Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
© 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
MAY 5-11
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 12
Tó O Bá Ṣiṣẹ́ Kára, Wàá Jèrè
Ìwà Rere Tó Ṣeyebíye Ju Dáyámọ́ǹdì Lọ
Nǹkan lè má fi bẹ́ẹ̀ ṣẹnuure fáwọn kan lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà, kí awọ má sì kájú ìlù. Dípò tí wọ́n á fi dọ́gbọ́n sọ́rọ̀ ara wọn, ṣe ni wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ kára. Wọ́n gbà pé ó yẹ káwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa hùwà rere ká sì jẹ́ olóòótọ́, dípò ká máa wá àǹfààní táwọn nǹkan tara lè fúnni.—Òwe 12:24; Éfé. 4:28.
Bí O Ṣe Lè Gbádùn Iṣẹ́ Àṣekára
Bá a bá rí àǹfààní tí iṣẹ́ wa ń ṣe fún àwọn èèyàn, ó máa mú kí iṣẹ́ túbọ̀ yá wa lára, kí inú wa sì dùn. Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Kì í ṣe àwọn oníbàárà wa àti àwọn tó gbà wá sí iṣẹ́ nìkan ni iṣẹ́ wa ń ṣe láǹfààní, ó tún ń ṣe ìdílé wa àtàwọn aláìní láǹfààní.
Ìdílé wa. Ọ̀nà méjì ni baálé ilé kan tó bá ń ṣiṣẹ́ kára ń gbà ṣe ìdílé rẹ̀ láǹfààní. Àkọ́kọ́ ni pé, á lè pèsè ohun tí ìdílé rẹ̀ nílò bí oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé. Ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ṣe iṣẹ́ pàtàkì tí Ọlọ́run gbé fún un, ìyẹn láti “pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀.” (1 Tímótì 5:8) Ọ̀nà kejì ni pé, baálé ilé tó bá ń ṣiṣẹ́ kára ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀. Shane tá a mẹ́nu bà ní àpilẹ̀kọ tó ṣáájú sọ pé: “Iṣẹ́ káfíńtà ni bàbá mi ń ṣe, ó sì máa ń fòótọ́ inú ṣiṣẹ́. Kò kẹ̀rẹ̀ tó bá kan ọ̀rọ̀ pé ká jára mọ́ṣẹ́, òun ló jẹ́ kí n mọ̀ pé ó dáa kéèyàn máa ṣiṣẹ́ ọwọ́, kó sì máa ṣe àwọn nǹkan tó máa wúlò fún àwọn èèyàn.”
Àwọn aláìní. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá nímọ̀ràn pé “kí [a] máa ṣe iṣẹ́ àṣekára . . . kí [a] lè ní nǹkan láti pín fún ẹni tí ó wà nínú àìní.” (Éfésù 4:28) Tí a bá ń ṣiṣẹ́ kára láti pèsè fún ìdílé wa, ó ṣeé ṣe ká ní àjẹṣẹ́kù tá a lè fi ran àwọn tí kò rí jájẹ lọ́wọ́. (Òwe 3:27) Torí náà, bá a bá ṣiṣẹ́ kára, àwa náà máa rí ayọ̀ tó wà nínú fífúnni.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Báwo Ni Mo Ṣe Ní Ìforítì Tó?
● Mọ bí ìṣòro rẹ ṣe le tó. Mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìṣòro ńlá àti ìṣòro tí kò tó nǹkan. Bíbélì sọ pé: “Òmùgọ̀ máa ń fi ìbínú rẹ̀ hàn lójú ẹsẹ̀, àmọ́ aláròjinlẹ̀ máa ń gbójú fo àbùkú tí wọ́n fi kàn án.” (Òwe 12:16) Kò pọn dandan kí gbogbo ìṣòro máa mu ẹ́ lómi.
“Níléèwé, àwọn ọmọ kíláàsì mi máa ń fẹ ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan lójú bíi pé nǹkan bàbàrà ni. Lẹ́yìn náà, tí wọ́n bá bá àwọn ọ̀rẹ́ wọn sọ̀rọ̀ lórí ìkànnì àjọlò, àwọn yẹn á tún tanná ran ọ̀rọ̀ náà bíi pé ó jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìyẹn ò wá ní lè jẹ́ kí wọ́n rí i pé ọ̀rọ̀ náà ò le tó bí wọ́n ṣe rò.”—Joanne.
MAY 12-18
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 13
Má Ṣe Jẹ́ Kí “Fìtílà Àwọn Ẹni Burúkú” Tàn Ẹ́ Jẹ
it-2 196 ¶2-3
Fìtílà
Àwọn nǹkan míì tá a fi wé. Bíbélì fi fìtílà wé ohun tí ẹnì kan ń lò láti mọ ohun tó yẹ kó ṣe. Bí ìwé Òwe ṣe fi ohun tá a fi ń ríran nínú òkùnkùn wé fìtílà jẹ́ ká rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín olódodo àti ẹni burúkú nígbà tó sọ pé: “Ìmọ́lẹ̀ àwọn olódodo mọ́lẹ̀ rekete, àmọ́ fìtílà àwọn ẹni burúkú ni a ó pa.” (Owe 13:9) Ìmọ́lẹ̀ àwọn olódodo máa ń mọ́lẹ̀ sí i bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àmọ́ bí fìtílà àwọn ẹni burúkú bá tiẹ̀ dà bíi pé ó ń mọ́lẹ̀, tó sì jọ pé nǹkan ń lọ dáadáa fún wọn, bópẹ́ bóyá Ọlọ́run máa pa fìtílà wọn, wọ́n á sì kọsẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ló máa rí fún ẹni tó bá ń bú ìyá àti bàbá ẹ̀.—Owe 20:20.
Yàtọ̀ síyẹn, tí ‘fìtílà ẹnì kan bá kú,’ á jẹ́ pé ọjọ́ ọ̀la ẹni náà kò lè dáa. Òwe míì sọ pé: “Ọjọ́ ọ̀la ẹni ibi kò lè dáa; fìtílà àwọn ẹni burúkú ni a ó pa.”—Owe 24:20.
Máa Sin Ọlọ́run Tí Ń sọni Di Òmìnira
3 Bí Sátánì bá lè tan ẹ̀dá èèyàn pípé méjì jẹ, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tí ọ̀pọ̀ àwọn áńgẹ́lì, débi tí gbogbo wọn fi kọ Ọlọ́run sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run, ó lè tan àwa pẹ̀lú jẹ. Ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí tó ń lò kò tíì yí pa dà. Ó ń gbìyànjú láti tàn wá jẹ ká lè máa ronú pé àwọn ìlànà Ọlọ́run jẹ́ ẹrù ìnira, wọn kì í sì í jẹ́ ká gbádùn ara wa tàbí ká dára yá. (1 Jòh. 5:3) Irú èrò yìí lè ní ipa tó lágbára gan-an lórí ẹni pàápàá tó bá jẹ́ pé lemọ́lemọ́ lèèyàn ń gbà á láyè. Arábìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún [24], tó sì ti ṣèṣekúṣe rí sọ pé: “Ẹgbẹ́ búburú ní ipa tó pọ̀ lórí mi, pàápàá jù lọ nítorí pé mò ń bẹ̀rù pé kí èrò mi má yàtọ̀ sí ti àwọn ojúgbà mi.” Ó lè ti ṣe ìwọ náà rí pé kó o dà bíi tàwọn ojúgbà rẹ.
