Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka Sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
NOVEMBER 4-10
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 JÒHÁNÙ 1-5
“Ẹ Má Ṣe Nífẹ̀ẹ́ Ayé Tàbí Àwọn Nǹkan Tó Wà Nínú Ayé”
Ẹ Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Tí Jésù Fi Lélẹ̀
13 Àwọn kan lè ronú pé kì í ṣe gbogbo ohun tó wà nínú ayé ló burú. Bó tiẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká mọ̀ pé ayé àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ lè pín ọkàn wa níyà nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà. Kò sì sí nǹkan kan nínú ayé yìí tó lè mú kéèyàn túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Nítorí náà, tá a bá lọ nífẹ̀ẹ́ àwọn ohun tí ń bẹ̀ nínú ayé, bí àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ò tiẹ̀ burú, ọ̀nà tó léwu là ń tọ̀ yẹn o. (1 Tímótì 6:9, 10) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ohun tó wà nínú ayé ló burú, tó sì lè sọni dìbàjẹ́. Tá a bá ń wo sinimá tàbí àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n tó ń fi ìwà ipá, ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, tàbí ìṣekúṣe hàn, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ràn àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ká sì fẹ́ máa fi wọ́n ṣèwà hù. Tó bá jẹ́ pé àwọn tí kì í ronú nǹkan míì ju bí ohun ìní wọn ṣe máa pọ̀ sí i tàbí bí wọ́n ṣe máa rí iṣẹ́ tó ń mówó ńlá wọlé ṣe là ń bá kẹ́gbẹ́, àwa náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ló ṣe pàtàkì jù.—Mátíù 6:24; 1 Kọ́ríńtì 15:33.
Máa Ronú Nípa Irú Ẹni Tó Yẹ Kó O Jẹ́
18 Ohun míì tí kò ní jẹ́ kí “àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé” kó èèràn ràn wá ni pé ká máa rántí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí Jòhánù láti kọ, pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòh. 2:17) Lóòótọ́, ayé tí Sátánì ń darí yìí dà bí èyí tí mìmì kan ò lè mì. Àmọ́, ọ̀sán kan òru kan ni Sátánì àtàwọn tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀ máa pa run. Kò sí ohun kankan nínú ayé Sátánì yìí tó láyọ̀lé. Tá a bá ń fi kókó yìí sọ́kàn, a ò ní jẹ́ kí àwọn nǹkan tí Èṣù ń lò láti fa àwọn èèyàn lọ́kàn mọ́ra tàn wá jẹ.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Ìránnilétí Jèhófà Ṣeé Gbẹ́kẹ̀ Lé
14 Ọ̀pọ̀ ìránnilétí ló wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni lédè Gíríìkì pé ká máa fìfẹ́ hàn síra wa. Jésù sọ pé òfin kejì tó tóbi jù ni pé, “kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mát. 22:39) Bákan náà, Jákọ́bù tó jẹ́ iyèkan Jésù sọ pé ìfẹ́ jẹ́ “ọba òfin.” (Ják. 2:8) Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, mo ń kọ̀wé sí yín, kì í ṣe àṣẹ tuntun, bí kò ṣe àṣẹ ti láéláé, èyí tí ẹ ti ní láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.” (1 Jòh. 2:7, 8) Kí ni Jòhánù ní lọ́kàn nígbà tó sọ nípa “àṣẹ ti láéláé”? Àṣẹ Jésù tó ní ká ní ìfẹ́ ni Jòhánù ní lọ́kàn. Ó jẹ́ “ti láéláé” torí pé ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá lẹ́yìn tí Jésù fún wọn lófin yẹn, ìyẹn “láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.” Àmọ́, ó tún jẹ́ “tuntun” torí pé ó gba pé kéèyàn ṣe tán láti fi ẹ̀mí ara rẹ̀ rúbọ nítorí àwọn ẹlòmíì. Ó sì lè gba pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe bẹ́ẹ̀ bí àwọn nǹkan ṣe ń yí pa dà. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Kristi, ṣé a mọrírì àwọn ìkìlọ̀ tí kì í jẹ́ ká fàyè gba ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan tó kúnnú ayé yìí? Tá ò bá ṣọ́ra, irú ẹ̀mí ayé bẹ́ẹ̀ lè mú ká gbàgbé ìfẹ́ ọmọnìkejì ẹni.
