ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 10/15 ojú ìwé 23-27
  • Jẹ́ Kí Ọ̀nà Tí o Gbà Ń gbé Ìgbésí Ayé Rẹ Fi Hàn Pé o Ní Ìgbàgbọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Kí Ọ̀nà Tí o Gbà Ń gbé Ìgbésí Ayé Rẹ Fi Hàn Pé o Ní Ìgbàgbọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Àpèjẹ Kékeré
  • Báwo Ni Nǹkan Ṣe Máa Lọ Sí Níbi Àpèjẹ Náà?
  • Ìgbéyàwó àti Àpèjẹ Ìgbéyàwó
  • “Olùdarí Àsè”
  • Fífúnni Lẹ́bùn Níbi Ìgbéyàwó
  • Àwọn Ìgbéyàwó Aláyọ̀ Tí Ń bọlá Fún Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ṣe Ohun Tó Máa Jẹ́ Kí Ayọ̀ àti Iyì Ọjọ́ Ìgbéyàwó Rẹ Pọ̀ Sí I
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ayẹyẹ Ìgbéyàwó Tí Ń Bọlá fún Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Báwo Ni Ìgbéyàwó Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Máa Ń Rí?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 10/15 ojú ìwé 23-27

Jẹ́ Kí Ọ̀nà Tí o Gbà Ń gbé Ìgbésí Ayé Rẹ Fi Hàn Pé o Ní Ìgbàgbọ́

“Ìgbàgbọ́, bí kò bá ní àwọn iṣẹ́, jẹ́ òkú nínú ara rẹ̀.”—JÁKỌ́BÙ 2:17.

1. Kí nìdí táwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní fi fi iṣẹ́ ti ìgbàgbọ́ wọn lẹ́yìn?

Ó FẸ́RẸ̀Ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ni wọ́n gbé ìgbésí ayé wọn lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n ní ìgbàgbọ́. Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù rọ gbogbo àwọn Kristẹni pé: “Ẹ di olùṣe ọ̀rọ̀ náà, kì í sì í ṣe olùgbọ́ nìkan.” Ó fi kún un pé: “Gẹ́gẹ́ bí ara láìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.” (Jákọ́bù 1:22; 2:26) Ní nǹkan bí ọdún márùndínlógójì lẹ́yìn tí Jákọ́bù sọ ọ̀rọ̀ yìí nínú lẹ́tà tó kọ, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ṣì ń ṣe àwọn iṣẹ́ rere tó fi hàn pé wọ́n ní ìgbàgbọ́. Àmọ́ o, àwọn kan ò ṣe bẹ́ẹ̀ ní tiwọn. Jésù yin ìjọ tó wà ní Símínà, ṣùgbọ́n ó sọ fún ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà nínú ìjọ tó wà ní Sádísì pé: “Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, pé ìwọ ní orúkọ pé o wà láàyè, ṣùgbọ́n o ti kú.”—Ìṣípayá 2:8-11; 3:1.

2. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ káwa Kristẹni bi ara wa nípa ìgbàgbọ́ wa?

2 Ìdí rèé tí Jésù fi rọ àwọn ará Sádísì pé kí wọ́n máa ṣe ohun tí yóò fi ẹ̀rí hàn pé wọ́n ṣì ní ìfẹ́ tí wọ́n ní fún òtítọ́ níbẹ̀rẹ̀, kí wọ́n sì jẹ́ kí níní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ wọ́n lógún. Ọ̀rọ̀ ìṣírí Jésù yìí kan àwọn tó máa kà á lẹ́yìn ìgbà yẹn. (Ìṣípayá 3:2, 3) Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè bi ara rẹ̀ pé: ‘Báwo làwọn iṣẹ́ tèmi ṣe rí? Ǹjẹ́ mò ń sa gbogbo ipá mi láti jẹ́ kó hàn nínú gbogbo ohun tí mò ń ṣe pé mo ní ìgbàgbọ́, àní nínú àwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ jẹ mọ́ iṣẹ́ ìwàásù tàbí ìpàdé ìjọ pàápàá?’ (Lúùkù 16:10) Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan là ń ṣe nígbèésí ayé tó lè fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí ẹyọ kan ṣoṣo, ìyẹn ni àwọn àpèjẹ wa, títí kan èyí tó máa ń wáyé lẹ́yìn ìgbéyàwó àwọn Kristẹni.

