Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka Sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
OCTOBER 7-13
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÉMÍÌSÌ 3-5
“Máa Fi Ọgbọ́n Ọlọ́run Ṣèwà Hù”
Ǹjẹ́ Ò Ń Lo “Ọgbọ́n Tí Ó Wá Láti Òkè” Nígbèésí Ayé Rẹ?
9 “A kọ́kọ́ mọ́ níwà.” Láti mọ́ níwà túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ onínú mímọ́ àti ẹni tí kì í hùwà ìbàjẹ́, kì í ṣe ní gbangba nìkan o, ṣùgbọ́n níkọ̀kọ̀, lọ́kàn ara rẹ̀ pẹ̀lú. Bíbélì so ọgbọ́n pọ̀ mọ́ ọkàn ẹni, àmọ́ ọgbọ́n àtọ̀runwá ò lè wọnú ọkàn tí àwọn èrò burúkú, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìwàkiwà ti sọ dìbàjẹ́. (Òwe 2:10; Mátíù 15:19, 20) Ṣùgbọ́n tí ọkàn wa bá mọ́, ìyẹn títí dé ìwọ̀n tí agbára èèyàn aláìpé mọ, a óò máa ‘yí padà kúrò nínú ohun búburú, a óò sì máa ṣe rere.’ (Sáàmù 37:27; Òwe 3:7) Ǹjẹ́ kò bá a mu pé mímọ́ níwà ni a kọ́kọ́ mẹ́nu kàn nínú àwọn ànímọ́ ọgbọ́n? Àbí, tí a kò bá jẹ́ mímọ́ ní ìwà àti nípa tẹ̀mí, ṣé àá lè gbé àwọn ànímọ́ yòókù lára ọgbọ́n tó ti òkè wá yọ lóòótọ́?
10 “Lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà.” Ọgbọ́n àtọ̀runwá máa ń mú ká máa lépa àlàáfíà, èyí tó jẹ́ ara èso ẹ̀mí Ọlọ́run. (Gálátíà 5:22) A ó máa sapá láti yẹra fún bíba ‘ìdè àlàáfíà’ tó ń so àwọn èèyàn Jèhófà pọ̀ ṣọ̀kan jẹ́. (Éfésù 4:3) A óò tún máa sapá gidigidi láti rí i pé àlàáfíà pa dà jọba tí ohunkóhun bá dà á rú. Kí nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì? Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ . . . ní gbígbé pẹ̀lú ẹ̀mí àlàáfíà; Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín.” (2 Kọ́ríńtì 13:11) Bí a bá ti lè máa bá a nìṣó láti gbé ní ẹ̀mí àlàáfíà, Ọlọ́run àlàáfíà yóò máa wà pẹ̀lú wa. Irú ìwà tá à ń hù sí àwọn tá a jọ ń jọ́sìn ń nípa lórí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà. Nítorí náà, báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà? Wo àpẹẹrẹ kan.
Ǹjẹ́ Ò Ń Lo “Ọgbọ́n Tí Ó Wá Láti Òkè” Nígbèésí Ayé Rẹ?
12 “Ó ń fòye báni lò.” Kí ni fífòye báni lò túmọ̀ sí? Àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ sọ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tá a tú sí “fòye báni lò” nínú Jákọ́bù 3:17 ṣòro túmọ̀ gan-an ni. Àwọn atúmọ̀ èdè lo àwọn ọ̀rọ̀ bí “ìwà pẹ̀lẹ́,” “ìpamọ́ra,” àti “ìgbatẹnirò” láti fi túmọ̀ rẹ̀. Ní ṣáńgílítí, ohun tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí túmọ̀ sí ni “mọwọ́ yí pa dà.” Báwo la ṣe lè fi hàn pé ànímọ́ yìí nínú ọgbọ́n tó wá láti òkè ń ṣiṣẹ́ nínú wa?
Ǹjẹ́ Ò Ń Lo “Ọgbọ́n Tí Ó Wá Láti Òkè” Nígbèésí Ayé Rẹ?
