ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • th ẹ̀kọ́ 7 ojú ìwé 10
  • Ọ̀rọ̀ Tó Péye Tó sì Ń Yíni Lérò Pa Dà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀rọ̀ Tó Péye Tó sì Ń Yíni Lérò Pa Dà
  • Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀rọ̀ Tó Jóòótọ́ Délẹ̀
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Yẹ
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Sọ Bí Ọ̀rọ̀ Rẹ Ṣe Wúlò
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Lo Ìbéèrè Bó Ṣe Yẹ
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
Àwọn Míì
Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
th ẹ̀kọ́ 7 ojú ìwé 10

Ẹ̀KỌ́ 7

Ọ̀rọ̀ Tó Péye Tó sì Ń Yíni Lérò Pa Dà

Ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí

Lúùkù 1:3

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Lo ẹ̀rí tó ṣeé gbára lé láti mú kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ gbà pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Mú ọ̀rọ̀ rẹ láti ibi tó ṣeé gbára lé. Orí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni kó o gbé ọ̀rọ̀ rẹ kà, kà á jáde ní tààràtà láwọn ìgbà tó bá ṣeé ṣe. Tó o bá fẹ́ fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwádìí tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe tàbí ìròyìn kan, ó sì lè jẹ́ ìrírí kan tàbí ńṣe lo fẹ́ lo àwọn ẹ̀rí míì láti ti ọ̀rọ̀ rẹ lẹ́yìn, rí i dájú pé o ṣe ìwádìí tó yẹ, kó o lè mọ̀ bóyá àwọn nǹkan yẹn ṣì rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́ tí wọ́n sì bá ìgbà mu.

  • Lo ìsọfúnni lọ́nà tó tọ́. Jẹ́ kí àlàyé tó o bá ṣe nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan bá ohun tí ẹsẹ yẹn ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ mu, kó bá ohun tí Bíbélì dá lé mu, kó sì bá ohun tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jádé “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” mu. (Mát. 24:45) Lo àwọn ìsọfúnni míì tó o mú láti àwọn ibòmíì tó yàtọ̀ sí Bíbélì lọ́nà tó bá ohun tí òǹkọ̀wé ní lọ́kàn mu.

    Àwọn àbá

    Má ṣe sọ àsọjù tàbí kó o ṣe àbùmọ́ àwọn ìsọfúnni tàbí iye nǹkan. Tí wọ́n bá sọ pé “àwọn kan,” má ṣe sọ ọ́ di “àwọn tó pọ̀ jù lọ,” má ṣe sọ “láwọn ìgbà míì” di “nígbà gbogbo,” má sì ṣe sọ “ó ṣeé ṣe” di “ó dájú pé.”

  • Mú kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ ronú lórí ẹ̀rí tó o mú wá. Lẹ́yìn tó o bá ti ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí tó o tọ́ka sí ìsọfúnni kan, béèrè àwọn ìbéerè tó ń múni ronú jinlẹ̀ tàbí kó o ṣàkàwé kókó tó wà níbẹ̀ kí àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀ lè rí ohun tó jẹ́ òótọ́ ọ̀rọ̀ fúnra wọn.

LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

Nígbàkigbà tó o bá ń múra láti lọ wàásù, máa ronú nípa àwọn ìbéèrè táwọn èèyàn lè bi ẹ́, kó o sì ṣèwádìí nípa bó o ṣe lè dáhùn. Tí ẹnì kan bá bi ẹ́ ní ìbéèrè kan tí o kò mọ ìdáhùn rẹ̀, sọ fún un pé wàá lọ ṣèwádìí nípa ẹ̀, wàá sì pa dà wá dáhùn nígbà míì.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́