Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
© 2024 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
MARCH 3-9
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 3
Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
‘Má Ṣe Gbára Lé Òye Tìrẹ’
2 Ta lo máa ń gbẹ́kẹ̀ lé tó o bá wà nínú ipò tí ń kó ìdààmú báni, tó o bá fẹ́ ṣe ìpinnu, tàbí kó o lè borí ìdẹwò? Ṣé o máa ń rò pé o lè dá bójú tó ọ̀ràn ara rẹ, àbí o máa ń “ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà”? (Sm. 55:22) Bíbélì sọ pé: “Ojú Jèhófà ń bẹ lọ́dọ̀ àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́.” (Sm. 34:15) Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó nígbà náà pé ká fi gbogbo ọkàn-àyà wa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká má sì gbára lé òye tiwa!—Òwe 3:5.
3 Bá a bá fẹ́ fi gbogbo ọkàn wa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ìyẹn gba pé ká máa ṣe àwọn ohun tó bá fẹ́ ká ṣe, ká sì ṣe é lọ́nà tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa gbàdúrà sí i nígbà gbogbo, ká sì máa fi tọkàntọkàn béèrè fún ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Àmọ́, ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ń jẹ́ Lynn sọ pé, “Mo ṣì ń tiraka láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nínú gbogbo ohun tí mo bá ń ṣe.” Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ó sọ pé: “Bàbá mi ò rí tèmi rò, màmá mi kì í ráyè gbọ́ tèmi, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò bójú tó mi. Torí náà, kò pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í dá bójú tó ọ̀ràn ara mi.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Lynn yìí ò tiẹ̀ jẹ́ kó lè gbẹ́kẹ̀ lé ẹnikẹ́ni. Bí ẹnì kan bá mọ ohun kan ṣe dáadáa tó sì ń ṣàṣeyọrí, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í rò pé òun lè dá bójú tó ọ̀ràn ara òun. Alàgbà kan lè fẹ́ láti máa lo ìrírí tó ti ní láti bójú tó àwọn ọ̀ràn tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọ kó má sì kọ́kọ́ gbàdúrà sí Ọlọ́run.
Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
22 Àmọ́ ṣá o, Òwe 3:6 sọ pé a gbọ́dọ̀ ‘ṣàkíyèsí Jèhófà ní gbogbo ọ̀nà wa,’ kì í ṣe kìkì ìgbà tí ìṣòro bá dé. Nítorí náà, àwọn ìpinnu tá a ń ṣe nínú ìgbésí ayé wa lójoojúmọ́ gbọ́dọ̀ fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Bí ìṣòro bá dé, a kò gbọ́dọ̀ sọ̀rètí nù, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí jìnnìjìnnì bò wá, a sì gbọ́dọ̀ gbé ìlànà Jèhófà yẹ̀ wò lórí ọ̀nà tó dára jù lọ láti bójú tó àwọn ọ̀ràn náà. A gbọ́dọ̀ ka àdánwò sí àǹfààní láti ṣètìlẹ́yìn fún ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, láti fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì, àti láti jẹ́ onígbọràn ká sì ní àwọn ànímọ́ mìíràn tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí.—Hébérù 5:7, 8.
23 A lè fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà láìfi ìṣòro èyíkéyìí tó lè máa dẹ́rù bà wá pè. A ń ṣe èyí nípasẹ̀ àwọn àdúrà tá a ń gbà àti nípa bá a ṣe ń wá ìtọ́sọ́nà nínú Ọ̀rọ̀ Jèhófà àti nínú ètò àjọ rẹ̀. Àmọ́ báwo la ṣe lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà táwọn ìṣòro tó wà nínú ayé lónìí bá dé bá wa? Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò jíròrò kókó yìí.
Máa Tẹ̀ Síwájú
Bójú ẹnì kan bá ti rí ọ̀pọ̀ nǹkan sẹ́yìn láyé yìí, bí nǹkan mìíràn bá sẹlẹ̀, onítọ̀hún lè ronú pé: ‘Irú nǹkan yìí ti ṣẹlẹ̀ sí mi rí. Mo mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe.’ Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀? Òwe 3:7 sọ pé: “Má ṣe di ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ.” Lóòótọ́ o, ó yẹ kí ìrírí ayé lè túbọ̀ múni gbé ipò tó bá dójú kọni láyé yẹ̀ wò láti onírúurú ìhà. Àmọ́ tí a bá ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó yẹ kí ìrírí wa ní ìgbésí ayé jẹ́ ká mọ̀ lọ́kàn wa pé láìsí ìbùkún Jèhófà, ìsapá ẹni ò lè láṣeyọrí rárá. Ó hàn pé kì í ṣe ìdára-ẹni-lójú àti ìgboyà tá a bá fi kojú àwọn ipò tó bá dojú kọ wá ló ń fi hàn pé a ti ní ìlọsíwájú, bí kò ṣe bí a ṣe tètè máa ń yíjú sí Jèhófà fún ìtọ́sọ́nà ní ìgbésí ayé wa. Ó máa ń hàn nínú dídá tí ó bá dá wa lójú pé kò sóhun tó lè ṣẹlẹ̀ láìjẹ́ pé Ọlọ́run gbà á láyè, àti nínú bí a ṣe ń rí i pé a ní àjọṣe tímọ́tímọ́ tó ṣeé fọkàn tẹ̀ láàárín àwa àti Bàbá wa ọ̀run.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Òwe
3:3. Ó yẹ ká wo inú rere onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tó ṣe pàtàkì gan-an, ká sì jẹ́ kí nǹkan méjèèjì yìí máa hàn kedere nínú ìwà wa bí ìgbà téèyàn fi ìlẹ̀kẹ̀ iyebíye sọ́rùn. A tún ní láti kọ wọ́n sínú ọkàn wa, ìyẹn ni pé ká rí i pé wọ́n mọ́ wa lára.
MARCH 10-16
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 4
“Dáàbò Bo Ọkàn Rẹ”
Báwo Lo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ọkàn Rẹ?
4 Nínú Òwe 4:23, Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà ọkàn nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ẹni tá a jẹ́ nínú. (Ka Sáàmù 51:6.) Lédè míì, ọkàn ń tọ́ka sí èrò wa, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa, ohun tó ń sún wa ṣe nǹkan àti ìfẹ́ ọkàn wa. Ó ṣe kedere pé ẹni tá a jẹ́ nínú ni ọkàn ń tọ́ka sí, kì í ṣe ohun tá a jẹ́ lóde tàbí ohun táwọn èèyàn gbà pé a jẹ́.
Báwo Lo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ọkàn Rẹ?
10 Tá a bá máa dáàbò bo ọkàn wa, a gbọ́dọ̀ mọ àwọn nǹkan tó lè wu wá léwu, ká sì gbé ìgbésẹ̀ láìjáfara láti dáàbò bo ara wa. Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò fún “fi ìṣọ́ ṣọ́” tàbí dáàbò bò nínú Òwe 4:23 rán wa létí iṣẹ́ táwọn ẹ̀ṣọ́ máa ń ṣe. Lásìkò Ọba Sólómọ́nì, orí ògiri ìlú làwọn ẹ̀ṣọ́ máa ń wà tí wọ́n á máa ṣọ́ ohun tó ń lọ, tí wọ́n bá sì kó fìrí ewu, wọ́n á ké jáde kí àwọn aráàlú lè mọ̀. Àpẹẹrẹ yìí máa jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun tó yẹ ká ṣe kí Sátánì má bàa sọ ọkàn wa dìbàjẹ́.
