Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
© 2022 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
MARCH 6-12
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 KÍRÓNÍKÀ 23-26
“Bí Wọ́n Ṣe Ń Jọ́sìn Nínú Tẹ́ńpìlì Túbọ̀ Wà Létòlétò”
it-2 241
Àwọn Ọmọ Léfì
Dáfídì ṣètò iṣẹ́ àwọn ọmọ Léfì kí wọ́n lè wà létòlétò. Bí àpẹẹrẹ, ó yan àwọn alábòójútó, aláṣẹ, onídàájọ́, aṣọ́bodè àtàwọn tó ń bójú tó àwọn ibi ìṣúra. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún yan ọ̀pọ̀ àwọn míì tó máa ran àwọn àlùfáà lọ́wọ́ nínú tẹ́ńpìlì, nínú àgbàlá àti nínú yàrá ìjẹun. Lára ohun tí wọ́n máa ń ṣe ni pé, wọ́n máa ń ran àwọn àlùfáà lọ́wọ́ tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ọrẹ, tí wọ́n bá fẹ́ rúbọ, tí wọ́n bá ń ṣe ìwẹ̀mọ́, tí wọ́n bá fẹ́ wọn nǹkan tàbí kí wọ́n bá wọn ṣọ́ nǹkan. Wọ́n tún ṣètò àwọn ọmọ léfì tó jẹ́ akọrin sí àwùjọ mẹ́rìnlélógún (24) bíi tàwọn àlùfáà, àwùjọ kọ̀ọ̀kan sì máa ń ṣiṣẹ́ lẹ́yìn tí àwùjọ míì bá parí iṣẹ́ wọn. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa ń ṣẹ́ kèké láti mọ àwùjọ tí iṣẹ́ máa kàn. Ọ̀nà kan náà sì ni wọ́n máa ń gbà yan iṣẹ́ fún àwùjọ àwọn aṣọ́bodè.—1Kr 23; 25; 26; 2Kr 35:3-5, 10.
it-2 686
Àlùfáà
Nígbà tí wọ́n ń ṣètò iṣẹ́ àwọn àlùfáà nínú tẹ́ńpìlì, wọ́n yan àwọn aláṣẹ láti máa bójú tó iṣẹ́ wọn. Wọ́n tún ṣẹ́ kèké kí wọ́n lè mọ iṣẹ́ tí kálukú máa bójú tó. Àwùjọ mẹ́rìnlélógún (24) ni wọ́n pín àwọn àlùfáà sí, àwùjọ kọ̀ọ̀kan sì máa ń ṣiṣẹ́ fún ọ̀sẹ̀ kan, ìyẹn túmọ̀ sí pé ẹ̀ẹ̀mejì lọ́dùn ni àwùjọ kan máa ṣiṣẹ́. Ẹ̀rí fi hàn pé gbogbo àwọn àlùfáà ló máa ń ṣiṣẹ́ nígbà àjọyọ̀ torí pé àwọn èèyàn máa ń rú ẹbọ tó pọ̀ lásìkò yẹn, bí wọ́n ṣe ṣe nígbà ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì. (1Kr 24:1-18, 31; 2Kr 5:11; fi wé 2Kr 29:31-35; 30:23-25; 35:10-19.) Àlùfáà kan lè ṣiṣẹ́ láwọn ìgbà míì tí ò bá ṣáà ti dí àwọn àlùfáà tí wọ́n yàn láti ṣiṣẹ́ lákòókò yẹn lọ́wọ́. Bó ṣe wà nínú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn rábì, nígbà ayé Jésù, àwọn àlùfáà pọ̀ débi pé wọ́n máa ń tún iṣẹ́ pín fún ìdílé kọ̀ọ̀kan tó wà nínú àwùjọ tó ń ṣiṣẹ́ lọ́sẹ̀ kan, tó fi jẹ́ pé ìdílé kan lè ṣiṣẹ́ fún ọjọ́ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìye ìdílé tó sì wà nínú àwùjọ kan ló máa pinnu bí wọ́n ṣe máa pín iṣẹ́ fún wọn.
