ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • th ẹ̀kọ́ 4 ojú ìwé 7
  • Nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Yẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Yẹ
  • Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jẹ́ Kí Ìdí Tó O Fi Ka Ìwé Mímọ́ Ṣe Kedere
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Nínasẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tó Dára
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
Àwọn Míì
Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
th ẹ̀kọ́ 4 ojú ìwé 7

Ẹ̀KỌ́ 4

Nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Yẹ

Ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí

Mátíù 22:41-45

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Kọ́kọ́ múra ọkàn àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ sílẹ̀ kó o tó ka Ìwé Mímọ́.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Ronú nípa ìdí tó o fi fẹ́ ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà. Nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ tó o fẹ́ kà lọ́nà tó máa pe àfíyèsí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ sí kókó pàtàkì tó o fẹ́ mú jáde níbẹ̀.

    Àwọn àbá

    Ṣàyẹ̀wò ohun tí wọ́n ń bá bọ̀ ṣáájú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o fẹ́ kà àti ohun tí wọ́n sọ tẹ̀ lé e. Tó o bá fẹ́ sọ orúkọ ẹni tó sọ̀rọ̀ nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o fẹ́ kà tàbí orúkọ ẹni tó kọ ìwé Bíbélì kan, rí i dájú pé àwọn orúkọ yẹn tọ̀nà.

  • Jẹ́ kó ṣe kedere pé ohun tí Bíbélì bá sọ la gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé. Tó bá jẹ́ pé àwọn tó gba Ọlọ́run gbọ́ lò ń bá sọ̀rọ̀, sọ ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n rí i pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì, inú rẹ̀ la sì ti lè rí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó ga jù lọ.

  • Sọ ohun tó máa jẹ́ káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà. Béèrè ọ̀rọ̀ kan tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà máa dáhùn, sọ ìṣòro kan tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà máa yanjú tàbí kó o sọ ìlànà kan tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà máa mú kó ṣe kedere.

    Àwọn àbá

    Ronú nípa ohun táwọn tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀ ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nípa kókó tó ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o fẹ́ kà. Tó o bá fẹ́ ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ táwọn tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀ ti mọ̀ dáadáa, ńṣe ni kó o nasẹ̀ rẹ̀ lọ́nà tó máa mú kí wọ́n túbọ̀ ronú lórí rẹ̀ tàbí kó túbọ̀ yé wọn sí i.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́