Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
MAY 2-8
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 SÁMÚẸ́LÌ 27-29
“Ọgbọ́n Tí Dáfídì Dá Kó lè Dáàbò Bo Àwọn Èèyàn Ọlọ́run”
it-1 41
Ákíṣì
Ẹ̀ẹ̀mejì ni Dáfídì fara pa mọ́ sọ́dọ̀ Ọba Ákíṣì nígbà tó ń sá fún Sọ́ọ̀lù. Nígbà àkọ́kọ́ tí Dáfídì lọ sọ́dọ̀ Ákíṣì, àwọn ará Filísínì bẹ̀rẹ̀ sí í fura sí i, àmọ́ Dáfídì díbọ́n bíi pé orí òun ti yí, ìyẹn mú kí Ákíṣì kà á sí wèrè, ó sì jẹ́ kó máa lọ. (1Sa 21:10-15; Sm 34:Àkọlé; 56:Àkọlé) Nígbà kejì, Dáfídì àtàwọn jagunjagun ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti gbogbo ìdílé wọn ló wá sọ́dọ̀ Ákíṣì, Ákíṣì sì ní kí wọ́n máa gbé ní Síkílágì. Ní gbogbo odún kan àti oṣù mẹ́rin tí Dáfídì lò níbẹ̀, Ákíṣì rò pé àwọn ìlú tó wà ní ilẹ̀ Júdà ni Dáfídì ń gbéjà kò láìmọ̀ pé àwọn ará Géṣúrì, àwọn ará Gísì àtàwọn ọmọ Ámálékì ni Dáfídì ń gbéjà kò. (1Sa 27:1-12) Ọgbọ́n tí Dáfídì dá yìí gbéṣẹ́ gan-an débi pé Ákíṣì yan Dáfídì ṣe ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ nígbà táwọn Filísínì ń múra láti gbéjà ko Ọba Sọ́ọ̀lù. Àmọ́ “àwọn ìjòyè” yòókù ò gbà kí Dáfídì tẹ̀ lé àwọn, torí náà Ákíṣì rán Dáfídì àtàwọn ọkùnrin ẹ̀ pa dà sí Síkílágì. (1Sa 28:2; 29:1-11) Lẹ́yìn tí Dáfídì di ọba, tó sì gbógun ja Gátì, ó jọ pé wọn ò pa Ákíṣì torí pé ó ṣì wà láàyè títí di ìgbà ìṣàkóso Sólómọ́nì.—1Ọb 2:39-41; wo GÁTÌ.
it-2 245 ¶6
Irọ́
Òótọ́ ni pé Bíbélì dẹ́bi fún irọ́ pípa, síbẹ̀ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ sọ gbogbo bọ́rọ̀ kan ṣe rí fún ẹnì kan tí ò lẹ́tọ̀ọ́ sí i. Jésù Kristi sọ pé: “Ẹ má ṣe fún àwọn ajá ní ohun tó jẹ́ mímọ́, ẹ má sì sọ àwọn péálì yín síwájú àwọn ẹlẹ́dẹ̀, kí wọ́n má bàa fi ẹsẹ̀ wọn tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, kí wọ́n wá yíjú pa dà, kí wọ́n sì fà yín ya.” (Mt 7:6) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn ìgbà kan wà tí Jésù ò sọ gbogbo bọ́rọ̀ ṣe rí tàbí kó dáhùn ìbéèrè kan ní tààràtà, torí ó mọ̀ pé tóun bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàhálà lè tibẹ̀ yọ. (Mt 15:1-6; 21:23-27; Jo 7:3-10) Èrò kan náà ló yẹ ká ní nípa bí Ábúráhámù, Ísákì, Ráhábù àti Èlíṣà ṣe fi òtítọ́ pa mọ́, tí wọn ò sì sọ gbogbo bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ fáwọn tí ò sin Jèhófà.—Jẹ 12:10-19; orí 20; 26:1-10; Joṣ 2:1-6; Jem 2:25; 2Ọb 6:11-23.
MAY 16-22
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 SÁMÚẸ́LÌ 1-3
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 369 ¶2
Arákùnrin
Wọ́n tún máa ń pe àwọn tí nǹkan kan pa wọ́n pọ̀ tàbí tí wọ́n ní àfojúsùn kan náà ní “arákùnrin.” Bí àpẹẹrẹ, Hírámù ọba Tírè pe Ọba Sólómọ́nì ní arákùnrin ẹ̀. Kì í ṣe torí pé àwọn méjèèjì jẹ́ ọba nìkan ló ṣe pè é bẹ́ẹ̀, àmọ́ ó ṣeé ṣe kó tún jẹ́ torí pé ó wu àwọn méjèèjì láti kó àwọn igi àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n nílò fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì jọ. (1Ọb 9:13; 5:1-12) Dáfídì sọ pé: “Wò ó! Ó mà dára o, ó mà dùn o pé kí àwọn ará máa gbé pọ̀ ní ìṣọ̀kan!” Ìyẹn fi hàn pé kì í ṣe okùn ọmọ ìyá nìkan ló ń jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà láàárín àwọn èèyàn. (Sm 133:1) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì àti Jónátánì kì í ṣe ọmọ ìyá, Dáfídì pè é ní arákùnrin òun torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, àwọn méjèèjì sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (2Sa 1:26) Bákan náà, wọ́n máa ń pe àwọn tí ìwà wọn jọra ní arákùnrin, kódà kó jẹ́ pé ìwà burúkú ni wọ́n ní.—Owe 18:9.
