ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 12/15 ojú ìwé 8-10
  • Àwọn Ará Ammoni Àwọn Afibi-San-Oore

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ará Ammoni Àwọn Afibi-San-Oore
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Gileadi—Ẹkùn-Ilẹ̀ fún Àwọn Ènìyàn Onígboyà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Jẹ́fútà Mú Ẹ̀jẹ́ Tó Jẹ́ Fún Jèhófà Ṣẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Àwọn Orílẹ̀-Èdè “Á sì Wá Mọ̀ Pé Èmi Ni Jèhófà”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
  • Sọ́ọ̀lù—ọba Àkọ́kọ́ Ní Ísírẹ́lì
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 12/15 ojú ìwé 8-10

Àwọn Ará Ammoni Àwọn Afibi-San-Oore

ÌLÚ òde òní tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Amman, olú ìlú ìjọba àwọn ọmọ Hashim ní Jordani, pa ìrántí àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ti pòórá kúrò lórí ilẹ̀ ayé mọ́. A ń pè wọ́n ní àwọn ará Ammoni. Ta ni wọ́n, ẹ̀kọ́ wo ni a sì rí kọ́ láti inú ìṣubú wọn?

Àwọn ará Ammoni jẹ́ àtọmọdọ́mọ Loti olódodo. (Genesisi 19:35-38) Níwọ̀n bí Loti ti jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n Abrahamu, o lè sọ pé àwọn ará Ammoni jẹ́ ìbátan àwọn ọmọ Israeli. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn àtọmọdọ́mọ Loti yí padà sí jíjọ́sìn àwọn ọlọrun èké. Síbẹ̀, Jehofa Ọlọrun ní ọkàn-ìfẹ́ sí wọn. Bí orílẹ̀-èdè Israeli ti ń sún mọ́ Ilẹ̀ Ìlérí náà, Ọlọrun kìlọ̀ fún wọn pé: “Má ṣe bí [àwọn ará Ammoni] nínú, bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe bá wọn jà: nítorí pé èmi kì yóò fi nínú ilẹ̀ àwọn ọmọ Ammoni fún ọ ní ìní: nítorí tí mo ti fi í fún àwọn ọmọ Lot[i] ní ìní.”—Deuteronomi 2:19.

Àwọn ará Ammoni ha mọrírì irú inú rere bẹ́ẹ̀ bí? Rárá o, wọ́n kò gbà pé Jehofa fún wọn ní ohunkóhun. Ìkóguntini tí kò dẹ́kun lòdì sí àwọn ènìyàn Ọlọrun, àwọn ọmọ Israeli, ni wọ́n fi san ọkàn-ìfẹ́ onínúure tí Ọlọrun ní sí wọn padà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Israeli bọlá fún àṣẹ Jehofa, tí wọn kò sì gbé ìgbésẹ̀ oníbìínú èyíkéyìí lòdì sí wọn, àwọn ará Ammoni àti àwọn arákùnrin wọn, ará Moabu, rò pé a wu wọ́n léwu. Lóòótọ́, àwọn ará Ammoni kò lo ìgbéjàkoni ológun láti gbéjà kò wọ́n, ṣùgbọ́n wọ́n bẹ wòlíì kan tí ń jẹ́ Balaamu lọ́wẹ̀ pé kí ó bá wọn fi àwọn ọmọ Israeli bú!—Numeri 22:1-6; Deuteronomi 23:3-6.

Ohun kan tí ó ṣàjèjì ṣẹlẹ̀. Bibeli ròyìn pé, Balaamu kò lè ṣépè náà. Kìkì ìre ni ó lè sú fún wọn, ní sísọ pé: “Ìbùkún ni fún ẹni tí ó súre fún ọ, ìfibú sì ni ẹni tí ó fi ọ́ bú.” (Numeri 24:9) Àwọn tí ọ̀ràn náà kàn, títí kan àwọn ará Ammoni, ti ní láti kẹ́kọ̀ọ́ lílágbára láti inú èyí pé: Nígbà tí ọ̀ràn bá kan àwọn ènìyàn Ọlọrun, ó ti wà ní sẹpẹ́ láti gbèjà wọn!

Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ará Ammoni ń bá a nìṣó ní wíwá ọ̀nà láti dojú ìjà kọ Israeli. Ní àkókò àwọn Onídàájọ́, Ammoni lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú Moabu àti Amaleki, wọ́n sì gbógun ti Ilẹ̀ Ìlérí náà, wọ́n lọ jìnnà dé Jeriko. Ṣùgbọ́n, ìṣẹ́gun wọn kò tọ́jọ́, Onídàájọ́ Ehudi, ti ilẹ̀ Israeli, lé àwọn agbóguntini náà padà. (Onidajọ 3:12-15, 27-30) Dídáwọ́ ìjà dúró fún ìgbà díẹ̀ lọ́nà tí kò fara rọ ń bá a nìṣó títí di àwọn ọjọ́ Onídàájọ́ Jefta. Nígbà yẹn, orílẹ̀-èdè Israeli ti ṣubú sínú ìbọ̀rìṣà, nítorí náà, Jehofa fawọ́ ààbò rẹ̀ sẹ́yìn. Fún nǹkan bí ọdún 18, Ọlọrun ti tipa bẹ́ẹ̀ “tà wọ́n . . . sí ọwọ́ àwọn ọmọ Ammoni.” (Onidajọ 10:6-9) Lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn ará Ammoni jìyà ìṣẹ́gun gbígbóná janjan bí àwọn ọmọ Israeli ṣe kọ ìbọ̀rìṣà sílẹ̀, tí wọ́n sì gbára jọ sábẹ́ ìdarí Jefta.—Onidajọ 10:16–11:33.