11 Láyé àtijọ́, àwọn ẹ̀ṣọ́ máa ń ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn aṣọ́bodè ìlú. (2 Sám. 18:24-26) Bí wọ́n ṣe jọ ń ṣiṣẹ́ yìí mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti dáàbò bo ìlú, wọ́n máa ń rí i pé ẹnubodè ìlú wà ní títì pa nígbàkigbà táwọn ọ̀tá bá sún mọ́ tòsí. (Neh. 7:1-3) Bákan náà lónìí, Sátánì máa ń wọ́nà àtidarí ọkàn wa, èrò wa, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa, ohun tó ń sún wa ṣe nǹkan àti ìfẹ́ ọkàn wa. Àmọ́, ẹ̀rí ọkàn tá a fi Bíbélì kọ́ máa ń ṣiṣẹ́ bí àwọn ẹ̀ṣọ́, ó máa ń kìlọ̀ fún wa nígbà tí Sátánì bá gbé ìṣe rẹ̀ dé. Torí náà, nígbàkigbà tí ẹ̀rí ọkàn wa bá kìlọ̀ fún wa, ó yẹ ká tẹ́tí sí i, ká sì ti ilẹ̀kùn ọkàn wa pa.
Báwo Lo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ọkàn Rẹ?
14 Ká lè dáàbò bo ọkàn wa, a ò gbọ́dọ̀ fàyè gba ohunkóhun tó lè sọ ọkàn wa dìbàjẹ́, àmọ́ a tún gbọ́dọ̀ ṣí ọkàn wa sílẹ̀ káwọn nǹkan rere lè wọnú rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká pa dà sórí àpẹẹrẹ àwọn ẹ̀ṣọ́ àtàwọn aṣọ́bodè tá a sọ lẹ́ẹ̀kan. Àwọn aṣọ́bodè máa ń ti ilẹ̀kùn pa kí àwọn ọ̀tá má bàa wọlé, àmọ́ láwọn ìgbà míì wọ́n máa ń ṣílẹ̀kùn káwọn èèyàn lè kó oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì wọlé. Àbí kí lẹ rò pé ó máa ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ pé wọn kì í ṣí ilẹ̀kùn náà rárá? Ó dájú pé ebi máa pa àwọn ará ìlú. Lọ́nà kan náà, ó yẹ ká máa ṣí ilẹ̀kùn ọkàn wa sílẹ̀ kí èrò Ọlọ́run lè wọlé, kó sì máa darí wa.
“Máa Ṣọ́ Ọkàn Rẹ!”
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣọ́ ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa? Ọlọ́run mí sí Sólómọ́nì Ọba láti sọ pé: “Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ, nítorí láti inú rẹ̀ ni àwọn orísun ìyè ti wá.” (Òwe 4:23) Bí ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa ṣe rí máa ń nípa lórí irú ìgbésí ayé tí à ń gbé nísinsìnyí àti lórí bí a ṣe máa rí ìyè lọ́jọ́ iwájú. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Ọlọ́run rí ohun tó wà nínú ọkàn wa. (1 Sámúẹ́lì 16:7) Irú èèyàn tá a jẹ́ ní inú, ìyẹn “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà,” ló máa pinnu ojú tí Ọlọ́run máa fi wò wá.—1 Pétérù 3:4.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Ṣé Wàá Dúró De Jèhófà?
4 Òwe 4:18 sọ pé: “Ipa ọ̀nà àwọn olódodo dà bí ìmọ́lẹ̀ àárọ̀ tó ń mọ́lẹ̀ sí i títí di ọ̀sán gangan.” Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé díẹ̀díẹ̀ ni Jèhófà ń mú káwọn èèyàn rẹ̀ mọ ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe. Àmọ́, a tún lè lo ẹsẹ Bíbélì yìí láti ṣàpèjúwe bí Kristẹni kan ṣe ń ṣe ìyípadà nígbèésí ayé ẹ̀, tó sì túbọ̀ ń sún mọ́ Jèhófà. Gbogbo wa la mọ̀ pé ó máa ń gba àkókò kéèyàn tó lè fàwọn ìwà àtijọ́ sílẹ̀ kó sì sún mọ́ Jèhófà. Tá a bá ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run, tá a sì ń fi àwọn ìmọ̀ràn inú ẹ̀ sílò, díẹ̀díẹ̀ a máa dà bíi Kristi. Yàtọ̀ síyẹn, àá túbọ̀ máa mọ Jèhófà sí i. Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe kan tí Jésù fi ṣàlàyé kókó yìí.
MARCH 17-23
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 5
Sá fún Ìṣekúṣe, Má Tiẹ̀ Sún Mọ́ Ọn Rárá
O Lè Jẹ́ Oníwà Mímọ́ Nínú Ayé Oníṣekúṣe
Nínú òwe yìí, oníwàkiwà èèyàn ni a fi wé “àjèjì obìnrin”—ìyẹn aṣẹ́wó. Àwọn ọ̀rọ̀ tó fi ń sún àwọn èèyàn dẹ́ṣẹ̀ dùn bí afárá oyin, ó sì jọ̀lọ̀ ju òróró ólífì lọ. Ǹjẹ́ báyìí kọ́ ni wọ́n ṣe sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ fi ìṣekúṣe lọni? Fún àpẹẹrẹ, gbọ́ ìrírí obìnrin akọ̀wé kan, tó jẹ́ ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Amy. Ó ròyìn pé: “Ojú ọkùnrin kan tó wà níbi iṣẹ́ wa kì í kúrò lára mi, ńṣe ló máa ń pọ́n mi ṣáá. Ó máa ń jẹ́ ìwúrí láti gba àfiyèsí àwọn èèyàn. Ṣùgbọ́n mo rí i kedere pé ìfẹ́ tó ní sí mi kò kọjá ìfẹ́ ìbálòpọ̀ takọtabo. Mi ò ní jẹ́ kó fi ẹ̀tàn fà mí lọ.” Ọ̀rọ̀ àpọ́nlé ẹlẹ́tàn, ì báà jẹ́ látẹnu ọkùnrin tàbí obìnrin, sábà máa ń dùn-ún gbọ́ létí, àfi téèyàn bá tètè fura pé ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ni. Ìdí nìyẹn tó fi gba ọgbọ́n ìrònú.
O Lè Jẹ́ Oníwà Mímọ́ Nínú Ayé Oníṣekúṣe
Ohun tí ìṣekúṣe máa ń yọrí sí nígbẹ̀yìn korò bí iwọ, ó sì mú bí idà olójú méjì—ó kún fún ìrora ó sì ń ṣekú pani. Ẹ̀rí ọkàn tí ń dani láàmú, oyún tí a kò fẹ́, tàbí àrùn téèyàn ń kó nípasẹ̀ ìbálòpọ̀, ló sábà máa ń jẹ́ àbájáde burúkú irú ìwà bẹ́ẹ̀. Sì tún ronú nípa ẹ̀dùn ọkàn ńláǹlà tó máa ń dé bá ọkọ tàbí aya aláìṣòótọ́ náà. Ìwà àìṣòótọ́ kan ṣoṣo ti tó láti fa ìròbìnújẹ́ tó lè báni dọjọ́ alẹ́. Dájúdájú, ìṣekúṣe ń ṣeni léṣe.