14 “Ó múra tán láti ṣègbọràn.” Yàtọ̀ síbí, kò síbòmíràn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tí wọ́n tún ti lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ó múra tán láti ṣègbọràn” yìí. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ ṣe wí, “àárín àwùjọ àwọn ológun ni wọ́n ti sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí.” Ó wé mọ́ ti pé ká jẹ́ ẹni “tó rọrùn láti pàrọwà fún,” àti “onítẹríba.” Ẹni tí ọgbọ́n tó wá láti òkè bá ń darí lóòótọ́ máa ń múra tán láti juwọ́ sílẹ̀ fún ohun tí Ìwé Mímọ́ wí. Kò ní jẹ́ ẹni tá a mọ̀ sí ẹni tó ń ta kú sórí ìpinnu tó ti ṣe bí ẹ̀rí tiẹ̀ fi hàn pé kò tọ̀nà. Kàkà bẹ́ẹ̀, kíá ló máa ń yí padà bí a bá ti fẹ̀rí tó dájú hàn án látinú Ìwé Mímọ́ pé ibi tó fojú sí ọ̀nà ò gbabẹ̀ tàbí pé èrò rẹ̀ ò tọ̀nà. Ṣé irú ẹni táwọn èèyàn mọ̀ ọ́ sí nìyẹn?
“Ó Kún fún Àánú àti Àwọn Èso Rere”
15 “Ó kún fún àánú àti àwọn èso rere.” Àánú jẹ́ apá pàtàkì nínú ọgbọ́n tó wá láti òkè, nítorí a sọ pé irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ “kún fún àánú.” Ṣàkíyèsí pé a mẹ́nu kan “àánú” àti “èso rere” pa pọ̀. Ó bá a mu bẹ́ẹ̀ nítorí pé nínú Bíbélì, àánú sábà máa ń tọ́ka sí àníyàn tó ń súnni ṣe nǹkan kan nípa ọ̀ràn ọmọnìkejì ẹni, àti ìyọ́nú tó ń súnni ṣoore lónírúurú ọ̀nà. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé àánú túmọ̀ sí “kíkẹ́dùn nípa ìyọnu tó bá ọmọnìkejì ẹni, kéèyàn sì gbìyànjú láti ṣe nǹkan nípa rẹ̀.” Nípa bẹ́ẹ̀, ọgbọ́n Ọlọ́run kì í ṣe ọ̀dájú tàbí aláìláàánú, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe èrò orí lásán. Dípò bẹ́ẹ̀ ó nínúure, ó ń ti ọkàn wá, ó sì ń gba tẹni rò. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ aláàánú èèyàn?
Ǹjẹ́ Ò Ń Lo “Ọgbọ́n Tí Ó Wá Láti Òkè” Nígbèésí Ayé Rẹ?
18 “Kì í ṣe àwọn ìyàtọ̀ olójúsàájú.” Ọgbọ́n Ọlọ́run máa ń borí ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti fífi orílẹ̀-èdè ẹni ṣe fọ́ńté. Bí irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ bá ń darí wa, a ó sapá láti fa ẹ̀mí ìṣègbè tu pátápátá lọ́kàn wa. (Jákọ́bù 2:9) A ò ní ṣojúsàájú sí àwọn kan nítorí ipò wọn gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé, bí wọ́n ṣe rí jájẹ sí, tàbí ẹrù iṣẹ́ wọn nínú ìjọ; bẹ́ẹ̀ ni a ò ní fojú pa olùjọsìn bí i tiwa rẹ́ bó ti wù kó dà bí pé wọ́n tálákà tó. Bí Jèhófà bá lè ka irú àwọn bẹ́ẹ̀ sẹ́ni tó yẹ fún ìfẹ́ òun, dájúdájú, ó yẹ kí àwa náà lè kà wọ́n yẹ fún ìfẹ́ tiwa pẹ̀lú.
