ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́sírà 10
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́sírà

      • Wọ́n dá májẹ̀mú láti lé àwọn aya àjèjì lọ (1-14)

      • Wọ́n lé àwọn aya àjèjì lọ (15-44)

Ẹ́sírà 10:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 9:5, 6

Ẹ́sírà 10:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “mú àwọn obìnrin àjèjì wá sílé wa.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 10:26, 44
  • +Ẹsr 2:1, 7
  • +Ẹsr 9:2

Ẹ́sírà 10:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ìbẹ̀rù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 11:17; 2Kr 29:10; 34:31
  • +Ẹsr 9:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2006, ojú ìwé 20

Ẹ́sírà 10:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 10:28-30

Ẹ́sírà 10:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gbọ̀ngàn ìjẹun.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 9:3, 4; Da 9:3-5

Ẹ́sírà 10:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “fòfin de.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 7:26

Ẹ́sírà 10:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 13:23

Ẹ́sírà 10:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 7:3, 4; Ne 13:3; 2Kọ 6:17

Ẹ́sírà 10:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 9:1

Ẹ́sírà 10:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 8:7; 11:16

Ẹ́sírà 10:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 9:1, 2; Ne 13:28; Isk 44:22; Mal 2:7, 8
  • +Ẹsr 2:1, 2; 3:2; Sek 6:11

Ẹ́sírà 10:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “wọ́n na ọwọ́ wọn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 5:17, 18

Ẹ́sírà 10:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 24:3, 14; Ẹsr 2:1, 37

Ẹ́sírà 10:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 24:3, 8; Ẹsr 2:1, 39

Ẹ́sírà 10:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 2:1, 38

Ẹ́sírà 10:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 2:1, 3; Ne 3:25

Ẹ́sírà 10:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 2:1, 7; 8:1, 7
  • +Ẹsr 10:2

Ẹ́sírà 10:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 2:1, 8

Ẹ́sírà 10:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 2:1, 11; 8:1, 11

Ẹ́sírà 10:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 2:1, 6

Ẹ́sírà 10:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 2:1, 32
  • +Ne 3:11

Ẹ́sírà 10:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 2:1, 19; Ne 8:4

Ẹ́sírà 10:44

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 7:3, 4
  • +Ẹsr 10:16, 17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2006, ojú ìwé 20

Àwọn míì

Ẹ́sírà 10:1Ẹsr 9:5, 6
Ẹ́sírà 10:2Ẹsr 10:26, 44
Ẹ́sírà 10:2Ẹsr 2:1, 7
Ẹ́sírà 10:2Ẹsr 9:2
Ẹ́sírà 10:32Ọb 11:17; 2Kr 29:10; 34:31
Ẹ́sírà 10:3Ẹsr 9:4
Ẹ́sírà 10:5Ne 10:28-30
Ẹ́sírà 10:6Ẹsr 9:3, 4; Da 9:3-5
Ẹ́sírà 10:8Ẹsr 7:26
Ẹ́sírà 10:10Ne 13:23
Ẹ́sírà 10:11Di 7:3, 4; Ne 13:3; 2Kọ 6:17
Ẹ́sírà 10:14Ẹsr 9:1
Ẹ́sírà 10:15Ne 8:7; 11:16
Ẹ́sírà 10:18Ẹsr 9:1, 2; Ne 13:28; Isk 44:22; Mal 2:7, 8
Ẹ́sírà 10:18Ẹsr 2:1, 2; 3:2; Sek 6:11
Ẹ́sírà 10:19Le 5:17, 18
Ẹ́sírà 10:201Kr 24:3, 14; Ẹsr 2:1, 37
Ẹ́sírà 10:211Kr 24:3, 8; Ẹsr 2:1, 39
Ẹ́sírà 10:22Ẹsr 2:1, 38
Ẹ́sírà 10:25Ẹsr 2:1, 3; Ne 3:25
Ẹ́sírà 10:26Ẹsr 2:1, 7; 8:1, 7
Ẹ́sírà 10:26Ẹsr 10:2
Ẹ́sírà 10:27Ẹsr 2:1, 8
Ẹ́sírà 10:28Ẹsr 2:1, 11; 8:1, 11
Ẹ́sírà 10:30Ẹsr 2:1, 6
Ẹ́sírà 10:31Ẹsr 2:1, 32
Ẹ́sírà 10:31Ne 3:11
Ẹ́sírà 10:33Ẹsr 2:1, 19; Ne 8:4
Ẹ́sírà 10:44Di 7:3, 4
Ẹ́sírà 10:44Ẹsr 10:16, 17
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
  • 37
  • 38
  • 39
  • 40
  • 41
  • 42
  • 43
  • 44
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ẹ́sírà 10:1-44