“Gbogbo Ẹni Tí Ó Jẹ́ Afọgbọ́nhùwà Yóò Fi Ìmọ̀ Hùwà”
Ọlọgbọ́n àti adúróṣinṣin èèyàn tó jẹ́ pé ìfẹ́ tòótọ́ ló ń sún un láti ṣe àwọn nǹkan yóò rí ìbùkún gbà. Sólómọ́nì mú un dá wa lójú pé: “Olódodo ń jẹ títí yóò fi tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn, ṣùgbọ́n ikùn àwọn ẹni burúkú yóò ṣófo.” (Òwe 13:25) Jèhófà mọ ohun tó yẹ wá ní apá èyíkéyìí nínú ìgbésí ayé wa, ì báà jẹ́ nínú ọ̀ràn ìdílé, nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, tàbí nígbà tí wọ́n bá ń bá wa wí. Bá a bá sì ń fi àwọn ìmọ̀ràn inú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílò, ó dájú hán-ún hán-ún pé a óò gbádùn ìgbésí ayé tó dára jù lọ.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-2 276 ¶2
Ìfẹ́
A lè fìfẹ́ hàn lọ́nà tí kò tọ́. Èyí fi hàn pé tẹ́nì kan bá máa fìfẹ́ hàn lọ́nà tó tọ́ tó sì yẹ, àfi kó jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí òun, kó sì tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí máa ń nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn. Àmọ́, òbí kan lè nífẹ̀ẹ́ ọmọ ẹ̀ lọ́nà tí kò tọ́ tí ìfẹ́ tó ní fún ọmọ náà bá ru bò ó lójú, débi pé gbogbo nǹkan tí ọmọ náà bá fẹ́ ló máa ń fún un. Irú òbí bẹ́ẹ̀ lè máa gbọ̀jẹ̀gẹ́, ó lè má lo àṣẹ tó ní láti bá ọmọ náà wí. (Owe 22:15) Lọ́pọ̀ ìgbà, ìgbéraga ló máa ń jẹ́ káwọn òbí kan fi irú ìfẹ́ tí kò tọ́ yìí hàn sí ọmọ wọn, ìyẹn sì fi hàn pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀. Bíbélì sọ pé irú òbí bẹ́ẹ̀ ò nífẹ̀ẹ́ ọmọ ẹ̀, ṣe ló kórìíra ẹ̀ torí òbí náà ò ṣe ohun tó máa gba ọmọ ẹ̀ lọ́wọ́ ikú.—Owe 13:24; 23:13, 14.
MAY 19-25
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 14
Ronú Jinlẹ̀ Kó O Tó Gbé Ìgbésẹ̀ Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀
Bó O Ṣe Lè Mọyì Ìwàláàyè Tí Ọlọ́run Fún Ẹ
10 Nígbà míì, táwọn àjálù kan bá fẹ́ ṣẹlẹ̀, a ò lè dènà wọn. Ó ṣeé ṣe kí ìmìtìtì ilẹ̀ tàbí omíyalé ṣẹlẹ̀, ó sì lè jẹ́ àjàkálẹ̀ àrùn tàbí káwọn èèyàn máa bára wọn jà ládùúgbò. Àmọ́ táwọn àjálù yìí bá ṣẹlẹ̀, àwọn nǹkan kan wà tá a lè ṣe ká lè là á já. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ ká ṣègbọràn tí ìjọba bá sọ pé ká má jáde nílé láwọn àkókò kan, tí wọ́n bá ní ká tètè kúrò lágbègbè kan tàbí ká má dé agbègbè kan. (Róòmù 13:1, 5-7) A lè múra sílẹ̀ de àwọn àjálù kan, torí náà ó yẹ ká tẹ̀ lé ohun táwọn aláṣẹ bá sọ fún wa kí àjálù náà tó dé. Bí àpẹẹrẹ, a lè tọ́jú omi, oúnjẹ tí ò lè tètè bà jẹ́ àtàwọn oògùn tá a lè lò sínú báàgì kan.
11 Kí ló yẹ ká ṣe tí àjàkálẹ̀ àrùn bá ń jà níbi tá à ń gbé? Ó yẹ ká máa ṣègbọràn sáwọn aláṣẹ tí wọ́n bá ní ká máa fọwọ́ wa, tí wọ́n bá ní ká máa jìnnà síra wa dáadáa, tí wọ́n bá ní ká máa wọ ìbòmú tàbí tí wọ́n bá ní ká sé ara wa mọ́lé nítorí àrùn náà. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ìyẹn á fi hàn pé a mọyì ìwàláàyè tí Ọlọ́run fún wa.
12 Nígbà míì tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ wa, àwọn aládùúgbò wa àtàwọn oníròyìn lè sọ ohun tí kì í ṣòótọ́ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀. Dípò kó jẹ́ pé “gbogbo ọ̀rọ̀” tá a bá gbọ́ la máa gbà gbọ́, ohun tí ìjọba àtàwọn dókítà bá sọ ló yẹ ká gbà gbọ́. (Ka Òwe 14:15.) Ìgbìmọ̀ Olùdarí àtàwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì máa ń rí i dájú pé àwọn mọ òótọ́ nípa ọ̀rọ̀ kan kí wọ́n tó sọ bá a ṣe máa ṣe ìpàdé àti bá a ṣe máa wàásù. (Héb. 13:17) Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n ń sọ fún wa, a ò ní kó ara wa àtàwọn míì síṣòro. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ará àdúgbò máa rí i pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tẹ̀ lé òfin ìjọba.—1 Pét. 2:12.
Ní Ìgboyà Bíi Sádókù
11 Táwọn ará wa bá níṣòro tó sì gba pé ká ràn wọ́n lọ́wọ́, báwo la ṣe lè jẹ́ onígboyà bíi Sádókù? (1) Máa ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run sọ. Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ onígbọràn, ká lè wà níṣọ̀kan. Máa ṣe ohun tí ẹ̀ka ọ́fíìsì sọ. (Héb. 13:17) Látìgbàdégbà, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ máa ṣàyẹ̀wò ètò tí wọ́n ṣe láti múra sílẹ̀ de àjálù, kí wọ́n sì máa ṣàyẹ̀wò ìtọ́sọ́nà ètò Ọlọ́run nípa ohun tí wọ́n máa ṣe tí àjálù bá ṣẹlẹ̀. (1 Kọ́r. 14:33, 40) (2) Jẹ́ onígboyà, àmọ́ máa ṣọ́ra. (Òwe 22:3) Ronú dáadáa kó o tó ṣe ohunkóhun. Má ṣe ohun tó máa kó ẹ sínú ewu. (3) Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Rántí pé Jèhófà ò fẹ́ kí ohunkóhun ṣe ìwọ àtàwọn ará. Torí náà, Jèhófà máa dáàbò bò ẹ́ kó o lè ran àwọn ará lọ́wọ́.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-2 1094
Àròjinlẹ̀
Àmọ́, ó tún ṣeé ṣe káwọn èèyàn kórìíra ẹni tó láròjinlẹ̀. Ó sì lè jẹ́ pé ohun tí Òwe 14:17 ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nìyẹn nígbà tó sọ pé: “Ẹni tó bá ń ro ọ̀rọ̀ wò ni aráyé ń kórìíra.” Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tí kì í ronú jinlẹ̀ máa ń fojú burúkú wo àwọn tó máa ń ronú jinlẹ̀ tó sì ní làákàyè. Bákan náà, àwọn èèyàn máa ń kórìíra àwọn tó máa ń ro ọ̀rọ̀ wò dáadáa, tí wọ́n sì ń sapá láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Jésù Kristi tiẹ̀ sọ pé: “Ẹ kì í ṣe apá kan ayé, àmọ́ mo ti yàn yín látinú ayé, torí èyí ni ayé ṣe kórìíra yín.” (Jo 15:19) Ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tá a tú sí “ro ọ̀rọ̀ wò” tó wà ní Òwe 14:17 tún lè máa sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan tó máa ń fara balẹ̀ ronú nípa bóun ṣe máa ṣeni níkà. Torí náà, ẹsẹ Bíbélì yẹn tún lè túmọ̀ sí pé àwọn èèyàn máa ń kórìíra ẹni tó máa ń gbèrò ibi, ohun táwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan sì sọ nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, ìtumọ̀ Bíbélì kan sọ pé: “A sì kórìíra eléte ènìyàn.”—Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.