19 “Kì í ṣe àgàbàgebè.” Ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tá a tú sí “àgàbàgebè” lè tọ́ka sí “òṣèré orí ìtàgé kan tó máa ń gbé ìṣe ẹlòmíràn wọ̀.” Láyé àtijọ́, àwọn ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì àti ti Róòmù tó jẹ́ òṣèré sábà máa ń lo ìbòjú ńlá nígbà tí wọ́n bá ń ṣeré. Bí ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a túmọ̀ sí “àgàbàgebè” ṣe wá di ohun tá à ń lò fún ẹní bá ń díbọ́n tàbí ẹni tó ń tanni jẹ nìyẹn. Yàtọ̀ sí pé ó yẹ kí apá yìí lára ọgbọ́n Ọlọ́run kan ìwà tá à ń hù sí àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa, ó yẹ kó nípa lórí irú ojú tá a fi ń wò wọ́n.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jákọ́bù, Ìwé Pétérù Kìíní àti Pétérù Kejì
4:5—Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ni Jákọ́bù fà yọ níbí yìí? Kì í ṣe pé Jákọ́bù fa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan yọ ní pàtó. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí gbólóhùn tí Ọlọ́run mí sí tó sọ yẹn jẹ́ kókó inú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Jẹ́nẹ́sísì 6:5; 8:21; Òwe 21:10 àti Gálátíà 5:17.
Ìgbàgbọ́ Ń jẹ́ Kí A Mú Sùúrù, Kí A Sì Kún fún Àdúrà
8 Ẹ̀ṣẹ̀ ni láti sọ̀rọ̀ lòdì sí onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni. (Jákọ́bù 4:11, 12) Síbẹ̀, àwọn kan ń ṣe lámèyítọ́ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn, bóyá nítorí ẹ̀mí ìrònú jíjẹ́ olódodo lójú ara wọn tàbí nítorí pé wọ́n fẹ́ gbé ara wọn ga nípa títẹ́ńbẹ́lú àwọn ẹlòmíràn. (Orin Dáfídì 50:20; Òwe 3:29) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a túmọ̀ sí ‘sọ̀rọ̀ lòdì sí’ tọ́ka sí ẹ̀tanú, ó sì dọ́gbọ́n túmọ̀ sí ẹ̀sùn tí a fẹ̀ lójú tàbí ẹ̀sùn èké. Èyí jẹ́ dídá arákùnrin lẹ́jọ́ lọ́nà tí kò bára dé. Báwo ni èyí ṣe jẹ́ ‘sísọ̀rọ̀ lòdì sí òfin Ọlọ́run àti dídá a lẹ́jọ́’? Tóò, àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí ‘fi ọgbọ́n féfé pa àṣẹ Ọlọ́run tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan’ wọ́n sì ń fi ọ̀pá ìdiwọ̀n tiwọn dájọ́. (Máàkù 7:1-13) Lọ́nà tí ó jọra, bí a bá dá arákùnrin kan lẹ́bi tí ó sì jẹ́ pé Jèhófà kì yóò dá a lẹ́bi, a kò ha ti ‘ń dá òfin Ọlọ́run lẹ́jọ́’ tí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ń dọ́gbọ́n sọ pé òfin náà kò pegedé bí? Bí a bá sì ń ṣe lámèyítọ́ arákùnrin wa lọ́nà tí kò tọ́, a kì yóò mú òfin ìfẹ́ ṣẹ.—Róòmù 13:8-10.