Àwọn Àpèjẹ Kékeré

3. Kí ni Bíbélì sọ nípa àpèjẹ?

3 Inú ọ̀pọ̀ lára wa máa ń dùn tí wọ́n bá pè wá síbi táwọn Kristẹni aláyọ̀ kóra jọ sí. Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀” tó fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láyọ̀. (1 Tímótì 1:11) Ó fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí Sólómọ́nì láti kọ ọ̀rọ̀ kan tó jẹ́ òótọ́ pọ́ńbélé sínú Bíbélì. Ọ̀rọ̀ náà ni pé: “Èmi alára sì gbóríyìn fún ayọ̀ yíyọ̀, nítorí pé aráyé kò ní nǹkan kan tí ó sàn lábẹ́ oòrùn ju pé kí wọ́n máa jẹ, kí wọ́n sì máa mu, kí wọ́n sì máa yọ̀, kí ó sì máa bá wọn rìn nínú iṣẹ́ àṣekára wọn ní àwọn ọjọ́ ìgbésí ayé wọn.” (Oníwàásù 3:1, 4, 13; 8:15) Èèyàn lè yọ irú ayọ̀ bẹ́ẹ̀ nígbà tóun àtàwọn tí wọ́n wà nínú ìdílé rẹ̀ bá ń jẹun pọ̀ tàbí tó bá wà níbi àpèjẹ kéékèèké mìíràn táwọn olùjọsìn tòótọ́ ṣètò.—Jóòbù 1:4, 5, 18; Lúùkù 10:38-42; 14:12-14.

4. Kí ló yẹ kí ẹni tó bá pe àpèjẹ fi sọ́kàn?

4 Bó bá jẹ́ pé ìwọ lo fẹ́ pe irú àpèjẹ bẹ́ẹ̀, o ní láti gbé gbogbo ètò tó o ṣe yẹ̀ wò dáadáa, kódà bó bá jẹ́ pé ìwọ̀nba àwọn Ẹlẹ́rìí díẹ̀ lo fẹ́ pè kẹ́ ẹ lè jọ jẹun kẹ́ ẹ sì jọ fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀. (Róòmù 12:13) Rí i pé ‘ohun gbogbo ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu,’ kó o sì tún rí i pé “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè” lẹ fi ń ṣe gbogbo ohun tó wáyé níbẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 14:40; Jákọ́bù 3:17) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Yálà ẹ ń jẹ tàbí ẹ ń mu tàbí ẹ ń ṣe ohunkóhun mìíràn, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run. Ẹ máa fà sẹ́yìn kúrò nínú dídi okùnfà ìkọ̀sẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 10:31, 32) Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò? Bó o bá gbé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ yẹ̀ wò ṣáájú, wàá mọ ohun tó o lè ṣe láti rí i dájú pé ohun tí ìwọ àtàwọn àlejò rẹ bá ṣe yóò fi hàn pé ẹ̀ ń fi ohun tí Bíbélì kọ́ yín sílò.—Róòmù 12:2.

Báwo Ni Nǹkan Ṣe Máa Lọ Sí Níbi Àpèjẹ Náà?