MAY 26–JUNE 1
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 15
Máa Múnú Àwọn Míì Dùn
Àwa Yóò Máa Rìn Nínú Ìwà Títọ́ wa!
16 Jóòbù ní ẹ̀mí aájò àlejò. (Jóòbù 31:31, 32) Lóòótọ́, a lè máà jẹ́ ọlọ́rọ̀, síbẹ̀ a lè “máa tẹ̀ lé ipa ọ̀nà aájò àlejò.” (Róòmù 12:13) A lè ṣàjọpín ìpápánu pẹ̀lú àwọn èèyàn, ká máa rántí pé “oúnjẹ tí a fi ọ̀gbìn oko sè, níbi tí ìfẹ́ wà, sàn ju akọ màlúù tí a bọ́ yó ní ibùjẹ ẹran tòun ti ìkórìíra.” (Òwe 15:17) Jíjẹ oúnjẹ pẹ̀lú àwọn tá a jọ ń pa ìwà títọ́ mọ́ níbi tí ìfẹ́ wà máa mú kí ìpápánu lásán gbádùn mọ́ni, ó sì dájú pé ó máa ṣe wá láǹfààní nípa tẹ̀mí.
Ìsinsìnyí Ló Yẹ Ká Máa Fún Ara Wa Níṣìírí Ju ti Ìgbàkigbà Rí Lọ
16 Kò yẹ ká máa ronú pé a ò lè fún àwọn míì níṣìírí bóyá torí pé a ò mọ ohun tá a máa sọ. Ká sòótọ́, kò dìgbà tá a bá sọ̀rọ̀ rẹpẹtẹ ká tó lè fúnni ní ìṣírí, kódà a lè má ṣe ju pé ká rẹ́rìn-ín músẹ́ sí ẹnì kan. Tá a bá rẹ́rìn-ín sẹ́nì kan àmọ́ tí kò rẹ́rìn-ín pa dà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nǹkan kan ń jẹ ẹni náà lọ́kàn. Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, tá a bá fara balẹ̀ tẹ́tí sí i, ìyẹn á jẹ́ kí ara tù ú.—Ják. 1:19.
17 Ìbànújẹ́ dorí ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Henri kodò nígbà tí àwọn kan nínú ẹbí rẹ̀ fi òtítọ́ sílẹ̀, títí kan bàbá ẹ̀ tó jẹ́ alàgbà. Alábòójútó àyíká kan kíyè sí i pé inú Henri ò dùn rárá, torí náà ó gbé Henri jáde, ó sì ra kọfí fún un, lẹ́yìn náà ó jẹ́ kí ọ̀dọ́kùnrin yẹn sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀, ó sì tẹ́tí sí i. Henri wá rí i pé tóun bá máa ran àwọn ẹbí òun tó fi òtítọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́, àfi kóun jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, ara tù ú gan-an lẹ́yìn tó ka Sáàmù 46; Sefanáyà 3:17; àti Máàkù 10:29, 30.
18 Àpẹẹrẹ Marthe àti Henri jẹ́ ká rí i pé gbogbo wa la lè fún àwọn ará wa tó nílò ìtùnú ní ìṣírí. Ọba Sólómọ́nì sọ pé: ‘Ọ̀rọ̀ tí ó bọ́ sí àkókò mà dára o! Ìtànyòò ojú tàbí ọ̀yàyà a máa mú kí ọkàn-àyà yọ̀; ìròyìn tí ó dára a máa mú àwọn egungun sanra.’ (Òwe 15:23, 30) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́ àtèyí tó wà lórí ìkànnì wa lè ran ẹni tó bá ní ẹ̀dùn ọkàn lọ́wọ́. Bákan náà, Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé kíkọ orin Ìjọba Ọlọ́run pa pọ̀ máa ń fúnni ní ìṣírí. Ó sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní kíkọ́ ara yín àti ní ṣíṣí ara yín létí lẹ́nì kìíní-kejì pẹ̀lú àwọn sáàmù, àwọn ìyìn sí Ọlọ́run, àwọn orin tẹ̀mí pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, kí ẹ máa kọrin nínú ọkàn-àyà yín sí Jèhófà.”—Kól. 3:16; Ìṣe 16:25.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Ṣé Ó Yẹ Kí Kristẹni Gba Ìtọ́jú Lọ́dọ̀ Àwọn Dókítà?
2. Ṣé ó yẹ kí n wádìí lọ́dọ̀ dókítà méjì tàbí mẹ́ta nípa ìtọ́jú yìí? Tí àìsàn tó ń ṣe ọ́ bá le gan-an, ó máa dáa kó o ní “ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn.”—Òwe 15:22.
JUNE 2-8
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 16
Ìbéèrè Mẹ́ta Táá Jẹ́ Ká Lè Ṣèpinnu Tó Dáa
Bó O Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tó Bọ́gbọ́n Mu Nígbà Ọ̀dọ́
11 Ohun tó lè mú kéèyàn láyọ̀ jù lọ ni pé kó máa ṣiṣẹ́ sin Jèhófà. (Òwe 16:20) Ó jọ pé Bárúkù tó jẹ́ akọ̀wé Jeremáyà gbàgbé pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Láwọn àkókò kan, kò fi bẹ́ẹ̀ gbádùn iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Jèhófà mọ́. Jèhófà wá sọ fún un pé: “Ìwọ ń wá àwọn ohun ńláńlá fún ara rẹ. Má ṣe wá wọn mọ́. Nítorí kíyè sí i, èmi yóò mú ìyọnu àjálù wá sórí gbogbo ẹran ara, . . . èmi yóò sì fi ọkàn rẹ fún ọ bí ohun ìfiṣèjẹ ní gbogbo ibi tí ìwọ bá lọ.” (Jer. 45:3, 5) Kí lèrò rẹ? Kí ni ì bá ti mú kí Bárúkù láyọ̀? Ṣé wíwá àwọn nǹkan ńláńlá ni àbí líla ìparun Jerúsálẹ́mù já gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run?—Ják. 1:12.
12 Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Ramiro rí ayọ̀ nínú kéèyàn máa ṣiṣẹ́ sin àwọn ẹlòmíì. Ó sọ pé: “Tálákà làwọn òbí mi, abúlé kan tó wà nítòsí àwọn Òkè Andes là ń gbé. Torí náà, àǹfààní ńlá ló jẹ́ nígbà tí bùrọ̀dá mi sọ pé òun máa rán mi lọ sí yunifásítì. Àmọ́, mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn ni àti pé aṣáájú-ọ̀nà kan sọ pé kí n wá bá òun ká jọ máa wàásù ní ìlú kékeré kan. Mo lọ síbẹ̀, mo kọ́ṣẹ́ irun gígẹ̀, mo ṣí ṣọ́ọ̀bù bábà, owó tí mò ń rí níbẹ̀ ni mo sì fi ń gbọ́ bùkátà ara mi. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tá a fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ni wọ́n mọrírì rẹ̀ tí wọ́n sì ní ká wá máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tó yá, mo dara pọ̀ mọ́ ìjọ kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀, tí wọ́n ti ń sọ èdè ìbílẹ̀. Ọdún kẹwàá rèé tí mo ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Kò sí iṣẹ́ míì tó lè fún mi nírú ayọ̀ ti mò ń rí bí mo ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní èdè ìbílẹ̀ wọn.”
Ǹjẹ́ Ẹ Ti Para Dà?
KÒ SẸ́NÌ kan nínú wa tó lè sọ pé bí wọ́n ṣe tọ́ òun dàgbà àti ibi tí òun gbé dàgbà kò nípa lórí òun. Ó ní bá a ṣe ń múra, ó nírú oúnjẹ tá a fẹ́ràn, ó sì ní bá a ṣe ń hùwà. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Àárín àwọn tá à ń gbé àtàwọn ipò tó yí wa ká wà lára ohun tó fà á.