Bíbélì Kíkà
OCTOBER 14-20
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 PÉTÉRÙ 1–2
“Ẹ Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Mímọ́”
Ìràpadà “Ọrẹ Pípé” Tí Baba Fún Wa
5 Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ orúkọ Jèhófà? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa ìwà wa. Jèhófà ní ká jẹ́ mímọ́. (Ka 1 Pétérù 1:15, 16.) Èyí gba pé ká jọ́sìn Jèhófà nìkan ṣoṣo, ká sì máa fi gbogbo ọkàn wa tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀. Táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń ṣenúnibíni sí wa, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti pa àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà mọ́. Bá a ṣe ń hùwà mímọ́, ṣe là ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa máa tàn, tá a sì ń tipa bẹ́ẹ̀ bọlá fún orúkọ Jèhófà. (Mát. 5:14-16) Torí pé a jẹ́ èèyàn Jèhófà, ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbé ayé wa fi hàn pé àwọn òfin Jèhófà ṣàǹfààní àti pé irọ́ ni ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Jèhófà. Nítorí àìpé wa, gbogbo wa la máa ń ṣàsìṣe. Tó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká ronú pìwà dà tọkàntọkàn, ká sì jáwọ́ nínú ìwà èyíkéyìí tó lè tàbùkù sórúkọ Jèhófà.—Sm. 79:9.
Bó O Ṣe Lè Yan Eré Ìnàjú Tó Gbámúṣé
6 Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù níyànjú pé: “Ẹ má ṣe máa bá a lọ ní jíjọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara yín fún ẹ̀ṣẹ̀.” Pọ́ọ̀lù tún sọ fún wọn pé kí wọ́n “fi ikú pa àwọn ìṣe ti ara.” (Róòmù 6:12-14; 8:13) Nínú lẹ́tà tó kọ́kọ́ kọ sí wọn, ó fún wọn ní àpẹẹrẹ irú “àwọn ìṣe ti ara” bẹ́ẹ̀. A kà nípa aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ pé: “Ẹnu wọ́n sì kún fún ègún.” “Ẹsẹ̀ wọ́n yára kánkán láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.” “Kò sí ìbẹ̀rù Ọlọ́run níwájú wọn.” (Róòmù 3:13-18) Bí Kristẹni kan bá ń lo “àwọn ẹ̀yà ara” ẹ̀ láti dẹ́ṣẹ̀ nípa híhu irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀, ó máa sọ ara ẹ̀ di èyí tó ní àléébù. Bí àpẹẹrẹ, bí Kristẹni kan lóde òní bá ń mọ̀ọ́mọ̀ wo àwòrán rádaràda tí ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe tàbí tó ń wo ìwà ipá tí ẹ̀jẹ̀ ti ń ṣàn bí omi, ńṣe ni irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń ‘jọ̀wọ́ ojú rẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀,’ tó sì ń ba gbogbo ara rẹ̀ jẹ́. Ìjọsìn èyíkéyìí tó bá ṣe kì í ṣe ẹbọ mímọ́ mọ́, Ọlọ́run ò sì ní í tẹ́wọ́ gbà á. (Diutarónómì 15:21; 1 Pétérù 1:14-16; 2 Pétérù 3:11) Ẹ ò rí i pé ìyọnu ńlá gbáà ni fẹ́ni tó bá ń lọ́wọ́ sí eré ìnàjú tí kò gbámúṣé!
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jákọ́bù, Ìwé Pétérù Kìíní àti Pétérù Kejì
1:10-12. Àwọn áńgẹ́lì ń fẹ́ láti wo àwòfín àwọn ohun ìjìnlẹ̀ táwọn wòlíì Ọlọ́run ti kọ nígbà àtijọ́ nípa ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kí wọ́n lè lóye rẹ̀. Àmọ́, ìgbà tí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìjọ Kristẹni làwọn òtítọ́ wọ̀nyí wá ṣe kedere. (Éfé. 3:10) Ṣé kò yẹ káwa náà máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn áńgẹ́lì, ká máa sapá láti wádìí “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run”?—1 Kọ́r. 2:10.
