́run Máa Ṣẹ

10 Nínú ìwé Hébérù orí 11, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa onírúurú àdánwò táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run fara dà. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan àwọn obìnrin tó nígbàgbọ́ táwọn ọmọ wọn kú, àmọ́ tí àwọn ọmọ náà tún jíǹde. Ó tún mẹ́nu ba àwọn míì tí kò “tẹ́wọ́ gba ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà kankan, kí ọwọ́ wọn lè tẹ àjíǹde tí ó sàn jù.” (Héb. 11:35) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ àwọn tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn, síbẹ̀ wọ́n sọ Nábótì àti Sekaráyà lókùúta pa torí pé wọ́n ṣègbọràn sí Ọlọ́run, wọ́n sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. (1 Ọba 21:3, 15; 2 Kíró. 24:20, 21) Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kò “tẹ́wọ́ gba ìtúsílẹ̀,” ìyẹn ni pé wọ́n yàn láti fẹ̀mí wọn wewu dípò kí wọ́n ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú agbára Ọlọ́run, èyí sì mú kí “wọ́n dí ẹnu àwọn kìnnìún,” kí ‘wọ́n sì dá ipá iná dúró’ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ.—Héb. 11:33, 34; Dán. 3:16-18, 20, 28; 6:13, 16, 21-23.

11 Wòlíì Mikáyà àti Jeremáyà fara da “ìfiṣẹlẹ́yà . . . àti ẹ̀wọ̀n” torí ìgbàgbọ́ wọn. Àwọn míì bí Èlíjà “rìn káàkiri nínú àwọn aṣálẹ̀ àti àwọn òkè ńlá àti àwọn hòrò àti àwọn ihò inú ilẹ̀.” Gbogbo wọn ló fara dà á torí pé wọ́n ní “ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí [wọ́n] ń retí.”—Héb. 11:1, 36-38; 1 Ọba 18:13; 22:24-27; Jer. 20:1, 2; 28:10, 11; 32:2.

Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

it-1 804 ¶5

Ìgbàgbọ́

Àpẹẹrẹ Àwọn Tó Nígbàgbọ́ Láyé Àtijọ́. Ohun kan ló mú kí “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tó pọ̀ gan-an” tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ wọn (Heb 12:1) nígbàgbọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó dájú pé Ébẹ́lì gbọ́ ìlérí Ọlọ́run nípa “ọmọ” tó máa fọ́ “ejò náà” ní orí. Jèhófà gégùn-ún fàwọn òbí Ébẹ́lì nígbà tí wọ́n wà ní Édẹ́nì, Ébẹ́lì sì rí bí gbogbo ẹ̀ ṣe ń ṣẹ mọ́ wọn lára. Lẹ́yìn tí wọ́n jáde kúrò ní Édẹ́nì, iṣẹ́ àṣelàágùn ni Ádámù àti ìdílé rẹ̀ máa ń ṣe kí wọ́n tó lè jẹun, torí pé Jèhófà ti gégùn-ún fún ilẹ̀ pé ẹ̀gún àti òṣùṣú lá máa hù. Ó ṣeé ṣe kí Ébẹ́lì tí rí bí ọkàn Éfà ṣe ń fà sí ọkọ rẹ̀ àti bí Ádámù ṣe ń jọba lé e lórí. Kò sí àní-àní pé Ébẹ́lì ti máa gbọ́ nípa ìrora tí ìyá rẹ̀ máa ń ní nígbà tó bá fẹ́ bímọ. Bákan náà, ó rí àwọn kérúbù tí wọ́n ń ṣọ́ àbáwọlé ọgbà Édẹ́nì pẹ̀lú idà oníná. (Jẹ 3:14-19, 24) Gbogbo “ẹ̀rí tó dájú” yìí ló mú kí Ébẹ́lì nígbàgbọ́ pé Ọlọ́run máa gbà wá sílẹ̀ nípasẹ̀ ‘ọmọ tó ṣèlérí.’ Ìgbàgbọ́ yìí ló mú kí “Ébẹ́lì rú ẹbọ tó níye lórí ju ti Kéènì lọ sí Ọlọ́run.”—Heb 11:1, 4.

