Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé “ìfẹ́ pípé a máa ju ìbẹ̀rù sóde,” kí ni “ìfẹ́ pípé” yẹn túmọ̀ sí, kí sì ni “ìbẹ̀rù” tó máa jù sóde?
Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Kò sí ìbẹ̀rù nínú ìfẹ́, ṣùgbọ́n ìfẹ́ pípé a máa ju ìbẹ̀rù sóde, nítorí ìbẹ̀rù a máa ṣèdíwọ́ fúnni. Ní tòótọ́, ẹni tí ó bá wà lábẹ́ ìbẹ̀rù ni a kò tíì sọ di pípé nínú ìfẹ́.”—1 Jòhánù 4:18.
Àyíká ọ̀rọ̀ yẹn fi hàn pé òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ni Jòhánù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ìyẹn àjọṣe tó wà láàárín ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti òmìnira láti bá A sọ̀rọ̀. A lè rí èyí nínú ohun tá a kà ní ẹsẹ kẹtàdínlógún, tó sọ̀ pé: “Báyìí ni a ṣe sọ ìfẹ́ di pípé lọ́dọ̀ wa, kí a lè ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ní ọjọ́ ìdájọ́.” Bí Kristẹni kan ṣe nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó àti bó ṣe gbà pé Ọlọ́run fẹ́ràn òun tó ló máa pinnu bóyá á lómìnira ọ̀rọ̀ sísọ—tàbí bóyá kò ní ní i—nígbà tó bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run.
Gbólóhùn náà “ìfẹ́ pípé” ṣe pàtàkì gan-an. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe lò ó nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “pípé” kì í fi gbogbo ìgbà túmọ̀ sí ìjẹ́pípé pátápátá, ìyẹn ìjẹ́pípé délẹ̀délẹ̀, àmọ́ ó máa ń túmọ̀ sí ìjẹ́pípé dé àyè kan lọ́pọ̀ ìgbà. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè pé: “Kí ẹ jẹ́ pípé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí Baba yín ọ̀run ti jẹ́ pípé.” Jésù ń sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé tí wọ́n bá nífẹ̀ẹ́ kìkì àwọn tó fẹ́ràn wọn, a jẹ́ pé ìfẹ́ wọn ò pé nìyẹn, ó mẹ́hẹ, ó sì kù-díẹ̀-ká-à-tó. Wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìfẹ́ wọn di pípé, tàbí kí ó dé ìwọ̀n tó kún rẹ́rẹ́ nípa nínífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn pàápàá. Bákan náà, nígbà tí Jòhánù kọ̀wé nípa “ìfẹ́ pípé,” ohun tó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni béèyàn ṣe gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn, kí ìfẹ́ náà jinlẹ̀ dáadáa, kó sì fara hàn nínú gbogbo ohun téèyàn bá ń ṣe ní ìgbésí ayé rẹ̀.—Mátíù 5:46-48; 19:20, 21.
Nígbà tí Kristẹni kan bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó mọ̀ dájú pé ẹlẹ́ṣẹ̀ àti aláìpé lòun. Àmọ́, tí ìfẹ́ tó ní fún Ọlọ́run àti bó ṣe gbà pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ òun bá jinlẹ̀ dáadáa, ìbẹ̀rù ìdálẹ́bi tàbí dídi ẹni ìtanù kò ní ṣèdíwọ́ fún un. Kàkà bẹ́ẹ̀ á ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ láti sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ jáde àti láti tọrọ ìdáríjì lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà tí Ọlọ́run ti fìfẹ́ pèsè nípasẹ̀ Jésù Kristi. Ọkàn rẹ̀ á sì balẹ̀ pé Ọlọ́run á gbọ́ àdúrà òun.
Báwo la ṣe lè sọ ẹnì kan “di pípé nínú ìfẹ́,” kó sì tipa bẹ́ẹ̀ ‘ju’ ìbẹ̀rù ìdálẹ́bi àti ti dídí ẹni ìtanù ‘sóde’? Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ [Ọlọ́run] mọ́, lótìítọ́ nínú ẹni yìí ni a ti sọ ìfẹ́ fún Ọlọ́run di pípé.” (1 Jòhánù 2:5) Rò ó wò ná: Tí Ọlọ́run bá nífẹ̀ẹ́ wa nígbà tá a ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ǹjẹ́ kò ní nífẹ̀ẹ́ wa jù bẹ́ẹ̀ lọ tá a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, tá a sì ń fi gbogbo ara “pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́”? (Róòmù 5:8; 1 Jòhánù 4:10) Láìsí àní-àní, tá a bá ṣáà ti jẹ́ olóòótọ́, a lè ní irú ìdánilójú kan náà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní nígbà tó sọ nípa Ọlọ́run pé: “Ẹni tí kò dá Ọmọ tirẹ̀ pàápàá sí, ṣùgbọ́n tí ó jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ fún gbogbo wa, èé ṣe tí òun kò ní tún fi inú rere fún wa ní gbogbo ohun yòókù pẹ̀lú rẹ̀?”—Róòmù 8:32.