it-2 565 ¶3
Alábòójútó
Alábòójútó Gíga Jù Lọ. Láìsí tàbí ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ inú Àìsáyà 53:6 ni Pétérù fà yọ nínú 1 Pétérù 2:25 nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ‘dà bí àwọn àgùntàn tó sọnù,’ ó wá fi kún un pé: “Àmọ́ ẹ ti wá pa dà sọ́dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn àti alábòójútó ọkàn yín.” Kò sí àní-àní pé Jèhófà Ọlọ́run ni Pétérù ń tọ́ka sí níbi, torí kì í ṣe pé àwọn tó ń sọ̀rọ̀ nípa wọn ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ Jésù Kristi, àmọ́ nípasẹ̀ rẹ̀, a ti ṣamọ̀nà wọn pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà tó jẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn Gíga Jù Lọ fáwọn èèyàn rẹ̀. (Sm 23:1; 80:1; Jer 23:3; Isk 34:12) Jèhófà tún jẹ́ alábòójútó ní ti pé ó máa ń ṣe ìbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀. (Sm 17:3) Ìbẹ̀wò yìí (e·pi·sko·peʹ lédè Gíríìkì) lè tọ́ka sí ìgbà tó bá mú ìdájọ́ wá sórí àwọn tí kò ṣèfẹ́ rẹ̀. Àpẹẹrẹ kan lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, ìdí sì ni pé kò fi òye mọ àkókò tí a máa ‘bẹ̀ ẹ́ wò [e·pi·sko·pesʹ lédè Gíríìkì].’ (Lk 19:44) Ó sì lè tọ́ka sí ìgbà tí Ọlọ́run ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ kó lè bù kún wọn, àpẹẹrẹ kan ni ìgbà tàwọn èèyàn ń yin Ọlọ́run lógo lọ́jọ́ “àbẹ̀wò rẹ̀ [e·pi·sko·pesʹ lédè Gíríìkì].”—1Pe 2:12.
Bíbélì Kíkà
OCTOBER 21-27
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 PÉTÉRÙ 3-5
“Òpin Ohun Gbogbo Ti Sún Mọ́lé”
“Ẹ Wà Lójúfò Kí Ẹ Lè Máa Gbàdúrà”
ỌKÙNRIN kan tó ti ṣiṣẹ́ alẹ́ rí sọ pé: “Béèyàn bá ṣiṣẹ́ lóru, ọwọ́ ìdájí ni ìgbà tó máa ń ṣòro jù láti wà lójúfò.” Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ alẹ́ máa gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Àwọn Kristẹni òde òní dojú kọ ìṣòro kan náà nítorí òru ètò nǹkan búburú Sátánì ti lọ jìnnà, ó ti wà ní ọwọ́ ìdájí báyìí, ìyẹn ìgbà tí nǹkan burú jù lọ láyé. (Róòmù 13: 12) Ó léwu gan-an tá a bá sùn lọ nígbà tí ilẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ́ yìí. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká “yè kooro ní èrò inú” ká sì tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Ìwé Mímọ́ gbà wá pé ká “wà lójúfò ní jíjẹ́ kí àdúrà jẹ” wá lọ́kàn.—1 Pét. 4:7.
Bá A Ṣe Lè Mọ Àìlera Tẹ̀mí Kí A sì Borí Rẹ̀
Paríparí rẹ̀, ẹ jẹ́ ká fi ìṣílétí onífẹ̀ẹ́ tí àpọ́sítélì Pétérù fún wa sọ́kàn pé: “Òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé. Nítorí náà, ẹ yè kooro ní èrò inú, kí ẹ sì wà lójúfò ní jíjẹ́ kí àdúrà jẹ yín lọ́kàn. Lékè ohun gbogbo, ẹ ní ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.” (1 Pétérù 4:7, 8) Ó rọrùn láti jẹ́ kí àìpé ẹ̀dá ènìyàn—ti àwọn ẹlòmíràn àti tiwa fúnra wa—ráyè wọnú ọkàn-àyà àti èrò inú wa, kí ó sì wá di ìdènà, òkúta ìkọ̀sẹ̀. Sátánì mọ àwọn àìlera ẹ̀dá ènìyàn yìí dáradára. Bó o ba o pá, bó ò ba o bù ú lẹ́sẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ tara ṣàṣà láti jẹ́ kí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ fún ẹnì kìíní kejì bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀, kí a má ṣe “fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù.”—Éfésù 4:25-27.