wp17.1 12-13

“Ó Ti Wu Ọlọ́run Dáadáa”

Ó dáa, báwo ni Ọlọ́run ṣe ṣí Énọ́kù nípò pa dà tó fi jẹ́ pé kò rí ikú”? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Jèhófà rọra mú kí Énọ́kù sùn kó sì gba ibẹ̀ kú láìjẹ ìrọra kankan. Àmọ́ kí Énọ́kù tó kú, Ọlọ́run jẹ́ kó yé e pé, ‘ó ti wu òun dáadáa.’ Báwo nìyẹn ṣe ṣẹlẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣáájú kí Énọ́kù tó kú, Ọlọ́run jẹ́ kó rí bí ayé ṣe máa rí lẹ́yìn tó bá di Párádísè. Énọ́kù sùn nínú oorun ikú lẹ́yìn tó rí ẹ̀rí tó ṣe kedere pé Jèhófà tẹ́wọ́ gba òun. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ nípa Énọ́kù àtàwọn olóòótọ́ míì lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ó sọ pé: “Gbogbo àwọn wọ̀nyí kú nínú ìgbàgbọ́.” (Hébérù 11:13) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn èèyàn burúkú yẹn wá òkú Énọ́kù, àmọ́ wọn ‘kò rí i níbi kankan.’ Jèhófà kò jẹ́ káwọn èèyànkéèyàn náà rí òkú Énọ́kù kí wọ́n má bàa fi òkú rẹ̀ gbé ìjọsìn èké lárugẹ.

Bíbélì Kíkà

SEPTEMBER 23-29

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | HÉBÉRÙ 12-13

“Ìbáwí Máa Ń Fi Hàn Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa”

w12 3/15 29 ¶18

Ẹ Má Ṣe Wo “Àwọn Ohun Tí Ń bẹ Lẹ́yìn”

18 Ìbáwí tó dùn wá gan-an. Tá a bá wá bẹ̀rẹ̀ sí í bínú nítorí ìbáwí tí wọ́n fún wa ńkọ́? Èyí lè dùn wá gan-an, ó lè mú ká banú jẹ́, kó sì mú ká “rẹ̀wẹ̀sì.” (Héb. 12:5) Yálà a kọ ìbáwí náà torí pé a “fi ojú kékeré” wò ó tàbí ńṣe la “rẹ̀wẹ̀sì” lẹ́yìn tá a gbà á, tí a kò sì fi sílò, ohun kan náà ló máa ń yọrí sí, ìbáwí náà kò ní ṣe wá láǹfààní tàbí kó mú ká ṣàtúnṣe. Ẹ ò rí i pé ó dára gan-an ká fi ọ̀rọ̀ Sólómọ́nì sílò, ó sọ pé: “Di ìbáwí mú; má ṣe jẹ́ kí ó lọ. Fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ, nítorí òun ni ìwàláàyè rẹ.” (Òwe 4:13) Bíi ti awakọ̀ tó ń tẹ̀ lé àwọn àmì ojú ọ̀nà, ẹ jẹ́ ká máa gba ìbáwí, ká máa fi í sílò, ká sì máa bá ìgbésí ayé wa lọ.—Òwe 4:26, 27; ka Hébérù 12:12, 13.

w12 7/1 21 ¶3

“Nígbàkigbà Tí Ẹ Bá Ń Gbàdúrà, Ẹ Wí Pé, ‘Baba’ ”