5. Kí nìdí tí ẹni tó pe àpèjẹ fi ní láti ronú jinlẹ̀ nípa pípèsè ọtí àti orin?

5 Ọ̀pọ̀ àwọn tó pe àpèjẹ máa ń ronú nípa bóyá káwọn fún àwọn àlejò wọn ní ọtí tàbí káwọn má ṣe bẹ́ẹ̀. Kò dìgbà tí ọtí bá wà níbi àpèjẹ kí irú àpèjẹ bẹ́ẹ̀ tó dùn. Wàá rántí pé Jésù pèsè oúnjẹ fún ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó wá bá a, ó fún wọn ní búrẹ́dì àti ẹja. Ìtàn yẹn ò sọ pé ó pèsè wáìnì lọ́nà ìyanu, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a mọ̀ pé ó lè ṣe é. (Mátíù 14:14-21) Bó o bá fẹ́ pèsè ọtí níbi àpèjẹ, jẹ́ kó wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, kó o sì rí i pé àwọn ohun mímu míì wà yàtọ̀ sí ọtí fáwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ sí irú rẹ̀. (1 Tímótì 3:2, 3, 8; 5:23; 1 Pétérù 4:3) O ò gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun tó máa jẹ́ kí ẹnikẹ́ni rò pé òun ní láti mu ọtí tó jẹ́ ohun tó lè “buni ṣán gẹ́gẹ́ bí ejò.” (Òwe 23:29-32) Bí orin bá máa wà níbẹ̀ ńkọ́? Bí orin bá máa wà níbẹ̀, rí i pé o fara balẹ̀ ṣe àṣàyàn àwọn orin tó o máa lò, kó o sì wo ìlù tí wọ́n lù nínú rẹ̀ àti ọ̀rọ̀ inú orin náà. (Kólósè 3:8; Jákọ́bù 1:21) Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ti rí i pé gbígbọ́ àwọn orin atunilára tí ètò Ọlọ́run ṣe, ìyẹn Kingdom Melodies, tàbí kíkọ irú orin bẹ́ẹ̀ pa pọ̀ máa ń jẹ́ kí àpèjẹ dùn. (Éfésù 5:19, 20) Bákan náà, o tún ní láti rí i pé ò ń kíyè sí bí orin náà ṣe lọ sókè sí látìgbàdégbà kí orin náà má bàa ṣèdíwọ́ fáwọn àlejò rẹ tó ń fọ̀rọ̀ wérọ̀ àtàwọn ará àdúgbò.—Mátíù 7:12.

6. Báwo lẹni tó pe àpèjẹ ṣe lè jẹ́ kó hàn pé ìgbàgbọ́ òun kì í ṣe òkú nígbà táwọn èèyàn bá ń fọ̀rọ̀ wérọ̀ tàbí táwọn nǹkan mìíràn bá ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀?

6 Nígbà táwọn Kristẹni bá kóra jọ fún àpèjẹ, wọ́n lè sọ̀rọ̀ nípa onírúurú nǹkan, kí wọ́n ka àwọn ohun kan jáde látinú ìwé tàbí kí wọ́n sọ àwọn ìrírí tí ń gbéni ró. Bó bá di pé àwọn tó wà níbẹ̀ fẹ́ máa sọ ohun tí kò bójú mu, ẹni tó pe àpèjẹ náà lè rọra fi ọgbọ́n darí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ náà sí ohun tó bá ìlànà Bíbélì mu. Ó tún yẹ kó rí i dájú pé ẹnì kan ṣoṣo kọ́ ló ń dá gbogbo ọ̀rọ̀ sọ. Bó bá kíyè sí i pé ẹnì kan fẹ́ máa sọ̀rọ̀ ṣáá, ó lè rọra fi ọgbọ́n sọ ohun tó máa jẹ́ káwọn mìíràn lè dá sí ọ̀rọ̀ náà, bóyá kó sọ pé káwọn ọmọdé sọ èrò wọn lórí àwọn nǹkan kan tàbí kó ju ọ̀rọ̀ kan sílẹ̀ táwọn èèyàn máa dá sí. Àtọmọdé àtàgbà ni inú wọn máa dùn bí àpèjẹ bá rí báyìí. Bí ìwọ tó o pe àpèjẹ bá fi ọgbọ́n àti òye ṣe ètò náà, ‘ìfòyebánilò rẹ á di mímọ̀’ fún àwọn tó wà níbẹ̀. (Fílípì 4:5) Wọ́n á rí i pé ìgbàgbọ́ rẹ kì í ṣe òkú, pé ó ń nípa lórí gbogbo ohun tó ò ń ṣe.