it-1 862 ¶5
Ìdáríjì
Kò sóhun tó burú tá a bá fi àwọn míì tàbí gbogbo ìjọ lápapọ̀ sínú àdúrà wa pé kí Ọlọrun dárí jì wá tá a bá ṣẹ̀. Mósè ṣe bẹ́ẹ̀ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè náà, Jèhófà gbọ́ àdúrà yẹn, ó sì dárí jì wọ́n. (Nọ 14:19, 20) Bákan náà, nígbà ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì, Sólómọ́nì gbàdúrà pé kí Jèhófà dárí ji àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀, tí wọ́n sì ronú pìwà dà. (1Ọb 8:30, 33-40, 46-52) Ẹ́sírà náà bẹ Jèhófà pé kó dárí ji orílẹ̀-èdè náà nígbà tó ṣojú àwọn Júù tó pa dà dé láti ìgbèkùn nínú àdúrà. Àdúrà àtọkànwá tó gbà mú káwọn èèyàn náà ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí Jèhófà lè dárí jì wọ́n. (Ẹsr 9:13–10:4, 10-19, 44) Yàtọ̀ síyẹn, Jémíìsì rọ ẹni tó bá ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí pé kó pe àwọn àgbà ọkùnrin inú ìjọ, kí wọ́n lè gbàdúrà fún un, àti pé ‘tó bá ti dẹ́ṣẹ̀, a máa dárí jì í.’ (Jem 5:14-16) Àmọ́, “ẹ̀ṣẹ̀ kan wà tó yẹ fún ikú,” ìyẹn ẹ̀ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́, kéèyàn mọ̀ọ́mọ̀ máa dẹ́ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì. Kristẹni kan ò gbọ́dọ̀ gbàdúrà fáwọn tó ń dẹ́ṣẹ̀ lọ́nà yìí.—1Jo 5:16; Mt 12:31; Heb 10:26, 27; wo Ẹ̀ṢẸ̀, I; Ẹ̀MÍ.
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé “ìfẹ́ pípé a máa ju ìbẹ̀rù sóde,” kí ni “ìfẹ́ pípé” yẹn túmọ̀ sí, kí sì ni “ìbẹ̀rù” tó máa jù sóde?
Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Kò sí ìbẹ̀rù nínú ìfẹ́, ṣùgbọ́n ìfẹ́ pípé a máa ju ìbẹ̀rù sóde, nítorí ìbẹ̀rù a máa ṣèdíwọ́ fúnni. Ní tòótọ́, ẹni tí ó bá wà lábẹ́ ìbẹ̀rù ni a kò tíì sọ di pípé nínú ìfẹ́.”—1 Jòhánù 4:18.
Àyíká ọ̀rọ̀ yẹn fi hàn pé òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ni Jòhánù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ìyẹn àjọṣe tó wà láàárín ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti òmìnira láti bá A sọ̀rọ̀. A lè rí èyí nínú ohun tá a kà ní ẹsẹ kẹtàdínlógún, tó sọ̀ pé: “Báyìí ni a ṣe sọ ìfẹ́ di pípé lọ́dọ̀ wa, kí a lè ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ní ọjọ́ ìdájọ́.” Bí Kristẹni kan ṣe nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó àti bó ṣe gbà pé Ọlọ́run fẹ́ràn òun tó ló máa pinnu bóyá á lómìnira ọ̀rọ̀ sísọ—tàbí bóyá kò ní ní i—nígbà tó bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run.
Gbólóhùn náà “ìfẹ́ pípé” ṣe pàtàkì gan-an. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe lò ó nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “pípé” kì í fi gbogbo ìgbà túmọ̀ sí ìjẹ́pípé pátápátá, ìyẹn ìjẹ́pípé délẹ̀délẹ̀, àmọ́ ó máa ń túmọ̀ sí ìjẹ́pípé dé àyè kan lọ́pọ̀ ìgbà. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè pé: “Kí ẹ jẹ́ pípé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí Baba yín ọ̀run ti jẹ́ pípé.” Jésù ń sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé tí wọ́n bá nífẹ̀ẹ́ kìkì àwọn tó fẹ́ràn wọn, a jẹ́ pé ìfẹ́ wọn ò pé nìyẹn, ó mẹ́hẹ, ó sì kù-díẹ̀-ká-à-tó. Wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìfẹ́ wọn di pípé, tàbí kí ó dé ìwọ̀n tó kún rẹ́rẹ́ nípa nínífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn pàápàá. Bákan náà, nígbà tí Jòhánù kọ̀wé nípa “ìfẹ́ pípé,” ohun tó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni béèyàn ṣe gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn, kí ìfẹ́ náà jinlẹ̀ dáadáa, kó sì fara hàn nínú gbogbo ohun téèyàn bá ń ṣe ní ìgbésí ayé rẹ̀.—Mátíù 5:46-48; 19:20, 21.
Nígbà tí Kristẹni kan bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó mọ̀ dájú pé ẹlẹ́ṣẹ̀ àti aláìpé lòun. Àmọ́, tí ìfẹ́ tó ní fún Ọlọ́run àti bó ṣe gbà pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ òun bá jinlẹ̀ dáadáa, ìbẹ̀rù ìdálẹ́bi tàbí dídi ẹni ìtanù kò ní ṣèdíwọ́ fún un. Kàkà bẹ́ẹ̀ á ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ láti sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ jáde àti láti tọrọ ìdáríjì lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà tí Ọlọ́run ti fìfẹ́ pèsè nípasẹ̀ Jésù Kristi. Ọkàn rẹ̀ á sì balẹ̀ pé Ọlọ́run á gbọ́ àdúrà òun.