Baba onífẹ̀ẹ́ máa ń bá àwọn ọmọ rẹ̀ wí torí ó fẹ́ kí ayé wọn dáa lọ́jọ́ ọ̀la. (Éfésù 6:4) Kò ní gba ìgbàkugbà láyè, àmọ́ kò ní fi ọwọ́ tó le koko jù bá àwọn ọmọ rẹ̀ wí. Bákàn náà, nígbà míì, Baba wa ọ̀run máa ń bá wa wí tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ṣá, ìfẹ́ ni Ọlọ́run fi máa ń bá wa wí, kì í bá wa wí lọ́nà ìkà. Jésù náà ṣe bíi ti Baba rẹ̀, kò fi ọwọ́ tó le koko mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kódà nígbà tí wọn kò tètè ṣe àtúnṣe lórí ohun tó ti sọ fún wọn.—Mátíù 20:20-28; Lúùkù 22:24-30.

w18.03 32 ¶18

‘Fetí sí Ìbáwí Kó O sì Di Ọlọ́gbọ́n’

18 Òótọ́ ni pé ìbáwí máa ń dunni, àmọ́ téèyàn ò bá gba ìbáwí, ohun tó máa ń yọrí sí máa ń burú jùyẹn lọ. (Héb. 12:11) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Kéènì àti Ọba Sedekáyà. Nígbà tí Kéènì kórìíra Ébẹ́lì débi pé ó ń ronú bó ṣe máa pa á, Ọlọ́run gbà á níyànjú pé: “Èé ṣe tí ìbínú rẹ fi gbóná, èé sì ti ṣe tí ojú rẹ fi rẹ̀wẹ̀sì? Bí ìwọ bá yíjú sí ṣíṣe rere, ara rẹ kò ha ní yá gágá bí? Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá yíjú sí ṣíṣe rere, ẹ̀ṣẹ̀ lúgọ sí ẹnu ọ̀nà, ìfàsí-ọkàn rẹ̀ sì wà fún ọ; ní tìrẹ, ìwọ yóò ha sì kápá rẹ̀ bí?” (Jẹ́n. 4:6, 7) Kéènì ò tẹ́tí sí Jèhófà, ó kó sínú ẹ̀ṣẹ̀ náà, jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ ló sì fi jìyà ohun tó ṣe yẹn. (Jẹ́n. 4:11, 12) Ká sọ pé ó gba ìbáwí tí Jèhófà fun un ni, kò bá má jìyà tóyẹn.

Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

w11 9/15 17-18 ¶11

Ẹ Fi Ìfaradà Sá Eré Ìje Náà

11 Àwọn tó para pọ̀ di “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀” yìí kì í ṣe òǹwòran lásán tàbí ẹni tó wulẹ̀ dúró sítòsí pápá, tá a lè sọ pé ó wá síbẹ̀ torí àtiwo eré ìje tàbí torí àtiwo bí sárésáré tàbí àwùjọ àwọn olùdíje tó yàn láàyò ṣe máa borí. Ńṣe làwọn náà kópa nínú rẹ̀ bí àwọn sárésáré ṣe máa ń ṣe nínú eré ìje. Wọ́n sì ti sá eré ìje náà dópin. Àmọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kú báyìí, a lè máa fojú inú wò ó pé wọ́n jẹ́ sárésáré tó pegedé, wọ́n sì lè jẹ́ ìṣírí fún àwọn sárésáré tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ eré ìje náà. Ronú nípa bó ṣe máa rí lára sárésáré kan tó bá mọ̀ pé díẹ̀ lára àwọn sárésáré tó pegedé jù lọ wà yí òun ká tí wọ́n ń wo òun. Ṣé ìyẹn ò ní mú kó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe tàbí kó tiẹ̀ ṣe ju ohun tágbára rẹ̀ gbé lọ? Àwọn ẹlẹ́rìí ayé ọjọ́un lè jẹ́rìí sí i pé bó ti wù kí eré ìṣàpẹẹrẹ yẹn máa tánni lókun tó, èèyàn lè borí. Torí náà, bí àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù ní ọ̀rúndún kìíní ṣe ń fi àpẹẹrẹ “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí” yìí sọ́kàn, wọ́n ń ní ìgboyà, wọ́n ń “fi ìfaradà sá eré ìje” náà, àwa náà sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí.