O Lè Jẹ́ Oníwà Mímọ́ Nínú Ayé Oníṣekúṣe
Ó yẹ ká rìn jìnnà réré sí ọ̀nà àwọn oníṣekúṣe. Èé ṣe tí a ó fi rìn nítòsí ọ̀nà wọn nípa gbígbọ́ àwọn orinkórin, nípa wíwo àwọn eré oníwà ìbàjẹ́, tàbí nípa wíwo àwọn nǹkan tó ń ru ìfẹ́ ìbálòpọ̀ sókè? (Òwe 6:27; 1 Kọ́ríńtì 15:33; Éfésù 5:3-5) Ẹ sì wo bó ti jẹ́ ìwà òmùgọ̀ tó láti máa fa ojú wọn mọ́ra nípa bíbá wọn tage tàbí nípa wíwọṣọ àti mímúra lọ́nà tí kò bójú mu!—1 Tímótì 4:8; 1 Pétérù 3:3, 4.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
O Lè Jẹ́ Oníwà Mímọ́ Nínú Ayé Oníṣekúṣe
Ọ̀rọ̀ òkè yìí tí Sólómọ́nì sọ fi hàn kedere pé aburú tó máa ń tẹ̀yìn ìṣekúṣe yọ kò kéré rárá. Ẹni tó bá ṣe panṣágà kì í jìnnà sí àbùkù tàbí ẹ̀tẹ́. Ǹjẹ́ kì í ṣe òótọ́ ni pé ó ń tẹ́ni lógo láti wulẹ̀ sọ ara wa di ohun èlò tí a fi ń tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wa tàbí ti ẹlòmíràn lọ́rùn? Kì í ha í ṣe ìfara-ẹni-wọ́lẹ̀ láti lọ́wọ́ nínú ìbálòpọ̀ takọtabo pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya wa?
MARCH 24-30
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 6
Kí La Lè Kọ́ Lára Àwọn Èèrà?
it-1 115 ¶1-2
Èèrà
‘Ọgbọ́n Àdámọ́ni.’ Kì í ṣe torí pé àwọn èèrà ń kẹ́kọ̀ọ́ ni wọ́n ṣe gbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, ọgbọ́n tí Ẹlẹ́dàá dá mọ́ wọn ni wọ́n fi ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe. Bíbélì sọ nípa àwọn èèrà pé wọ́n ń ‘ṣètò oúnjẹ wọn sílẹ̀ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, wọ́n sì ń kó oúnjẹ wọn jọ nígbà ìkórè.’ (Owe 6:8) Ọ̀kan lára àwọn èèrà tó wọ́pọ̀ ní agbègbè Palestine ni harvester (Messor semirufus), àwọn èèrà yìí máa ń kó ọkà jọ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn kí àsìkò òjò tàbí òtútù tó dé torí pé ó máa ń ṣòro láti rí oúnjẹ nígbà yẹn. Àwọn èèrà yìí máa ń pọ̀ láwọn agbègbè tí wọ́n ti ń pa ọkà torí pé oúnjẹ máa ń pọ̀ níbẹ̀. Tí òjò bá mú kí oúnjẹ tí wọ́n gbé pa mọ́ tutù, àwọn èèrà yìí máa kó oúnjẹ yìí jáde, wọ́n á sì sa á sóòrùn kó lè gbẹ. Wọ́n tiẹ̀ tún máa ń gé ibi tó máa ń hù lára kóró kúrò, kó má bàa hù níbi tí wọ́n kó o pa mọ́ sí. Àwọn èèyàn tètè máa ń rí ibi táwọn èèrà yìí ń gbé torí àwọn èèrà náà máa ń la ọ̀nà dé ilé wọn, wọ́n sì máa ń kó èèpo oúnjẹ síbi àbáwọlé.
Ohun Tá A Lè Kọ́ Lára Wọn. Àwọn ohun tá a gbé yẹ̀ wò yìí jẹ́ ká rí ìdí tí Bíbélì fi sọ pé: “Tọ èèrà lọ, ìwọ ọ̀lẹ; kíyè sí àwọn ọ̀nà rẹ̀, kí o sì gbọ́n.” (Owe 6:6) Kì í ṣe bí wọ́n ṣe máa ń múra sílẹ̀ fún ọjọ́ iwájú nìkan ló gbàfiyèsí, wọ́n tún ní ìforítì, wọ́n sì máa ń fara da nǹkan gan-an. Bí àpẹẹrẹ, tí oúnjẹ tí wọ́n fẹ́ gbé bá tóbi jù wọ́n lọ, wọ́n á rí i pé àwọn gbé e, wọn ò sì ní fi í sílẹ̀ kódà kí wọ́n já bọ́ níbi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, wọ́n á rí i pé àwọn gbé e délé. Ohun míì tó tún jọni lójú ni pé wọ́n máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀, ilé wọn sì máa ń mọ́ tónítóní. Bákan náà, wọ́n máa ń ran ara wọn lọ́wọ́, nígbà míì wọ́n máa ń gbé èyí tó ti rẹ̀ tàbí tó fara pa wálé.
Má Ba Ara Rẹ Lórúkọ Jẹ́
Bíi ti eèrà, ǹjẹ́ kò yẹ kí àwa náà jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn? Ṣíṣe iṣẹ́ ní àṣekára àti gbígbìyànjú láti jẹ́ kí iṣẹ́ wa túbọ̀ dáa sí i yóò ṣe wá láǹfààní, yálà wọ́n ń ṣọ́ wa tàbí wọn ò ṣọ́ wa. Bẹ́ẹ̀ ni o, bó jẹ́ ilé ìwé la wà ni o, tàbí níbi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa ni o, ì báà sì jẹ́ nígbà táa bá ń nípìn-ín nínú ìgbòkègbodò tẹ̀mí pàápàá, a gbọ́dọ̀ ṣe ipa tiwa dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Bí eèrà ṣe ń jàǹfààní nínú jíjẹ́ tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí àwa náà ‘rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára wa.’ (Oníwàásù 3:13, 22; 5:18) Ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ àti ayọ̀ àtọkànwá ni èrè iṣẹ́ àṣekára.—Oníwàásù 5:12.
Nípa lílo ìbéèrè mọ̀-ọ́n-nú méjì, Sólómọ́nì gbìyànjú láti ta onímẹ̀ẹ́lẹ́ ènìyàn jí kúrò nínú ìwà ọ̀lẹ rẹ̀, ó ní: “Yóò ti pẹ́ tó, ìwọ ọ̀lẹ, tí ìwọ yóò fi wà ní ìdùbúlẹ̀? Ìgbà wo ni ìwọ yóò dìde kúrò lójú oorun rẹ?” Ọba náà tún ń sín ọ̀lẹ jẹ, ó ní: “Oorun díẹ̀ sí i, ìtòògbé díẹ̀ sí i, kíká ọwọ́ pọ̀ díẹ̀ sí i ní ìdùbúlẹ̀, ipò òṣì rẹ yóò sì dé dájúdájú gẹ́gẹ́ bí alárìnkiri kan, àti àìní rẹ bí ọkùnrin tí ó dìhámọ́ra.” (Òwe 6:9-11) Ibi tí ọ̀lẹ sùn kaakà sí ni ipò òṣì yóò ti dé bá a, tí yóò sì kọlù ú bí olè, àìní yóò sì kọlù ú bí ọkùnrin tí ó dìhámọ́ra. Kíá ni èpò àti èsìsì bo oko ọ̀lẹ. (Òwe 24:30, 31) Kò pẹ́ tí gbogbo òwò rẹ̀ fi pòórá. Ìgbà wo ni agbanisíṣẹ́ kan yóò máa wo ọ̀lẹ ènìyàn níran dà? Ǹjẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kan tó lẹ ju isó lọ nídìí ìwé kíkà lè retí pé òun ó ṣe dáadáa nílé ìwé?
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Má Ba Ara Rẹ Lórúkọ Jẹ́
Ohun méje tí òwe náà mẹ́nu kàn ní ọ̀kan-ò-jọ̀kan làwọn nǹkan tó ṣe kókó tó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ kó gbogbo ohun tó jẹ́ ibi ní àkótán. “Ojú gíga fíofío” àti “ọkàn-àyà tí ń fẹ̀tàn hùmọ̀ àwọn ìpètepèrò tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́,” jẹ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ téèyàn máa ń dá nínú èrò. “Ahọ́n èké” àti “ẹlẹ́rìí èké tí ń gbé irọ́ yọ” jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀. “Ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀” àti “ẹsẹ̀ tí ń ṣe kánkán láti sáré sínú ìwà búburú” jẹ́ àwọn ìṣe búburú. Ohun tí Jèhófà tún kórìíra gan-an ni kéèyàn ní inú dídùn sí dídá gbọ́nmisi-omi-ò-to sílẹ̀ láàárín àwọn tó yẹ kí wọ́n máa gbé pa pọ̀ ní àlàáfíà. Bí iye náà ṣe lọ sókè láti orí mẹ́fà sí méje fi hàn pé kò tíì parí síbẹ̀, nítorí pé ìwà ibi àwọn ènìyàn yóò máa pọ̀ sí i ṣáá ni.