it-2 451-452
Orin
Bí wọ́n ṣe ń múra sílẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣètò bí wọ́n á ṣe ṣiṣẹ́ ní tẹ́ńpìlì, Dáfídì yan ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) àwọn ọmọ Léfì láti jẹ́ akọrin. (1Kr 23:4, 5) Igba ó lé ọgọ́rin àti mẹ́jọ (288) lára àwọn yìí ló jẹ́ ọ̀jáfáfá “tí a ti kọ́ níṣẹ́ orin láti máa kọrin sí Jèhófà.” (1Kr 25:7) Àwọn akọrin mẹ́ta tó jẹ́ ọ̀jáfáfá, ìyẹn Ásáfù, Hémánì àti Jédútúnì (tó ṣeé ṣe kó tún máa jẹ́ Étánì) ló ń bójú tó àwọn akọrin. Ásáfù jẹ́ ọmọ Gẹ́ṣómù, Hémánì jẹ́ ọmọ Kóhátì, Jédútúnì sì jẹ́ ọmọ Mérárì, torí náà ìlà ìdílé mẹ́tẹ̀ẹ̀ta táwọn ọmọ Léfì ti wá ló wà nínú ètò tí wọ́n ṣe fún orin kíkọ́ nínú tẹ́ńpìlì. (1Kr 6:16, 31-33, 39-44; 25:1-6) Ọmọkùnrin mẹ́rìnlélógún (24) láwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí bí, gbogbo àwọn ọmọkùnrin yìí sì wà lára àwọn igba ó lé ọgọ́rin àti mẹ́jọ (288) tí wọ́n jẹ́ ọ̀jáfáfá akọrin. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọkùnrin yìí ló jẹ́ olórí àwùjọ akọrin kọ̀ọ̀kan, kèké sì ni wọ́n fi yan àwùjọ tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn á máa bójú tó. Torí náà bíi tàwọn àlùfáà, àwùjọ akọrin mẹ́rìnlélógún (24) ló wà, àwùjọ kọ̀ọ̀kan sì ní ọ̀jáfáfá akọrin méjìlá. Àwọn “ọ̀jáfáfá” méjìlá (12) tó wà nínú àwùjọ kọ̀ọ̀kan ni, ẹni tó jẹ́ alábòójútó, àwọn ọmọ rẹ̀ àtàwọn ọmọ Léfì míì ([1 + 11] × 24 = 288). Tá a bá wá pín àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọgọ́rùn-ún méje àti méjìlá (3,712) tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ sínú àwùjọ akọrin mẹ́rìnlélógún (24) tó wà, á jẹ́ pé àwùjọ kọ̀ọ̀kan máa ní nǹkan bí àwọn márùndínlọ́gọ́jọ (155) míì tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́. Èyí fi hàn pé ọ̀jáfáfá akọrin kọ̀ọ̀kan máa ní awọn bíi mẹ́tàlá (13) tá a máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. (1Kr 25:1-31) Torí pé àwọn àlùfáà ló ń fun kàkàkí, ṣe ni wọ́n máa kún àwọn ọmọ Léfì tó jẹ́ akọrin.—2Kr 5:12; fi wé Nọ 10:8.
