ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • sjj orin 73
  • Fún Wa Ní Ìgboyà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fún Wa Ní Ìgboyà
  • “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fún Wá Ní Ìgboyà
    Kọrin sí Jèhófà—Àwọn Orin Tuntun
  • ‘Máa Sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Láìṣojo’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù Máa Fìgboyà Wàásù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ǹjẹ́ O Ń Wàásù Láìṣojo?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
Àwọn Míì
“Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
sjj orin 73

ORIN 73

Fún Wa Ní Ìgboyà

Bíi Ti Orí Ìwé

(Ìṣe 4:29)

  1. 1. Báa ṣe ń sọ̀rọ̀ Ìjọba náà,

    Tá à ń kéde orúkọ rẹ,

    Àwọn tó ń ta kò wá pọ̀ gan-an;

    Wọ́n fẹ́ kó ‘tìjú bá wa.

    Àwa kò bẹ̀rù èèyàn.

    Ìwọ la gbọ́dọ̀ gbọ́ràn sí.

    Fún wa ní ẹ̀mí rẹ, Jèhófà;

    Jọ̀ọ́ bàbá, gbọ́ àdúrà wa.

    (ÈGBÈ)

    Fún wa nígboyà, ká wàásù.

    Mú ìbẹ̀rù wa kúrò.

    Kì wá láyà, fún wa lókun

    Ká lè wàásù fáráyé

    Pé Amágẹ́dọ́nì dé tán.

    Àmọ́ kọ́jọ́ ńlá náà tó dé,

    Fún wa nígboyà, ká wàásù;

    Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa.

  2. 2. Nígbà míì, ẹ̀rù lè bà wá.

    O mọ̀ pérùpẹ̀ ni wá.

    A mọ̀ pé wàá dúró tì wá;

    Atóófaratì ni ọ́.

    Àwọn ọ̀tá wa ń halẹ̀.

    Wo bí wọ́n ṣe ń gbógun tì wá.

    Ràn wá lọ́wọ́, ká má ṣe bọ́hùn

    Báa ṣe ń wàásù lórúkọ rẹ.

    (ÈGBÈ)

    Fún wa nígboyà, ká wàásù.

    Mú ìbẹ̀rù wa kúrò.

    Kì wá láyà, fún wa lókun

    Ká lè wàásù fáráyé

    Pé Amágẹ́dọ́nì dé tán.

    Àmọ́ kọ́jọ́ ńlá náà tó dé,

    Fún wa nígboyà, ká wàásù;

    Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa.

(Tún wo 1 Tẹs. 2:2; Héb. 10:35.)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́