Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí ló mú kí Júdà bá obìnrin kan tí ó rò pé ó jẹ́ aṣẹ́wó lò pọ̀, gẹ́gẹ́ bí Jẹ́nẹ́sísì 38:15,16 ti wí?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lóòótọ́ ni Júdà bá obìnrin kan tó rò pé ó jẹ́ aṣẹ́wó lò pọ̀, ni tòdodo obìnrin náà kì í ṣe aṣẹ́wó. Gẹ́gẹ́ bí Jẹ́nẹ́sísì orí 38 ṣe wí, ohun tó ṣẹlẹ̀ ló wà nísàlẹ̀ yìí.
Ọmọkùnrin tí Júdà kọ́kọ́ bí, tí ó fẹ́ Támárì kò ní ọmọ kó tó kú nítorí pé ó “jẹ́ ẹni búburú ní ojú Jèhófà.” (Jẹ́nẹ́sísì 38:7) Ní àkókò yẹn, àṣà ṣíṣú opó ṣì wà. Ohun tí wọ́n máa ń ṣe ni pé bí ọkùnrin kan bá kú láìní ọmọ, arákùnrin ẹni tó kú yẹn yóò fẹ́ aya rẹ̀ kí ó bàa lè bímọ fún un. Àmọ́ Ónánì ọmọkùnrin kejì tí Júdà bí kọ̀ láti ṣe ohun tó yẹ kó ṣe yìí. Nítorí èyí, ó kú nípasẹ̀ ìdájọ́ àtọ̀runwá. Ìgbà yẹn ni Júdà wá dá Támárì aya ọmọ rẹ̀ padà sí ilé baba rẹ̀ títí dìgbà tí Ṣélà ọmọkùnrin kẹta tí Júdà bí yóò fi dàgbà tó láti fi í ṣaya. Àmọ́ bí ọjọ́ tí ń gorí ọjọ́, Júdà kò jẹ́ kí Ṣélà fẹ́ Támárì. Nítorí náà, gbàrà tí aya Júdà kú ni Támárì dá ọgbọ́n kan kí ó lè rí ọmọ bí látọ̀dọ̀ Júdà, ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ baba ọkọ rẹ̀. Ó díbọ́n pé aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì ni òun, ó sì jókòó sẹ́bàá ọ̀nà tó mọ̀ pé Júdà yóò gbà kọjá.
Níwọ̀n bí Júdà kò ti mọ̀ pé Támárì ni, ó bá a lòpọ̀. Támárì fọgbọ́n gba àwọn nǹkan kan lọ́wọ́ rẹ̀ tó máa fi hàn pé ó ti bá òun lòpọ̀, nígbà tó yá ó fi àwọn ohun tó gbà yìí ṣe ẹ̀rí pé Júdà ló fún òun lóyún. Nígbà tí ọ̀rọ̀ náà tú síta, Júdà kò dá a lẹ́bi àmọ́ ó fi ìrẹ̀lẹ̀ sọ pé: “Ó jẹ́ olódodo jù mí lọ, nítorí ìdí náà pé èmi kò fi í fún Ṣélà ọmọkùnrin mi.” Bó ṣe yẹ, “Ọkùnrin náà kò sì ní ìbádàpọ̀ kankan mọ́ pẹ̀lú rẹ̀ lẹ́yìn èyíinì.” —Jẹ́nẹ́sísì 38:26.
Júdà ṣe ohun tí kò dára ní ti pé kò jẹ́ kí ọmọkùnrin rẹ̀ Ṣélà fi Támárì ṣe aya gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí tẹ́lẹ̀. Ó tún bá obìnrin kan tí ó rò pé ó jẹ́ aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì lò pọ̀. Ohun tó ṣe yìí lòdì sí ètò ìgbéyàwó tí Ọlọ́run ṣe pé ọkùnrin kan kò gbọ́dọ̀ bá obìnrin mìíràn lò pọ̀ àyàfi ìyàwó rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Ní tòdodo, Júdà kò bá aṣẹ́wó lòpọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó rọ́pò ọmọkùnrin rẹ̀ Ṣélà láìmọ̀ọ́mọ̀, ó sì ṣú obìnrin náà lópó tó fi bí àwọn ọmọ tó bá ohun tí òfin wí mu.
Ohun tí Támárì ṣe ní tiẹ̀ kì í ṣe ìṣekúṣe. Àwọn ìbejì tó bí kì í ṣe ọmọ tá a fi àgbèrè bí. Nígbà tí Bóásì ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ṣú Rúùtù ọmọbìnrin Móábù lópó, àwọn àgbààgbà Bẹ́tílẹ́hẹ́mù sọ̀rọ̀ Pérésì ọmọkùnrin Támárì ní rere, wọ́n sọ fún Bóásì pé: “Kí ilé rẹ sì dà bí ilé Pérésì, ẹni tí Támárì bí fún Júdà, láti inú ọmọ tí Jèhófà yóò fi fún ọ nípasẹ̀ ọ̀dọ́bìnrin yìí.” (Rúùtù 4:12) Wọ́n tún ka orúkọ Pérésì mọ́ àwọn baba ńlá Jésù Kristi.—Mátíù 1:1-3; Lúùkù 3:23-33.