Ìgbéyàwó àti Àpèjẹ Ìgbéyàwó

7. Kí nìdí tí ètò ìgbéyàwó àtàwọn ayẹyẹ míì tó máa wáyé lákòókò náà fi gba àròjinlẹ̀?

7 Ìgbéyàwó àwa Kristẹni jẹ́ ohun pàtàkì kan tó ń fún wa láyọ̀. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láyé àtijọ́ fi tayọ̀tayọ̀ kópa nínú irú ayẹyẹ alárinrin bẹ́ẹ̀ àti àsè tó ń bá a rìn. Kódà, Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pàápàá lọ síbi ayẹyẹ bẹ́ẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 29:21, 22; Jòhánù 2:1, 2) Àmọ́ o, láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbi ìgbéyàwó ti jẹ́ ká rí i kedere pé a ní láti gbé gbogbo ètò tá à ń ṣe yẹ̀ wò dáadáa tá a bá fẹ́ kí ohun tó máa wáyé níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó wa fi hàn pé Kristẹni tó lóye ni wá àti pé à ń ṣe nǹkan ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Ó ṣe tán, ayẹyẹ ìgbéyàwó jẹ́ ara irú àwọn ohun tí Kristẹni kan lè lọ́wọ́ sí, tó sì lè lo àǹfààní èyí láti fi hàn pé ìgbàgbọ́ òun kì í ṣe òkú.

8, 9. Báwo lohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbi ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó ṣe fi hàn kedere pé òótọ́ lohun tó wà nínú 1 Jòhánù 2:16, 17?

8 Ọ̀pọ̀ àwọn tí kò mọ àwọn ìlànà Bíbélì tàbí tí wọn kò kà á sí máa ń wo ìgbà ìgbéyàwó gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí wọ́n lè ṣe bó ṣe wù wọ́n, láìsí pé ẹnikẹ́ni ń ká wọn lọ́wọ́ kò. Nínú ìwé ìròyìn kan tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Yúróòpù, obìnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó sọ pé wọ́n ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó òun ayé gbọ́ ọ̀run mọ̀, ó ní: ‘Inú kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí ẹṣin mẹ́rin ń fà la wà lọ́jọ́ náà. Kẹ̀kẹ́ ẹṣin méjìlá ló tẹ̀ lé wa, bẹ́ẹ̀ làwọn olórin náà wà nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin tiwọn. Lẹ́yìn èyí la wá lọ jẹ oúnjẹ àjẹpọ́nnulá, tá a sì gbádùn orin aládùn. Ayẹyẹ yẹn ti lọ wà jù. Bí mo ṣe fẹ́ gan-an ló rí, ńṣe ni mo dà bí ayaba lọ́jọ́ náà.’

9 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà ibì kọ̀ọ̀kan máa ń yàtọ̀, ohun tó sọ yẹn fi hàn kedere pé òótọ́ lohun tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ sílẹ̀, ó ní: “Ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími—kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé.” Ǹjẹ́ o rò pé àwọn Kristẹni méjì tí wọ́n dàgbà dénú á fẹ́ ṣe ìgbéyàwó tó jẹ́ pé ayé á gbọ́ ọ̀run á mọ̀? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo ètò tí wọ́n bá ṣe ní láti fi hàn pé wọ́n ti ronú jinlẹ̀ lórí ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé “ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:16, 17.

10. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn ronú dáadáa tó bá fẹ́ ṣe ìgbéyàwó tó mọ́gbọ́n dání? (b) Báwo ló ṣe yẹ kí wọ́n ṣèpinnu nípa àwọn tí wọ́n máa pè?