2 Àmọ́, àwọn nǹkan kan wà tó ṣe pàtàkì ju irú oúnjẹ tá a yàn láàyò àti irú aṣọ tá à ń wọ̀. Bí àpẹẹrẹ, láti kékeré ni wọ́n ti kọ́ wa láwọn ohun tó dára tá a lè ṣe àtàwọn ohun tí kò dára tó yẹ ká sá fún. Ọ̀pọ̀ nínú irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ló jẹ́ ọ̀rọ̀ ara ẹni, ọwọ́ tí kálukú sì fi mú un yàtọ̀ síra. Àwọn ìpinnu tá à ń ṣe tiẹ̀ lè jẹ́ àbájáde ohun tí ẹ̀rí ọkàn wa sọ. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ‘àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè tí kò ní òfin máa ń ṣe àwọn ohun tí ó jẹ́ ti òfin lọ́nà ti ẹ̀dá.’ (Róòmù 2:14) Ṣé ohun tá a wá ń sọ ni pé tí kò bá ti sí òfin kan pàtó nínú Bíbélì lórí ọ̀rọ̀ kan, a kàn lè ṣe nǹkan lọ́nà tí wọ́n gbà tọ́ wa dàgbà àti bí wọ́n ti ń ṣe nǹkan lágbègbè wa?
3 Ó kéré tán, ìdí méjì pàtàkì ni kò fi yẹ kí àwa Kristẹni ronú lọ́nà yẹn. Àkọ́kọ́ ni pé, Bíbélì sọ pé: “Ọ̀nà kan wà tí ó dúró ṣánṣán lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ikú ni òpin rẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.” (Òwe 16:25) Torí pé a jẹ́ aláìpé, àwa èèyàn kò kúnjú ìwọ̀n láti pinnu ohun tó lè mú kí ìgbésí ayé wa yọrí sí rere láìsí àṣìṣe èyíkéyìí. (Òwe 28:26; Jer. 10:23) Ìdí kejì ni pé, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Sátánì tó jẹ́ “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí” ló ń darí àwọn àṣà tó gbòde àtàwọn ìlànà tí ayé ń tẹ̀ lé. (2 Kọ́r. 4:4; 1 Jòh. 5:19) Nípa bẹ́ẹ̀, tá a bá fẹ́ rí ojú rere Jèhófà, tá a sì fẹ́ kó bù kún wa, ó yẹ ká ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ ìyànjú tó wà nínú Róòmù 12:2.—Kà á.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 629
Ìbáwí
Àbájáde Ìgbọràn àti Àìgbọràn. Àwọn ẹni burúkú, àwọn òmùgọ̀ àtàwọn tó máa ń fi ohun búburú ṣayọ̀, máa ń kọ ìbáwí Jèhófà pátápátá torí pé wọ́n kórìíra ìbáwí ẹ̀. (Sm 50:16, 17; Owe 1:7) Tẹ́nì kan bá sì kórìíra ìbáwí Jèhófà, àbájáde rẹ̀ kì í dáa rárá torí ìyà tẹ́ni náà máa jẹ á wá le ju ìbáwí náà lọ. Ìwé Òwe ṣàlàyé ẹ̀ lọ́nà yìí: “Ìwà ẹ̀gọ̀ àwọn òmùgọ̀ ló ń bá wọn wí.” (Owe 16:22) Lára ìṣòro táwọn irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń fi ọwọ́ ara wọn fà ni ẹ̀sín, ipò òṣì, àìsàn àti ikú àìtọ́jọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ká rí ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó bá kọ ìbáwí Jèhófà. Jèhófà lo àwọn wòlíì ẹ̀ láti tọ́ wọn sọ́nà kó sì bá wọn wí, àmọ́ wọ́n kọtí ikún. Kódà, Jèhófà tún bá wọn wí ní ti pé kò dáàbò bò wọ́n mọ́, kò sì bù kún wọn mọ́. Síbẹ̀, wọn ò ṣàtúnṣe. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọ́n jẹ palaba ìyà torí àìgbọràn wọn bí Jèhófà ṣe sọ. Àwọn ọ̀tá ṣẹ́gun wọn, wọ́n sì kó wọn lọ sí ìgbèkùn.—Jer 2:30; 5:3; 7:28; 17:23; 32:33; Ho 7:12-16; 10:10; Sef 3:2.
JUNE 9-15
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 17
Ohun Táá Jẹ́ Kí Àlàáfíà Wà Nínú Ìdílé
Bí O Ṣe Lè Dárí Ji Aya Tàbí Ọkọ Rẹ
Fara balẹ̀ yẹ ara rẹ wò. Bíbélì sọ pé àwọn kan máa ń “fi ara [wọn] fún ìbínú,” wọ́n tún máa ń “fi ara [wọn] fún ìhónú.” (Òwe 29:22) Ṣé kì í ṣe ìwọ ni ọ̀rọ̀ yẹn ń bá wí? Ó yẹ kó o bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ mo máa ń gbin ìbínú sọ́kàn? Ṣé mo máa ń tètè bínú? Ṣé mo máa ń sọ ọ̀rọ̀ tí ò tó nǹkan di bàbàrà?’ Rántí ohun tí Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ ṣáá nípa ọ̀ràn, ń ya àwọn tí ó mọ ara wọn dunjú nípa.” (Òwe 17:9; Oníwàásù 7:9) Tó ò bá ṣọ́ra, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ nínú ìgbéyàwó tìẹ náà. Torí náà, tó o bá jẹ́ ẹni tó ń gbin ìbínú sọ́kàn, á dáa kó o bi ara rẹ pé: ‘Kí ni mo lè ṣe tí màá fi máa mú sùúrù fún ọkọ tàbí aya mi?’—Ìlànà Bíbélì: 1 Pétérù 4:8.
Bá A Ṣe Lè Yanjú Ìṣòro Tó Bá Jẹ Yọ
1. Ẹ fohùn ṣọkan lórí àkókò tẹ́ ẹ ó máa jíròrò àwọn ọ̀ràn tó bá wáyé. “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún, . . . ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀.” (Oníwàásù 3:1, 7) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn àwọn tọkọtaya tá a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ lẹ́ẹ̀kan yẹn ṣe fi hàn, tí àríyànjiyàn bá bẹ́ sílẹ̀, ó lè ká èèyàn lára ju bó ṣe yẹ lọ. Nígbà tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ẹ lo ìkóra-ẹni-níjàánu kẹ́ ẹ bàa lè fòpin sí ìjíròrò yẹn fúngbà díẹ̀ kó tó di pé inú bí yín jù, kẹ́ ẹ ka àkókò yẹn sí “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́.” Ohun tẹ́ ẹ lè ṣe tí wàhálà kankan ò fi ní da àárín yín rú ni pé kẹ́ ẹ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì yìí pé: “Ẹni ti o daju fun omi dabi olupilẹsẹ ìja; nitorina fi ìja silẹ ki o to di nla.”—Òwe 17:14, Bibeli Mimọ.