Báwo la ṣe lè sọ ẹnì kan “di pípé nínú ìfẹ́,” kó sì tipa bẹ́ẹ̀ ‘ju’ ìbẹ̀rù ìdálẹ́bi àti ti dídí ẹni ìtanù ‘sóde’? Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ [Ọlọ́run] mọ́, lótìítọ́ nínú ẹni yìí ni a ti sọ ìfẹ́ fún Ọlọ́run di pípé.” (1 Jòhánù 2:5) Rò ó wò ná: Tí Ọlọ́run bá nífẹ̀ẹ́ wa nígbà tá a ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ǹjẹ́ kò ní nífẹ̀ẹ́ wa jù bẹ́ẹ̀ lọ tá a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, tá a sì ń fi gbogbo ara “pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́”? (Róòmù 5:8; 1 Jòhánù 4:10) Láìsí àní-àní, tá a bá ṣáà ti jẹ́ olóòótọ́, a lè ní irú ìdánilójú kan náà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní nígbà tó sọ nípa Ọlọ́run pé: “Ẹni tí kò dá Ọmọ tirẹ̀ pàápàá sí, ṣùgbọ́n tí ó jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ fún gbogbo wa, èé ṣe tí òun kò ní tún fi inú rere fún wa ní gbogbo ohun yòókù pẹ̀lú rẹ̀?”—Róòmù 8:32.
10 Kò yẹ káwọn Kristẹni tó fẹ́ ṣègbéyàwó ṣe ju ara wọn lọ, wọ́n sì ní láti ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu. Bíbélì lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe èyí. Ọjọ́ ìgbéyàwó ṣe pàtàkì lóòótọ́, àmọ́ wọ́n mọ̀ pé ńṣe ló wulẹ̀ jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé àwọn Kristẹni méjì tí wọ́n ní ìrètí pé àwọn yóò jọ wà láàyè títí láé. Kò pọn dandan kí wọ́n filé pọntí fọ̀nà rokà nígbà ìgbéyàwó wọn. Bí wọ́n bá fẹ́ pe àpèjẹ, wọ́n ní láti ronú nípa iye tó máa ná wọn àti bí ètò náà a ṣe lọ sí. (Lúùkù 14:28) Nígbà táwọn Kristẹni méjèèjì bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya, ọkọ ni yóò jẹ́ orí gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ. (1 Kọ́ríńtì 11:3; Éfésù 5:22, 23) Nítorí náà, ọkọ ìyàwó gan-an ló máa pinnu ohun tó máa wáyé níbi àpèjẹ ìgbéyàwó náà. Á dára kó gba èrò ìyàwó rẹ̀ nípa ètò àpèjẹ náà yẹ̀ wò ṣá o, kí wọ́n jọ sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí wọ́n fẹ́ kó wá tàbí iye àwọn tí agbára wọn gbé láti pè. Ó lè má ṣeé ṣe láti pe gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ wọn àti mọ̀lẹ́bí wọn, ó tiẹ̀ lè máà mọ́gbọ́n dání láti ṣe bẹ́ẹ̀; nítorí náà, wọ́n ní láti mọ̀wọ̀n ara wọn kí wọ́n sì ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Ó yẹ kí ọkàn àwọn tó fẹ́ di tọkọtaya náà balẹ̀ pé bí àwọn kò bá pe àwọn kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí bíi tiwọn, wọ́n á gba tàwọn rò wọn ò sì ní fi ṣe ìbínú.—Oníwàásù 7:9.
Bíbélì Kíkà
NOVEMBER 11-17
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 JÒHÁNÙ 1–JÚÙDÀ
“A Gbọ́dọ̀ Jà Fitafita Ká Lè Dúró Nínú Òtítọ́”
“Ẹ Máa Bá a Lọ Ní Gbígba Agbára Nínú Olúwa”
8 A kò ṣàìmọ ètekéte Sátánì nítorí Ìwé Mímọ́ táṣìírí àwọn ọgbọ́n tó ń dá. (2 Kọ́ríńtì 2:11) Àwọn ohun tí Èṣù fi gbógun ti Jóòbù olódodo ni pé ó dojú ọrọ̀ ajé rẹ̀ dé, ó ṣekú pa àwọn ọmọ ẹ̀, ó gbé ogun ìdílé dìde sí i, ó kó o sí ìnira tó ga, ó tún sún àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù láti fẹ̀sùn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ kàn án. Ni ìdààmú ọkàn bá bá Jóòbù, ó rò pé Ọlọ́run ti kọ òun sílẹ̀. (Jóòbù 10:1, 2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro wọ̀nyí lè wáyé lóde òní láìjẹ́ pé Sátánì dojú rẹ̀ kọni, irú àwọn ìnira bẹ́ẹ̀ máa ń bá ọ̀pọ̀ Kristẹni, Èṣù sì lè gùn lé wọn láti fi gbógun tì wá.