10 Kò yẹ káwọn Kristẹni tó fẹ́ ṣègbéyàwó ṣe ju ara wọn lọ, wọ́n sì ní láti ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu. Bíbélì lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe èyí. Ọjọ́ ìgbéyàwó ṣe pàtàkì lóòótọ́, àmọ́ wọ́n mọ̀ pé ńṣe ló wulẹ̀ jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé àwọn Kristẹni méjì tí wọ́n ní ìrètí pé àwọn yóò jọ wà láàyè títí láé. Kò pọn dandan kí wọ́n filé pọntí fọ̀nà rokà nígbà ìgbéyàwó wọn. Bí wọ́n bá fẹ́ pe àpèjẹ, wọ́n ní láti ronú nípa iye tó máa ná wọn àti bí ètò náà a ṣe lọ sí. (Lúùkù 14:28) Nígbà táwọn Kristẹni méjèèjì bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya, ọkọ ni yóò jẹ́ orí gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ. (1 Kọ́ríńtì 11:3; Éfésù 5:22, 23) Nítorí náà, ọkọ ìyàwó gan-an ló máa pinnu ohun tó máa wáyé níbi àpèjẹ ìgbéyàwó náà. Á dára kó gba èrò ìyàwó rẹ̀ nípa ètò àpèjẹ náà yẹ̀ wò ṣá o, kí wọ́n jọ sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí wọ́n fẹ́ kó wá tàbí iye àwọn tí agbára wọn gbé láti pè. Ó lè má ṣeé ṣe láti pe gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ wọn àti mọ̀lẹ́bí wọn, ó tiẹ̀ lè máà mọ́gbọ́n dání láti ṣe bẹ́ẹ̀; nítorí náà, wọ́n ní láti mọ̀wọ̀n ara wọn kí wọ́n sì ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Ó yẹ kí ọkàn àwọn tó fẹ́ di tọkọtaya náà balẹ̀ pé bí àwọn kò bá pe àwọn kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí bíi tiwọn, wọ́n á gba tàwọn rò wọn ò sì ní fi ṣe ìbínú.—Oníwàásù 7:9.

“Olùdarí Àsè”

11. Ipa wo ni ẹni tó bá ṣe “olùdarí àsè” ń kó níbi ìgbéyàwó?

11 Bí àwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó bá fẹ́ kó àwọn èèyàn lẹ́nu jọ nígbà ìgbéyàwó wọn, báwo ni wọ́n ṣe lè rí i dájú pé àwọn ohun tó bójú mu ló máa wáyé níbi ayẹyẹ náà? Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti mọ̀ pé ó bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn ṣe irú ètò kan tí Bíbélì sọ pé wọ́n ṣe níbi àsè ìgbéyàwó tí Jésù lọ ní Kánà. Ètò tí wọ́n ṣe níbẹ̀ ni pé wọ́n yan “olùdarí àsè,” ó sì dájú pé olùjọsìn Ọlọ́run kan tó dàgbà dénú ni wọ́n fi ṣe olùdarí yìí. (Jòhánù 2:9, 10) Bákan náà, arákùnrin kan tó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí ni ọkọ ìyàwó tó bá gbọ́n yóò yàn láti kó ipa pàtàkì yìí. Tí olùdarí àsè náà bá ti mọ àwọn ohun tí ọkọ ìyàwó fẹ́, yóò tẹ̀ lé àwọn ohun náà ṣáájú kí ayẹyẹ náà tó bẹ̀rẹ̀ àti nígbà tó bá ń lọ lọ́wọ́.

