Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
JULY 3-9
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́SÍRÀ 4-6
“Ẹ Má Ṣe Dí Iṣẹ́ Náà Lọ́wọ́”
w86 6/1 29, àpótí ¶2-3
Oju-iriran Jehofah ‘Nbẹ Lara Awon Agba Ọkunrin’
Lehin ipada iyoku awon Jew lati Babylon, akoko-igba 16 ọdun aiṣiṣẹmọti bere. Awọn woli Haggai ati Zechriah jàjà gbọn awọn Jew kuro ninu iwa aibikita wọn, iṣẹ ikọle temple Jehofah ni a sì pada sẹnu rẹ̀. Laipẹ, bi o ti wu ki o ri, iṣẹ yii ni awọn ijoye-oṣiṣẹ persia pe nija. “Tani fun yin ni aṣẹ lati kọ ile yii?” ni awọn alatako beere.—Ezra 5:1-3.
Èsì si iwadii yii takókó. Bi awọn alagba naa ba yọnda ki a dẹruba wọn, imupadabọsipo temple naa yoo dawọduro lojiji. Bi awọn alagba naa bá bá awọn ijoye-oṣiṣẹ wọnyi jà, eyi yoo yori si ifofinde iṣẹ naa lẹsẹkẹsẹ. Nitori naa awọn alagba (laisi ani-ani ti Gomina Zerubbabel ati Olori Alufa Joshua jẹ aṣaaju fun) fi òye fesi lọna ọgbọn-ẹwẹ ṣugbọn ti o munadoko. Wọn ran awọn ijoye-oṣiṣẹ naa leti aṣẹ-ofin ti a ti gbagbe tipẹtipẹ ti Cyrus ti o fun awon Jew ni iyọnda ọba lati tẹsiwaju pẹlu iṣẹ yii. Ni mimọ ilana-eto Persia ti aileṣee yipada mọ́ ofin tí a ti sọjade, awọn ijoye-oṣiṣẹ wọnyi fi laakaye yàn lati yẹra fun ṣiṣe atako si aṣẹ-ofin oba kan. Nipa bayii iṣẹ iṣẹ naa ni a gba láyè lati tẹsiwaju titi ti ọba Darius lehin naa fi aṣẹ-ọba funni pe ki a maa ba iṣẹ niṣo!—Ezra 5:11-17; 6:6-12.
JULY 10-16
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́SÍRÀ 7-8
“Ẹ́sírà Fi Ìwà Rẹ̀ Gbé Orúkọ Jèhófà Ga”
si 75 ¶5
Ìwé Kẹtàlá Nínú Bíbélì—1 Kíróníkà
5 Kò sẹ́lòmíì tó lè ṣàkọsílẹ̀ ìtàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́nà tó péye bíi ti Ẹ́sírà. Ìdí ni pé “Ẹ́sírà ti múra ọkàn rẹ̀ sílẹ̀ láti wádìí nínú Òfin Jèhófà àti láti pa á mọ́ àti láti máa kọ́ àwọn èèyàn ní àwọn ìlànà àti ìdájọ́ inú rẹ̀ ní Ísírẹ́lì.” (Ẹ́sírà 7:10) Bákan náà, Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ràn án lọ́wọ́. Ọba Páṣíà tó ń ṣàkóso ayé nígbà yẹn rí i pé Ọlọ́run fún Ẹ́sírà lọ́gbọ́n, ó wá yàn án pé kó máa bójú tó bí nǹkan ṣe ń lọ láwọn agbègbè Júdà. (Ẹ́sírà 7:12-26) Ní báyìí tí Jèhófà ń fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ràn án lọ́wọ́, tí ọba Páṣíà sì tún fún un láṣẹ, Ẹ́sírà lè lo àwọn àkọsílẹ̀ tó dáa jù nígbà yẹn láti ṣàkójọ ìtàn yìí.
