ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • th ẹ̀kọ́ 1 ojú ìwé 4
  • Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tó Dára

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tó Dára
  • Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tí Ń Múni Nífẹ̀ẹ́ Sí Ọ̀rọ̀
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Sọ Bí Ọ̀rọ̀ Rẹ Ṣe Wúlò
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
th ẹ̀kọ́ 1 ojú ìwé 4

Ẹ̀KỌ́ 1

Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tó Dára

Ẹṣẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí

Ìṣe 17:22

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Ó yẹ kí ohun tó o máa sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ mú kó wu àwọn èèyàn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ ohun tí ọ̀rọ̀ rẹ dá lé, kó o sì jẹ́ kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ náà. Béèrè ìbéèrè kan, sọ ọ̀rọ̀ kan, sọ ohun kan tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ tàbí kó o sọ ohun kan tó o gbọ́ nínú ìròyìn tó máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn.

    Àwọn àbá

    Ṣáájú ọjọ́ tó o fẹ́ sọ̀rọ̀, sapá láti mọ ohun táwọn tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí, kó o sì fi ohun náà sínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ.

  • Sọ ohun tí ọ̀rọ̀ rẹ dá lé. Rí i dájú pé ohun tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí àti idí tó fi yẹ káwọn èèyàn gbọ́ nípa rẹ̀ ṣe kedere nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ.

  • Sọ ìdí tí ohun tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fi ṣe pàtàkì. Rí i dájú pé ohun tó o fẹ́ sọ wúlò fún àwọn tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀. Ó yẹ kí wọ́n rí bí ohun tó ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí ṣe máa ràn wọ́n lọ́wọ́.

    Àwọn àbá

    Tó o bá ń múra àsọyé sílẹ̀, bi ara rẹ pé, ‘Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà nínú ìjọ mi?’ Kó o wá jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ bá ipò wọn mu.

LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

Tó o bá fẹ́ mọ ohun tí ẹnì kan nífẹ̀ẹ́ sí, kíyè sí àwọn nǹkan tó ń ṣe àtàwọn nǹkan tó wà láyìíká rẹ̀. Tó o bá wá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ, béèrè ohun kan lọ́wọ́ rẹ̀ nípa àwọn nǹkan tó o kíyè sí, tàbí kó o sọ nǹkan kan nípa wọn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́