Àmọ́ ṣá, “ìgbà sísọ̀rọ̀” náà wà o. Ṣe ni ìṣòro dá bí igbó tó ń hù, téèyàn ò bá tètè ro ó dà nù, ṣe lá máa kún sí i. Torí náà, ẹ má ṣe rò pé ẹ kàn lè fi ìṣòro náà sílẹ̀ láìbójútó, pẹ̀lú èrò pé ọ̀ràn á yanjú ara rẹ̀. Tó o bá dábàá pé kẹ́ ẹ fòpin sí ìjíròrò kan, fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fún ọkọ tàbí aya rẹ nípa sísọ àkókò tí kò ní pẹ́ púpọ̀ tẹ́ ẹ tún máa padà sọ̀rọ̀ lórí ìṣòro yẹn. Tẹ́ ẹ bá ṣe irú ìlérí yẹn, á ran ẹ̀yin méjèèjì lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì yìí, pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú.” (Éfésù 4:26) Àmọ́ ṣá, o ní láti mú ìlérí tó o ṣe ṣẹ.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 790 ¶2
Ojú
Ọ̀nà kan tá a máa ń gbà mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹnì kan ni bí ojú ẹni náà ṣe rí lẹ́yìn tó gbọ́ tàbí rí ohun kan. Bí àpẹẹrẹ, ojú ẹnì kan lè fi hàn bóyá ó ń káàánú ẹlòmíì tàbí kò ṣe bẹ́ẹ̀ (Di 19:13); ẹnì kan lè wo ẹlòmíì tìkà-tẹ̀gbin tàbí kó ṣẹ́jú lọ́nà táá fi hàn pé ṣe ló ń gbèrò ibi. (Sm 35:19; Owe 6:13; 16:30) Tẹ́nì kan ò bá fẹ́ fara balẹ̀ kíyè sí ohun kan tàbí tí kò wù ú láti ran ẹnì kan lọ́wọ́, a lè sọ pé ẹni náà di ojú ẹ̀ tàbí pé ó gbé ojú ẹ̀ kúrò. (Mt 13:15; Owe 28:27) Bíbélì sọ pé “ojú àwọn òmùgọ̀ ń rìn gbéregbère títí dé ìkángun ayé,” ìyẹn túmọ̀ sí pé wọn ò kì í pọkàn pọ̀ lórí ohun kan, ohun tí kò sì yẹ kí wọ́n máa rò ni wọ́n ń rò. (Owe 17:24) Ojú ẹnì kan tún lè jẹ́ ká mọ bí ìlera ẹ̀ ṣe rí, bó ṣe lókun tó, àti bóyá inú ẹ̀ dùn tàbí kò dùn. (1Sa 14:27-29; Di 34:7; Job 17:7; Sm 6:7; 88:9) Ọba Jèhóṣáfátì sọ fún Jèhófà pé: “Ojú rẹ là ń wò.”—2Kr 20:12.
JUNE 16-22
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 18
Máa Sọ̀rọ̀ Ìtùnú Fáwọn Tó Ń Ṣàìsàn
Jèhófà Fẹ́ Kó O Ní Ọgbọ́n Tòótọ́
17 Máa ronú kó o tó sọ̀rọ̀. Tá ò bá ṣọ́ra, ọ̀rọ̀ ẹnu wa lè kó bá wa. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀rọ̀ téèyàn sọ láìronú dà bí ìgbà tí idà gúnni, àmọ́ ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń woni sàn.” (Òwe 12:18) Àárín àwa àtàwọn èèyàn máa dáa tá ò bá sọ kùdìẹ̀-kudiẹ wọn fáwọn ẹlòmíì. (Òwe 20:19) Tá a bá fẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu wa tu àwọn èèyàn lára dípò táá fi máa múnú bí wọn, ó yẹ ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ká sì máa ronú lórí ohun tá a kà. (Lúùkù 6:45) Torí náà, tá a bá ń ronú nípa ohun tí Bíbélì sọ, ọ̀rọ̀ ẹnu wa máa dà bí “orísun ọgbọ́n” tó ń tu àwọn èèyàn lára.—Òwe 18:4.
mrt àpilẹ̀kọ 19 àpótí
Bó o ṣe lè ran ọ̀rẹ́ rẹ tó ń ṣàìsàn lọ́wọ́
Máa fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn. Ọ̀nà kan tó dára jù lọ tó o lè fi ran ọ̀rẹ́ rẹ lọ́wọ́ ni kó pé kó o fetí sí i tó bá ń bá ẹ sọ̀rọ̀. Má ṣe rò pé gbogbo ohun tó bá sọ lo gbọ́dọ̀ fèsì ẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, kó o kàn fetí sílẹ̀ ti tó. Rí i pé o ní àmúmọ́ra, má sì máa sọ fún un pé ó ń ro èrò tí kò tọ́. Má ṣe rò pé o mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀, pàápàá tí àìsàn tó ń ṣe é kò bá hàn síta.—Òwe 11:2.
Máa sọ ohun tó dáa. O lè má mọ ohun tó yẹ kó o sọ, àmọ́ tó o bá kàn sọ fún un pé o mọ̀ pé ipò tó wà nira gan-an, ìyẹn máa tù ú lára ju pé kó o kàn dákẹ́. Tó ò bá mọ ohun tó yẹ kó o sọ, gbìyànjú láti sọ̀rọ̀ ṣókí tó wá látọkàn ẹ, o lè sọ pé “Mi ò mọ ohun tí mo lè sọ, àmọ́ mo fẹ́ kó o mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ẹ jẹ́ mí lógún gan-an.” Yẹra fáwọn ọ̀rọ̀ bí, “A dúpẹ́ pé kò ju báyìí lọ” tàbí “O ò máa dúpẹ́ tiẹ̀ . . . . ”
O lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ tó o bá ṣèwádìí nípa àìsàn tó ń ṣe é. Ó ṣeé ṣe kó mọrírì bó o ṣe sapá láti mọ ìṣòro tó ń bá yí, ìyẹn sì máa jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tó o bá sọ túbọ̀ nítumọ̀. (Òwe 18:13) Àmọ́, ṣọ́ra kó o má lọ fún un nímọ̀ràn láìjẹ́ pé ó béèrè lọ́wọ́ ẹ.
Ṣe ohun pàtó láti ran ẹni náà lọ́wọ́. Dípò tí wàá fi gbà pé o mọ bó o ṣe lè ṣèrànwọ́, béèrè ohun tó o lè ṣe lọ́wọ́ ẹ̀. Síbẹ̀, rántí pé ọ̀rẹ́ rẹ lè má gbà pé òun nílò ìrànlọ́wọ́ torí pé kò fẹ́ mú kí nǹkan nira fún ẹ. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, sọ fún un bóyá o lè bá a ṣe àwọn iṣẹ́ kan, bíi kó o lọ ra nǹkan lọ́jà, kó o bá a tún ilé ṣe, tàbí kó o bá a ṣe àwọn iṣẹ́ míì.—Gálátíà 6:2.
Má ṣe sọ̀rètí nù. Bí ọ̀rẹ́ rẹ ṣe ń fara da àìsàn tó ń ṣe é, ó lè da ètò tẹ́ ẹ ti ṣe rú láwọn ìgbà míì, tàbí kó má tiẹ̀ wù ú pé kó bá ẹ sọ̀rọ̀. Máa ṣe sùúrù fún un kó o sì lóye ẹ̀. Má jẹ́ kó sú ẹ láti máa pèsè ìrànlọ́wọ́ tó nílò.—Òwe 18:24.
Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Tó Ní Àárẹ̀ Ọpọlọ Lọ́wọ́
“Máa sọ̀rọ̀ ìtùnú.”—1 TẸSALÓNÍKÀ 5:14.
Ọkàn ọ̀rẹ́ ẹ lè má balẹ̀, ó sì lè gbà pé òun ò wúlò rárá. Tó ò bá tiẹ̀ mọ ohun tó o lè sọ, tó o bá jẹ́ kó mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an sí ẹ, ìyẹn máa tù ú nínú, ó sì máa fún un lókun.
“Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo.”—ÒWE 17:17.
Ṣe ohun tó máa ràn án lọ́wọ́. Dípò tí wàá fi gbà pé o mọ ohun tó yẹ kó o ṣe láti ràn án lọ́wọ́, ńṣe ni kó o béèrè ohun tó fẹ́. Tí kò bá rọrùn fún un láti sọ ohun tó fẹ́, o lè dábàá ohun kan tẹ́ ẹ lè jọ ṣe pa pọ̀, bóyá kẹ́ ẹ jọ ṣeré jáde. O sì lè bá a ra nǹkan lọ́jà, kó o bá a tún ilé ṣe tàbí kó o bá a ṣe àwọn nǹkan míì.—Gálátíà 6:2.
“Máa mú sùúrù.”—1 TẸSALÓNÍKÀ 5:14.
