ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lffi ẹ̀kọ́ 2
  • Bíbélì Sọ Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bíbélì Sọ Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa
  • Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
  • KÓKÓ PÀTÀKÌ
  • ṢÈWÁDÌÍ
  • Bíbélì Sọ Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì
  • Ìdí Tó Fi Dá Wa Lójú Pé Ọ̀la Máa Dáa
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Bá A Ṣe Wọ Ọdún 2023, Kí Lá Jẹ́ Kọ́kàn Wa Balẹ̀ Pé Ọ̀la Máa Dáa?​—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ohun Tó Lè Fi Wá Lọ́kàn Balẹ̀ Lọ́dún 2024—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì
lffi ẹ̀kọ́ 2
Ẹ̀kọ́ 2. Oòrùn ràn sórí oko wíìtì tó lọ salalu.

Ẹ̀KỌ́ 02

Bíbélì Sọ Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa

Bíi Ti Orí Ìwé
Bíi Ti Orí Ìwé
Bíi Ti Orí Ìwé

Oríṣiríṣi ìṣòro ló ń dojú kọ àwọn èèyàn kárí ayé. Ìṣòro náà sì ń fa ìbànújẹ́, àìbalẹ̀ ọkàn àti ìrora fún wọn. Ṣé ìwọ náà ti dojú kọ́ ìṣòro tó kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ rí? Ṣé ikú èèyàn rẹ, àìsàn tàbí nǹkan míì ló ń bà ẹ́ lọ́kàn jẹ́? O lè máa bi ara rẹ pé, ‘Ṣé nǹkan ṣì máa dáa báyìí?’ Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí lọ́nà tó fini lọ́kàn balẹ̀.

1. Kí ni Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ìṣòro wa lọ́jọ́ iwájú?

Bíbélì sọ ìdí tí ìṣòro fi kún ayé yìí, àmọ́ ó tún sọ ìròyìn ayọ̀ fún wa pé àwọn ìṣòro náà ò ní pẹ́ dópin. Bíbélì sọ pé a ní “ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.” (Ka Jeremáyà 29:11, 12.) Àwọn ohun rere tá à ń retí yẹn máa jẹ́ ká lè fara da àwọn ìṣòro tá a ní báyìí, wọ́n á jẹ́ ká ní èrò tó dáa, wọ́n á sì jẹ́ ká láyọ̀ títí láé.

2. Kí ni Bíbélì sọ nípa bí ọjọ́ ọ̀la ṣe máa rí?

Bíbélì sọ bí ọjọ́ ọ̀la ṣe máa rí, ó ní “ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Ka Ìfihàn 21:4.) Àwọn ìṣòro tó ń mú káyé súni lónìí ò ní sí mọ́, irú bí ipò òṣì, ìrẹ́jẹ, àìsàn àti ikú. Bíbélì tún ṣèlérí pé àwọn èèyàn máa gbádùn ayé títí láé nínú Párádísè.

3. Kí ló máa jẹ́ kó dá ẹ lójú pé àwọn ohun tí Bíbélì sọ máa ṣẹ?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń retí àwọn nǹkan rere, síbẹ̀ kò dá wọn lójú pé ọwọ́ wọn máa tẹ àwọn nǹkan náà. Àmọ́ àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì yàtọ̀. Tá a bá “ń ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ kínníkínní,” ó máa dá wá lójú pé òótọ́ làwọn ìlérí yìí. (Ìṣe 17:11) Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìwọ fúnra ẹ máa rí i pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Wo díẹ̀ lára àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Wo bí àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì ṣe ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.

Àwòrán: Ipò tí kò dára táwọn èèyàn wà lónìí àti àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Àwọn àwòrán náà tún fara hàn nísàlẹ̀.

4. Bíbélì sọ pé a máa gbé ayé títí láé láìsí ìṣòro kankan mọ́

Wo àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀. Àwọn wo ló wù ẹ́ jù? Kí sì nìdí?

Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ohun rere yẹn, kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Àǹfààní wo làwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí máa ṣe ẹ́? Àǹfààní wo ló máa ṣe ìdílé rẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ?

Wo bó ṣe máa rí lára ẹ tó o bá ń gbé ayé nígbà tí

ẸNÌ KANKAN Ò NÍ . . .

GBOGBO ÈÈYÀN MÁA . . .

  • jẹ̀rora mọ́, a ò ní darúgbó mọ́, a ò sì ní kú mọ́.​—Àìsáyà 25:8.

  • rí àwọn èèyàn wọn tó ti kú nígbà tí wọ́n bá jíǹde sí ayé.​—Jòhánù 5:28, 29.