it-1 1158 ¶4
Ìrẹ̀lẹ̀
Ó Máa Ń Jẹ́ Kí Ọlọ́run Tọ́ni Sọ́nà. Tẹ́nì kan bá rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, ó dájú pé Ọlọ́run máa tọ́ ọ sọ́nà. Iṣẹ́ ńlá kan wà tó já lé Ẹ́sírà léjìká. Òun ló fẹ́ ṣáájú àwọn ọkùnrin tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ (1,500) títí kan àwọn àlùfáà, àwọn Nétínímù, àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé láti Bábílónì sí Jerúsálẹ́mù. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà àti fàdákà tí wọ́n á fi ṣe tẹ́ńpìlì lọ́ṣọ̀ọ́ dání. Kò sí àní-àní pé wọ́n máa nílò ààbò torí ewu ojú ọ̀nà. Àmọ́ Ẹ́sírà ò béèrè fáwọn ọmọ ogun lọ́dọ̀ ọba Páṣíà torí ó mọ̀ pé Jèhófà máa dáàbò bo àwọn. Bákan náà, ṣáájú ìgbà yẹn ló ti sọ fún ọba pé: “Ọwọ́ rere Ọlọ́run wa wà lára gbogbo àwọn tó ń wá a.” Torí náà, ó kéde ààwẹ̀, àwọn èèyàn náà sì rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú Jèhófà. Wọ́n bẹ Ọlọ́run pé kó dáàbò bo àwọn, kó sì tọ́ àwọn sọ́nà, Ọlọ́run sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ó dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá àtàwọn dánàdánà, wọ́n sì dé Jerúsálẹ́mù láyọ̀ àti àlàáfíà. (Ẹsr 8:1-14, 21-32) Nígbà tí Dáníẹ́lì wà nígbèkùn ní Bábílónì, ó rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀ níwájú Jèhófà, ó bẹ̀ ẹ́ pé kó tọ́ òun sọ́nà, kó sì fún òun lóye, Jèhófà fojúure hàn sí i, ó sì rán áńgẹ́lì rẹ̀ pé kó fi ìran kan hàn án.—Da 10:12.
JULY 24-30
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | NEHEMÁYÀ 1-2
“Lójú Ẹsẹ̀, Mo Gbàdúrà”
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
w86 6/1 21
Ijọsin Tootọ Yọ Ayọ-iṣẹgun
Bẹẹ kọ, nitori ipo iparun-dahoro ti Jerusalem wà jẹ koko ọrọ awọn adura “tọsan-toru” ti Nehemiah gba fun awọn akoko gigun diẹ ṣaaju (1:4,6) Nigba ti a yọnda fun akoko-anfani lati sọ fun Ọba Artaxerxes nipa ifẹ-ọkan rẹ̀ lati tun awọn ogiri Jerusalem kọ́, Nehemiah gbadura leekan sí i, nipa bẹẹ ó nṣe ohun ti oun ti ṣe leralera ṣaaju akoko naa. Idahun Jehofah ti o kún fun ojurere-iṣeun yọrisi iṣe-aṣẹ kan lati tun awọn ogiri ilu-nla naa kọ́.
Ekọ-arikọgbọn fun Wa: Nehemiah yiju si Jehofah fun idari-tọsọna. Nigba ti a ba dojukọ awọn ipinu pataki-pataki, awa, pelu nilati “maa duro gangan ninu adura” ki a si huwa ni ibamu pelu itọsọna Jehofah.—Rome 12:12.
AUGUST 14-20
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | NEHEMÁYÀ 8-9
“Ìdùnnú Jèhófà Ni Ibi Ààbò Yín”
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 145 ¶2
Árámáíkì
Ọdún mélòó kan lẹ́yìn táwọn Júù pa dà dé láti Bábílónì, Ẹ́sírà tó jẹ́ àlùfáà ka ìwé Òfin fáwọn Júù tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Àwọn ọmọ Léfì sì ń ṣàlàyé ẹ̀ fáwọn èèyàn náà. Nehemáyà 8:8 sọ pé: “Wọ́n ń ka ìwé náà sókè nìṣó látinú Òfin Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n ń ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà tó ṣe kedere, wọ́n sì ń túmọ̀ rẹ̀; torí náà, wọ́n jẹ́ kí àwọn èèyàn náà lóye ohun tí wọ́n kà.” Ó lè jẹ́ pé ohun tí wọ́n ń ṣe ni pé wọ́n túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ náà láti èdè Hébérù sí èdè Árámáíkì torí ó ṣeé ṣe káwọn Hébérù tí máa sọ èdè Árámáíkì nígbà tí wọ́n wà ní Bábílónì. Ìtumọ̀ tí wọ́n ń ṣe yìí tún gba pé kí wọ́n ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà dáadáa fáwọn Júù kó lè yé wọn yékéyéké. Ìdí ni pé táwọn Júù yẹn bá tiẹ̀ gbọ́ èdè Hébérù, wọn lè má lóye ọ̀rọ̀ náà dáadáa.