w89 12/15 22 ¶10

Rú Awọn Ẹbọ Tí Wọn Dùnmọ́ Jehofah Nínú

10 Nitori-naa awọn Hebrew wàlábẹ́-ọ̀ranyàn lati yẹra fun didi ‘ẹniti a gbá lọ nipasẹ oniruuru awọn ẹ̀kọ́ àjèjì’ ti awọn onisin Jew. (Galatia 5:1-6) Kì í ṣe nipasẹ irúfẹ́ awọn ẹ̀kọ́ bẹẹ bikose ‘nipasẹ inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run ni a fi lè fún ọkàn-àyà ní ìfìdímúlẹ̀gbọnyin’ lati lè fẹsẹ̀múlẹ̀ṣinṣin dúró-títílọ nínú otitọ. Ó hàn gbangba-kedere pé awọn kan jiyàn nipa awọn ounjẹ ati ẹbọ, nitorí Pọ́ọ̀lù sọ pé ọkàn-àyà ni a kò múfìdímúlẹ̀gbọnyin ‘nipa ohun-ṣiṣeéjẹ, nipa eyiti awọn wọnni tí wọn mú-ọwọ́-dí-jọjọ ninu wọn kò jèrè-àǹfààní.’ Awọn èrè-àǹfààní tẹ̀mí máa ń jẹyọ lati inú ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run ati imọriri fun irapada naa, kìí ṣe lati inú ìdàníyàn aláìyẹ nipa jíjẹ awọn ounjẹ kan báyìí ati kíkíyèsípa awọn ọjọ́ pàtàkì kan mọ́. (Rome 14:5-9) Jù-bẹ́ẹ̀-lọ, ẹbọ Kristi sọ awọn ẹbọ ọmọ Levi di aláàgbéṣẹ́.—Hebrew 9:9-14; 10:5-10.

it-1 629

Ìbáwí

Ìdí Tí Jèhófà fi Ń Báni Wí. Ìfẹ́ tí Jèhófà ní fún àwọn èèyàn rẹ̀ ló ṣe máa ń bá wọn wí. (Owe 3:11, 12) Àwọn ìtọ́ni tó fún wọn ló máa ń tọ́ wọ́n sọ́nà láti ní èrò tó tọ́, ó máa ń tún èrò wọn ṣe àti bí wọ́n ṣe ń ṣe nǹkan. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà ayé Mósè máa ń rí ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run, èyí jẹ́ ọ̀nà kan tí Jèhófà máa ń gbà bá wọn wí. Wọ́n rí oríṣiríṣi ọ̀nà àrà tí Jèhófà gbà mú ìdájọ́ wá sórí àwọn òòṣà ilẹ̀ Íjíbítì, bó ṣe dá wọn sílẹ̀ lómìnira, tó sì pa àwọn ọmọ ogun Íjíbítì sínú Òkun Pupa. Ọ̀nà tó ń báni lẹ́rù tún ni Jèhófà gbà mú ìdájọ́ wá sórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ya ọlọ̀tẹ̀. Jèhófà tún pèsè oúnjẹ àti omi fún wọn lọ́nà ìyanu, ó sì fìyẹn tẹ̀ ẹ́ mọ́ wọn lọ́kàn pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa ṣe gbogbo ohun tí òun bá sọ. Kí nìdí tí Jèhófà fi bá wọn wí láwọn ọ̀nà yìí? Ó ṣe bẹ́ẹ̀ kó lè rẹ̀ wọ́n wálẹ̀, kí wọ́n lè mọ̀ pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa bẹ̀rù òun, ó sì fẹ́ kí wọ́n nígbàgbọ́, kí wọ́n sì máa ṣègbọràn sí òun.—Di 8:3-5; 11:2-7.

