ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w15 11/1 ojú ìwé 9
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ìtúmọ̀ Kò Ha Jẹ́ Ti Ọlọ́run?”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Jèhófà Ò Gbàgbé Jósẹ́fù
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • “Èmi Ha Wà ní Ipò Ọlọ́run Bí?”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Jèhófà Máa Jẹ́ Kó O Ṣàṣeyọrí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
w15 11/1 ojú ìwé 9

ǸJẸ́ O MỌ̀?

Kí nìdí tí Jósẹ́fù fi fá irun rẹ̀ kó tó lọ rí Fáráò?

Ògiri tí wọ́n ya àwòrán bábà tó ń gẹrun ní Íjíbítì ìgbàanì

Ògiri tí wọ́n ya àwòrán bábà tó ń gẹrun ní Íjíbítì ìgbàanì

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì, Fáráò pàṣẹ pé kí wọ́n mú Jósẹ́fù ọmọ Hébérù tó wà nínú ẹ̀wọ̀n wá ní kíá, kó lè wá túmọ̀ àwọn àlá tí Fáráò lá. Ní àkókò yìí, Jósẹ́fù ti lo ọdún mélòó kan lẹ́wọ̀n. Láìka pé ojú ń kán Fáráò, Jósẹ́fù ṣì kọ́kọ́ lọ fá irun rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 39:​20-23; 41:​1, 14) Bí ẹni tó kọ ìwé yìí ṣe sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ tó dà bíi pé kò pọn dandan yìí fi hàn pé ó mọ àṣà àwọn ará Íjíbítì dunjú.

Dídá irùngbọ̀n sí wọ́pọ̀ láàárín àwọn èèyàn ìgbàanì, títí kan àwọn ọmọ Hébérù. Àmọ́, ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ọmọ Íjíbítì. Ìwé tí McClintock àti Strong ṣe tí wọ́n pè ní, Cyclopedia of Biblical, Theological, and Ecclesiastical Literature sọ pé “àwọn ọmọ Íjíbítì ìgbàanì nìkan ni orílẹ̀-èdè tí kì í dá irùngbọ̀n sí nígbà náà lọ́hùn-ún.”

Ṣé irùngbọ̀n nìkan ni wọ́n máa ń fá? Ìwé ìròyìn Biblical Archaeology Review sọ pé àwọn àṣà kan ní Íjíbítì ìgbàanì gba pé kí ọkùnrin tó bá máa wọlé sọ́dọ̀ Fáráò múra bí ẹni tó ń lọ sínú tẹ́ńpìlì. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, Jósẹ́fù máa ní láti fá gbogbo irun ara rẹ̀.

Ìwé Ìṣe sọ pé Gíríìkì ni bàbá Tímótì. Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé ọmọ ìbílẹ̀ Gíríìsì ni?

Màmá Tímótì ń ká ìwé fún un, bàbá rẹ̀ sì wà lẹ́yìn

Kò fi dandan rí bẹ́ẹ̀. Nínú Bíbélì, tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí kì í ṣe Júù, nígbà mí ì, ó máa ń pè wọ́n ní Gíríìkì. (Róòmù 1:​16; 10:12) Ọ̀kan lára ohun tó fà á ni pé èdè àti àṣà àwọn Gíríìkì ló gbòde kan ní ọ̀pọ̀ ibi tí Pọ́ọ̀lù ti wàásù.

Àwọn wo ni àwọn ará ìgbàanì kà sí Gíríìkì? Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ọmọ Áténì kan tó ń jẹ́ Isocrates, fi bí àṣà àwọn Gíríìkì ṣe ń tàn kárí ayé nígbà náà ṣe fọ́ńté. Ó ní wọ́n máa ń pe àwọn àjèjì tó kọ́ èdè àti àṣà wa ní ọmọ Gíríìkì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe ọmọ ìbílẹ̀ Gíríìsì. Ó lè jẹ́ pé èyí ló mú kí Pọ́ọ̀lù pe bàbá Tímótì àtàwọn èèyàn míì ní Gíríìkì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí wọn má jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Gíríìsì.​—Ìṣe 16:1.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́