MARCH 31–APRIL 6
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 7
Yẹra Fáwọn Ipò Tó O Ti Lè Kó sí Ìdẹwò
“Pa Àwọn Àṣẹ Mi Mọ́ Kí o Sì Máa Bá a Lọ Ní Wíwà Láàyè”
Àgánrándì wà lójú fèrèsé tí Sólómọ́nì ń gbà wòta—ó dájú pé iṣẹ́ ọ̀nà kan ló jẹ́, èyí tó láwọn ọ̀pá tín-ínrín-tín-ínrín lára, bóyá tó tiẹ̀ tún ní àwọn ohun gbígbẹ́ táa fi ṣe ẹ̀ṣọ́ sí i lára pẹ̀lú. Bí ìmọ́lẹ̀ àṣálẹ́ ti ń pòórá, tí àwọn òpópónà sì di èyí tó ṣú dùdù. Ó rí ọ̀dọ́kùnrin kan tó fira ẹ̀ sínú ewu. Nítorí pé kò ní ìfòyemọ̀, tàbí agbára ìmòye rere, ọkàn àyà kù fún un. Ó ṣeé ṣe kó mọ irú àdúgbò tí òun wà yẹn àti nǹkan tó lè ṣẹlẹ̀ sóun níbẹ̀. Ọ̀dọ́kùnrin náà sún mọ́ ìtòsí “igun ọ̀nà rẹ̀,” ìyẹn igun tó wà ní ọ̀nà tó lọ sí ilé obìnrin náà. Ta ni obìnrin ọ̀hún? Àrà wo ló sì wà lọ́wọ́ ẹ̀?
“Pa Àwọn Àṣẹ Mi Mọ́ Kí o Sì Máa Bá a Lọ Ní Wíwà Láàyè”
Ètè obìnrin yìí mà dùn o. Kò tiẹ̀ tijú, ó sì ń sọ̀rọ̀ láìfìkan pe méjì. Ó ń ro gbogbo nǹkan tó ń sọ dáadáa kó tó sọ ọ́, kí ó ṣáà lè rí ọkùnrin yìí mú. Nípa sísọ pé òun ti ṣe àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ lọ́jọ́ yẹn gan-an àti pé òun ti san àwọn ẹ̀jẹ́ òun, ńṣe ló ń fi hàn pé òun jẹ́ olódodo, ó sì ń jẹ́ kó mọ̀ pé òun kò kù síbì kan nípa tẹ̀mí. Ní tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ máa ń ní ẹran, ìyẹ̀fun, òróró àti wáìnì nínú. (Léfítíkù 19:5, 6; 22:21; Númérì 15:8-10) Níwọ̀n ìgbà tó sì kúkú jẹ́ pé ẹni tó ń ṣèrúbọ lè mú lára ẹbọ ìdàpọ̀ náà fún ara rẹ̀ àtàwọn ìdílé rẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi ń sọ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà fún jíjẹ àti mímu ní ilé òun. Ohun tó ń sọ ṣe kedere: Ọ̀dọ́kùnrin yẹn á gbádùn ara rẹ̀ dọ́ba níbẹ̀. Nítorí kó lè rí i ló kúkú ṣe jáde kúrò nílé. Ó mà ṣe o, bí ẹnì kan bá lọ gba irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ gbọ́. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kan sọ pé, “òótọ́ ni pé obìnrin náà jáde láti wá ẹnì kan rí, àmọ́ ṣé ẹni yìí gan-an ní pàtàkì ló ń wá kiri ni? Òpònú èèyàn—bóyá bí irú ẹni yìí—nìkan ló lè gba nǹkan tóbìnrin yẹn sọ gbọ́.”
Lẹ́yìn tó ti fi aṣọ ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ lọ́nà tí ń fani mọ́ra tán, tó sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ tí ń tanni jẹ, tó tún lo ìfarakanra nípa ìgbánimọ́ra àti adùn ètè rẹ̀, oníṣekúṣe náà tún wá lo agbára òórùn. Ó sọ pé: “Mo ti fi àwọn aṣọ ìtẹ́lébùsùn ṣe ọ̀ṣọ́ fún àga ìnàyìn mi, pẹ̀lú àwọn ohun tí ó jẹ́ kàlákìnní, aṣọ ọ̀gbọ̀ Íjíbítì. Mo ti fi òjíá, álóè àti sínámónì wọ́n ibùsùn mi.” (Òwe 7:16, 17) Ó ti ṣe ibùsùn rẹ̀ lọ́nà tó lẹ́wà pẹ̀lú aṣọ ọ̀gbọ̀ Íjíbítì aláwọ̀ mèremère, ó sì ti fi àwọn òórùn dídùn ti òjíá, álóè àti sínámónì wọ́n ibùsùn náà.
“Ó tẹ̀ síwájú pé: “Wá, jẹ́ kí a mu ìfẹ́ ní àmuyó títí di òwúrọ̀; jẹ́ kí a fi àwọn ìfihàn ìfẹ́ gbádùn ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” Ìkésíni yẹn ju kìkì pé káwọn èèyàn méjì wulẹ̀ gbádùn oúnjẹ alẹ́ alárinrin kan pa pọ̀ lọ. Ìlérí tó ń ṣe fún un jẹ́ ti gbígbádùn ìbálòpọ̀ pa pọ̀. Lójú ọmọkùnrin yẹn ní tiẹ̀, kò sóhun tó tún lè dùn ju ìyẹn lọ! Kó lè túbọ̀ kó sí i lórí pátápátá, ló bá tún fi kún-un pé: “Nítorí ọkọ kò sí ní ilé rẹ̀; ó ti rin ìrìn àjò lọ sí ọ̀nà tí ó jìn. Ó mú àpò owó lọ́wọ́. Ọjọ́ òṣùpá àrànmọ́jú ni yóò wá sí ilé rẹ̀.” (Òwe 7:18-20) Ó fi yé e pé kó séwu fáwọn, nítorí ọkọ̀ rẹ̀ ti lọ sí àjò lọ ṣòwò, yóò sì ṣe díẹ̀ kó tó padà dé. Ẹ ò rí i pé ó mọ ọgbọ́n tí wọ́n fi ń mú ẹnì kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ gan-an ni! “Ó ti fi ọ̀pọ̀ yanturu ìyíniléròpadà rẹ̀ ṣì í lọ́nà. Ó fi dídùn mọ̀nràn-ìn mọnran-in ètè rẹ̀ sún un dẹ́ṣẹ̀.” (Òwe 7:21) Àyàfi irú èèyàn kan tó níwà bíi ti Jósẹ́fù nìkan ló lè dènà irú ìfanimọ́ra tí ń réni lọ bí èyí. (Jẹ́nẹ́sísì 39: 9, 12) Ṣé ọ̀dọ́kùnrin yìí kúnjú ìwọ̀n?