Àwọn ìgbà míì wà tó lè má rọrùn fún ọ̀rẹ́ ẹ láti sọ̀rọ̀. Jẹ́ kó mọ̀ pé inú ẹ máa dùn láti tẹ́tí sí i tó bá ti ṣe tán láti sọ̀rọ̀. Torí ohun tó ń ṣe é, ó lè sọ̀rọ̀ tàbí kó ṣe ohun tó máa dùn ẹ́. Ó lè ṣàdédé sọ pé òun ò ṣe ohun tẹ́ ẹ ti jọ sọ pé ẹ fẹ́ ṣe tẹ́lẹ̀ tàbí kó kàn máa kanra. Má torí ìyẹn sọ pé o ò ní ràn án lọ́wọ́ mọ́, ńṣe ni kó o ṣe sùúrù, kó o sì jẹ́ kó mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ẹ̀ yé ẹ.—Òwe 18:24.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-2 271-272
Kèké, I
Láyé àtijọ́, àwọn èèyàn máa ń ṣẹ́ kèké kí wọ́n lè pinnu ohun tó yẹ káwọn ṣe lórí ọ̀rọ̀ kan. Wọ́n máa ń lo òkúta kéékèèké tàbí wàláà tí wọ́n fi igi tàbí òkúta ṣe láti fi ṣẹ́ kèké. Wọ́n máa kó òkúta tàbí igi náà sínú aṣọ, ní “orí itan,” tàbí kí wọ́n kó o sínú kòkò, wọ́n á sì mì í pò. Kèké tó bá já bọ́ tàbí tí wọ́n fà yọ ni wọ́n máa lò. Bó ṣe jẹ́ pé iwájú Ọlọ́run ni èèyàn ti ń búra, tó sì dà bí àdúrà, bẹ́ẹ̀ náà ni ṣíṣẹ́ kèké ṣe rí. Àmọ́ láwọn ìgbà míì, wọ́n lè pinnu láti gbàdúrà ní tààràtà. Tí wọ́n bá ṣẹ́ kèké, wọ́n máa ń retí pé Jèhófà máa lo kèké náà láti jẹ́ káwọn mọ ohun tó fẹ́ kí wọ́n ṣe. Bíbélì máa ń lo ọ̀rọ̀ náà kèké (Heb., goh·ralʹ) ní tààràtà tàbí lọ́nà àpèjúwe, ó sì máa ń túmọ̀ sí “ìpín.”—Joṣ 15:1; Sm 16:5; 125:3; Ais 57:6; Jer 13:25.
Ohun tí wọ́n ń lò ó fún. Òwe 16:33 sọ pé: “Orí itan ni à ń ṣẹ́ kèké lé, àmọ́ ọ̀dọ̀ Jèhófà ni gbogbo ìpinnu tí ó bá ṣe ti wá.” Nílẹ̀ Ísírẹ́lì, wọ́n máa ń ṣẹ́ kèké kí wọ́n lè yanjú àríyànjiyàn. Bíbélì sọ pé: “Ṣíṣẹ́ kèké máa ń parí awuyewuye ó sì ń làjà láàárín àwọn alágbára tí wọ́n ń fa ọ̀rọ̀.” (Owe 18:18) Wọn kì í lò ó nídìí eré ìdárayá tàbí nídìí tẹ́tẹ́. Bákan náà, wọn kì í ta tẹ́tẹ́ lórí ohun tó bá máa jẹ́ àbájáde kèké tí wọ́n ṣẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, wọn kì í ṣẹ́ kèké kí wọ́n lè sọ àwọn àlùfáà di ọlọ́rọ̀ tàbí kí wọ́n lè rí owó tí wọ́n á máa lò ní tẹ́ńpìlì, tàbí kí wọ́n fi ṣàánú àwọn èèyàn. Àmọ́, tara wọn ni àwọn ọmọ ogun Róòmù ń rò nígbà tí wọ́n ṣẹ́ kèké lórí aṣọ Jésù bí Sáàmù 22:18 ṣe sọ.—Mt 27:35.
Ọ̀rọ̀ Tútù Máa Ń Mú Kí Àjọṣe Wa Pẹ̀lú Àwọn Míì Sunwọ̀n Sí I
4 Yálà àwọn tó jẹ́ ará là ń bá da nǹkan pọ̀ ni o tàbí àwọn tí kì í ṣe ará, ì báà sì jẹ́ àwọn tó wà nínú ìdílé wa pàápàá, ó ṣe pàtàkì pé ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn.” (Kól. 4:6) Irú àsọjáde tó dùn mọ́ni, tó sì bójú mu bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì fún ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dán mọ́rán, ó sì máa ń jẹ́ kí àlàáfíà jọba.
5 Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dára kò túmọ̀ sí pé kéèyàn máa sọ gbogbo ohun tó bá wá síni lọ́kàn àti bí ọ̀rọ̀ bá ṣe rí lára ẹni nígbàkigbà, pàápàá jù lọ bí inú bá ń bíni. Ìwé Mímọ́ fi hàn pé ìwà òmùgọ̀ ni féèyàn láti máa fi ìbínú sọ̀rọ̀, kì í ṣe ìwà ọmọlúwàbí. (Ka Òwe 25:28; 29:11.) Ìgbà kan wà tí Mósè, tó “fi gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ jẹ́ ọlọ́kàn tútù” ju gbogbo èèyàn tó wà láyé nígbà yẹn, jẹ́ kí ìwà ọ̀tẹ̀ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sún òun láti bínú tó sì wá kùnà láti fi ògo fún Ọlọ́run. Mósè sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀ láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀, àmọ́ ohun tó ṣe kò dùn mọ́ Jèhófà nínú. Lẹ́yìn ogójì ọdún tí Mósè fi jẹ́ aṣáájú fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kò ní àǹfààní láti kó wọn wọ Ilẹ̀ Ìlérí.—Núm. 12:3; 20:10, 12; Sm. 106:32.
6 Ìwé Mímọ́ gbóríyìn fún àwọn tó bá ń lo ìkóra-ẹni-níjàánu, òye tàbí làákàyè nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀. Bíbélì sọ pé: “Nínú ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀rọ̀ kì í ṣàìsí ìrélànàkọjá, ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣàkóso ètè rẹ̀ ń hùwà tòyetòye.” (Òwe 10:19; 17:27) Síbẹ̀, lílo òye tá a bá ń sọ̀rọ̀ kò túmọ̀ sí pé ká má ṣe sọ̀rọ̀ rárá. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé ká máa sọ̀rọ̀ “pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́,” ìyẹn ni pé ká máa sọ̀rọ̀ tútù, nípa lílo ahọ́n wa láti gbéni ró, ká má ṣe lò ó láti kó ẹ̀dùn ọkàn báni.—Ka Òwe 12:18; 18:21.
JUNE 23-29
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 19
Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Àtàtà Sáwọn Ará
Bá A Ṣe Lè Mú Kí Ìfẹ́ Tá A Ní Sáwọn Ará Túbọ̀ Lágbára
16 Ibi táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa dáa sí ló yẹ kó o máa wò, kì í ṣe ibi tí wọ́n kù sí. Wo àpèjúwe yìí. Ká sọ pé ìwọ àtàwọn ará wà níbi ìkórajọ kan tẹ́ ẹ̀ ń gbádùn ara yín, lẹ́yìn tẹ́ ẹ ṣe tán, o ya fọ́tò gbogbo yín. Kódà, o ya fọ́tò méjì míì torí ó ṣeé ṣe kí tàkọ́kọ́ má dáa. Ní báyìí, o ti ní fọ́tò mẹ́ta. Àmọ́, o kíyè sí pé arákùnrin kan lejú koko nínú ọ̀kan lára àwọn fọ́tò yẹn. Kí lo máa ṣe sí fọ́tò náà? Ńṣe lo máa yọ ọ́ kúrò torí o ṣì ní fọ́tò méjì míì tí gbogbo yín ti rẹ́rìn ín, títí kan arákùnrin yẹn.