9 Àwọn ewu nípa tẹ̀mí gbòde kan lákòókò òpin yìí. Ìlépa ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ti gbapò àwọn ohun tẹ̀mí lọ́kàn àwọn èèyàn láyé ìsinsìnyí. Lemọ́lemọ́ làwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde ń fi ìṣekúṣe hàn bí ohun ìdùnnú dípò ohun tí ń kó ìbànújẹ́ báni. Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn sì ti di “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Tímótì 3:1-5) Èrò àwọn èèyàn yìí lè ṣàkóbá fún wa nípa tẹ̀mí bá ò bá “máa ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́.”—Júùdù 3.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-2 279
Àsè Tí A Fìfẹ́ Pè
Bíbélì ò sọ ohun tí wọ́n máa ń ṣe nígbà àsè yìí, kò sì sọ bí wọ́n ṣe máa ń ṣe é tó. (Júùdù 12) Kì í ṣe Jésù Kristi Olúwa tàbí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ló pàṣẹ pé káwọn Kristẹni máa ṣe é, torí náà kì í ṣe dandan fáwọn Kristẹni láti ṣe àsè náà. Àwọn kan sọ pé àwọn Kristẹni tó lówó lọ́wọ́ ló máa ń ṣètò àsè yìí, wọ́n á sì pe àwọn Kristẹni míì tó jẹ́ tálákà kí wọ́n lè jọ jẹun pa pọ̀. Èyí máa ń mú kó ṣeé ṣe fáwọn Kristẹni tó jẹ́ aláìníbaba, opó, olówó àtàwọn tálákà láti wà pa pọ̀, kí wọ́n lè jọ gbádùn ìfẹ́ ará.
it-2 816
Àpáta
Ọ̀rọ̀ Gíríìkì míì, spi·lasʹ ń tọ́ka sí àpáta tàbí òkúta kan tó wà lábẹ́ omi. Júùdù lò ó láti ṣàpẹẹrẹ àwọn kan tó yọ́ wọnú ìjọ Kristẹni, tí wọ́n sì ń gbé ẹ̀kọ́ èké àti ìwàkiwà lárugẹ. Bí àpáta tó wà lábẹ́ omi ṣe lè ṣe ọkọ̀ ojú omi kan ní jàǹbá, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ọkùnrin yìí jẹ́ ewu ńlá fáwọn tó wà nínú ìjọ. Júùdù wá sọ nípa wọn pé: “Àwọn yìí máa ń wà níbi àsè tí ẹ fìfẹ́ pe ara yín sí, àmọ́ wọ́n dà bí àpáta tó fara pa mọ́ lábẹ́ omi.”—Júùdù 12.
“Ó Ti Wu Ọlọ́run Dáadáa”
Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Énọ́kù sọ? Àsọtẹ́lẹ̀ náà lọ báyìí: “Wò ó! Jèhófà wá pẹ̀lú ẹgbẹẹgbàárùn-ún rẹ̀ mímọ́, láti mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sí gbogbo ènìyàn, àti láti dá gbogbo aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run lẹ́bi nípa gbogbo ìṣe àìṣèfẹ́ Ọlọ́run wọn, èyí tí wọ́n ṣe lọ́nà àìṣèfẹ́ Ọlọ́run, àti nípa gbogbo ohun amúnigbọ̀nrìrì tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ti sọ lòdì sí i.” (Júúdà 14, 15) Ǹjẹ́ o kíyè sí i pé Énọ́kù sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí bíi pé ohun tó ń sọ ti ṣẹlẹ̀ kọjá. Ọ̀nà yìí ni wọ́n gbà sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì nínú Bíbélì. Ohun tí ìyẹn ń fi hàn ni pé: Wòlíì náà ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú pé àsọtẹ́lẹ̀ náà máa ṣẹ, àfi bíi pé nǹkan náà ti ṣẹlẹ̀ kọjá!—Aísáyà 46:10.