  • ṣàìsàn mọ́, kò sì ní sí aláàbọ̀ ara mọ́.​—Àìsáyà 33:24; 35:5, 6.

  • gbádùn ìlera tó pé, wọ́n á sì lágbára bíi ti ọ̀dọ́.​—Jóòbù 33:25.

  • rẹ́ ọ jẹ.​—Àìsáyà 32:16, 17.

  • ní oúnjẹ rẹpẹtẹ, ilé tó dáa àti iṣẹ́ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀.​—Sáàmù 72:16; Àìsáyà 65:21, 22.

  • ja ogun mọ́.​—Sáàmù 46:9.

  • ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.​—Sáàmù 37:11.

  • ní ìdààmú ọkàn tàbí kó máa rántí ohun aburú tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn.​—Àìsáyà 65:17.

  • gbé ayé títí láé nínú ìrọ̀rùn.​—Sáàmù 37:29.

Ara ọmọdékùnrin tó ń ṣàìsàn tẹ́lẹ̀ ti yá, ó sì gbá ìyá rẹ̀ mọ́ra. Ọkùnrin kan tó ti darúgbó ti di ọ̀dọ́, ó sì ń fi bárò kó ẹ̀fọ́. Àwọn ọmọ tí ò rí oúnjẹ jẹ tí wọ́n sì ń fi ṣiṣẹ́ bí ẹrú nígbà kan ti wá ń gbádùn báyìí, wọ́n ń gbin òdòdó, wọ́n sì ń gbá bọ́ọ̀lù. Obìnrin kan to sorí kọ́ tẹ́lẹ̀ ti wá túra ká báyìí, ó sì ń rẹ́rìn-ín.

5. Àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ máa tù ẹ́ nínú

Ọ̀pọ̀ èèyàn ni gbogbo nǹkan tojú sú, tí wọ́n sì tún ń bínú torí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn. Àwọn kan tiẹ̀ ń gbìyànjú gan-an kí wọ́n lè sọ ayé dẹ̀rọ̀, àmọ́ wọn ò rí i ṣe. Wo bí ìlérí tó wà nínú Bíbélì pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa ṣe ń ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọwọ́ ní báyìí. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

FÍDÍÒ: Mo Fẹ́ Jà fún Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn (4:07)

Àwòrán: Àwọn apá kan lára fídíò náà, ‘Mo Fẹ́ Jà fún Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn.’ 1. Rafika rèé nígbà tó wà lọ́mọdé tó ń kórè òwú pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ẹ̀yà kan náà. 2. Inú Rafika dùn gan-an nígbà tó rí àwọn èèyàn tó wá láti ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n jọ wà pa pọ̀ ní àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lọ nígbà àkọ́kọ́.
  • Nínú fídíò yìí, kí làwọn ohun tó ń kó ìdààmú bá Rafika?

  • Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwà ìrẹ́jẹ tí Rafika rí kò dópin, báwo ni Bíbélì ṣe ràn án lọ́wọ́?

Àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la máa jẹ́ ká borí ẹ̀dùn ọkàn, ká sì máa láyọ̀ bá a ṣe ń fara da àwọn ìṣòro wa. Ka Òwe 17:22 àti Róòmù 12:12, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Ṣé o rò pé àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la lè mú káyé ẹ dáa sí i ní báyìí? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Àlá tí ò lè ṣẹ làwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la.”

  • Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí ìwọ fúnra ẹ ṣèwádìí?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Èyí ń múnú wa dùn, ó sì ń jẹ́ ká lè fara da àwọn ìṣòro wa ní báyìí.

Kí lo rí kọ́?

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ̀ nípa àwọn ohun rere tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú?

  • Kí ni Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la?

  • Báwo ni ìrètí tó o ní pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ ní báyìí?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa bí ìrètí pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa ṣe lè fún ẹ lókun.

“Ǹjẹ́ Ó Ní Nǹkan Tí Ìrètí Lè Ṣe fún Wa?” (Jí!, May 8, 2004)

Kà nípa bí ìrètí pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa ṣe ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń ṣàìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́.

“Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mo Bá Ń Ṣàìsàn Ọlọ́jọ́ Pípẹ́?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

Bó o ṣe ń wo fídíò yìí, fojú inú wo ara rẹ àti ìdílé rẹ pé ẹ̀ ń gbádùn ayé nínú Párádísè tí Bíbélì sọ.

Fojú Inú Wò Ó 3:37

Kà nípa bí ìgbésí ayé ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn kan ṣe yí pa dà nígbà tó mọ àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé ó má ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la.

“Kò Ṣe Mí Mọ́ Bíi Pé Mo Gbọ́dọ̀ Yí Ayé Yìí Pa Dà” (Ilé Ìṣọ́, July 1, 2013)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́