“Pa Àwọn Àṣẹ Mi Mọ́ Kí o Sì Máa Bá a Lọ Ní Wíwà Láàyè”
Ìkésíni yẹn ti wọ ọ̀dọ́kùnrin yìí lára débi tí kò fi lè kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ó gbàgbé gbogbo agbára ìmòye rere pátá, gọ̀ọ́gọ̀ọ́ ló tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ‘bí akọ màlúù tó ń lọ fún pípa.’ Bí kò ṣe ṣeé ṣe fún ọkùnrin kan tí wọ́n kó ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí lẹ́sẹ̀ láti bọ́ lọ́wọ́ ìjìyà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀dọ́kùnrin náà di ẹni tí a fà sínú ẹ̀ṣẹ̀. Kò rí ewu tó wà nínú ẹ̀ rárá, “títí ọfà fi la ẹ̀dọ̀ rẹ̀ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀,” ìyẹn túmọ̀ sí pé, àfìgbà tó gba ọgbẹ́ tó lè yọrí sí ikú rẹ̀. Ikú yẹn lè jẹ́ èyí tó ṣeé fojú rí nítorí pé ó ti ṣí ara rẹ̀ payá sí àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń fà èyí tí ń ṣekú pani. Ọgbẹ́ yẹn tún lè fa ikú ẹ̀ nípa tẹ̀mí nítorí pé “ó wé mọ́ ọkàn òun gan-an.” Gbogbo ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbésí ayé rẹ̀ pátá ni ọ̀ràn náà nípa tó lágbára lé lórí, ó sì tún ti dẹ́ṣẹ̀ tó wúwo sí Ọlọ́run. Ó tipa bẹ́ẹ̀ yára kánkán kó sínú ẹ̀mú ikú bí ẹyẹ kan tó kó sínú pańpẹ́!
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
“Pa Àwọn Àṣẹ Mi Mọ́ Kí o Sì Máa Bá a Lọ Ní Wíwà Láàyè”
Sólómọ́nì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “So wọ́n [àwọn àṣẹ mi] mọ́ ìka rẹ, kí o sì kọ wọ́n sára wàláà ọkàn-àyà rẹ.” (Òwe 7:3) Bó ṣe jẹ́ pé ìgbà gbogbo la máa ń yẹ àwọn ìka wa wò tí wọ́n sì tún ṣe pàtàkì fún wa láti ṣe àwọn nǹkan táa ní í ṣe, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹ̀kọ́ táa kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ láti kékeré tàbí ìmọ̀ Bíbélì táa jèrè ṣe gbọ́dọ̀ máa jẹ́ ìránnilétí fún wa nígbà gbogbo kó sì máa tọ́ wa nínú gbogbo ohun táa bá ń ṣe. A ní láti kọ wọ́n sínú wàláà ọkàn-àyà wa, ká sọ wọ́n di apá kan ara wa.
APRIL 7-13
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 8
Fetí sí Ọgbọ́n Jésù
“Mo Nífẹ̀ẹ́ Baba”
7 Ní ẹsẹ 22, ọgbọ́n sọ pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ni ó ṣẹ̀dá mi gẹ́gẹ́ bí ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọ̀nà rẹ̀, ìbẹ̀rẹ̀pàá àwọn àṣeyọrí rẹ̀ ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.” Nǹkan míì ní láti wà nínú ọ̀rọ̀ yìí, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ọgbọ́n ṣe lè wá di ohun tí Ọlọ́run “ṣẹ̀dá.” Ọgbọ́n ò níbẹ̀rẹ̀ torí Jèhófà fúnra rẹ̀ ò níbẹ̀rẹ̀ kò sí sígbà tí Jèhófà ò gbọ́n. (Sáàmù 90:2) Àmọ́, Ọmọ Ọlọ́run ni “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá.” Dídá ni Ọlọ́run dá a; òun ni ìbẹ̀rẹ̀pàá àwọn àṣeyọrí rẹ̀. (Kólósè 1:15) Ọmọ ti wà ṣáájú ayé àti ọ̀run, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Òwe inú Bíbélì ṣe sọ. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òun ni Agbẹnusọ fún Ọlọ́run, àní òun lẹni tó jẹ́ ká rí bí ọgbọ́n Jèhófà ṣe pé pérépéré tó.—Jòhánù 1:1.
“Mo Nífẹ̀ẹ́ Baba”
8 Kí ni Ọmọ Ọlọ́run ń ṣe ni gbogbo àìlóǹkà ọdún tó fi wà lọ́run kó tó wá sáyé? Ẹsẹ 30 sọ fún wa pé ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí “àgbà òṣìṣẹ́.” Kí nìyẹn wá túmọ̀ sí? Kólósè 1:16 ṣàlàyé pé: “Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá gbogbo ohun mìíràn ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé . . . Gbogbo ohun mìíràn ni a dá nípasẹ̀ rẹ̀ àti fún un.” Nípa báyìí, Jèhófà tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá lo Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ Àgbà Òṣìṣẹ́ láti dá gbogbo ohun mìíràn, látorí àwọn áńgẹ́lì tó wà lájùlé ọ̀run dórí àgbáyé wa tó lọ salalu, títí kan orí ilẹ̀ ayé wa tó kún fún onírúurú ewéko àti ẹranko tó ń ṣeni ní kàyéfì, kó tó wá kan ti olúborí gbogbo ìṣẹ̀dá lórí ilẹ̀ ayé ńbí, ìyẹn àwa èèyàn. Láwọn ọ̀nà kan, a lè fi ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tó wà láàárín Bàbá àti Ọmọ yìí wé ọ̀rọ̀ àárín ayàwòrán ilé kan tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú mọlémọlé tàbí agbaṣẹ́ṣe kan tó mọ béèyàn ṣe ń sọ àwòrán tí ayàwòrán ilé kan fi ọpọlọ pípé yà di ilé àrímáleèlọ. Bá a bá rí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá kan tó jọ wá lójú gan-an, Jèhófà tó jẹ́ Ayàwòrán tó ju ayàwòrán lọ là ń fìyìn fún. (Sáàmù 19:1) Bákan náà, èyí tún lè rán wa létí pé tipẹ́tipẹ́ ni ìfọwọ́sowọ́pọ̀ aláyọ̀ ti wà láàárín Ẹlẹ́dàá àti “àgbà òṣìṣẹ́” rẹ̀.
9 Báwọn èèyàn aláìpé méjì bá jọ ṣiṣẹ́ pọ̀, kì í rọrùn láti jọ wà lálàáfíà nígbà míì. Kò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀! Àìmọye ọdún ni Ọmọ fi bá Bàbá rẹ̀ ṣiṣẹ́, ńṣe ló sì “ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà.” (Òwe 8:30) Bó ṣe rí nìyẹn, inú rẹ̀ máa ń dùn láti máa wà pẹ̀lú Bàbá rẹ̀, ńṣe ni inú Bàbá náà sì máa ń dùn láti wà pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bá a ti lè retí, ńṣe ni Ọmọ yìí ń dà bíi Bàbá rẹ̀ sí i, ó sì ń kọ́ bó ṣe lè máa fi ànímọ́ Ọlọ́run ṣèwà hù. Abájọ tí okùn ìfẹ́ àárín Ọmọ àti Bàbá ṣe yi tó bẹ́ẹ̀! Ó tọ́ nígbà náà ká sọ pé ìdè yẹn ni ìdè ìfẹ́ tó tíì pẹ́ jù lọ tó sì lágbára ju lọ ní gbogbo ayé àtọ̀run.