“Ó Ti Wu Ọlọ́run Dáadáa”
Àpẹẹrẹ Énọ́kù lè mú ká ronú bóyá àwa náà kórìíra ohun tó ń lọ nínú ayé yìí bí Ọlọ́run ṣe kórìíra rẹ̀. Ìdájọ́ tí Énọ́kù fìgboyà kéde nígbà yẹn kan àwa náà lónìí. Bí Énọ́kù ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Jèhófà fi Àkúnya omi pa àwọn èèyàn burúkú run nígbà ayé Nóà. Àmọ́, ńṣe ní ìparun yẹn ń ṣàpẹẹrẹ ìparun ńlá tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. (Mátíù 24:38, 39; 2 Pétérù 2:4-6) Bíi ti ìgbà yẹn, Ọlọ́run ti múra àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára sílẹ̀ láti mú ìdájọ́ wá sórí àwọn èèyàn burúkú lóde òní. Torí náà, ó yẹ kí gbogbo wa pátá fi ìkìlọ̀ Énọ́kù sọ́kàn, ká sì sọ ọ́ fáwọn míì. Èyí lè mú káwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ wa kẹ̀yìn sí wa tàbí kó dà bíi pé a dá wà. Àmọ́ ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé bí Jèhófà ṣe dúró ti Énọ́kù, ló ṣe máa dúró ti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lónìí!
Bíbélì Kíkà
NOVEMBER 18-24
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌFIHÀN 1-3
“Mo Mọ Àwọn Iṣẹ́ Rẹ”
Irú Ẹ̀mí Wo Lò Ń fi Hàn?
8 Tá a bá fẹ́ yẹra fún irú ẹ̀mí yẹn, ó yẹ ká máa rántí pé Bíbélì sọ pé Jésù ní “ìràwọ̀ méje ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.” Àwọn “ìràwọ̀” náà dúró fún àwọn alábòójútó tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró. Ní àfikún sí ìyẹn, wọ́n tún dúró fún gbogbo àwọn alábòójútó nínú ìjọ. Jésù lè darí àwọn “ìràwọ̀” tó wà ní ọwọ́ rẹ̀ lọ́nà tó bá tọ́ ní ojú rẹ̀. (Ìṣí. 1:16, 20) Torí náà, gẹ́gẹ́ bí Orí ìjọ Kristẹni, Jésù ní gbogbo agbára pátápátá láti máa darí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà. Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ló yẹ kí alàgbà kan ṣe àwọn àtúnṣe kan, Ẹni tí ‘ojú rẹ̀ dà bí ọwọ́ iná ajófòfò’ yóò ṣe nǹkan kan nípa ọ̀ràn náà ní àkókò tó tọ́ lójú Rẹ̀ àti ní ọ̀nà tó wù Ú. (Ìṣí. 1:14) Ní báyìí ná, ẹ jẹ́ ká máa ní ọ̀wọ̀ tó yẹ fún àwọn tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ yàn, torí Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba, nítorí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín bí àwọn tí yóò ṣe ìjíhìn; kí wọ́n lè ṣe èyí pẹ̀lú ìdùnnú, kì í sì í ṣe pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn, nítorí èyí yóò ṣe ìpalára fún yín.”—Héb. 13:17.
Jèhófà Ń fi Ìṣọ́ Ṣọ́ Wa Ká Lè Rí Ìgbàlà
11 Nínú ìran tó wà nínú ìwé Ìṣípayá orí 2 àti 3, Jésù Kristi tá a ti ṣe lógo wo bí nǹkan ṣe ń lọ sí nínú àwọn ìjọ méje tó wà ní Éṣíà Kékeré. Ìran náà fi hàn pé kì í ṣe àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lápapọ̀ nìkan ni Kristi ń rí, ó tún ń kíyè sí àwọn nǹkan pàtó tó ń ṣẹlẹ̀. Ó tiẹ̀ dárúkọ àwọn kan, ó gbóríyìn fún àwọn kan lára wọn, ó sì fún àwọn míì ní ìbáwí. Kí ni èyí fi hàn? Nínú ìmúṣẹ ìran yẹn, ìjọ méje náà dúró fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà láyé lẹ́yìn ọdún 1914, ìlànà tó wà nínú ìbáwí tí Jésù fún ìjọ méjèèje náà sì kan gbogbo ìjọ àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà lórí ilẹ̀ ayé lóde òní. Torí náà, ó tọ́ tá a bá parí èrò sí pé Jèhófà ń lo Ọmọ rẹ̀ láti darí àwọn èèyàn rẹ̀ lóde òní. Àǹfààní wo la lè rí nínú bí Jésù ṣe ń darí ìjọ?