Aájò Àlejò Ṣe Pàtàkì Gan-An
2 Nígbà tí Pétérù ń gba àwọn Kristẹni yẹn níyànjú, ó ní: “Ẹ ní ẹ̀mí aájò àlejò fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Pét. 4:9) Lédè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ náà “aájò àlejò” túmọ̀ sí “ká fìfẹ́ hàn tàbí ká ṣe inúure sí àwọn tá ò mọ̀ rí.” Àmọ́, ẹ kíyè sí i pé Pétérù gba àwọn Kristẹni yẹn níyànjú pé kí wọ́n ní ẹ̀mí aájò àlejò sí ‘ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì,’ ìyẹn sí àwọn tí wọ́n mọ̀ rí, tí wọ́n sì jọ ń ṣe nǹkan pa pọ̀. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, báwo nìyẹn ṣe máa ṣe wọ́n láǹfààní?
3 Ó máa jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ra wọn. Ìwọ ńkọ́? Ṣé ẹnì kan ti gbà ẹ́ lálejò rí? Ṣé inú rẹ kì í dùn tó o bá ń rántí ọjọ́ náà? Nígbà tíwọ náà gba àwọn ará kan láti ìjọ yín lálejò, ó dájú pé ìyẹn mú kí àárín yín wọ̀ dáadáa, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Tá a bá ń gba ara wa lálejò, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ mọ ara wa dáadáa ju bá a ṣe lè mọ ara wa nípàdé tàbí lóde ẹ̀rí. Ó yẹ káwọn Kristẹni ìgbà yẹn túbọ̀ sún mọ́ra gan-an torí bí nǹkan ṣe túbọ̀ ń burú sí i. Bó sì ṣe yẹ káwa náà máa ṣe nìyẹn láwọn “ọjọ́ ìkẹyìn” yìí.—2 Tím. 3:1.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Bíbélì sọ pé Jésù “wàásù fún àwọn ẹ̀mí nínú ẹ̀wọ̀n.” (1 Pét. 3:19) Kí ni ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí?
▪ Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé àwọn ẹ̀mí yìí ni àwọn tí wọ́n “ti jẹ́ aláìgbọràn nígbà kan, nígbà tí sùúrù Ọlọ́run ń dúró ní àwọn ọjọ́ Nóà.” (1 Pét. 3:20) Èyí fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n dara pọ̀ mọ́ Sátánì nínú ọ̀tẹ̀ rẹ̀ ni Pétérù ń tọ́ka sí. Júúdà náà sọ̀rọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì tí ‘kò dúró ní ipò wọn ìpilẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣá ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu tì.’ Ó wá sọ pé Ọlọ́run “ti fi [wọ́n] pa mọ́ de ìdájọ́ ọjọ́ ńlá náà pẹ̀lú àwọn ìdè ayérayé lábẹ́ òkùnkùn biribiri.”—Júúdà 6.
Kí làwọn áńgẹ́lì kan ṣe ní ọjọ́ Nóà tó fi hàn pé wọ́n jẹ́ aláìgbọràn? Ṣáájú Ìkún-omi, àwọn áńgẹ́lì burúkú yìí ṣe ohun tó lódì sí ìfẹ́ Ọlọ́run, wọ́n gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀, wọ́n sì wá sáyé. (Jẹ́n. 6:2, 4) Ìyẹn nìkan kọ́, wọ́n tún ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin. Ohun tí wọ́n ṣe yìí lódì pátápátá torí pé Ọlọ́run ò dá àwọn áńgẹ́lì láti máa ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin. (Jẹ́n. 5:2) Torí náà, tó bá tó àkókò lójú Ọlọ́run, gbogbo àwọn áńgẹ́lì tó ṣàìgbọràn wọ̀nyí ló máa pa run. Àmọ́ ní báyìí, gẹ́gẹ́ bí ìwé Júúdà ṣe sọ, wọ́n wà nínú “òkùnkùn biribiri.” Ṣe ló dà bíi pé Ọlọ́run fi wọ́n sẹ́wọ̀n.