12. Kí ni ọkọ ìyàwó ní láti fi sọ́kàn nípa ọ̀rọ̀ ọtí?

12 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe jíròrò ní ìpínrọ̀ 5, àwọn kan tó fẹ́ ṣègbéyàwó kì í pèsè ọtí níbi àsè ìgbéyàwó wọn kó má bàa di pé ọtí àmupara ba ayọ̀ ayẹyẹ náà jẹ́. (Róòmù 13:13; 1 Kọ́ríńtì 5:11) Àmọ́, bí wọ́n bá máa pèsè ọtí, ọkọ ìyàwó ní láti rí i dájú pé ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ni wọ́n fún àwọn èèyàn. Wáìnì wà níbi ìgbéyàwó tí Jésù lọ ní Kánà, wáìnì tó dára gan-an sì ni. Àní, olùdarí àsè náà sọ pé: “Olúkúlùkù ènìyàn mìíràn a kọ́kọ́ gbé wáìnì àtàtà jáde, nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì ti mutíyó tán, yóò sì kan gbàrọgùdù. Ìwọ ti fi wáìnì àtàtà pa mọ́ títí di ìsinsìnyí.” (Jòhánù 2:10) Ó dájú pé Jésù ò ṣe ohun tó máa mú káwọn èèyàn mu ọtí àmupara, torí ó mọ̀ pé ọtí àmupara kò dára. (Lúùkù 12:45, 46) Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún olùdarí àsè náà láti rí bí wáìnì náà ṣe dára tó, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì fi hàn pé ó ti rí ibi táwọn kan ti mutí àmupara níbi ìgbéyàwó. (Ìṣe 2:15; 1 Tẹsalóníkà 5:7) Nítorí náà, ọkọ ìyàwó àti Kristẹni tó ṣeé gbára lé tó fi ṣe olùdarí àsè ní láti rí i dájú pé gbogbo àwọn tó pésẹ̀ ló tẹ̀ lé ìtọ́ni tó ṣe kedere yìí pé: “Ẹ má ṣe máa mu wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí ìwà wọ̀bìà wà.”—Éfésù 5:18; Òwe 20:1; Hóséà 4:11.

13. Kí ló yẹ kí àwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó fi sọ́kàn tí wọ́n bá fẹ́ kí orin wà níbi àpèjẹ ìgbéyàwó wọn, kí sì nìdí?

13 Gẹ́gẹ́ bó ṣe yẹ kó rí láwọn ibi táwọn Kristẹni bá kóra jọ sí, bí orin bá máa wà, wọ́n ní láti rí i pé kò lọ sókè jù débi pé àwọn èèyàn ò ní lè gbọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń bára wọn sọ. Alàgbà kan sọ pé: “Bí ilẹ̀ bá ti ń ṣú lọ, tó di pé ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn ń sọ ti wọ̀ wọ́n lára tàbí tí ijó ti bẹ̀rẹ̀, wọ́n máa ń yí ohùn orin sókè nígbà míì. Orin tó rọra ń dún tẹ́lẹ̀ lè wá lọ sókè gan-an débi pé àwọn èèyàn ò ní lè gbọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń bára wọn sọ. Èèyàn máa ń láǹfààní láti bá àwọn ẹlòmíràn fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀ níbi àpèjẹ ìgbéyàwó. Á mà burú o tó bá di pé ariwo orin ò jẹ́ kí ìyẹn lè ṣeé ṣe!” Lórí kókó yìí náà, ó yẹ kí ọkọ ìyàwó àti olùdarí àsè ṣe ojúṣe wọn. Kò yẹ kí wọ́n jẹ́ kí àwọn olórin tàbí àwọn tí wọ́n bá fi sídìí orin pinnu irú orin tí wọ́n máa lò àti bí orin náà yóò ṣe lọ sókè tó, ì báà jẹ́ pé wọ́n máa sanwó fún wọn àbí wọn ò gbowó. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ohun yòówù tí ẹ bá sì ń ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí ní iṣẹ́, ẹ máa ṣe ohun gbogbo ní orúkọ Jésù Olúwa.” (Kólósè 3:17) Nígbà táwọn tí wọ́n pè síbi àpèjẹ ìgbéyàwó bá padà sílé wọn, ǹjẹ́ kò yẹ kí wọ́n máa rántí pé orin tó wà níbẹ̀ fi hàn pé tọkọtaya náà ṣe ohun gbogbo lórúkọ Jésù? Bó ṣe yẹ kí ọ̀rọ̀ rí nìyẹn o.