it-1 898
Aṣọ́bodè
Nínú Tẹ́ńpìlì. Nígbà tó kù díẹ̀ kí Ọba Dáfídì kú, ó ṣètò àwọn ọmọ Léfì, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì àtàwọn aṣọ́bodè tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) láti máa ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì. Àwùjọ aṣọ́bodè kan máa ṣiṣẹ́ fún ọjọ́ méje kí àwùjọ míì tó wá gbaṣẹ́ lọ́wọ́ wọn. Ojúṣe wọn ni láti ṣọ́ ilé Jèhófà, kí wọ́n sì rí i dájú pé wọ́n ń ṣí ilẹ̀kùn, wọ́n sì ń tì í lásìkò tó tọ́. (1Kr 9:23-27; 23:1-6) Yàtọ̀ sí iṣẹ́ olùṣọ́, àwọn kan lára wọn tún máa ń bójú tó ọrẹ táwọn èèyàn bá mú wá sí tẹ́ńpìlì. (2Ọb 12:9; 22:4) Nígbà kan tí Jèhóádà àlùfáà àgbà fẹ́ fòróró yan Jèhóáṣì di ọba, wọ́n dìídì yan àwọn aṣọ́bodè kan láti wà ní ibodè tẹ́ńpìlì kí wọ́n lè dáàbò bo Jèhóáṣì lọ́wọ́ Ataláyà tó dìtẹ̀ gbàjọba. (2Ọb 11:4-8) Nígbà tí Ọba Jòsáyà fòpin sí ìbọ̀rìṣà, àwọn aṣọ́nà kó àwọn nǹkan tí wọ́n ń lò nínú ìjọ̀sìn Báálì kúrò nínú tẹ́ńpìlì, wọ́n sì sun wọ́n ní ìta ìlú náà.—2Ọb 23:4.
MARCH 20-26
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 KÍRÓNÍKÀ 1-4
“Ọba Sólómọ́nì Ṣe Ìpinnu Tí Ò Mọ́gbọ́n Dání”
it-1 174 ¶5
Àwọn Ọmọ Ogun
Nǹkan yàtọ̀ fáwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì nígbà ìṣàkóso Sólómọ́nì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àlàáfíà wà nígbà ìṣàkóso rẹ̀, ó kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ẹṣin jọ. (wo KẸ̀KẸ́ ẸṢIN.) Ọ̀pọ̀ àwọn ẹṣin yìí ló jẹ́ pé ilẹ̀ Íjíbítì ni wọ́n ti kó wọn wá. Kódà, ó kọ́ àwọn ìlú táwọn agẹṣin á máa lò, tí wọ́n á sì kó àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin sí káàkiri agbègbè tó ń ṣàkóso. (1Ọb 4:26; 9:19; 10:26, 29; 2Kr 1:14-17) Àmọ́ inú Jèhófà ò dùn sí ohun tí Sólómọ́nì ṣe yìí. Nígbà tó sì kú, ìjọba Ísírẹ́lì pín sí méjì, àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì ò sì lágbára mọ́. Abájọ tí Àìsáyà fi sọ nígbà tó yá pé: “Ó mà ṣe fún àwọn tó ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ Íjíbítì o, tí wọ́n gbójú lé ẹṣin, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé kẹ̀kẹ́ ogun, torí pé wọ́n pọ̀, àti àwọn ẹṣin ogun, torí pé wọ́n lágbára. Wọn ò yíjú sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, wọn ò sì wá Jèhófà.”—Ais 31:1.
it-1 427
Kẹ̀kẹ́ Ẹṣin
Àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì ò ní àwùjọ àwọn ọmọ ogun tó ń lo kẹ̀kẹ́ ẹṣin títí dìgbà ìṣàkóso Sólómọ́nì. Ohun tó sì fà á ni pé Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún àwọn ọba pé wọn ò gbọ́dọ̀ kó ẹṣin rẹpẹtẹ jọ bíi pé àwọn ẹṣin yẹn ló máa dáàbò bò wọ́n, èyí ló mú káwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí wọ́n ní kéré gan-an. (Di 17:16) Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń béèrè fún ọba, Sámúẹ́lì kìlọ̀ fún wọn pé, àwọn ọba náà “á mú àwọn ọmọkùnrin yín, á sì fi wọ́n sínú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀.” (1Sa 8:11) Nígbà tí Ábúsálómù àti Ádóníjà gbìyànjú láti sọ ara wọn dọba, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ṣe kẹ̀kẹ́ ẹṣin kan fún ara ẹ̀, àádọ́ta (50) ọkùnrin sì ń sáré níwájú rẹ̀. (2Sa 15:1; 1Ọb 1:5) Nígbà tí Dáfídì ṣẹ́gun ọba Sóbà, ó dá ọgọ́rùn-ún (100) ẹṣin rẹ̀ sí.—2Sa 8:3, 4; 10:18.