AUGUST 21-27
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | NEHEMÁYÀ 10-11
“Wọ́n Yááfì Ohun Ìní Wọn fún Jèhófà”
w86 6/1 21
Ijọsin Tootọ Yọ Ayọ-iṣẹgun
Fifi awọn ilẹ-ìní ajogunba sílẹ ati ṣiṣi lọ si Jerusalem yoo ti yọrisi inawo diẹ ati ipadanu awọn ọla-anfanni kan. Awọn wọnni tí n gbe ninu ilu-nla naa ni a ti le ṣisilẹ si oniruuru ewu. Labẹ iru awọn ayika-ipo bẹẹ, awọn ẹlomiran wo awọn oluyọnda ara-ẹni naa gẹgẹ bi awọn ti wọn yẹ fun ìyìn ati lasi ani-ani wọn gbadura pe Jehofah yoo bukun won.
AUGUST 28–SEPTEMBER 3
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | NEHEMÁYÀ 12-13
“Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Jèhófà Tó O Bá Fẹ́ Yan Ọ̀rẹ́”
it-1 95 ¶5
Àwọn Ọmọ Ámónì
Lẹ́yìn tí wọ́n lé Tobáyà kúrò nínú tẹ́ńpìlì, wọ́n tún òfin Ọlọ́run tó wà nínú Diutarónómì 23:3-6 kà tó sọ pé ọmọ Ámónì tàbí ọmọ Móábù kankan ò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà, wọ́n sì ṣiṣẹ́ lé e lórí. (Ne 13:1-3) Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún kan sẹ́yìn ni Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní òfin yẹn torí pé àwọn ọmọ Ámónì àtàwọn ọmọ Móábù kọ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n ń sún mọ́ Ilẹ̀ Ìlérí. Ohun tí òfin yìí túmọ̀ sí ni pé tí ọmọ Ámónì tàbí ọmọ Móábù kan bá tiẹ̀ ń gbé nílẹ̀ Ísírẹ́lì, kò ní lè di ọmọ Ísírẹ́lì, kò sì ní láwọn àǹfààní táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní. Ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ọmọ Ámónì tàbí ọmọ Móábù kan ò lè dara pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kó sì gbádùn ìbùkún tí Jèhófà ń fún àwọn èèyàn rẹ̀. Àpẹẹrẹ irú àwọn tó gbádùn ìbùkún bẹ́ẹ̀ ni Sélékì, tó wà lára àwọn jagunjagun Dáfídì tó lákíkanjú àti Rúùtù ará Móábù.—Rut 1:4, 16-18.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-2 452 ¶9
Orin
Ọwọ́ kékeré kọ́ ni wọ́n fi mú ọ̀rọ̀ orin kíkọ́ nínú tẹ́ńpìlì. Ohun tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn akọrin. Bákan náà, torí kí wọ́n lè gbájú mọ́ iṣẹ́ wọn, wọn “kò yan iṣẹ́ míì fún” wọn bí wọ́n ṣe yàn fáwọn ọmọ Léfì míì. (1Kr 9:33) Ẹ̀rí míì tó fi hàn pé wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì tá a yà sọ́tọ̀ tún ṣe kedere nínú bí wọ́n ṣe dárúkọ wọn lọ́tọ̀ nígbà tí wọ́n mẹ́nu kan àwọn tó pa dà láti Bábílónì. (Ẹsr 2:40, 41) Yàtọ̀ síyẹn, Ọba Atasásítà (Lọngimánọ́sì) ti ilẹ̀ Páṣíà pàṣẹ pé wọn ò gbọ́dọ̀ gba “owó orí, ìṣákọ́lẹ̀ tàbí owó ibodè” lọ́wọ́ àwọn olórin àtàwọn míì tí wọ́n yà sọ́tọ̀. (Ẹsr 7:24) Nígbà tó yá, ọba náà pàṣẹ pé kí wọ́n ṣètò “ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ máa fún àwọn akọrin bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe gbà.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Atasásítà ni wọ́n gbà pé ó ṣòfin náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Ẹ́sírà ló gbé ìlànà náà kalẹ̀ nítorí àṣẹ tí Atasásítà fún un. (Ne 11:23; Ẹsr 7:18-26) Torí náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọmọ Léfì làwọn akọrin, wọ́n yà wọ́n sọ́tọ̀, ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi máa ń mẹ́nu kan “àwọn akọrin àti àwọn ọmọ Léfì.”—Ne 7:1; 13:10.