Ẹ́sírà

10 Bí Ẹ́sírà ṣe ń gbàdúrà,+ tó sì ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́, tó ń sunkún, tó sì dojú bolẹ̀ níwájú ilé Ọlọ́run tòótọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lọ́kùnrin, lóbìnrin àti àwọn ọmọdé ní Ísírẹ́lì kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn èèyàn náà sì ń sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀. 2 Ni Ṣẹkanáyà ọmọ Jéhíélì+ látinú àwọn ọmọ Élámù+ bá sọ fún Ẹ́sírà pé: “A ti hùwà àìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wa, bí a ṣe fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì* láàárín àwọn èèyàn ilẹ̀ tó yí wa ká.+ Síbẹ̀ náà, ìrètí ṣì wà fún Ísírẹ́lì. 3 Ní báyìí, jẹ́ ká bá Ọlọ́run wa dá májẹ̀mú+ pé a máa lé gbogbo àwọn aya náà lọ àti àwọn ọmọ tí wọ́n bí, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Jèhófà pa àti ohun tí àwọn tó ní ọ̀wọ̀* fún àṣẹ Ọlọ́run wa sọ.+ Ká ṣe ohun tí Òfin sọ. 4 Dìde, torí ìwọ lo ni iṣẹ́ yìí, a sì wà pẹ̀lú rẹ. Jẹ́ onígboyà, kí o sì gbé ìgbésẹ̀.”

5 Ni Ẹ́sírà bá dìde, ó sì ní kí àwọn tó jẹ́ olórí láàárín àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì àti gbogbo Ísírẹ́lì búra láti ṣe ohun tí wọ́n sọ.+ Torí náà, wọ́n búra. 6 Ẹ́sírà wá dìde kúrò níwájú ilé Ọlọ́run tòótọ́, ó sì lọ sínú yàrá* Jèhóhánánì ọmọ Élíáṣíbù nínú tẹ́ńpìlì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lọ síbẹ̀, kò jẹun, kò sì mu omi, torí ó ń ṣọ̀fọ̀ lórí ìwà àìṣòótọ́ àwọn tó dé láti ìgbèkùn.+

7 Lẹ́yìn náà, wọ́n kéde káàkiri Júdà àti Jerúsálẹ́mù pé kí gbogbo àwọn tó wà nígbèkùn tẹ́lẹ̀ kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù; 8 ẹnikẹ́ni tí kò bá sì wá láàárín ọjọ́ mẹ́ta, a ó gba* gbogbo ẹrù rẹ̀, a ó sì lé e kúrò ní àwùjọ àwọn tó dé láti ìgbèkùn, gẹ́gẹ́ bí ìpinnu tí àwọn olórí àti àwọn àgbààgbà ṣe.+ 9 Nítorí náà, gbogbo àwọn èèyàn Júdà àti Bẹ́ńjámínì kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù láàárín ọjọ́ mẹ́ta, ìyẹn ní oṣù kẹsàn-án, ní ogúnjọ́ oṣù náà. Gbogbo àwọn èèyàn náà jókòó sí àgbàlá ilé Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n ń gbọ̀n nítorí ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ àti nítorí òjò ńlá tó ń rọ̀.

10 Nígbà náà, àlùfáà Ẹ́sírà dìde, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ ti hùwà àìṣòótọ́ bí ẹ ṣe lọ ń fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì,+ ẹ sì ti dá kún ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì. 11 Ní báyìí, ẹ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín, kí ẹ sì ṣe ohun tí ó fẹ́. Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn èèyàn ilẹ̀ náà àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn aya àjèjì.”+ 12 Gbogbo ìjọ náà wá dáhùn ní ohùn tó ròkè pé: “Ojúṣe wa ni láti ṣe ohun tí o sọ. 13 Àmọ́, àwọn èèyàn náà pọ̀, àsìkò òjò sì ni. Èèyàn ò lè dúró níta, ọ̀rọ̀ náà kì í sì í ṣe ohun tí a lè parí lọ́jọ́ kan tàbí méjì, nítorí a ti ṣọ̀tẹ̀ gan-an nínú ọ̀ràn yìí. 14 Ní báyìí, jọ̀wọ́, jẹ́ kí àwọn olórí wa ṣojú fún gbogbo ìjọ yìí;+ kí gbogbo àwọn tó wà nínú àwọn ìlú wa tí wọ́n ti fẹ́ àwọn aya àjèjì sì jáde wá ní àkókò tí a dá pẹ̀lú àwọn àgbààgbà àti àwọn onídàájọ́ ìlú kọ̀ọ̀kan, títí a ó fi yí ìbínú Ọlọ́run wa tó ń jó bí iná kúrò lórí wa, nítorí ọ̀ràn yìí.”

