Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
NOVEMBER 1-7
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓṢÚÀ 18-19
“Jèhófà Fọgbọ́n Pín Ilẹ̀ Fáwọn Èèyàn Rẹ̀”
it-1 359 ¶1
Ààlà
Torí náà, ó jọ pé ohun méjì ló ń pinnu bí wọ́n ṣe máa pín ilẹ̀ fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Àkọ́kọ́ ni ibi tí kèké bá mú, ìkejì sì ni bí ẹ̀yà kan bá ṣe tóbi tó. Wọ́n lè lo kèké láti mọ ibi tí wọ́n máa pín fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, bóyá àríwá tàbí gúúsù, ìlà oòrùn tàbí ìwọ̀ oòrùn, ilẹ̀ tó tẹ́jú tàbí orí òkè. Tí kèké bá mú ibì kan fún wọn, wọ́n mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìpinnu yẹn ti wá, torí náà wọn ò ní máa jowú ara wọn tàbí bá ara wọn jà. (Owe 16:33) Èyí á sì jẹ́ kí Jèhófà bójú tó bí nǹkan ṣe ń lọ nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, kó lè wà níbàámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù baba ńlá wọn sọ nípa wọn kó tó kú, bó ṣe wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 49:1-33.
it-1 1200 ¶1
Ogún
Ilẹ̀ Àjogúnbá. Jèhófà ló ṣètò bí wọ́n ṣe máa pín ogún fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Ó sì sọ ibi tí ààlà ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan máa dé fún Mósè. (Nọ 34:1-12; Joṣ 1:4) Mósè ló pín ogún fún àwọn ọmọ Gádì, àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè. (Nọ 32:33; Joṣ 14:3) Kèké ni Jóṣúà àti Élíásárì fi pín ogún fáwọn ẹ̀yà tó kù. (Joṣ 14:1, 2) Bí Jékọ́bù ṣe sọ tẹ́lẹ̀ nínú Jẹ́nẹ́sísì 49:5, 7, kò sí ibì kan pàtó tí wọ́n dìídì yàn fáwọn ọmọ Síméónì àti Léfì. Inú ogún Júdà ni wọ́n ti pín ilẹ̀ (títí kan àwọn ìlú àdádó) fáwọn ọmọ́ Síméónì (Joṣ 19:1-9), wọ́n sì fún àwọn ọmọ Léfì ní ìlú méjìdínláàádọ́ta (48) káàkiri ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Torí pé Jèhófà yan àwọn ọmọ Léfì láti máa ṣe àkànṣe iṣẹ́ ìsìn nínú ibi mímọ́, Jèhófà sọ pé òun ni ogún wọn, Ó sì ní kí wọ́n máa gba ìdámẹ́wàá gẹ́gẹ́ bí ìpín tàbí ogún torí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe. (Nọ 18:20, 21; 35:6, 7) Apá ibi tí wọ́n bá pín fún ẹ̀yà kan ni wọ́n ti máa ń yanṣẹ́ fún wọn. Bí ìdílé kọ̀ọ̀kan bá ṣe ń bímọ, táwọn ọmọ wọn sì ń pọ̀ sí í, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n á máa pín ogún wọn sí kéékèèké.
it-1 359 ¶2
Ààlà
Lẹ́yìn tí kèké bá ti jẹ́ kí wọ́n mọ apá ibi tí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan máa wà, wọ́n á wá lo ohun kejì, ìyẹn bí ẹ̀yà náà bá ṣe tóbi tó láti mọ bí ibi tí wọ́n máa pín fún wọn ṣe máa fẹ̀ tó. Bíbélì sọ pé: “Kí ẹ fi kèké pín ilẹ̀ náà bí ohun ìní láàárín àwọn ìdílé yín. Kí ẹ fi kún ogún tí ẹ máa pín fún àwùjọ tó bá pọ̀, kí ẹ sì dín ogún tí ẹ máa pín fún àwùjọ tó bá kéré kù. Ibi tí kèké kálukú bá bọ́ sí ni ohun ìní rẹ̀ máa wà.” (Nọ 33:54) Wọn ò ní yí ibi tí kèké bá mú fún ẹ̀yà kan pa dà, àmọ́ wọ́n lè dín bó ṣe tóbi tó kù tàbí kí wọ́n fi kún un. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n rí i pé ibi tí wọ́n pín fún ẹ̀yà Júdà ti fẹ̀ jù, wọ́n dín in kù, wọ́n sì fún ẹ̀yà Síméónì ní díẹ̀ lára rẹ̀.—Joṣ 19:9.
