-
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 25Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2013 | March
-
-
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 25
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 25
Orin 76 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 7 ìpínrọ̀ 1 sí 6 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Lúùkù 4-6 (10 min.)
No. 1: Lúùkù 4:22-39 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ipá Ìwàláàyè Ni A Ń Pè Ní Ẹ̀mí—td 13B (5 min.)
No. 3: Ẹ̀rí Wo Ló Wà Pé Jésù Jíǹde?—1 Kọ́r. 15:3-7 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́. Lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé 8 láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sátidé àkọ́kọ́ lóṣù April. Gba gbogbo àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n jáde òde ẹ̀rí lọ́jọ́ yẹn.
25 min: “Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 6, ṣe àṣefihàn méjì.
Orin 97 àti Àdúrà
-
-
Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2013 | March
-
-
3. Kí ni ìwé pẹlẹbẹ yìí fi yàtọ̀ sí àwọn ìwé míì tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
3 Bá A Ṣe Ṣe Ìwé Náà: Ọ̀pọ̀ àwọn ìwé tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ la ṣe lọ́nà tí àwọn tó ń kà á fi lè lóye rẹ̀ láìjẹ́ pé ẹnì kan ṣàlàyé rẹ̀ fún wọn. Àmọ́, ìwé tuntun yìí yàtọ̀. A ṣe é lọ́nà tó fi jẹ́ pé àwa la máa fi kọ́ onítọ̀hún lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí náà, tá a bá fẹ́ fún àwọn èèyàn ní ìwé náà, ohun tó máa dáa jù ni pé ká jọ jíròrò ìpínrọ̀ kan tàbí méjì nínú rẹ̀. Àwọn ìpínrọ̀ rẹ̀ kò gùn rárá, torí náà, a lè jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn lẹ́nu ọ̀nà tàbí lẹ́nu iṣẹ́ ajé wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dára láti bẹ̀rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ kìíní, a lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ní àkòrí èyíkéyìí nínú ìwé pẹlẹbẹ náà.
4. Báwo la ṣe lè fi ìwé náà kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ látinú Bíbélì ní tààràtà?
4 Inú àwọn ìpínrọ̀ la ti sábà máa ń rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa. Àmọ́, inú Bíbélì ni ìdáhùn ọ̀pọ̀ àwọn ìbéèrè tó wà nínú ìwé tuntun yìí wà. Inú Bíbélì ni ọ̀pọ̀ èèyàn ti máa ń fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ dípò látinú àwọn ìwé wa. Torí náà, a kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe àyọkà àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ nínú ìwé yìí. Inú Bíbélì la retí pé kẹ́ ẹ ti máa kà á jáde. Èyí máa jẹ́ kí àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ rí i pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ ti wá.—Aísá. 54:13.
5. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a fẹ́ lọ ṣe sílẹ̀ dáadáa?
5 Gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ náà kọ́ la ṣàlàyé síbẹ̀. Ìdí ni pé a ṣe ìwé náà lọ́nà tí yóò fi mú kí ẹni tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lè máa béèrè ìbéèrè. Kí ẹni tó ń kọ́ ọ sì lè lo ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a fẹ́ lọ ṣe sílẹ̀ dáadáa. Àmọ́ ẹ jẹ́ ká ṣọ́ra o, ká má ṣe sọ̀rọ̀ jù! Òótọ́ ni pé ó máa ń wù wá láti ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́. Àmọ́ àṣeyọrí ńlá la máa ṣe tá a bá jẹ́ kí ẹni tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sọ bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà ṣe yé e sí. Tá a bá fọgbọ́n bi í ní ìbéèrè, a lè ràn án lọ́wọ́ láti ronú jinlẹ̀ kó lè lóye ẹsẹ Bíbélì tá a bá kà.—Ìṣe 17:2.
-