14. Kí ló yẹ kó máa múnú àwọn Kristẹni dùn tí wọ́n bá ń rántí ibi ìgbéyàwó tí wọ́n lọ?

14 Ká má purọ́, bí nǹkan bá lọ létòlétò níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó kan, tìdùnnú-tìdùnnú làwọn èèyàn á fi máa rántí rẹ̀. Ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn ni Adam àti Edyta ṣègbéyàwó. Nígbà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó kan tí wọ́n lọ, wọ́n ní: “Kò sí béèyàn ò ṣe ní rí i pé àwọn Kristẹni ló ń ṣe nǹkan. Wọ́n kọ orin ìyìn sí Jèhófà, síbẹ̀ wọ́n tún fi àwọn nǹkan míì dá àwọn èèyàn lára yá. Kì í ṣe orin àti ijó ló kó ipa pàtàkì níbẹ̀. Ayẹyẹ ọ̀hún dùn ó sì gbéni ró, gbogbo ohun tó wáyé níbẹ̀ ló bá ìlànà Bíbélì mu.” Ó ṣe kedere pé, ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìyàwó àti ọkọ lè ṣe láti jẹ́ káwọn èèyàn rí i pé àwọn ń fi iṣẹ́ ti ìgbàgbọ́ wọn lẹ́yìn.

Fífúnni Lẹ́bùn Níbi Ìgbéyàwó

15. Ìmọ̀ràn Bíbélì wo la lè tẹ̀ lé tó bá di ọ̀rọ̀ fífúnni lẹ́bùn níbi ìgbéyàwó?

15 Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí sábà máa ń fún àwọn tó ń ṣègbéyàwó lẹ́bùn. Bó o bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, kí ló yẹ kó o fi sọ́kàn? Má ṣe gbàgbé ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù sọ nípa “fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími.” Ó jẹ́ ká mọ̀ pé, àwọn Kristẹni tí wọ́n ń fi iṣẹ́ ti ìgbàgbọ́ wọn lẹ́yìn kọ́ ló ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, ‘ayé tí ń kọjá lọ’ ló ń ṣe é. (1 Jòhánù 2:16, 17) Pẹ̀lú ohun tí ẹ̀mí mímọ́ darí Jòhánù láti sọ yìí, ǹjẹ́ ó yẹ káwọn tọkọtaya náà dárúkọ àwọn tó fún wọn lẹ́bùn fún gbogbo èèyàn? Àwọn Kristẹni tó wà ní Makedóníà àti Ákáyà fi nǹkan ránṣẹ́ sáwọn ará wọn ní Jerúsálẹ́mù, ṣùgbọ́n kò sóhun tó fi hàn pé wọ́n dárúkọ wọn fún gbogbo èèyàn. (Róòmù 15:26) Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tí wọ́n ń fúnni lẹ́bùn ìgbéyàwó kò ní fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé àwọn làwọn mú ẹ̀bùn wá torí pé wọn ò ní fẹ́ ṣe àṣehàn. Níbi tí ọ̀rọ̀ dé yìí, wo ìmọ̀ràn Jésù tó wà nínú Mátíù 6:1-4.

16. Báwo làwọn tó ń ṣègbéyàwó ṣe lè yẹra fún kíkó ìtìjú bá àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n bá ń gba ẹ̀bùn ìgbéyàwó?

16 Tí wọ́n bá ń dárúkọ àwọn tó fúnni lẹ́bùn, èyí lè mú káwọn èèyàn máa ‘ru ìdíje sókè pẹ̀lú ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì,’ kí wọ́n máa wo ẹni tí ẹ̀bùn tiẹ̀ dára jù tàbí tówó ẹ̀ pọ̀ jù. Nípa báyìí, àwọn Kristẹni ọlọ́gbọ́n tó ń ṣègbéyàwó ò ní dárúkọ àwọn tó fún wọn lẹ́bùn fún gbogbo èèyàn. Kíkéde orúkọ àwọn tó mú ẹ̀bùn wá lè kó ìtìjú bá àwọn tí kò bá lè mú ẹ̀bùn wá. (Gálátíà 5:26; 6:10) Kò burú tí ọkọ àti ìyàwó bá mọ ẹni tó fún wọn lẹ́bùn kọ̀ọ̀kan o. Wọ́n lè fi ìwé tàbí káàdì tó wà lára ẹ̀bùn náà mọ ẹni tó fún wọn lẹ́bùn, ṣùgbọ́n wọn ò ní ka orúkọ wọn jáde fún gbogbo èèyàn. Yálà àwa la fẹ́ ra ẹ̀bùn tá a máa fún àwọn tó ń ṣègbéyàwó tàbí àwa la fẹ́ gbà á, gbogbo wa lè fi hàn pé ìgbàgbọ́ wa ń nípa lórí ohun tí à ń ṣe, títí kan ohun tó jẹ́ ọ̀rọ̀ ara ẹni yìí pàápàá.a