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-1 359 ¶5
Ààlà
Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe pín apá ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì, ó jẹ́ ká mọ̀ pé lẹ́yìn tí wọ́n mọ ibi tí ààlà ilẹ̀ kọ̀ọ̀kan dé, tí wọ́n sì mọ iye ìlú tó wà níbẹ̀, wọ́n kọ́kọ́ pín ilẹ̀ fún ẹ̀yà Júdà (Joṣ 15:1-63), àwọn ọmọ Jóṣẹ́fù (Éfúrémù) (Joṣ 16:1-10) àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè tí wọ́n ń gbé lápá ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì. (Joṣ 17:1-13) Lẹ́yìn ìyẹn, ó jọ pé ohun kan ṣẹlẹ̀ tí ò jẹ́ kí wọ́n pín ilẹ̀ fáwọn ẹ̀yà tó kù, torí ohun tí Bíbélì sọ tẹ̀ lé e ni pé gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣí kúrò ní Gílígálì lọ sí Ṣílò. (Joṣ 14:6; 18:1) A ò lè sọ bó ṣe pẹ́ tó kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í pín ilẹ̀ náà pa dà, àmọ́ nígbà tó yá Jóṣúà bá àwọn ẹ̀yà méje tó kù wí torí pé wọn ò tètè lọ gba ilẹ̀ tó kù. (Joṣ 18:2, 3) Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn èèyàn sọ pé ó fà á táwọn ẹ̀yà méje yìí ò fi tètè lọ gba ilẹ̀ wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan sọ pé wọ́n ṣì ń gbádùn oríṣiríṣi nǹkan tí wọ́n kó láwọn ìlú tí wọ́n ṣẹ́gun, ọkàn wọn sì balẹ̀ pé kò ní rọrùn fáwọn ọmọ Kénáánì láti wá halẹ̀ mọ́ wọn tàbí gbógun jà wọ́n níbi tí wọ́n wà. Ó tún lè jẹ́ pé ẹ̀rù àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà ló ń ba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, torí wọ́n gbà pé àwọn èèyàn náà lágbára ju àwọn lọ. (Joṣ 13:1-7) Bákan náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwọ̀nba nǹkan ni wọ́n mọ̀ nípa bí ilẹ̀ tó kù ní Ilẹ̀ Ìlérí ṣe rí.
NOVEMBER 8-14
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓṢÚÀ 20-22
“Ohun Tá A Rí Kọ́ Látinú Èdèkòyédè Kan Tó Wáyé”
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-1 402 ¶3
Kénáánì
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ilẹ̀ Kénáánì kọ́ làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun nígbà tí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí, síbẹ̀ a ṣì lè sọ pé ‘Jèhófà fún wọn ní gbogbo ilẹ̀ tó búra pé òun máa fún àwọn baba ńlá wọn,’ Ó “fún wọn ní ìsinmi ní gbogbo àyíká wọn” àti pé “kò sí ìlérí tí kò ṣẹ nínú gbogbo ìlérí dáadáa tí Jèhófà ṣe fún ilé Ísírẹ́lì; gbogbo rẹ̀ ló ṣẹ pátá.” (Joṣ 21:43-45) Kò sẹ́ni tó lè halẹ̀ mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, torí gbogbo àwọn tó wà láyìíká wọn ló ń bẹ̀rù wọn. Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ pé “díẹ̀díẹ̀” lòun máa lé àwọn ọmọ Kénáánì kúrò ní ilẹ̀ náà, káwọn ẹranko búburú má bàa pọ̀ níbẹ̀ tí ò bá sẹ́ni tó ń gbébẹ̀. (Ẹk 23:29, 30; Di 7:22) Òótọ́ ni pé àwọn ọmọ Kénáánì láwọn ọmọ ogun tó lágbára àtàwọn kẹ̀kẹ́ ogun tó ní dòjé irin, síbẹ̀ a ò lè sọ pé Jèhófà ò mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ṣe ṣẹ́gun àwọn ìlú kan nílẹ̀ náà. (Joṣ 17:16-18; Ond 4:13) Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ jẹ́ ká mọ̀ pé àìṣòótọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló jẹ́ káwọn ọ̀tá ṣẹ́gun wọn láwọn ìgbà kan.—Nọ 14:44, 45; Joṣ 7:1-12.