Ìgbà wo ni Jésù wàásù fún ‘àwọn ẹ̀mí yìí nínú ẹ̀wọ̀n’? Báwo ló sì ṣe ṣe é? Pétérù sọ pé èyí wáyé lẹ́yìn tí Jésù jíǹde. (1 Pét. 3:18, 19) Tá a bá wo ẹsẹ tó ṣáájú ibi tí Pétérù ti sọ̀ pé Jésù “wàásù,” a máa rí i pé àárín ìgbà tí Jésù jíǹde àti ìgbà tí Pétérù kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ ni Jésù wàásù fún “àwọn ẹ̀mí nínú ẹ̀wọ̀n.” Èyí wá fi hàn pé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lẹ́yìn tí Jésù jíǹde ló sọ ìdájọ́ Ọlọ́run fún àwọn ẹ̀mí burúkú náà, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run máa tó fìyà tó tọ́ jẹ wọ́n. Àwọn ohun tí Jésù sọ fún wọn mú kó ṣe kedere sí wọn pé kò sí ìrètí kankan fún wọn mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló kéde ìdájọ́ lé wọn lórí. (Jónà 1:1, 2) Bí Jésù ṣe jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú, tó sì tún jíǹde fi hàn pé Èṣù kò ní agbára kankan lórí rẹ̀. Èyí ló sì mú kí ẹnú rẹ̀ gbà á láti kéde irú ìdájọ́ mímúná bẹ́ẹ̀ sórí Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀.—Jòh. 14:30; 16:8-11.
Láìpẹ́, Jésù máa de Sátánì àtàwọn áńgẹ́lì burúkú yẹn, á sì sọ wọ́n sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. (Lúùkù 8:30, 31; Ìṣí. 20:1-3) Ní báyìí ná, wọ́n ṣì wà nínú òkùnkùn biribiri nípa tẹ̀mí, ó sì dájú pé wọ́n máa pa run yàn-an yàn nígbẹ̀yìngbẹ́yín.—Ìṣí. 20:7-10.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jákọ́bù, Ìwé Pétérù Kìíní àti Pétérù Kejì
4:6—Àwọn wo ni “òkú” tí a “polongo ìhìn rere fún”? Àwọn wọ̀nyí làwọn tó ti “kú nínú àwọn àṣemáṣe àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀” wọn, ìyẹn ni pé wọ́n kú nípa tẹ̀mí, kí wọ́n tó gbọ́ ìhìn rere. (Éfé. 2:1) Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere, wọ́n dẹni tó “wà láàyè” nípa tẹ̀mí.
Bíbélì Kíkà
OCTOBER 28–NOVEMBER 3
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 PÉTÉRÙ 1-3
‘Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn Dáadáa’
Jèhófà Yóò ‘Ṣe Ìdájọ́ Òdodo’
11 Àmọ́, báwo ló ṣe yẹ ká lóye ọ̀rọ̀ ìdánilójú tí Jésù sọ pé Jèhófà yóò ṣe ìdájọ́ òdodo “pẹ̀lú ìyára kánkán”? Bíbélì fi hàn pé “bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé [Jèhófà] ní ìpamọ́ra,” kò ní fi nǹkan falẹ̀ rárá nígbà tó bá tó àkókò lójú rẹ̀ láti ṣe ìdájọ́ òdodo. (Lúùkù 18:7, 8; 2 Pétérù 3:9, 10) Nígbà ayé Nóà, ńṣe ni Ọlọ́run fi ìkún-omi pa àwọn èèyàn búburú run lórí ilẹ̀ ayé láìjáfara. Bẹ́ẹ̀ náà làwọn ẹni ibi ṣe ṣègbé nígbà tí Ọlọ́run rọ̀jò iná látọ̀run sórí wọn nígbà ayé Lọ́ọ̀tì. Jésù sọ pé: “Bákan náà ni yóò rí ní ọjọ́ tí a óò ṣí Ọmọ ènìyàn payá.” (Lúùkù 17:27-30) Lákòókò yẹn náà, “ìparun òjijì” yóò dé sórí àwọn ẹni ibi. (1 Tẹsalóníkà 5:2, 3) Bẹ́ẹ̀ ni o, kí ó dá wa lójú pé Jèhófà kì yóò jẹ́ kí ayé Sátánì yìí fi ọjọ́ kan kọjá ìgbà tó yẹ kó pa run.