17 A lè fi àwọn fọ́tò tá ò yọ kúrò yẹn wé àwọn nǹkan rere tá a fi ń rántí àwọn ará wa. A máa ń rántí àwọn nǹkan dáadáa táwa àtàwọn ará jọ ṣe. Àmọ́, ká sọ pé nígbà kan, ọ̀kan lára wọn sọ tàbí ṣe ohun tí ò dáa sí ẹ. Ṣé ó yẹ kó o gbé e sọ́kàn? O ò ṣe gbé e kúrò lọ́kàn, bí ìgbà tó o yọ fọ́tò tí ò dáa yẹn kúrò? (Òwe 19:11; Éfé. 4:32) Ó yẹ ká gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí ò tó nǹkan tẹ́ni tá a jọ ń sin Jèhófà ṣẹ̀ wá torí pé ọ̀pọ̀ nǹkan rere làwa àtẹni náà ti jọ ṣe tá a lè fi máa rántí ẹ̀. Irú àwọn nǹkan dáadáa táwọn ará ti ṣe yìí ló yẹ ká máa rántí, ká sì mọyì ẹ̀.
Túbọ̀ Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Àtàwọn Ará
10 Àwa náà máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lọ́wọ́. (Héb. 13:16) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arábìnrin Anna tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ ní àpilẹ̀kọ tó ṣáájú. Lẹ́yìn tí ìjì líle kan ṣẹlẹ̀, òun àti ọkọ ẹ̀ lọ bẹ ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wò. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n rí i pé ìjì náà ti ba òrùlé ilé wọn jẹ́, ìyẹn sì ti jẹ́ kí gbogbo aṣọ wọn dọ̀tí. Arábìnrin Anna sọ pé: “A kó gbogbo aṣọ wọn, a bá wọn fọ̀ ọ́, a sì lọ àwọn aṣọ náà ká tó dá a pa dà fún wọn. Lójú tiwa, ṣe ló dà bíi pé ohun tá a ṣe fún wọn yẹn ò tó nǹkan, àmọ́ ó jẹ́ ká túbọ̀ di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ títí di báyìí.” Ìfẹ́ tí Anna àti ọkọ ẹ̀ ní sáwọn ará ló jẹ́ kí wọ́n ràn wọ́n lọ́wọ́.—1 Jòh. 3:17, 18.
11 Tá a bá ń ṣe ohun tó fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, tá a sì ń fàánú hàn sí wọn, wọ́n á rí i pé a fìwà jọ Jèhófà, a sì ń ronú bó ṣe ń ronú. Wọ́n lè mọyì ohun tá a ṣe fún wọn ju bá a ṣe rò lọ. Nígbà tí Arábìnrin Khanh tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níṣàájú rántí àwọn tó ràn án lọ́wọ́ nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó sọ pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn arábìnrin mi ọ̀wọ́n tá a jọ máa ń lọ wàásù. Wọ́n máa ń wá sílé mi kí wọ́n lè fi mọ́tò wọn gbé mi, a jọ máa ń lọ jẹun ọ̀sán, wọ́n sì tún máa ń fi mọ́tò wọn gbé mi pa dà sílé. Mo wá rí i pé iṣẹ́ kékeré kọ́ ni wọ́n ṣe. Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi.” Òótọ́ kan ni pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa dúpẹ́ oore tá a ṣe fún wọn. Arábìnrin Khanh tún sọ nípa àwọn tó ran òun lọ́wọ́, ó ní: “Ó wù mí kí n san oore pa dà fún gbogbo àwọn tó ràn mí lọ́wọ́, àmọ́ ní báyìí, mi ò mọ ibi tí gbogbo wọn ń gbé. Àmọ́, Jèhófà mọ ibi tí wọ́n ń gbé, mo sì máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà bá mi san èrè fún wọn.” Òótọ́ lohun tí Arábìnrin Khanh sọ yìí. Jèhófà máa ń rí gbogbo ohun rere tá a ṣe fáwọn èèyàn, bó ti wù kó kéré tó. Ohun tá a bá ṣe máa ń ṣeyebíye lójú Jèhófà, ó sì máa ń wò ó bíi gbèsè tóun máa san pa dà fún wa.—Ka Òwe 19:17.
Ẹ Máa Fi Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn sí Ara Yín
6 Tí ẹnì kan bá ti ń bá ilé iṣẹ́ kan ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún, a lè sọ pé ẹni náà jẹ́ adúróṣinṣin. Síbẹ̀, látìgbà tó ti wà nílé iṣẹ́ yẹn, ó lè má tíì rí àwọn tó ni ilé iṣẹ́ náà rí. Ó lè má fara mọ́ gbogbo ìpinnu táwọn ọ̀gá ilé iṣẹ́ yẹn bá ṣe, ó sì lè má nífẹ̀ẹ́ ilé iṣẹ́ náà. Àmọ́, inú ẹ̀ ń dùn pé òun ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ láti rówó gbọ́ bùkátà. Á ṣì máa rọ́jú ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ yẹn títí táá fi fẹ̀yìn tì, àfi tó bá ríṣẹ́ tó dáa jùyẹn lọ sílé iṣẹ́ míì.
7 Ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìdúróṣinṣin tá a sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ní ìpínrọ̀ kẹfà àti ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni ohun tó ń mú kí ẹnì kan ṣe nǹkan. Nínú Bíbélì, ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wo ló ń mú káwọn èèyàn Ọlọ́run fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn? Ìdí tí àwọn tó fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn nínú Bíbélì fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó wá látọkàn wọn, kì í ṣe pé a fipá mú wọn. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Dáfídì. Ọkàn Dáfídì ló mú kó fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí Jónátánì ọ̀rẹ́ rẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé bàbá Jónátánì fẹ́ pa Dáfídì. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí Jónátánì kú, Dáfídì ṣì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí Méfíbóṣétì ọmọ Jónátánì.—1 Sám. 20:9, 14, 15; 2 Sám. 4:4; 8:15; 9:1, 6, 7.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 515
Ìmọ̀ràn, Agbani-nímọ̀ràn
Jèhófà lẹni tó gbọ́n jù lọ láyé àti lọ́run. Kò sì nílò ẹnikẹ́ni láti gbà á nímọ̀ràn. (Ais 40:13; Ro 11:34) Ọmọ ẹ̀ náà máa ń gbani nímọ̀ràn, ó sì máa ń tọ́ àwọn èèyàn sọ́nà torí pé òun ni “Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn.” Ohun tó sì jẹ́ kó lè ṣe iṣẹ́ yìí ni pé ó máa ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà, ẹ̀mí mímọ́ sì ń ṣiṣẹ́ lára ẹ̀. (Ais 9:6; 11:2; Jo 5:19, 30) Èyí jẹ́ ká rí i pé kí ìmọ̀ràn kan tó lè wúlò, ó gbọ́dọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà. Torí náà, gbogbo ìmọ̀ràn tó bá lòdì sí Ẹni Gíga Jù Lọ kò wúlò rárá àti rárá.—Owe 19:21; 21:30.