Máa Bá Ètò Jèhófà Rìn
20 Bíbá ètò Jèhófà tó ń tẹ̀ síwájú rìn ń béèrè pé ká mọ iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí “orí ìjọ.” (Éfésù 5:22, 23) Ìwé Aísáyà orí karùndínlọ́gọ́ta, ẹsẹ ìkẹrin tún yẹ fún àfiyèsí, ibẹ̀ kà pé: “Wò ó! Mo [Jèhófà] ti fi í fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí, gẹ́gẹ́ bí aṣáájú àti aláṣẹ fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè.” Ó dájú pé Jésù mọ iṣẹ́ aṣíwájú ṣe. Ó mọ àwọn àgùntàn rẹ̀, ó sì mọ iṣẹ́ wọn. Àní, nígbà tó bẹ ìjọ méje tí ń bẹ ní Éṣíà Kékeré wò, ẹ̀ẹ̀marùn-ún ló sọ pé: “Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ.” (Ìṣípayá 2:2, 19; 3:1, 8, 15) Jésù tún mọ àwọn àìní wa, bí Baba rẹ̀, Jèhófà, ṣe mọ̀ wọ́n. Kí Jésù tó bẹ̀rẹ̀ Àdúrà àwòfiṣàpẹẹrẹ náà, ó wí pé: “Ọlọ́run tí í ṣe Baba yín mọ àwọn ohun tí ẹ ṣe aláìní kí ẹ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ rárá.”—Mátíù 6:8-13.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ìjọba Ọlọ́run Mú Àwọn Ọ̀tá Rẹ̀ Kúrò
10 Ṣíṣe ìdájọ́. Gbogbo ọ̀tá Ìjọba Ọlọ́run pátá yóò wá fi tipátipá rí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó máa pa kún ìrora gógó wọn. Jésù sọ pé: “Wọn yóò sì rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ nínú àwọsánmà pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.” (Máàkù 13:26) Bí Jésù yóò ṣe fi agbára rẹ̀ hàn lọ́nà tó ju ti ẹ̀dá lọ yìí yóò jẹ́ àmì pé ó ti dé láti ṣe ìdájọ́. Ní apá míì nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí kan náà tí Jésù sọ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ó sọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan sí i nípa ìdájọ́ tó máa ṣe lákòókò náà. Inú àkàwé rẹ̀ nípa àwọn àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́ la ti rí èyí. (Ka Mátíù 25:31-33, 46.) Àwọn adúróṣinṣin alátìlẹyìn Ìjọba Ọlọ́run yóò gba ìdájọ́ pé wọ́n jẹ́ “àgùntàn,” wọ́n yóò sì “gbé orí [wọn] sókè,” torí wọ́n mọ̀ pé “ìdáǹdè [àwọn] ń sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:28) Àmọ́, àwọn alátakò Ìjọba náà yóò gba ìdájọ́ pé wọ́n jẹ́ “ewúrẹ́,” wọ́n yóò sì “lu ara wọn nínú ẹ̀dùn-ọkàn,” torí wọ́n rí i pé “ìkékúrò àìnípẹ̀kun” ló máa bá àwọn.—Mát. 24:30; Ìṣí. 1:7.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìṣípayá—Apá Kìíní
2:7—Kí ni “párádísè Ọlọ́run”? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀rọ̀ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni Jésù ń sọ níbí, párádísè yìí ní láti tọ́ka sí ipò ìdẹ̀ra tó dà bíi ti inú Párádísè, tí wọ́n máa wà lọ́run, níbi tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ wà. Èrè táwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró máa gbà ni pé wọ́n á jẹ “nínú igi ìyè.” Èyí fi hàn pé wọ́n á gba àìleèkú.—1 Kọ́r. 15:53.
Bíbélì Kíkà
NOVEMBER 25–DECEMBER 1
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌFIHÀN 4-6
“Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Tó Ń Gẹṣin Lọ”
Ta Ni Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Náà?
Ta ló gun ẹṣin funfun yìí? Inú ìwé Ìṣípayá náà la ti rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí. Lọ́wọ́ ìparí ìwé náà, ó pe ẹni tó ń gun ẹṣin náà lọ́run ní “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (Ìṣípayá 19:11-13) Jésù Kristi ni Bíbélì máa ń pè ní Ọ̀rọ̀ náà, torí pé òun ni agbẹnusọ fún Ọlọ́run. (Jòhánù 1:1, 14) Láfikún sí i, Bíbélì tún pè é ní “Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa,” ó sì tún jẹ́ “Aṣeégbíyèlé àti Olóòótọ́.” (Ìṣípayá 19:11, 16) Ó ṣe kedere pé, Jésù Kristi ní àṣẹ láti jẹ́ ọba ajagunṣẹgún, kì í sì í lo agbára rẹ̀ nílòkulò. Síbẹ̀, ó yẹ ká rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè kan.
wp17.3 4 ¶5
Ta Ni Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Náà?
Ìgbà wo làwọn ẹlẹ́ṣin náà bẹ̀rẹ̀ sí i gun ẹṣin wọn? Wàá kíyè sí i pé ìgbà tí Jésù tó jẹ́ ẹlẹ́ṣin àkọ́kọ́ gba adé ló bẹ̀rẹ̀ sí í gun ẹṣin náà. (Ìṣípayá 6:2) Ìgbà wo ni Ọlọ́run fi Jésù jẹ ọba lọ́run? Kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tó pa dà sí ọ̀run lẹ́yìn tó jíǹde. Bíbélì sọ pé ó dúró fún àkókò díẹ̀ kó tó di ọba. (Hébérù 10:12, 13) Jésù sọ àmì táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ á fi mọ ìgbà tí àkókò dídúró òun máa dópin, tí ìjọba rẹ̀ sì máa bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀run. Ó sọ pé níbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso òun, nǹkan máa yí pa dà sí búburú nínú ayé. Ogun, àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀-àrùn máa gbòde kan. (Mátíù 24:3, 7; Lúùkù 21:10, 11) Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kìíní bẹ́ sílẹ̀ lọ́dún 1914, ló ti hàn gbangba pé a ti wọ àkókò wàhálà tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”—2 Tímótì 3:1-5.