“Ọjọ́ Ńlá Jèhófà Sún Mọ́lé”
18 Nítorí pé ọjọ́ Jèhófà lè dé bá wa lójijì ni àpọ́sítélì Pétérù ṣe gbà wá níyànjú pé ká máa fi “wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà” sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí. Báwo la ṣe lè fi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa ṣe “ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run.” (2 Pétérù 3:11, 12) Tá a bá ń jẹ́ kí ọwọ́ wa dí lẹ́nu irú àwọn ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀, tayọ̀tayọ̀ la óò máa retí pé kí “ọjọ́ Jèhófà” dé. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí ‘fi sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí’ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí túmọ̀ sí “mú yára kánkán” ní ìtumọ̀ olówuuru. Ká sòótọ́, a ò lè mú kí àkókò tó kù kí ọjọ́ Jèhófà dé yá ju bí Jèhófà ṣe ṣètò rẹ̀ lọ. Àmọ́ bá a ṣe ń dúró de ọjọ́ yẹn, ńṣe ló máa dà bíi pé àkókò ń sáré tete tá a bá jẹ́ kí ọwọ́ wa dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.—1 Kọ́ríńtì 15:58.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jákọ́bù, Ìwé Pétérù Kìíní àti Pétérù Kejì
1:19— Ta ni “ìràwọ̀ ojúmọ́,” ìgbà wo ló yọ, báwo la sì ṣe mọ̀ pé ìràwọ̀ ojúmọ́ ti yọ? Jésù Kristi ni “ìràwọ̀ ojúmọ́” náà, ìyẹn lẹ́yìn tó ti di Ọba Ìjọba Ọlọ́run. (Ìṣí. 22:16) Lọ́dún 1914, Jésù Kristi di Mèsáyà Ọba, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ yọ bí ìràwọ̀ níwájú gbogbo ìṣẹ̀dá, èyí tó fi hàn pé ojúmọ́ ọjọ́ tuntun ti mọ́. Ìyípadà ológo tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù nígbà tó wà láyé jẹ́ àpẹẹrẹ ògo àti agbára tí Jésù máa ní nígbà tó bá di ọba Ìjọba Ọlọ́run, èyí sì jẹ́ ká rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní láti ṣẹ dandan. Bá a ṣe ń fiyè sí ọ̀rọ̀ yìí, ó ń tànmọ́lẹ̀ sínú ọkàn wa, èyí sì jẹ́ ká mọ̀ pé Ìràwọ̀ Ojúmọ́ ti yọ.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jákọ́bù, Ìwé Pétérù Kìíní àti Pétérù Kejì
2:4—Kí ni “Tátárọ́sì,” ìgbà wo sì ni Ọlọ́run ju àwọn áńgẹ́lì tó ṣọ̀tẹ̀ síbẹ̀? Ipò kan tó dà bí inú ẹ̀wọ̀n ni Tátárọ́sì, àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó jẹ́ áńgẹ́lì ló wà fún kò wà fáwọn ọmọ èèyàn. Òye àwọn ohun tó hàn kedere pé Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe ṣókùnkùn pátápátá sáwọn tó wà nínú ipò yẹn. Kò sí ìrètí kankan fáwọn tó wà ní Tátárọ́sì, ìparun ló ń dúró dè wọ́n. Ìgbà ayé Nóà ni Ọlọ́run ju àwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn sínú Tátárọ́sì, inú ipò ẹ̀tẹ́ yẹn ni wọ́n sì máa wà títí tí ìparun wọn á fi dé.
Bíbélì Kíkà