Nígbà tí Ọba Sólómọ́nì ń mú káwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì lágbára sí i, ó mú kí iye àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn di ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (1,400). (1Ọb 10:26, 29; 2Kr 1:14, 17) Yàtọ̀ sí Jerúsálẹ́mù, àwọn ìlú míì wà tí wọ́n ń pè ní ìlú kẹ̀kẹ́ ẹṣin torí pé wọ́n ní àwọn nǹkan tí wọ́n fi ń bójú tó àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin.—1Ọb 9:19, 22; 2Kr 8:6, 9; 9:25.
MARCH 27–APRIL 2
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 KÍRÓNÍKÀ 5-7
“Ọkàn Mi Á Máa Wà Níbẹ̀ Nígbà Gbogbo”
it-2 1077-1078
Tẹ́ńpìlì
Ìtàn. Tẹ́ńpìlì yìí wà títí di ọdún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni kó tó di pé Ọba Nebukadinésárì àtàwọn ọmọ ogun Bábílónì pa á run. (2Ọb 25:9; 2Kr 36:19; Jer 52:13) Ọlọ́run fàyè gba kí àwọn orílẹ̀-èdè míì fìyà jẹ ilẹ̀ Júdà àti Jerúsálẹ́mù torí pé wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀, wọ́n sì ń bọ̀rìṣà. Kódà nígbà míì, àwọn orílẹ̀-èdè yìí máa ń kó àwọn ìṣúra inú tẹ́ńpìlì. Àwọn ìgbà kan tiẹ̀ wà tí wọ́n pa tẹ́ńpìlì náà tì pátápátá. Ọba Ṣíṣákì ti ilẹ̀ Íjíbítì (993 Ṣ.S.K.) kó àwọn ìṣúra inú tẹ́ńpìlì nígbà ayé Rèhóbóámù ọmọ Sólómọ́nì. Ìyẹn sì jẹ́ nǹkan bí ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) péré lẹ́yìn tí wọ́n yà á sí mímọ́. (1Ọb 14:25, 26; 2Kr 12:9) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọba Ásà (977-937 Ṣ.S.K.) nífẹ̀ẹ́ ilé Jèhófà, ó hùwà òmùgọ̀ kan. Kó lè dáàbò bo Jerúsálẹ́mù, ó kó fàdákà àti wúrà nínú ilé Jèhófà lọ fún Ọba Bẹni-hádádì Kìíní ti ilẹ̀ Síríà kó lè yẹ àdéhùn tí ó bá Bááṣà ọba Ísírẹ́lì ṣe.—1Ọb 15:18, 19; 2Kr 15:17, 18; 16:2, 3.