17. Kí ló yẹ káwọn Kristẹni máa ní lọ́kàn nípa ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ wọn?

17 Dájúdájú, kì í ṣe híhùwà ọmọlúwàbí, lílọ sí ìpàdé ìjọ àti ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù nìkan ló máa fi hàn pé à ń fi iṣẹ́ ti ìgbàgbọ́ wa lẹ́yìn. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan rí i dájú pé ìgbàgbọ́ wa kì í ṣe òkú, ṣùgbọ́n pé ó ń nípa lórí gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni o, a lè fi ìgbàgbọ́ wa hàn nípa rírí i pé à ń ṣe àwọn iṣẹ́ wa “ní kíkún,” títí kan irú àwọn ohun tá a mẹ́nu kàn lókè yìí.—Ìṣípayá 3:2.

18. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Jòhánù 13:17 níbi ìgbéyàwó àwọn Kristẹni tàbí níbi àpèjẹ?

18 Lẹ́yìn tí Jésù fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ nípa fífi ìrẹ̀lẹ̀ wẹ ẹsẹ̀ wọn, ó ní: “Bí ẹ bá mọ nǹkan wọ̀nyí, aláyọ̀ ni yín bí ẹ bá ń ṣe wọ́n.” (Jòhánù 13:4-17) Níbi tí à ń gbé lónìí, ó lè má pọn dandan fáwọn èèyàn láti máa wẹ ẹsẹ̀ ẹlòmíì, irú bí àlejò tó bá wá kí wọn nílé, ó sì lè máà jẹ́ àṣà wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bá a ṣe gbé e yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí, àwọn nǹkan míì wà tá a ti lè fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ nípa ṣíṣe àwọn ohun tó máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn a sì gba tiwọn rò, títí kan irú àwọn ohun tó ń wáyé nígbà àpèjẹ àti nígbà ìgbéyàwó àwa Kristẹni. A lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, yálà àwa là ń ṣègbéyàwó tàbí wọ́n pè wá síbi ìgbéyàwó tàbí síbi àpèjẹ tó máa ń wáyé lẹ́yìn ìgbéyàwó àwọn Kristẹni tí wọ́n fẹ́ kí ohun tí wọ́n ń ṣe fi hàn pé àwọn ń fi iṣẹ́ ti ìgbàgbọ́ wọn lẹ́yìn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun mìíràn tó ń ṣẹlẹ̀ níbi ìgbéyàwó àti níbi àpèjẹ tó máa ń wáyé lẹ́yìn ìgbéyàwó nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, tó ní àkòrí náà, “Ṣe Ohun Tó Máa Jẹ́ Kí Ayọ̀ àti Iyì Ọjọ́ Ìgbéyàwó Rẹ Pọ̀ Sí I.”

Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?

Báwo lo ṣe lè fi hàn pé ò ń fi iṣẹ́ ti ìgbàgbọ́ rẹ lẹ́yìn

• tó o bá fẹ́ pe àpèjẹ?

• tó o bá fẹ́ ṣètò ìgbéyàwó tàbí àpèjẹ ìgbéyàwó?

• tó o bá fẹ́ fúnni lẹ́bùn tàbí tó o fẹ́ gbà á?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Àní bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ lo pè pàápàá, rí i pé ó fi “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè” darí ètò náà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́