MAY 30–JUNE 5
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 SÁMÚẸ́LÌ 7-8
“Jèhófà Bá Dáfídì Dá Májẹ̀mú”
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-2 206 ¶2
Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn
Àsọtẹ́lẹ̀ Báláámù. Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí, wòlíì Báláámù sọ fún Bálákì ọba Móábù pé: “Wá, jẹ́ kí n sọ fún ọ, ohun tí àwọn èèyàn yìí [Ísírẹ́lì] máa ṣe fún àwọn èèyàn rẹ lọ́jọ́ iwájú. . . . Ìràwọ̀ kan máa ti ọ̀dọ̀ Jékọ́bù wá, ọ̀pá àṣẹ kan sì máa dìde láti Ísírẹ́lì. Ó sì dájú pé ó máa fọ́ iwájú orí Móábù sí wẹ́wẹ́ àti agbárí gbogbo àwọn ọmọ ìdàrúdàpọ̀.” (Nọ 24:14-17) Nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí kọ́kọ́ ṣẹ, Ọba Dáfídì tó ṣẹ́gun àwọn ọmọ Móábù ni “ìràwọ̀” náà dúró fún. (2Sa 8:2) Torí náà, ó ṣe kedere pé àsìkò tí Dáfídì di ọba ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í nímùúṣẹ. Bó sì ṣe jẹ́ pé Dáfídì ń ṣàpẹẹrẹ Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run, àsọtẹ́lẹ̀ yìí tún máa ṣẹ sí Jésù lára nígbà tó bá ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀.—Ais 9:7; Sm 2:8, 9.
JUNE 6-12
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 SÁMÚẸ́LÌ 9-10
“Dáfídì Fi Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn”
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 266
Irùngbọ̀n
Láyé àtijọ́, àwọn tó ń gbé ní Ìlà Oòrùn títí kan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ka irùngbọ̀n sí ohun táwọn ọkùnrin gbọ́dọ̀ ní. Òfin Ọlọ́run kà á léèwọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti fá “irun ẹ̀gbẹ́ orí” wọn, irun tó wà láàárín etí àti ojú àti eteetí irùngbọ̀n wọn. (Le 19:27; 21:5) Ìdí ni pé àwọn abọ̀rìṣà kan ka fífá irùngbọ̀n sí ara ìjọsìn wọn.
JUNE 13-19
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 SÁMÚẸ́LÌ 11-12
“Má Ṣe Gba Èròkerò Láyè”
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 590 ¶1
Dáfídì
Àmọ́, Jèhófà rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sì tú àṣírí ọ̀rọ̀ náà. Ká sọ pé àwọn èèyàn ni Jèhófà fa ìdájọ́ náà lé lọ́wọ́, tí wọ́n sì tẹ̀ lé Òfin Mósè, wọn ò bá pa Dáfídì àti Bátí-ṣébà, ó sì dájú pé ọmọ tó wà nínú Bátí-ṣébà náà máa kú. (Di 5:18; 22:22) Àmọ́ Jèhófà fúnra ẹ̀ ló bójú tó ọ̀rọ̀ náà, ó sì fàánú hàn sí Dáfídì torí májẹ̀mú Ìjọba tó bá a dá. (2Sa 7:11-16) Yàtọ̀ síyẹn, Dáfídì máa ń fàánú hàn sáwọn míì. (1Sa 24:4-7; fi wé Jem 2:13) Bákan náà, Jèhófà rí i pé àwọn méjèèjì ronú pìwà dà tọkàntọkàn. (Sm 51:1-4) Àmọ́, wọ́n ṣì jìyà àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Jèhófà gbẹnu wòlíì Nátánì sọ pé: “Wò ó, màá mú kí àjálù bá ọ láti inú ilé ara rẹ.”—2Sa 12:1-12.