Dídé Saulu ládé gẹ́gẹ́ bí ọba àkọ́kọ́ fòpin sí sànmánì ìṣàkóso àwọn onídàájọ́ Israeli. Kò pẹ́ tí Saulu bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, tí ìjà àwọn ará Ammoni fi tún bẹ̀rẹ̀. Ọba Nahaṣi gbéjà ko Jabeṣi-Gileadi, ìlú àwọn ọmọ Israeli, láìròtẹ́lẹ̀. Nígbà tí àwọn ọkùnrin ìlú náà ké gbàjarè fún àlàáfíà, Nahaṣi ará Ammoni sọ ohun àbéèrèfún aláṣejù yìí jáde pé: “Nípa báyìí ni èmi óò fi báa yín dá májẹ̀mú, nípa yíyọ gbogbo ojú ọ̀tún yín kúrò.” Òpìtàn Flavius Josephus sọ pé, lọ́nà kan, a ṣe eléyìí gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìgbèjà, kí ó lè jẹ́ pé “nígbà tí asà wọn bá bo ojú wọn apá òsì, wọn kì yóò lè jagun mọ́.” Síbẹ̀, olórí ète òté aláìláàánú yìí ni láti fi àwọn ọmọ Israeli wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́yà.—1 Samueli 11:1, 2.

Lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn ará Ammoni ti fi ibi san oore Jehofa. Jehofa kò gbójú fo ìhalẹ̀mọ́ni rírorò yìí. “Ẹ̀mí Ọlọrun sì bà lé Saulu nígbà tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ [Nahaṣi] wọnnì, inú rẹ̀ sì ru púpọ̀.” Lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí Ọlọrun, Saulu kó ẹgbẹ́ ọmọ ogun 330,000 ọkùnrin jagunjagun jọ, tí wọ́n ṣe àwọn ará Ammoni bí ọṣẹ́ ti í ṣojú, tó bẹ́ẹ̀ tí “méjì wọn kò kù ní ibì kan.”—1 Samueli 11:6, 11.

Ọkàn-ìfẹ́ ara wọn tí ó jẹ àwọn ará Ammoni lógún jù lọ, àìláàánú wọn, àti ìwọra onímọtara ẹni nìkan wọn, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, yọrí sí ìparun wọn pátápátá. Gẹ́gẹ́ bí wòlíì Jehofa, Sefaniah, ṣe sọ tẹ́lẹ̀, wọ́n dà “bíi Gomorra, . . . ìdahoro títí láé, . . . nítorí pé wọ́n ti kẹ́gàn, wọ́n sì ti gbé ara wọn ga sí ènìyàn Oluwa àwọn ọmọ ogun.”—Sefaniah 2:9, 10.

Ó yẹ kí àwọn aṣáájú ayé lónìí kíyè sí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Ammoni. Ọlọrun ti fi ìwọ̀n inú rere díẹ̀ hàn sí àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà kan náà ní yíyọ̀ọ̀da fún wọn láti gbé orí àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀, ilẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n dípò títọ́jú ilẹ̀ ayé, àwọn orílẹ̀-èdè onímọtara-ẹni-nìkan ń bà á jẹ́, wọ́n tilẹ̀ ti fi ìparun átọ́míìkì halẹ̀ mọ́ pílánẹ́ẹ̀tì náà pàápàá. Kàkà kí wọ́n fi inú rere hàn sí àwọn olùjọsìn Jehofa lórí ilẹ̀ ayé, lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn orílẹ̀-èdè máa ń bá wọn jà, ní fífi wọn sábẹ́ inúnibíni líle koko. Nítorí náà, ẹ̀kọ́ tí a rí kọ́ lára àwọn ará Ammoni ni pé, Jehofa kì í fi ojú kékeré wo fífi ibi san oore rẹ̀. Nígbà tí ó bá sì tó àkókò lójú rẹ̀, yóò gbé ìgbésẹ̀, gan-an bí ó ti ṣe ní ìgbàanì.—Fi wé Orin Dafidi 2:6-12.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Òkìtì àlàpà Romu ní Amman, ibi tí Rabbah, olú ìlú àwọn ará Ammoni wà

[Credit Line]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àwọn ará Ammoni gbé agbègbè yìí

[Credit Line]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́