Ta Ni Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Náà?
Ẹni tó gun ẹṣin yìí ṣàpẹẹrẹ ogun. Wàá rí i pé kì í ṣe orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan ló ti mú àlááfíà kúrò, bí kò ṣe ní gbogbo ayé. Ogun kan jà kárí ayé lọ́dún 1914, èyí sì ni ìgbà àkọ́kọ́ tírú ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀. Ogun àgbáyé kejì jà tẹ̀ lé e, ó sì gbóná ju tàkọ́kọ́ lọ. Àwọn kan fojú bù ú pé àwọn èèyàn tó ti bá ogun àti rògbòdìyàn lọ láti ọdún 1914 ti lé ní ọgọ́rùn-ún [100] mílíọ̀nù! Láfikún sí i, àwọn tó fara pa yánna-yànnà kò lóǹkà.
wp17.3 5 ¶4-5
Ta Ni Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Náà?
“Mo sì rí, sì wò ó! ẹṣin dúdú kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ sì ní òṣùwọ̀n aláwẹ́ méjì ní ọwọ́ rẹ̀. Mo sì gbọ́ tí ohùn kan bí ẹni pé ní àárín àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà wí pé: ‘Ìlàrin òṣùwọ̀n àlìkámà fún owó dínárì kan, àti ìlàrin òṣùwọ̀n mẹ́ta ọkà báálì fún owó dínárì kan; má sì pa òróró ólífì àti wáìnì lára.’ ”—Ìṣípayá 6:5, 6.
Ẹni tó gun ẹṣin yìí ṣàpẹẹrẹ ìyàn. Ìràn yìí ṣàpẹẹrẹ àìtó oúnjẹ tó lékenkà débi pé èèyàn gbọ́dọ̀ ní owó dínárì kan, tó jẹ́ owó iṣẹ́ ọjọ́ kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, kó tó lè ra ìlàrin (kìlógíráàmù 0.7) òṣùwọ̀n àlìkámà! (Mátíù 20:2) Iye kan náà ni wọ́n máa fi ra ìlàrin (kìlógíráàmù 2.1) òṣùwọ̀n mẹ́ta ọkà báálì, tí kò níye lórí tó àlìkámà. Ṣé ìyẹn máa yó bàbá, ìyá àtàwọn ọmọ? Ẹlẹ́ṣin náà wá kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n má ṣe fi oúnjẹ ṣòfò, ó dìídì dárúkọ òróró ólífì àti wáìnì tó jẹ́ oúnjẹ pàtàkì lákòókò yẹn.
wp17.3 5 ¶8-10
Ta Ni Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Náà?
Ẹni tó gun ẹṣin kẹrin yìí ń fa àjàkálẹ̀ àrùn àtàwọn jàǹbá míì tó ń ṣekú pa ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn. Àkókò díẹ̀ lẹ́yìn ọdún 1914, àrùn gágá pa ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn. Ó tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] mílíọ̀nù èèyàn tó kó àrùn yìí, ìyẹn nǹkan bí èèyàn kan nínú mẹ́ta àwọn tó ń gbáyé nígbà yẹn!
Àmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ lásán ni èyí jẹ́. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n fojú bù ú pé àwọn tí àrùn ìgbóná pa láàárín ọgọ́rùn-ún [100] ọdún sẹ́yìn jẹ́ ìlọ́po-ìlọ́po àwọn tí àrùn gágá pa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ ìṣègùn ti tẹ̀ síwájú gan-an, síbẹ̀ àwọn àrùn bíi AIDS, ikọ́ ẹ̀gbẹ àti àìsàn ibà ṣì ń dá ẹ̀mí ẹgbàágbèje èèyàn légbodò.