NOVEMBER 15-21
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓṢÚÀ 23-24
“Ìmọ̀ràn Tí Jóṣúà Fún Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Kẹ́yìn”
it-1 75
Bá Da Nǹkan Pọ̀
Ọ̀tọ̀ lohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Ọlọ́run Olódùmarè ti fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́tọ̀ọ́ láti gba ilẹ̀ náà kó lè mú ìlérí tó ṣe fáwọn baba ńlá wọn ṣẹ. Torí náà, wọn kì í ṣe àjèjì nígbà tí wọ́n wọbẹ̀, Jèhófà sì sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ bá àwọn abọ̀rìṣà tó ń gbé ilẹ̀ náà da nǹkan pọ̀. (Ẹk 23:31-33; 34:11-16) Òfin Ọlọ́run àtàwọn ìlànà rẹ̀ nìkan ni wọ́n gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé, wọn ò gbọ̀dọ̀ ṣe bíi tàwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà ò ní pẹ́ pa run yẹn. (Le 18:3, 4; 20:22-24) Jèhófà dìídì kìlọ̀ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ bá àwọn orílẹ̀-èdè yẹn dána. Torí tí wọ́n bá ń fẹ́ àwọn abọ̀rìṣà yẹn, wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn èèyàn wọn ṣe wọléwọ̀de, wọ́n á bá wọn lọ́wọ́ sí ìjọsìn èkè àtàwọn àṣà tínú Ọlọ́run ò dùn sí débi pé wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í fi Jèhófà sílẹ̀, wọ́n á sì di apẹ̀yìndà.—Di 7:2-4; Ẹk 34:16; Joṣ 23:12, 13.
DECEMBER 13-19
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÀWỌN ONÍDÀÁJỌ́ 8-9
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-1 753 ¶1
Éfódì, I
Ohun tó dáa ló wà lọ́kàn Gídíónì nígbà tó ṣe éfódì. Ìdí tó fi ṣe é ni pé ó fẹ́ fi ìmoore hàn fún ohun tí Jèhófà ṣe nígbà tó mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ja àjàṣẹ́gun, síbẹ̀ éfódì yẹn “di ìdẹkùn fún Gídíónì àti agbo ilé rẹ̀,” torí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn éfódì náà. (Ond 8:27) Àmọ́, Bíbélì ò sọ pé Gídíónì fúnra rẹ̀ jọ́sìn éfódì yẹn; kàkà bẹ́ẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dìídì dárúkọ Gídíónì nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí” tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà ṣáájú kí ẹ̀sìn Kristẹni tó bẹ̀rẹ̀.—Heb 11:32; 12:1.
DECEMBER 20-26
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÀWỌN ONÍDÀÁJỌ́ 10-12
it-2 27 ¶2
Jẹ́fútà
Akíkanjú ni Jẹ́fútà, gbogbo àsìkó tó fi darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló sì fi jẹ́ aṣáájú tó dáa. Ó ránṣẹ́ sí ọba Ámónì, ó sì sọ fún un pé àwọn ọmọ Ámónì ti ń kọjá àyè wọn bí wọ́n ṣe wá gbógun ja ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Ọba Ámónì fèsì pé ọwọ́ àwọn ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti gba ilẹ̀ yẹn. (Ond 11:12, 13) Yàtọ̀ sí pé Jẹ́fútà lákíkanjú, tó sì lágbára, kì í dédé jagun kó lè fi bóun ṣe lágbára tó hàn, ohun tó ṣe nínú ọ̀rọ̀ yìí tún fi hàn pé ó máa ń kẹ́kọ̀ọ́ kó lè mọ àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fáwọn èèyàn rẹ̀ nígbà àtijọ́. Kò gbà pé òótọ́ lohun táwọn ọmọ Ámónì sọ, ó ṣàlàyé fún wọn pé: (1) àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò halẹ̀ mọ́ àwọn ọmọ Ámónì, Móábù tàbí Édómù (Ond 11:14-18; Di 2:9, 19, 37; 2Kr 20:10, 11); (2) àwọn ọmọ Ámónì ò tíì débẹ̀ nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣẹ́gun Ilẹ̀ Ìlérí, torí pé àwọn ọmọ Ámórì ló ń gbébẹ̀ nígbà yẹn, Ọlọ́run sì ti fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nílẹ̀ náà nígbà tó mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ́gun Síhónì ọba wọn; (3) àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń gbé ilẹ̀ yẹn láti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọdún sẹ́yìn, àwọn ọmọ Ámónì ò sì yọ wọ́n lẹ́nu látìgbà yẹn; kí ló dé tó fi jẹ́ pé àsìkò yìí ni wọ́n wá ń halẹ̀ mọ́ wọn?—Ond 11:19-27.