JUNE 20-26
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 SÁMÚẸ́LÌ 13-14
“Ámínónì Mọ Tara Ẹ̀ Nìkan, Ìyẹn sì Yọrí sí Àdánù Ńlá”
it-1 32
Ábúsálómù
Bó Ṣe Pa Ámínónì. Támárì àbúrò Ábúsálómù rẹwà gan-an, ìyẹn sì mú kí ìfẹ́ rẹ̀ kó sórí Ámínónì tó jẹ́ ọbàkan rẹ̀. Ámínónì díbọ́n bíi pé ara òun ò yá, ó sì ní kí Támárì wá dáná fóun nílé, ó wá fipá bá a lòpọ̀. Lẹ́yìn náà, Ámínónì bẹ̀rẹ̀ sí í kórìíra rẹ̀ burúkú-burúkú débi pé ó wá kórìíra ẹ̀ ju bó ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, ó sì lé e jáde. Bí Támárì ṣe ń jáde lọ, ó fa aṣọ ara ẹ̀ ya, ìyẹn aṣọ tí wọ́n fi ń dá àwọn wúńdíá ọmọ ọba mọ̀, ó sì da eérú sórí. Nígbà tó pàdé Ábúsálómù, Ábúsálómù fòye gbé ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sì fura pé Ámínónì ló máa hùwà ìkà sí àbúrò òun torí ó mọ̀ pé ọkàn Ámínónì ti ń fà sí Támárì tẹ́lẹ̀. Ábúsálómù wá sọ fún Támárì pé kó má sọ̀rọ̀ náà fún ẹnikẹ́ni, ó sì ní kó máa gbé nílé òun.—2Sa 13:1-20.
it-1 33 ¶1
Ábúsálómù
Lẹ́yìn tí ọdún méjì kọjá, àsìkò tó fún Ábúsálómù láti rẹ́ irun àwọn àgùntàn rẹ̀, èyí sì máa ń jẹ́ àsìkò àjọyọ̀. Ábúsálómù wá ṣètò àjọyọ̀ ní Baali-hásórì tó wà ní nǹkan bí máìlì mẹ́rìnlá sí apá àríwá Jerúsálẹ́mù, ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba títí kan Dáfídì fúnra ẹ̀. Nígbà tí Dáfídì sọ pé òun ò ní lè wá, Ábúsálómù bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kí Ámínónì àkọ́bí rẹ̀ tẹ̀ lé àwọn lọ. (Owe 10:18) Nígbà tí ‘wáìnì ń mú inú Ámínónì dùn’ níbi àjoyọ̀ náà, Ábúsálómù pàṣẹ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n pa Ámínónì. Àwọn ọmọ ọba tó kù pa dà sí Jerúsálẹ́mù, Ábúsálómù sì sá lọ sọ́dọ̀ bàbá rẹ̀ àgbà ní ìlú Géṣúrì tó wà ní Ìlà Oòrùn Òkun Gálílì. (2Sa 13:23-38) “Idà” tí wòlíì Nátánì sọ tẹ́lẹ̀ ti wá wọ “ilé” Dáfídì, kò sì ní kúrò níbẹ̀ títí Dáfídì á fi kú.—2Sa 12:10.
JUNE 27–JULY 3
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 SÁMÚẸ́LÌ 15-17
“Ìgbéraga Mú Kí Ábúsálómù Ṣọ̀tẹ̀”
it-1 860
Ẹni Tó Ń Lọ Ṣáájú
Láyé àtijọ́, ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ará Ìlà Oòrùn pé káwọn sárésáré máa lọ ṣáájú kẹ̀kẹ́ ẹṣin tó gbé ọba, kí wọ́n lè máa kéde pé ọba ń bọ̀, kí wọ́n sì ran ọba lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì. (1Sa 8:11) Ohun tí Ábúsálómù àti Ádóníjà ṣe nìyẹn nígbà tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀, wọ́n yan àádọ́ta ọkùnrin táá máa sáré níwájú kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn kí wọ́n lè gbayì lójú àwọn èèyàn.—2Sa 15:1; 1Ọb 1:5; wo SÁRÉSÁRÉ.
it-1 1083-1084
Hébúrónì
Lẹ́yìn ọdún mélòó kan, Ábúsálómù ọmọ Dáfídì pa dà sí Hébúrónì, ibẹ̀ ló sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò bó ṣe máa dìtẹ̀ gbàjọba lọ́wọ́ bàbá rẹ̀. (2Sa 15:7-10) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé torí ìlú Hébúrónì ni Ábúsálómù ti wá, ó sì tún jẹ́ ìlú pàtàkì torí òun ni olú ìlú Júdà tẹ́lẹ̀, ni Ábúsálómù ṣe pinnu láti dìtẹ̀ gbàjọba látibẹ̀. Nígbà tó yá, Ọba Rèhóbóámù tó jẹ́ ọmọ-ọmọ Dáfídì tún Hébúrónì kọ́. (2Kr 11:5-10) Lẹ́yìn táwọn Júù pa dà láti ìgbèkùn Bábílónì, àwọn kan lára àwọn Júù tó pa dà yẹn tẹ̀ dó sí Hébúrónì (ìyẹn Kiriati-ábà).—Ne 11:25.