ORIN 56
Sọ Òtítọ́ Di Tìrẹ
1. Ọ̀nà òtítọ́ ló dára jù láti rìn,
Àmọ́ ìwọ lo máa ṣèpinnu.
Torí náà, ó sàn kó o gbàmọ̀ràn Jèhófà.
Gbà pé òótọ́ ló ń sọ fún ọ.
(ÈGBÈ)
S’òótọ́ di tìrẹ.
Kó hàn nínú ayé rẹ.
Jèhófà yóò jẹ́
Kó o láyọ̀ tòótọ́,
Tó o bá s’òótọ́ di tìrẹ.
2. Bó o ṣe ńgbìyànjú, tóò ńlo ọ̀pọ̀ àkókò
Lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run,
Yóò mérè ńlá wá àtìyè àìnípẹ̀kun
Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.
(ÈGBÈ)
S’òótọ́ di tìrẹ.
Kó hàn nínú ayé rẹ.
Jèhófà yóò jẹ́
Kó o láyọ̀ tòótọ́,
Tó o bá s’òótọ́ di tìrẹ.
3. Lójú Ọlọ́run, ọmọ kékeré la jẹ́.
Ó yẹ ká jẹ́ kó tọ́ wa sọ́nà.
Ká b’Ọ́lọ́run rìn lójoojúmọ́ ayé wa;
Yóò bù kún wa lọ́pọ̀lọpọ̀.
(ÈGBÈ)
S’òótọ́ di tìrẹ.
Kó hàn nínú ayé rẹ.
Jèhófà yóò jẹ́
Kó o láyọ̀ tòótọ́,
Tó o bá s’òótọ́ di tìrẹ.
(Tún wo Sm. 26:3; Òwe 8:35; 15:31; Jòh. 8:31, 32.)