it-2 27 ¶3
Jẹ́fútà
Nǹkan míì tó jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yẹn ká Jẹ́fútà lára ni pé ó kan ìjọsìn Jèhófà. Jẹ́fútà sọ pé Jèhófà Ọlọ́run ti fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nílẹ̀ yẹn, torí náà òun ò ní gbà kí ìkankan lára ẹ̀ bọ́ sọ́wọ́ àwọn abọ̀rìṣà. Jẹ́fútà pe Kémóṣì ní ọlọ́run àwọn Ámónì, àmọ́ àwọn kan gbà pé àṣìṣe lohun tó sọ yẹn. Òótọ́ ni pé àwọn ọmọ Móábù ló ń jọ́sìn Kémóṣì, táwọn ọmọ Ámónì sì ń jọ́sìn Mílíkómù, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ọlọ́run làwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì ń sìn, ó ṣe tán mọ̀lẹ́bí ni wọ́n. Nígbà tí Sólómọ́nì fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì, ó mú ìjọsìn Kémóṣì wọ Ísírẹ́lì. (Ond 11:24; 1Ọb 11:1, 7, 8, 33; 2Ọb 23:13) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ó ṣeé ṣe kí “Kémóṣì” túmọ̀ sí “ẹni tó ń tẹni lórí ba tàbí Aṣẹ́gun.” (Wo Gesenius’s Hebrew and Chaldee Lexicon, tí S. Tregelles túmọ̀ lọ́dún 1901, ojú ìwé 401.) Nígbà tí Jẹ́fútà pe Kémóṣì ní ọlọ́run àwọn ọmọ Ámónì, ó ṣeé ṣe kó sọ bẹ́ẹ̀ torí báwọn ọmọ Ámónì ṣe máa ń gbógo fún Kémóṣì pé òun ló ń ti àwọn lẹ́yìn bí wọ́n ṣe ń tẹ àwọn èèyàn lórí ba, tí wọ́n sì ń gba ilẹ̀ wọn.
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-2 26
Jẹ́fútà
Ọmọ Ọkọ ni Jẹ́fútà. Bíbélì pe ìyá Jẹ́fútà ní “aṣẹ́wó,” àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ṣe nìyá ẹ̀ gboyún ẹ̀ tàbí pé ọmọ àlè ni. Ó ti ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó kí Gílíádì tó fẹ́ ẹ ṣe ìyàwó onípò kejì. Ṣe lọ̀rọ̀ ẹ̀ dà bíi ti Ráhábù tó ti fìgbà kan rí ṣíṣẹ́ aṣẹ́wó kó tó di ìyàwó Sálímọ́nì. (Ond 11:1; Joṣ 2:1; Mt 1:5) Ọ̀kan lára nǹkan tó fi hàn pé Jẹ́fútà kì í ṣe ọmọ àlè ni pé àwọn ọmọ ìyàwó bàbá ẹ̀ lé e jáde, torí wọn ò fẹ́ kó bá àwọn pín nínú ogun bàbá wọn. (Ond 11:2) Nígbà tó yá àwọn àgbààgbà Gílíádì sọ Jẹ́fútà di aṣáájú wọn (ó sì jọ pé àwọn ọmọ bàbá ẹ̀ ló múpò iwájú láàárín wọn). (Ond 11:11) Yàtọ̀ síyẹ̀n, Jẹ́fútà rúbọ sí Ọlọ́run nínú àgọ́ ìjọsìn. (Ond 11:30, 31) Kò sí ìkankan nínú àwọn nǹkan yìí tí Jẹ́fùtà ì bá lè ṣe ká ní ọmọ àlè ni, ó ṣe tán Òfin Ọlọ́run dìídì sọ pé: “Ọmọ àlè kankan ò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà. Àní títí dé ìran rẹ̀ kẹwàá, àtọmọdọ́mọ rẹ̀ kankan ò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà.”—Di 23:2.