APRIL 10-16
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 KÍRÓNÍKÀ 8-9
it-2 990-991
Sólómọ́nì
Nígbà tí ọbabìnrin náà rí bí tẹ́ńpìlì àti ilé Sólómọ́nì ṣe rẹwà tó, tó sì tún rí oúnjẹ orí tábìlì rẹ̀, àwọn agbọ́tí rẹ̀, bó ṣe ṣètò àwọn tó ń gbé oúnjẹ fún un àti aṣọ tí wọ́n ń wọ̀ àti àwọn ẹbọ sísun tó ń rú déédéé ní ilé Jèhófà, “ẹnu yà á gan-an,” débi tó fi sọ pé, “Wò ó! Ohun tí mo gbọ́ kò tiẹ̀ tó ìdajì rárá. Ọgbọ́n rẹ àti aásìkí rẹ kọjá àwọn ohun tí mo gbọ́.” Lẹ́yìn náà, ó sọ pé aláyọ̀ ni gbogbo àwọn ìránṣẹ́ tí wọ́n ń bá irú ọba bẹ́ẹ̀ ṣiṣẹ́. Èyí mú kó yin Jèhófà lógo, torí ó gbà pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní fún Ísírẹ́lì ló mú kó fi Sólómọ́nì jọba kó lè máa dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, kó sì máa ṣe òdodo.—1Ọb 10:4-9; 2Kr 9:3-8.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-2 1097
Ìtẹ́
Ìtẹ́ Sólómọ́nì nìkan ni ìtẹ́ ọba Ísírẹ́lì tí Bíbélì ṣàlàyé ní kíkún. (1Ọb 10:18-20; 2Kr 9:17-19) Ó jọ pé inú “Gbọ̀ngàn Ìtẹ́,” ni ìtẹ́ yìí wà, gbọ̀ngàn yìí sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilé tó wà lórí Òkè Moráyà ní Jerúsálẹ́mù. (1Ọb 7:7) Sólómọ́nì fi ‘eyín erin ṣe ìtẹ́ ńlá kan, ó sì fi wúrà tí a yọ́ mọ́ bò ó, ó tún ní ìbòrí ribiti kan lẹ́yìn, ibi ìgbápálé sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì ìjókòó náà.’ Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lo eyín erin gan-an láti ṣe ìtẹ́ yìí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣe àwọn ohun èlò inú tẹ́ńpìlì ni wọ́n gbà ṣe ìtẹ́ yìí. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé igi ni wọ́n fi kàn án, wọ́n wá fi wúrà tí a yọ́ mọ́ bò ó, wọ́n sì fi eyín erin ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́. Lójú ẹni tó bá ń wò ó, ṣe ló máa dà bíi pé eyín erin àti wúrà ni wọ́n fi ṣe é látòkèdélẹ̀. Lẹ́yìn tí Bíbélì mẹ́nu kan Àtẹ̀gùn mẹ́fà tí ìtẹ́ náà ní, ó fi kún un pé: “Ère kìnnìún kọ̀ọ̀kan sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ibi ìgbápálé náà. Àwọn kìnnìún tó dúró lórí àtẹ̀gùn mẹ́fà náà jẹ́ méjìlá (12), ọ̀kọ̀ọ̀kan wà ní eteetí àtẹ̀gùn kọ̀ọ̀kan.” (2Kr 9:17-19) Wọ́n fi àwọn kìnnìún yẹn ṣàpẹẹrẹ agbára ìṣàkóso, ìyẹn sì bá a mu wẹ́kú. (Jẹ 49:9, 10; Ifi 5:5) Kìnnìún méjìlá (12) náà dúró fún àwọn ẹ̀yà méjìlá (12) Ísírẹ́lì, ìyẹn sì fi hàn pé wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹni tó wà lórí ìtẹ́ náà, wọ́n sì fi ara wọn sábẹ́ rẹ̀. Àpótí ìtìsẹ̀ tí wọ́n fi wúrà ṣe tún wà lára ìtẹ́ náà. Ìtẹ́ yìí tí wọ́n fi eyín erin àti wúrà ṣe, tó sì ní ìbòrí títí kan ère àwọn kìnnìún rẹwà ju ìtẹ́ èyíkéyìí tó wà láyé ìgbà yẹn lọ, yàlà ìtẹ́ táwọn awalẹ̀pìtàn rí tàbí èyí tí wọ́n ya àwòrán ẹ̀ tàbí èyí tí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ ẹ̀ sínú wàláà àtijọ́. Bí òǹkọ̀wé Bíbélì náà ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́ ló rí, pé: “Kò sí ìjọba kankan tó ṣe irú rẹ̀ rí.”—2Kr 9:19.