Lọ́pọ̀ ìgbà, Jèhófà máa ń ló àwọn tó ń múpò iwájú láti bá àwọn èèyàn rẹ̀ wí. Tí ọmọ Ísírẹ́lì kán bá parọ́ mọ́ ìyàwó ẹ̀ pé ó tí ní ìbálòpọ̀ kí òun tó fẹ́ ẹ, àwọn àgbààgbà ìlú tí Jèhófà yan ṣe onídàájọ́ máa bá a wí. (Di 22:13-19) Tí àwọn òbí bá ń bá àwọn ọmọ wọn wí lọ́nà tó yẹ, Jèhófà ni wọ́n ń ṣojú fún. Ó sì yẹ káwọn ọmọ mọ̀ pé àwọn òbí àwọn ń bá àwọn wí torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ wọn, wọ́n sì fẹ́ káyé àwọn dáa. (Owe 1:8; 4:1, 13; 6:20-23; 13:1, 24; 15:5; 22:15; 23:13, 14; Ef 6:4) Nínú ìjọ, àwọn alàgbà máa ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run báni wí, wọ́n fí ń gbani nímọ̀ràn, wọ́n sì fi ń gbani níyànjú tàbí kí wọ́n fi tún èrò àwọn míì ṣe. (2Ti 3:16) Tí Kristẹni kan bá ṣàṣìṣe, Jèhófà ṣètò pé kí wọ́n bá a wí, kó lè yí pa dà, kó má báa ní ìpín nínú ìdájọ́ tó ń bọ̀ lórí àwọn èèyàn burúkú. (1Kọ 11:32) Jésù Kristi ni orí ìjọ Kristẹni, ìfẹ́ tó sì ní fún wa ló ń jẹ́ kó bá wa wí lásìkò tó yẹ.—Ifi 3:14, 19.

Irúfẹ́ ìbáwí kan tó le, ni kí wọ́n yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́ nínú ìjọ. Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fún Híméníọ́sì àti Alẹkisáńdà nìyẹn torí pé ó “fi wọ́n lé Sátánì lọ́wọ́.” (1Ti 1:20) Bí wọ́n ṣe yọ wọ́n lẹ́gbẹ́ nínú ìjọ, ṣe ni wọ́n pa dà sínú ayé tó wà lábẹ́ àkóso Sátánì.—1Kọ 5:5, 11-13.

Nígbà míì, Jèhófà máa ń fàyè gbà á káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kojú inúnibíni. Ìdí ni pé inúnibíni lè mú kí wọ́n túbọ̀ lókun nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì láwọn ànímọ́ míì tó máa ṣe wọ́n láǹfààní nígbà tí inúnibíni náà bá dópin. (Heb 12:4-11) Kódà Jèhófà fàyè gbà á kí Ọmọ Rẹ̀ kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro, èyí sì mú kó túbọ̀ lójú àánú, kó sì di àlùfáà àgbà tó lẹ́mìí ìbánikẹ́dùn.—Heb 4:15.

Bíbélì Kíkà

SEPTEMBER 30–OCTOBER 6

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÁKỌ́BÙ 1-2

“Ohun Tó Ń Fa Ẹ̀ṣẹ̀ àti Ikú”

g17.4 14

Ìdẹwò

Ìdẹwò ni kí ọkàn èèyàn máa fà sí nǹkan kan, pàápàá ohun tí kò dára. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o wà nínú ilé ìtajà kan, o sì rí ohun kan tó wọ̀ ẹ́ lójú. Ó ṣe ẹ́ bíi pé kó o jí i, o sì mọ̀ pé kò sẹ́nì kankan tó máa mọ̀. Àmọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ ń sọ fún ẹ pé kó o má ṣe jí i! Lo bá gbé èrò burúkú náà kúrò lọ́kàn, o sì bá tìẹ lọ. Bó o ṣe borí ìdẹwò nìyẹn tó o sì di aṣẹ́gun.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ti pé nǹkan kan jẹ́ ìdẹwò fún ẹnì kan, ìyẹn ò sọ ọ́ di èèyàn burúkú. Bíbélì sọ pé gbogbo wa la máa ń kojú ìdẹwò. (1 Kọ́ríńtì 10:13) Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì ni ohun tá a ṣe nígbà ìdẹwò náà. Àwọn kan máa ń gba èròkérò náà láyè, tí wọ́n á sì kó wọnú ìdẹwò. Àwọn míì máa ń tètè gbé e kúrò lọ́kàn.

“Olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀.”—Jákọ́bù 1:14.

g17.4 14

Ìdẹwò

Bíbélì ṣàlàyé àwọn nǹkan tó máa ń mú kí èèyàn hùwà tí kò tọ́. Jákọ́bù 1:15 sọ pé: “Ìfẹ́-ọkàn náà [ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́], nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀.” Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé tí ẹnì kan bá ń ro èròkérò ṣáá, ọjọ́ kan ń bọ̀ tó máa ṣe ohun tó ń rò lọ́kàn yẹn, bó ṣe jẹ́ pé bó pẹ́, bó yá aboyún máa bí ọmọ tó wà ní ikún rẹ̀. Àwọn nǹkan kan wà tá a lè ṣe kí èròkérò má bàa sọ wá di ẹrú. Ó dájú pé a lè ṣẹ́gun èròkérò.

Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

it-2 253-254

Ìmọ́lẹ̀

Jèhófà ni “Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá.” (Jem 1:17) Kì í ṣe pé ó kàn jẹ́ “Ẹni tó ń mú kí oòrùn máa tan ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán” nìkan, tó tún “ṣe òfin pé kí òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ máa tàn ní òru” (Jer 31:35) òun náà ló tún jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ tàn sí òye wa nípa tẹ̀mí. (2Kọ 4:6) Òfin rẹ̀, ìdájọ́ rẹ̀ àti ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo àwọn tó bá fi ara wọn sílẹ̀ fún un. (Sm 43:3; 119:105; Owe 6:23; Ais 51:4) Onísáàmù náà sọ pé: “Ipasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ ni a fi lè rí ìmọ́lẹ̀.” (Sm 36:9; fi wé Sm 27:1; 43:3.) Bí ìmọ́lẹ̀ oòrùn ṣe máa ń mọ́lẹ̀ sí i láti àárọ̀ “títí di ọ̀sán gangan,” bẹ́ẹ̀ náà ni òye Ọlọ́run ṣe máa ń mú kí ipa ọ̀nà àwọn olódodo túbọ̀ máa mọ́lẹ̀ sí i. (Owe 4:18) Ohun tó túmọ̀ sí láti máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ ni pé kéèyàn máa rìn ní ipa ọ̀nà tí Jèhófà fi lélẹ̀. (Ais 2:3-5) Lọ́wọ́ kejì, tí ẹnì kan bá ń fojú burúkú wo nǹkan tàbí tó ń ní èrò tí kò dáa, irú ẹni bẹ́ẹ̀ wà nínú òkùnkùn biribiri nípa tẹ̀mí. Bí Jésù ṣe sọ ọ́ ló rí: “Tí ojú rẹ bá ń ṣe ìlara, gbogbo ara rẹ máa ṣókùnkùn. Tó bá jẹ́ òkùnkùn ni ìmọ́lẹ̀ tó wà nínú rẹ lóòótọ́, òkùnkùn yẹn mà pọ̀ o!”—Mt 6:23; fi wé Di 15:9; 28:54-57; Owe 28:22; 2Pe 2:14.

it-2 222 ¶4

Òfin

“Ọba Òfin.” Ipò tí ọba máa ń wà ga ju tàwọn ará ìlú lọ, irú ipò yìí ni “ọba òfin” wà sí àwọn òfin tó kù. (Jem 2:8) Kókó inú Májẹ̀mú Òfin ni ìfẹ́; “kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ” (ọba òfin) ni òfin kejì tí gbogbo Òfin àti àwọn Wòlíì rọ̀ mọ́. (Mt 22:37-40) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa Kristẹni ò sí lábẹ́ Òfin Mósè, a wà lábẹ́ òfin Jèhófà ọba wa àti Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀, tí Jèhófà yàn ṣe ọba, ní ìsopọ̀ pẹ̀lú májẹ̀mú tuntun.

Bíbélì Kíkà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́