JUNE 30–JULY 6
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 20
Bó O Ṣe Lè Mọ̀ Bóyá Kó O Fẹ́ Ẹnì Kan Tàbí Kó O Má Fẹ́ Ẹ
Bó O Ṣe Lè Mọ̀ Bóyá Kó O Fẹ́ Ẹnì Kan Tàbí Kó O Má Fẹ́ Ẹ
3 Lóòótọ́, àsìkò alárinrin ni àsìkò táwọn méjì bá ń fẹ́ra sọ́nà, síbẹ̀ wọn ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú un torí pé ó ṣeé ṣe káwọn méjèèjì di tọkọtaya. Lọ́jọ́ ìgbéyàwó, tọkọtaya máa ń jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú Jèhófà pé àwọn máa nífẹ̀ẹ́ ara àwọn, àwọn á sì máa bọ̀wọ̀ fúnra wọn ní gbogbo àsìkò táwọn bá fi wà láàyè. Àmọ́ ká tó jẹ́ ẹ̀jẹ́ èyíkéyìí, ó yẹ ká fara balẹ̀ ro ọ̀rọ̀ náà dáadáa. (Ka Òwe 20:25.) Ohun tó sì yẹ ká ṣe náà nìyẹn tó bá kan ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó. Ó yẹ káwọn méjì tó ń fẹ́ra sọ́nà lo àsìkò yẹn láti mọ ara wọn dáadáa, kí wọ́n lè ṣe ìpinnu tó tọ́. Nígbà míì, wọ́n lè pinnu pé àwọn máa ṣègbéyàwó, ìgbà míì sì rèé, wọ́n lè pinnu pé káwọn má fẹ́ra mọ́. Táwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà bá sọ pé àwọn ò fẹ́ra mọ́, ìyẹn ò sọ pé ohun tí wọ́n ṣe burú. Kàkà bẹ́ẹ̀, àsìkò tí wọ́n fi fẹ́ra wọn sọ́nà yẹn jẹ́ kí wọ́n mọ̀ bóyá àwọn máa lè ṣègbéyàwó àbí bẹ́ẹ̀ kọ́.
4 Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fojú tó tọ́ wo ìfẹ́sọ́nà? Táwọn tí ò tíì lẹ́ni tí wọ́n ń fẹ́ bá mọ ìdí táwọn èèyàn fi ń fẹ́ra sọ́nà, wọn ò ní máa fẹ́ ẹni tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ò ní bá ṣègbéyàwó. Àmọ́ o, kì í ṣe àwọn tí ò tíì ṣègbéyàwó nìkan ló yẹ kó máa fojú tó tọ́ wo ìfẹ́sọ́nà. Gbogbo wa ló yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, èrò àwọn kan ni pé dandan ni káwọn méjì tó ń fẹ́ra sọ́nà ṣègbéyàwó. Àkóbá wo nirú èrò yìí máa ń ṣe fáwọn Kristẹni tí ò tíì lẹ́ni tí wọ́n ń fẹ́? Arábìnrin kan tí ò tíì lọ́kọ tó ń jẹ́ Melissa lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Táwọn ará bá mọ̀ pé arákùnrin àti arábìnrin kan ń fẹ́ra, ohun tí wọ́n máa ń retí ni pé wọ́n gbọ́dọ̀ ṣègbéyàwó. Torí náà, táwọn tó ń fẹ́ra bá rí i pé ìwà àwọn ò bára mu, nígbà míì wọn kì í fẹ́ fòpin sí ìfẹ́sọ́nà náà torí nǹkan táwọn èèyàn máa sọ. Kódà, àwọn kan ò tiẹ̀ fẹ́ ní àfẹ́sọ́nà torí ọ̀rọ̀ náà máa ń kó wọn lọ́kàn sókè.”
Báwo Lo Ṣe Lè Rí Ẹni Tó O Máa Fẹ́
8 Báwo lo ṣe lè fara balẹ̀ wo ẹni tó o máa fẹ́, tí ò sì ní fura? Tẹ́ ẹ bá wà nípàdé tàbí níbi ìkórajọ, o lè kíyè sí ìwà ẹni náà àti bó ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó. Àwọn wo lọ̀rẹ́ ẹ̀, àwọn nǹkan wo ló máa ń sọ? (Lúùkù 6:45) Ṣé àwọn nǹkan tó o fẹ́ ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lòun náà fẹ́ ṣe? O lè béèrè nípa ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn alàgbà ìjọ ẹ̀ tàbí kó o ní káwọn Kristẹni míì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, tí wọ́n sì mọ̀ ọ́n dáadáa sọ ohun tí wọ́n mọ̀ nípa ẹ̀ fún ẹ. (Òwe 20:18) O tún lè wádìí bóyá àwọn èèyàn ń sọ ohun tó dáa nípa ẹ̀. (Rúùtù 2:11) Bó o ṣe ń fara balẹ̀ wo ẹni náà, rí i pé o ò ṣe nǹkan tó máa jẹ́ kó fura torí ara ẹ̀ ò ní balẹ̀ mọ́. Kò yẹ kó o máa tẹ̀ lé e ṣòóṣòó kiri tàbí kó o máa bi í láwọn ìbéèrè tí kò pọn dandan.
Bó O Ṣe Lè Mọ̀ Bóyá Kó O Fẹ́ Ẹnì Kan Tàbí Kó O Má Fẹ́ Ẹ
7 Báwo lo ṣe lè mọ ẹni tó ò ń fẹ́ sọ́nà dáadáa? Ọ̀kan lára ohun tó dáa jù tó o lè ṣe ni pé kó o máa bá a sọ̀rọ̀, máa béèrè ìbéèrè, máa fetí sílẹ̀ dáadáa, má sì fi ohunkóhun pa mọ́ fún un. (Òwe 20:5; Jém. 1:19) Torí náà, á dáa kẹ́ ẹ máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kó rọrùn fún yín láti jọ máa sọ̀rọ̀, irú bíi kẹ́ ẹ jọ máa jẹun, kẹ́ ẹ jọ máa rìn níbi táwọn èèyàn wà, kẹ́ ẹ sì jọ máa wàásù. Ẹ tún lè mọ ara yín sí i tẹ́ ẹ bá jọ ń wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ àti ìdílé yín. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ ṣètò àwọn nǹkan tẹ́ ẹ lè máa ṣe táá jẹ́ kó o mọ bí ẹni tó ò ń fẹ́ ṣe máa hùwà sí oríṣiríṣi èèyàn láwọn ipò tó yàtọ̀ síra. Ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun tí Aschwin tó wá láti orílẹ̀-èdè Netherlands sọ nípa ìgbà tó ń fẹ́ Alicia ìyàwó ẹ̀ sọ́nà, ó ní: “A jọ máa ń ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ ká túbọ̀ mọra wa. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn nǹkan kéékèèké la sábà máa ń ṣe pa pọ̀, bíi ká jọ se oúnjẹ tàbí ká jọ ṣiṣẹ́ ilé. Àsìkò yẹn la mọ ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe àtàwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tá a ní.”
8 Ẹ máa túbọ̀ mọ ara yín tẹ́ ẹ bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ṣègbéyàwó, ó ṣe pàtàkì pé kẹ́ ẹ máa ṣe ìjọsìn ìdílé déédéé torí ìyẹn máa jẹ́ kẹ́ ẹ fi Jèhófà ṣáájú nínú ìdílé yín. (Oníw. 4:12) Torí náà, ẹ ò ṣe ṣètò àkókò tí ẹ̀ẹ́ jọ máa kẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀ ní báyìí tẹ́ ẹ ṣì ń fẹ́ra sọ́nà? Lóòótọ́, àwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà ò tíì di ìdílé, arákùnrin yẹn ò sì tíì di orí arábìnrin náà. Síbẹ̀, tẹ́ ẹ bá jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá mọ̀ bóyá ẹni tó ò ń fẹ́ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, tọkọtaya ni Max àti Laysa, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n sì ti wá. Wọ́n rí àǹfààní míì tó wà nínú káwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà jọ máa kẹ́kọ̀ọ́. Max sọ pé: “Gbàrà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra sọ́nà la ti jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìfẹ́sọ́nà, ìgbéyàwó àti ọ̀rọ̀ ìdílé nínú àwọn ìwé ètò Ọlọ́run. Àwọn nǹkan tá à ń kọ́ yẹn jẹ́ ká lè máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó nira fún wa láti sọ.”
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-2 196 ¶7
Fìtílà
Òwe 20:27 sọ pé: “Èémí èèyàn jẹ́ fìtílà Jèhófà, ó ń ṣàyẹ̀wò inú rẹ̀ lọ́hùn-ún.” Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà “èémí” láti fi ṣàpèjúwe ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu ẹnì kan. Àwọn ọ̀rọ̀ tẹ́nì kan ń sọ, yálà ó dáa tàbí kò dáa máa jẹ́ ká mọ irú èèyàn tó jẹ́.—Fi wé Iṣe 9:1.