Àbájáde kan náà ni ogun, ìyàn tàbí àjàkálẹ̀ àrùn máa ń ní, ikú ló máa ń gbẹ̀yìn gbogbo rẹ̀. Ńṣe ni isà òkú kàn ń gbé àwọn èèyàn mì káló ṣáá láìsinmi.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ògo Ìtẹ́ Jèhófà ní Ọ̀run
8 Jòhánù mọ̀ pé a yan àwọn àlùfáà kí wọ́n máa sìn nínú àgọ́ ìjọsìn ìgbàanì. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kó yà á lẹ́nu láti rí ohun tó ṣàpèjúwe tẹ̀ lé e yìí: “Àti yí ká ìtẹ́ náà ni ìtẹ́ mẹ́rìnlélógún wà, mo sì rí àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún tí wọ́n wọ ẹ̀wù àwọ̀lékè funfun, tí wọ́n jókòó sórí ìtẹ́ wọ̀nyí, adé wúrà sì ń bẹ ní orí wọn.” (Ìṣípayá 4:4) Bẹ́ẹ̀ ni, kàkà kó rí àwọn àlùfáà, alàgbà mẹ́rìnlélógún ló rí, tí wọ́n wà lórí ìtẹ́ tí wọ́n sì dé adé bí ọba. Àwọn wo ni alàgbà wọ̀nyí? Àwọn ẹni àmì òróró inú ìjọ Kristẹni ni, tó jẹ́ pé wọ́n ti jíǹde tí wọ́n sì wà ní ipò tí Jèhófà ṣèlérí fún wọn lọ́run. Báwo la ṣe mọ èyí?
Ògo Ìtẹ́ Jèhófà ní Ọ̀run
19 Kí ni àwọn ẹ̀dá wọ̀nyí dúró fún? Ìran kan tí wòlíì mìíràn, ìyẹn Ìsíkíẹ́lì, ròyìn jẹ́ ká rí ìdáhùn rẹ̀. Ìsíkíẹ́lì rí Jèhófà lórí ìtẹ́ kan tó wà lórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run tó láwọn ẹ̀dá alààyè kan, àwọn ẹ̀dá alààyè yìí sì fàwọn nǹkan kan jọ àwọn tí Jòhánù ṣàpèjúwe. (Ìsíkíẹ́lì 1:5-11, 22-28) Lẹ́yìn èyí, Ìsíkíẹ́lì tún rí kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí ìtẹ́ wà lórí rẹ̀ yìí kan náà tòun tàwọn ẹ̀dá alààyè náà. Ṣùgbọ́n, lọ́tẹ̀ yí, kérúbù ló pe àwọn ẹ̀dá alààyè náà. (Ìsíkíẹ́lì 10:9-15) Nígbà náà, ẹ̀dá alààyè mẹ́rin tí Jòhánù rí ní láti dúró fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn kérúbù Ọlọ́run, ìyẹn àwọn ẹ̀dá tó wà nípò gíga nínú ètò Rẹ̀ tó jẹ́ tàwọn ẹ̀dá ẹ̀mí. Kò ní ṣàjèjì sí Jòhánù láti rí àwọn kérúbù pé wọ́n wà ní ipò tó sún mọ́ ibi tí Jèhófà wà pẹ́kípẹ́kí, nítorí pé nínú ìṣètò àgọ́ ìjọsìn ìgbàanì, àwọn kérúbù oníwúrà méjì wà lórí ọmọrí àpótí májẹ̀mú, èyí tó dúró fún ìtẹ́ Jèhófà. Ohùn Jèhófà sì máa ń sọ àwọn òfin fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì láti àárín àwọn kérúbù wọ̀nyí.—Ẹ́kísódù 25:22; Sáàmù 80:1.
“Wò Ó! Kìnnìún Tí Ó Jẹ́ ti Ẹ̀yà Júdà”
5 A sábà máa ń fi kìnnìún ṣàpẹẹrẹ ìgboyà. Ǹjẹ́ o ti dúró níwájú akọ kìnnìún rí? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ó ní láti jẹ́ pé inú àkámọ́ tó wà nínú ọgbà ẹranko ni wọ́n fi ẹranko ẹhànnà yìí sí, tí ìwọ sì wà lódìkejì. Pẹ̀lú ìyẹn náà, kì í ṣe pé kẹ́rù má máa bà ọ́. Bó o ṣe ń wo ojú ẹranko ńlá tó lágbára púpọ̀ yìí tóun náà sì ń wò ẹ́ ṣùn-ùn, o ò ní rò ó láéláé pé nǹkan kan lè dẹ́rù ba kìnnìún tó ò ń wò yìí débi tó fi máa sá. Bíbélì sọ pé kìnnìún ni “alágbára ńlá jù lọ láàárín àwọn ẹranko, tí kì í sì í yí padà kúrò níwájú ẹnikẹ́ni.” (Òwe 30:30) Irú ìgboyà tí Kristi ní nìyẹn.
6 Ọ̀nà mẹ́ta ni Jésù gbà fi ìgboyà tó jọ ti kìnnìún hàn. Ọ̀nà kìíní ni bó ṣe dúró lórí òtítọ́; ọ̀nà kejì ni bó ṣe ń ṣẹ̀tọ́; ọ̀nà kẹta sì ni ti bó ṣe kojú àtakò. Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò wọn lọ́kọ̀ọ̀kan. Ká tún wá wo bí àwa náà ṣe lè fìwà jọ Jésù nípa jíjẹ́ onígboyà, láìwo ti pé a láyà tàbí pé a ò láyà.
Bíbélì Kíkà