Bá a Ṣe Lè Mọyì Jésù Tó Jẹ́ Dáfídì Àti Sólómọ́nì Títóbi Jù
14 Ẹnì kan ṣoṣo la tíì rí rí tí ọgbọ́n rẹ̀ ju ti Sólómọ́nì lọ fíìfíì. Ẹni náà ni Jésù Kristi, tó sọ pé òun ni “ohun kan tí ó ju Sólómọ́nì lọ.” (Mát. 12:42) Jésù sọ “àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 6:68) Bí àpẹẹrẹ, nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù ṣàláyé síwájú sí i lórí ìlànà tó wà nínú àwọn kan lára òwe Sólómọ́nì. Sólómọ́nì ṣàlàyé ọ̀pọ̀ nǹkan tó lè mú káwọn olùjọsìn Jèhófà ní ayọ̀. (Òwe 3:13; 8:32, 33; 14:21; 16:20) Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn ohun tó lè mú kéèyàn ní ayọ̀ tòótọ́ ni àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Jèhófà àti ìmúṣẹ́ ìlérí rẹ̀. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, níwọ̀n bí ìjọba ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.” (Mát. 5:3) Àwọn tó bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú ẹ̀kọ́ Jésù yóò máa sún mọ́ Jèhófà tó jẹ́ “orísun ìye.” (Sm. 36:9; Òwe 22:11; Mát. 5:8) Kristi gan-an la lè pè ní “ọgbọ́n Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 1:24, 30) Gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà Ọba, Jésù Kristi ní “ẹ̀mí ọgbọ́n.”—Aísá. 11:2.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
‘Ọgbọ́n Ń ké Jáde’ Ṣé Ò Ń gbọ́ Ohun Tó Ń sọ?
▪ Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The World Book Encyclopedia sọ pé, Bíbélì ni “ìwé tí a pín kiri jù lọ láyé. Wọ́n ti túmọ̀ rẹ̀ níye ìgbà tí ó pọ̀ àti sí iye èdè tí ó pọ̀, ju ti ìwé èyíkéyìí mìíràn lọ.” Wọ́n ti túmọ̀ odindi Bíbélì tàbí apá kan rẹ̀ sí ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀tàlá [2,600] èdè, tó fi jẹ́ pé ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó èyí tó pọ̀ jù nínú gbogbo èèyàn tó wà láyé.
▪ Ọ̀nà míì tún wà tá a fi lè sọ pé “ọgbọ́n ń bá a nìṣó ní kíké jáde.” Mátíù 24:14 sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin [ayé yìí] yóò sì dé.”
APRIL 14-20
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 9
Jẹ́ Ọlọgbọ́n, Má Ṣe Jẹ́ Afiniṣẹ̀sín
“Fetí Sí Ọ̀rọ̀ Ọlọgbọ́n”
4 Ká sòótọ́, tí wọ́n bá fún wa nímọ̀ràn tó ṣe tààràtà, kì í rọrùn fún wa láti gbà á. Kódà, ó lè bí wa nínú. Kí nìdí? Ó máa ń rọrùn fún wa láti gbà pé aláìpé ni wá, àmọ́ kì í rọrùn láti gbà tẹ́nì kan bá sọ ibi tá a kù sí fún wa. (Ka Oníwàásù 7:9.) A lè má fẹ́ gbà pé òótọ́ lohun tẹ́ni náà sọ. A lè máa ronú pé kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀ tàbí ká bínú torí bó ṣe bá wa sọ̀rọ̀. Kódà, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàríwísí ẹni náà, ká wá máa sọ pé: ‘Ṣé irú ẹ̀ ló yẹ kó wá gbà mí nímọ̀ràn? Òun náà ṣá máa ń ṣàṣìṣe!’ Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, a lè má gba ìmọ̀ràn náà, ká sì fọ̀rọ̀ lọ ẹni tó máa sọ ohun táá bá wa lára mu.
“Fetí Sí Ọ̀rọ̀ Ọlọgbọ́n”
12 Kí ló máa jẹ́ ká gba ìbáwí? Ó yẹ ká nírẹ̀lẹ̀, ká sì máa rántí pé aláìpé ni wá àti pé a máa ń hùwà òmùgọ̀ nígbà míì. Bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, Jóòbù ní èrò tí kò tọ́. Àmọ́ nígbà tó yá, ó yí èrò ẹ̀ pa dà, Jèhófà sì bù kún un. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jóòbù nírẹ̀lẹ̀. Ó fi hàn pé òun nírẹ̀lẹ̀ nígbà tó gba ìbáwí tí Élíhù fún un, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Élíhù kéré sí i lọ́jọ́ orí. (Jóòbù 32:6, 7) Ìrẹ̀lẹ̀ tún máa jẹ́ ká ṣiṣẹ́ lórí ìbáwí tí wọ́n fún wa kódà tó bá ń ṣe wá bíi pé kò yẹ kí wọ́n fún wa nírú ìbáwí yẹn tàbí tí ẹni tó sọ fún wa bá kéré sí wa lọ́jọ́ orí. Alàgbà kan ní Kánádà sọ pé, “Kò sí bá a ṣe lè tẹ̀ síwájú táwọn míì ò bá gbà wá nímọ̀ràn torí pé àwọn ló máa ń rí ibi tá a kù sí.” Gbogbo wa ló yẹ ká ṣiṣẹ́ kára ká lè túbọ̀ ní èso tẹ̀mí, ká sì túbọ̀ já fáfá nínú iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni.—Ka Sáàmù 141:5.
13 Gbà pé torí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ ló ṣe ń bá ẹ wí. Ohun tó dáa jù ni Jèhófà fẹ́ fún wa. (Òwe 4:20-22) Ó máa ń bá wa wí nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì tàbí àwọn ará tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, ìyẹn ló sì ń fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Hébérù 12:9, 10 sọ pé: ‘Torí ire wa ló ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀.
14 Ohun tí wọ́n bá ẹ sọ ni kó o wò, má wo bí wọ́n ṣe sọ ọ́. Nígbà míì, tí wọ́n bá gbà wá nímọ̀ràn, ó lè máa ṣe wá bíi pé ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n gbà sọ ọ́ kọ́ nìyẹn. Ká sòótọ́, ó yẹ kẹ́ni tó fẹ́ gba èèyàn nímọ̀ràn sapá láti sọ ọ́ lọ́nà tó máa rọrùn fún ẹni náà láti gbà á. (Gál. 6:1) Tó bá jẹ́ àwa ni wọ́n gbà nímọ̀ràn, ohun tí wọ́n sọ fún wa ló yẹ ká wò, kódà tó bá ń ṣe wá bíi pé ọ̀nà tí wọ́n gbà sọ ọ́ yẹn ò dáa tó. Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Tí inú mi ò bá tiẹ̀ dùn sí ohun tẹ́ni náà sọ fún mi, ṣé òótọ́ ọ̀rọ̀ wà níbẹ̀? Ṣé mo lè gbójú fo àìpé ẹni tó fún mi nímọ̀ràn kí n lè jàǹfààní látinú ohun tó sọ?’ A máa fi hàn pé a gbọ́n tá a bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí wọ́n fún wa.—Òwe 15:31.
‘Nípasẹ̀ Ọgbọ́n Ni Ọjọ́ Wa Yóò Fi Di Púpọ̀’
Ojú tí ọlọgbọ́n èèyàn fi ń wo ìbáwí yàtọ̀ pátápátá sí ti olùyọṣùtì. Sólómọ́nì sọ pé: “Fún ọlọ́gbọ́n ní ìbáwí àfitọ́nisọ́nà, òun yóò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ. Fi fún ọlọ́gbọ́n, òun yóò sì túbọ̀ gbọ́n sí i.” (Òwe 9:8b, 9a) Ọlọgbọ́n èèyàn mọ̀ pé “kò sí ìbáwí tí ó dà bí ohun ìdùnnú nísinsìnyí, bí kò ṣe akó-ẹ̀dùn-ọkàn-báni; síbẹ̀ nígbà tí ó bá yá, fún àwọn tí a ti kọ́ nípasẹ̀ rẹ̀, a máa so èso ẹlẹ́mìí àlàáfíà, èyíinì ni, òdodo.” (Hébérù 12:11) Bí ìbáwí náà tiẹ̀ dà bí èyí tó dunni, èé ṣe tí a ó fi máa ṣàwáwí tàbí kí a máa wí àwíjàre bí gbígbà á yóò bá mú wa gbọ́n sí i?