APRIL 17-23
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 KÍRÓNÍKÀ 10-12
“Tá A Bá Tẹ̀ Lé Ìmọ̀ràn Tó Dáa Ó Máa Ṣe Wá Láǹfààní”
it-2 768 ¶1
Rèhóbóámù
Ìgbéraga Rèhóbóámù àti bó ṣe jọ ara ẹ̀ lójú mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn kẹ̀yìn sí ilé Dáfídì. Èyà Júdà àti Bẹ́ńjámínì nìkan ló fara mọ́ ìṣàkóso ilé Dáfídì. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì tí wọ́n wà nínú ìjọba méjèèjì títí kan àwọn mélòó kan láti ìjọba èyà mẹ́wàá náà fara wọn sábẹ́ ìṣàkóso ilé Dáfídì.—1Ọb 12:16, 17; 2Kr 10:16, 17; 11:13, 14, 16.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 966-967
Ẹ̀mí Èṣù Tó Rí Bí Ewúrẹ́
Ohun tí Jóṣúà sọ nínú Jóṣúà 24:14 fi hàn pé àsìkò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò ní Íjíbítì ti mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ sí ìjọsìn èké táwọn ará Íjíbítì ń ṣe, ohun tí Ìsíkíẹ́lì sọ sì fi hàn pé àwọn èèyàn náà ṣì ń lọ́wọ́ nínú ìbọ̀rìṣà náà títí di àsìkò yẹn. (Isk 23:8, 21) Èyí ló mú káwọn ọ̀mọ̀wé kan gbà pé òfin tí Ọlọ́run fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú aginjù pé kí wọ́n “má ṣe rú ẹbọ mọ́ sí àwọn ẹ̀mí èṣù tó rí bí ewúrẹ́” (Le 17:1-7) àti bí Jèróbóámù ṣe yan àwọn àlùfáà “fún àwọn ibi gíga àti fún àwọn ẹ̀mí èṣù tó rí bí ewúrẹ́ àti fún àwọn ère ọmọ màlúù tí ó ṣe” (2Kr 11:15) fi hàn pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń jọ́sìn àwọn ẹ̀mí èṣù tó rí bí ewúrẹ́ bíi táwọn ará Íjíbítì, pàápàá àwọn tó ń gbé lọ́wọ́ ìsàlẹ̀ ilẹ̀ Íjíbítì. Herodotus (Kejì, 46) sọ pé àwọn Gíríìkì mú lára ìjọsìn àwọn ará Íjíbítì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Gíríìkì nígbàgbọ́ nínú àwọn òòṣà kan tí wọ́n ń pè ní Pan àti satyrs, ìyẹn àwọn òòṣà ìnú igbó tó ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ. Wọ́n gbà pé àwọn òòṣà yìí ní ìwo, ìrù àti ẹsẹ̀ ewúrẹ́. Àwọn kan tiẹ̀ gbà pé àwọn òòṣà tí apá kan wọn jẹ́ ẹranko yìí ló mú káwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ láyé àtijọ́ máa yàwòrán Sátánì bí ẹni tó ní ìrù àti ìwo, tí ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dà bí ẹsẹ̀ ẹranko.
A ò lè sọ ohun táwọn “ewúrẹ́” (seʽi·rimʹ) yìí jẹ́ gan-an. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan sọ pé ewúrẹ́ ni wọ́n ní ti gidi tàbí ere tí wọ́n gbẹ́ bí ewúrẹ́, ẹsẹ Bíbélì yẹn ò sọ ní pàtó; kò sì sí ẹ̀rí kankan nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì míì tó fi hàn bẹ́ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wọ́n lo ọ̀rọ̀ náà torí pé lọ́kàn àwọn tó ń sìn wọ́n, ìrísí àwọn òòṣà náà dà bíi ti ewúrẹ́ tàbí pé wọ́n nírun lára. Ó sì lè jẹ́ pé wọ́n lo ọ̀rọ̀ náà “ewúrẹ́” láti fi bẹnu àtẹ́ lu irú ìbọ̀rìṣà tó ń kóni nírìíra bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ tí wọ́n túmọ̀ sí òrìṣà wá látinú gbólóhùn tó túmọ̀ sí “ohun ẹlẹ́gbin,” bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ohun ẹlẹ́gbin ni wọ́n fi ṣe àwọn òòṣà náà.—Le 26:30; Di 29:17.