15 Àmọ́, Jónátánì ọmọ Ásáhélì àti Jaseáyà ọmọ Tíkífà ta ko ọ̀rọ̀ yìí, Méṣúlámù àti Ṣábétáì+ tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì sì tì wọ́n lẹ́yìn. 16 Ṣùgbọ́n àwọn tó wà nígbèkùn tẹ́lẹ̀ ṣe ohun tí wọ́n fẹnu kò sí; àlùfáà Ẹ́sírà àti àwọn olórí ìdílé nínú àwọn agbo ilé bàbá wọn, tí orúkọ wọn wà lákọsílẹ̀, kóra jọ lọ́tọ̀ ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹwàá láti bójú tó ọ̀rọ̀ náà; 17 nígbà tó di ọjọ́ kìíní oṣù kìíní, wọ́n yanjú ọ̀rọ̀ gbogbo àwọn ọkùnrin tó fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì. 18 A sì wá rí i pé lára àwọn ọmọ àlùfáà ti fẹ́ àwọn aya àjèjì,+ àwọn ni: látinú àwọn ọmọ Jéṣúà+ ọmọ Jèhósádákì àti àwọn arákùnrin rẹ̀, Maaseáyà, Élíésérì, Járíbù àti Gẹdaláyà. 19 Àmọ́, wọ́n ṣèlérí* pé àwọn máa lé àwọn aya wọn lọ, bákan náà, torí pé wọ́n jẹ̀bi, wọ́n máa fi àgbò kan látinú agbo ẹran rúbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.+

20 Látinú àwọn ọmọ Ímérì,+ Hánáánì àti Sebadáyà; 21 látinú àwọn ọmọ Hárímù,+ Maaseáyà, Èlíjà, Ṣemáyà, Jéhíélì àti Ùsáyà; 22 látinú àwọn ọmọ Páṣúrì,+ Élíóénáì, Maaseáyà, Íṣímáẹ́lì, Nétánélì, Jósábádì àti Éléásà. 23 Látinú àwọn ọmọ Léfì, Jósábádì, Ṣíméì, Keláyà (ìyẹn, Kélítà), Petaháyà, Júdà àti Élíésérì; 24 látinú àwọn akọrin, Élíáṣíbù; látinú àwọn aṣọ́bodè, Ṣálúmù, Télémù àti Úráì.

25 Látinú Ísírẹ́lì, nínú àwọn ọmọ Páróṣì,+ Ramáyà, Isáyà, Málíkíjà, Míjámínì, Élíásárì, Málíkíjà àti Bẹnáyà; 26 látinú àwọn ọmọ Élámù,+ Matanáyà, Sekaráyà, Jéhíélì,+ Ábídì, Jérémótì àti Èlíjà; 27 látinú àwọn ọmọ Sátù,+ Élíóénáì, Élíáṣíbù, Matanáyà, Jérémótì, Sábádì àti Ásísà; 28 látinú àwọn ọmọ Bébáì,+ Jèhóhánánì, Hananáyà, Sábáì àti Átíláì; 29 látinú àwọn ọmọ Bánì, Méṣúlámù, Málúkù, Ádáyà, Jáṣúbù, Ṣéálì àti Jérémótì; 30 látinú àwọn ọmọ Pahati-móábù,+ Ádúnà, Kélálì, Bẹnáyà, Maaseáyà, Matanáyà, Bẹ́sálẹ́lì, Bínúì àti Mánásè; 31 látinú àwọn ọmọ Hárímù,+ Élíésérì, Isiṣíjà, Málíkíjà,+ Ṣemáyà, Ṣíméónì, 32 Bẹ́ńjámínì, Málúkù àti Ṣemaráyà; 33 látinú àwọn ọmọ Háṣúmù,+ Máténáì, Mátáátà, Sábádì, Élífélétì, Jérémáì, Mánásè àti Ṣíméì; 34 látinú àwọn ọmọ Bánì, Máádáì, Ámúrámù, Yúẹ́lì, 35 Bẹnáyà, Bedeáyà, Kélúhì, 36 Fanáyà, Mérémótì, Élíáṣíbù, 37 Matanáyà, Máténáì àti Jáásù; 38 látinú àwọn ọmọ Bínúì, Ṣíméì, 39 Ṣelemáyà, Nátánì, Ádáyà, 40 Makinádébáì, Ṣáṣáì, Ṣáráì, 41 Ásárẹ́lì, Ṣelemáyà, Ṣemaráyà, 42 Ṣálúmù, Amaráyà àti Jósẹ́fù; 43 látinú àwọn ọmọ Nébò, Jéélì, Matitáyà, Sábádì, Sébínà, Jádáì, Jóẹ́lì àti Bẹnáyà. 44 Gbogbo àwọn yìí ni wọ́n fẹ́ àwọn aya àjèjì,+ wọ́n sì lé àwọn aya wọn lọ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́