Ọlọgbọ́n ọba náà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Fi ìmọ̀ fún olódodo, òun yóò sì pọ̀ sí i ní ẹ̀kọ́.” (Òwe 9:9b) Kò sẹ́ni tó ti gbọ́n kọjá ẹ̀kọ́ kíkọ́, kò sì sẹ́ni tó ti dàgbà jù ú lọ. Ẹ wò bínú wa ṣe máa ń dùn tó nígbà táa bá rí àwọn tó jẹ́ arúgbó pàápàá tí wọ́n ń tẹ́wọ́ gba òtítọ́, tí wọ́n sì ń ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà! Ǹjẹ́ kí àwa náà làkàkà láti máa nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ kíkọ́ kí èrò inú wa lè máa jí pépé.
‘Nípasẹ̀ Ọgbọ́n Ni Ọjọ́ Wa Yóò Fi Di Púpọ̀’
Ojúṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni láti sapá ká lè jèrè ọgbọ́n. Nígbà tí Sólómọ́nì ń tẹnu mọ́ kókó yìí, ó ní: “Bí o bá ti di ọlọ́gbọ́n, o ti di ọlọ́gbọ́n fún ire ara rẹ; bí o bá sì ti yọ ṣùtì, ìwọ ni yóò rù ú, ìwọ nìkan ṣoṣo.” (Òwe 9:12) Ẹni tí ó jẹ́ ọlọgbọ́n, gbọ́n fún àǹfààní ara rẹ̀, olùyọṣùtì sì ni yóò dá ni ẹ̀bi ìyà rẹ̀. Láìsí àní-àní, ohun tí a bá gbìn la óò ká. Nítorí ìdí èyí, ẹ jẹ́ ká ‘dẹ etí wa sí ọgbọ́n.’—Òwe 2:2.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Òwe
9:17—Kí ni ọ̀rọ̀ náà “omi tí a jí” túmọ̀ sí, kí sì nìdí tó fi ń “dùn”? Bíbélì fi ìgbádùn ìbálòpọ̀ láàárín tọkọtaya wé bí ìgbà téèyàn ń mu omi kànga tó tuni lára. Nítorí náà, omi tí a jí yìí dúró fún ṣíṣe ìṣekúṣe níkọ̀kọ̀. (Òwe 5:15-17) Bí onítọ̀hún ṣe rí ìṣekúṣe yẹn ṣe ní bòókẹ́lẹ́ tó sì dà bíi pé àṣírí rẹ̀ ò tú ló jẹ́ kó dà bíi pé ó dùn.
APRIL 21-27
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 10
Kí Ló Ń Jẹ́ Kéèyàn Ní Ọrọ̀ Tòótọ́?
‘Ìbùkún Wà Fún Olódodo’
A tún ń bù kún olódodo lọ́nà mìíràn. “Ẹni tí ń fi ọwọ́ dẹngbẹrẹ ṣiṣẹ́ yóò jẹ́ aláìnílọ́wọ́, ṣùgbọ́n ọwọ́ ẹni aláápọn ni yóò sọni di ọlọ́rọ̀. Ọmọ tí ń fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà ń kó jọ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn; ọmọ tí ń hùwà lọ́nà tí ń tini lójú sùn lọ fọnfọn nígbà ìkórè.”—Òwe 10:4, 5.
Ọ̀rọ̀ tí ọba sọ yìí nítumọ̀ gan-an fáwọn òṣìṣẹ́, àgàgà nígbà ìkórè. Ìgbà ìkórè kì í ṣe ìgbà ṣíṣe ìmẹ́lẹ́. Ìgbà iṣẹ́ àṣekára, iṣẹ́ àṣeṣúlẹ̀ ni. Àní sẹ́, àkókò kánjúkánjú ni.
Kì í ṣe kíkórè ọkà, bí kò ṣe kíkórè àwọn èèyàn ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè [Jèhófà Ọlọ́run] láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Mátíù 9:35-38) Lọ́dún 2000, àwọn tó wá sí Ìṣe Ìrántí ikú Jésù lé ní mílíọ̀nù mẹ́rìnlá—wọ́n pọ̀ ju ìlọ́po méjì iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ta ló wá lè jiyàn pé ‘àwọn pápá kò tíì funfun fún ìkórè’? (Jòhánù 4:35) Àwọn olùjọsìn tòótọ́ ń bẹ Ọ̀gá ìkórè fún òṣìṣẹ́ púpọ̀ sí i, ṣùgbọ́n láàárín àkókò kan náà, wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn níbàámu pẹ̀lú àdúrà wọn. (Mátíù 28:19, 20) Ẹ sì wo bí Jèhófà ti bù kún ìsapá wọn tó! Ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2000, àwọn ẹni tuntun táa batisí lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá [280,000]. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ń làkàkà láti di olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ kí a ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn ní sáà ìkórè yìí nípa jíjẹ́ kí ọwọ́ wa dí nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn.
Máa Rìn Ní ‘Ipa Ọ̀nà Ìdúróṣánṣán’
Sólómọ́nì tọ́ka sí ìjẹ́pàtàkì òdodo. Ó sọ pé: “Àwọn nǹkan tí ó níye lórí tí ó jẹ́ ti ọlọ́rọ̀ ni ìlú lílágbára rẹ̀. Ìparun àwọn ẹni rírẹlẹ̀ ni ipò òṣì wọn. Ìgbòkègbodò olódodo ń yọrí sí ìyè; èso ẹni burúkú ń yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀.”—Òwe 10:15, 16.
Ọrọ̀ lè jẹ́ ààbò nígbà táa bá dojú kọ àwọn ohun àìdánilójú inú ìgbésí ayé, gẹ́gẹ́ bí ìlú olódi kan ṣe lè jẹ́ ààbò fún àwọn tó ń gbé inú rẹ̀. Ipò òṣì sì lè ba nǹkan jẹ́ pátápátá nígbà táwọn nǹkan tí a kò retí bá yọjú. (Oníwàásù 7:12) Àmọ́, ó lè jẹ́ ewu tó wà nínú ọrọ̀ àti ipò òṣì ni ọlọgbọ́n ọba náà tún ń sọ̀rọ̀ lé lórí. Ọlọ́rọ̀ lè gbé gbogbo ọkàn rẹ̀ lé ọrọ̀ tó ní, kó máa lérò pé àwọn ohun iyebíye òun “dà bí ògiri adáàbòboni.” (Òwe 18:11) Tálákà sì lè fàṣìṣe ronú pé ipò òṣì tóun wà kò lè jẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la òun nítumọ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn méjèèjì á wá kùnà láti ní orúkọ rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
it-1 340
Ìbùkún
Jèhófà Máa Ń Bù Kún Àwa Èèyàn Rẹ̀. “Ìbùkún Jèhófà ló ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.” (Owe 10:22) Jèhófà máa ń bù kún àwọn tó bá rí ojú rere rẹ̀, ní ti pé, ó máa ń dáàbò bò wọ́n, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n tẹ̀ síwájú, ó máa ń tọ́ wọn sọ́nà, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n ṣàṣeyọrí, ó tún máa ń pèsè àwọn nǹkan tí wọ́n nílò, ìyẹn sì máa ń ṣe wọ́n láǹfààní.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Ayọ̀ Tó Wà Nínú Rírìn Nínú Ìwà Títọ́
18 “Ìbùkún Jèhófà” ló mú káwọn èèyàn rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí. Ọlọ́run sì ti ṣèlérí fún wa pé òun ò ní “fi ìrora kún un.” (Òwe 10:22) Kí wá nìdí tí ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin fi ń rí àdánwò àti ìṣòro tó ń mú kí wọ́n wà nínú ìrora àti ìpọ́njú púpọ̀? Ohun mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ń mú kí àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa rí ìṣòro àti ìpọ́njú. Ìkínní, ọkàn èèyàn tó máa ń fà sí ẹ̀ṣẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 6:5; 8:21; Jákọ́bù 1:14, 15) Ìkejì, Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀. (Éfésù 6:11, 12) Ìkẹta, ayé búburú tá a wà yìí. (Jòhánù 15:19) Bí Jèhófà tiẹ̀ fàyè gba ohun búburú láti ṣẹlẹ̀ sí wa, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé òun ló fà á. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé jẹ́ láti òkè, nítorí a máa sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá.” (Jákọ́bù 1:17) Kò sí ìrora kankan nínú ìbùkún Jèhófà.
APRIL 28–MAY 4
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 11
Má Ṣe Sọ Ọ̀rọ̀ Tí Kò Yẹ!
Ìwà Títọ́ Ń ṣamọ̀nà Àwọn Adúróṣánṣán
Ìwà títọ́ àwọn adúróṣánṣán àti ìwà ibi àwọn aṣebi tún máa ń nípa lórí àwọn ẹlòmíràn. Ọba Ísírẹ́lì náà sọ pé: “Ẹnu ara rẹ̀ ni apẹ̀yìndà fi ń run ọmọnìkejì rẹ̀, ṣùgbọ́n ìmọ̀ ni a fi ń gba olódodo sílẹ̀.” (Òwe 11:9) Ta ló lè sẹ́ pé ìbanilórúkọjẹ́, òfófó, ọ̀rọ̀ rírùn, àti ẹjọ́ wẹ́wẹ́ kì í pa àwọn ẹlòmíràn lára? Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, ńṣe ni ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo máa ń mọ́ gaara, tó máa ń jẹ́ èyí tó ronú sí dáadáa kó tó sọ, tó sì máa ń gba ti àwọn ẹlòmíràn rò. Ìmọ̀ ni a fi ń gbà á sílẹ̀ nítorí pé ìwà títọ́ rẹ̀ á jẹ́ kó ní ẹ̀rí púpọ̀ láti fi hàn pé irọ́ ni àwọn tó ń fẹ̀sùn kàn án ń pa.
Ìwà Títọ́ Ń ṣamọ̀nà Àwọn Adúróṣánṣán
Àwọn aráàlú tó tẹ̀ lé ipa ọ̀nà ìdúróṣánṣán máa ń fi kún àlàáfíà àti ìlera, wọ́n sì máa ń gbé àwọn ẹlòmíràn ró láwùjọ. Nípa bẹ́ẹ̀, ìlú á ní ìgbéga—ìyẹn ni pé á láásìkí. Àwọn tó máa ń sọ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́, tí wọ́n máa ń sọ ọ̀rọ̀ tí ń pani lára, tí wọ́n sì máa ń fi dúdú pe funfun máa ń fa àìbalẹ̀ ọkàn, àìláyọ̀, ìyapa àti wàhálà. Èyí máa ń rí bẹ́ẹ̀, àgàgà bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá lọ wà nípò àṣẹ. Irú ìlú bẹ́ẹ̀ máa ń di rúdurùdu, ó máa ń kún fún ìwà ìbàjẹ́, ìwà rere àti ọrọ̀ ajé rẹ̀ sì máa ń jó àjórẹ̀yìn.
Ìlànà tó wà nínú Òwe 11:11 kan àwọn ènìyàn Jèhófà gan-an, bí wọ́n ti ń bá ara wọn kẹ́gbẹ́ pọ̀ láwọn ìjọ wọn tó dà bí ìlú. Ìjọ tí àwọn ẹni tẹ̀mí—ìyẹn àwọn adúróṣánṣán tí ìwà títọ́ ń darí—bá pọ̀ sí máa ń jẹ́ àwùjọ àwọn aláyọ̀, tí wọ́n jẹ́ aláápọn, tí wọ́n ń ran ara wọn lọ́wọ́, tí wọ́n sì ń bọlá fún Ọlọ́run. Jèhófà máa ń bù kún ìjọ náà, ó sì máa ń láásìkí nípa tẹ̀mí. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn díẹ̀ tí wọ́n jẹ́ aláìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn, tí wọ́n máa ń ṣe lámèyítọ́, tí wọ́n sì máa ń fi ìkorò ọkàn sọ̀rọ̀ nípa bí nǹkan ṣe ń lọ, dà bí “gbòǹgbò onímájèlé” tó lè tàn kálẹ̀, kí ó sì ṣèpalára fáwọn ẹlòmíràn tí kò mọ́wọ́ mẹsẹ̀ tẹ́lẹ̀. (Hébérù 12:15) Irú àwọn bẹ́ẹ̀ sábà máa ń wá ipò ọlá àti òkìkí. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń tan àhesọ kálẹ̀ pé ìwà ìrẹ́nijẹ, ìwà ẹlẹ́yàmẹ̀yà, tàbí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ tàbí látọ̀dọ̀ àwọn alàgbà. Láìsí àní-àní, ẹnu wọn lè fa ìyapa nínú ìjọ. Ǹjẹ́ kò yẹ ká di etí wa sí ọ̀rọ̀ wọn, ká sì gbìyànjú láti jẹ́ ẹni tẹ̀mí tó ń fi kún àlàáfíà àti ìṣọ̀kan ìjọ?
Ìwà Títọ́ Ń ṣamọ̀nà Àwọn Adúróṣánṣán
Ẹ ò rí i pé wàhálà ńlá ni ẹni tí kò ní òye, tàbí ẹni tí “ọkàn-àyà kù fún” ń dá sílẹ̀! Ó tiẹ̀ lè bá bórobòro rẹ̀ dórí fífọ̀rọ̀ èké bani jẹ́ tàbí kíkẹ́gàn. Àwọn alàgbà tí a yàn sípò gbọ́dọ̀ tètè fi òpin sí irú ipa búburú bẹ́ẹ̀. Láìdàbí “ẹni tí ọkàn-àyà kù fún,” ẹni tó ní òye mọ ìgbà tó yẹ kí òun dákẹ́. Dípò kí ó tú ọ̀rọ̀ àṣírí síta, á kúkú yàn láti panu mọ́. Ẹni tó ní ìfòyemọ̀ jẹ́ “olùṣòtítọ́ ní ẹ̀mí,” nítorí ó mọ̀ pé ahọ́n tí a kò bá kó níjàánu lè fa ọ̀pọ̀ jàǹbá. Ó jẹ́ adúróṣinṣin sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, kì í sọ ọ̀rọ̀ àṣírí tó lè pa wọ́n lára síta. Ẹ ò rí i pé ìbùkún ńlá ni irú àwọn olùpa ìwà títọ́ mọ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ fún ìjọ!
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
g20.1 11, àpótí
Bó O Ṣe Lè Kojú Àìbalẹ̀ Ọkàn
“FI INÚURE ṢẸ́GUN ÀÌBALẸ̀ ỌKÀN”
“Ẹni tó ń ṣoore ń ṣe ara rẹ̀ láǹfààní, àmọ́ ìkà èèyàn ń fa wàhálà bá ara rẹ̀.”—ÒWE 11:17.
Ìwé kan tó ń jẹ́ Overcoming Stress ní àkòrí kan tó ní kéèyàn fi inúure ṣẹ́gun àìbalẹ̀ ọkàn. Dókítà Tim Cantopher tó ṣe ìwé náà sọ pé tó o bá ń ṣoore fáwọn èèyàn, ìlera rẹ á máa dára sí i, wàá sì máa láyọ̀. Àmọ́, ẹni tí kò láàánú tàbí ẹni tó burú kì í láyọ̀ torí ńṣe làwọn èèyàn á máa sá fún un.
Tá ò bá lo ara wa nílòkulò, ara máa tù wá. Bí àpẹẹrẹ, a ò ní máa ṣe ohun tí agbára wa ò gbé tàbí ká ní àfojúsùn tí ọwọ́ wa kò lè tẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni a ò ní máa rò pé a ò já mọ́ nǹkan kan. Jésù Kristi sọ pé: “Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.”—Máàkù 12:31.