Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
© 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
JULY 7-13
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 21
Àwọn Ìlànà Táá Jẹ́ Kí Tọkọtaya Láyọ̀
Báwo Lo Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tó Mọ́gbọ́n Dání?
Kíkánjú ṣe ìpinnu kì í ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mú. Òwe 21:5 sọ pé: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní, ṣùgbọ́n ó dájú pé àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.” Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ káwọn ọ̀dọ́langba tó bá ní ìfẹ́ onígbòónára fara balẹ̀ dáadáa kí wọ́n tó ṣèpinnu láti ṣègbéyàwó. Bi bẹ́ẹ̀ kọ́, ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn ní William Congreve, tó jẹ́ òǹkọ̀wé eré onítàn lédè Òyìnbó ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kejìdínlógún sọ pé: “Ẹni tó bá kánjú gbéyàwó lè kábàámọ̀ títí ayé.”
Bí Ìgbéyàwó Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí
Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. “[Má ṣe] ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ.” (Fílípì 2:3) Tọkọtaya ò ní yé forí gbárí bí ìgbéraga bá ń sún àwọn méjèèjì láti máa di ẹ̀bi ru ara wọn bí ìṣòro bá dé, dípò kí wọ́n máa fìrẹ̀lẹ̀ wá ọ̀nà tí wọ́n fi lè mú káwọn nǹkan sunwọ̀n sí i. Ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, tàbí ìwà ìrẹ̀lẹ̀, lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má ṣe máa rin kinkin pé ìwọ lo jàre bí èdèkòyédè bá wáyé.
“Máa Yọ̀ Pẹ̀lú Aya Ìgbà Èwe Rẹ”
13 Tó bá wá jẹ́ pé ọ̀nà tí ọkọ àti aya gbà ń bá ara wọn lò ló fa ìṣòro náà ńkọ́? Kí irú ìṣòro báyìí tó lè yanjú, ó gba pé kí àwọn méjèèjì sapá gidigidi. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ pé ó ti ń mọ́ wọn lára láti máa sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí ara wọn. (Òwe 12:18) Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè da àárín ọkọ àti aya rú. Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Ó sàn láti máa gbé ní ilẹ̀ aginjù ju gbígbé pẹ̀lú aya alásọ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú pákáǹleke.” (Òwe 21:19) Tó o bá jẹ́ aya nínú irú ìdílé bẹ́ẹ̀, bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ ìwà mi máa ń lé ọkọ mi sá nílé?’ Bíbélì sọ fáwọn ọkọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, ẹ má sì bínú sí wọn lọ́nà kíkorò.” (Kólósè 3:19) Tó bá sì jẹ́ pé ọkọ ni ọ́, bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ mo máa ń le koko mọ́ ìyàwó mi jù débi táá fi máa ronú àtilọ wá ẹni tó lè fara mọ́ níta?’ Àmọ́ o, pé nǹkan ò lọ bó ṣe yẹ kò ní kí ọkọ tàbí aya lọ ṣèṣekúṣe. Síbẹ̀, pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ yẹ kó mú kí ọkọ àti aya jọ sọ ọ̀rọ̀ náà pa pọ̀.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Ìran Tó Jẹ́ Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Ìjọba Ọlọ́run Nímùúṣẹ
9 Jésù ti di Ọba alágbára ní ọ̀run báyìí, kì í ṣe èèyàn tó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́. Bíbélì ṣàpèjúwe Jésù gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń gẹṣin, ogun sì ni ẹṣin gígùn dúró fún nínú Bíbélì. (Òwe 21:31) Ìṣípayá 6:2 sọ pé: “Wò ó! ẹṣin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ sì ní ọrun kan; a sì fún un ní adé, ó sì jáde lọ ní ṣíṣẹ́gun àti láti parí ìṣẹ́gun rẹ̀.” Ìyẹn nìkan kọ́ o, onísáàmù náà Dáfídì kọ ọ̀rọ̀ kan nípa Jésù, ó ní: “Ọ̀pá okun rẹ ni Jèhófà yóò rán jáde láti Síónì, pé: ‘Máa ṣẹ́gun lọ láàárín àwọn ọ̀tá rẹ’ ”—Sáàmù 110:2.
JULY 14-20
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 22
Àwọn Ìlànà Táá Jẹ́ Ká Lè Tọ́ Ọmọ Yanjú
Ṣé Wọ́n Máa Sin Jèhófà Tí Wọ́n Bá Dàgbà?
7 Tẹ́ ẹ bá ti ṣègbéyàwó tẹ́ ẹ sì fẹ́ bímọ, ó yẹ kẹ́ ẹ bi ara yín pé: ‘Ṣé a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ṣé òtítọ́ sì jinlẹ̀ nínú wa débi tí àá fi lè bójú tó ọmọ tí Jèhófà máa fún wa?’ (Sm. 127:3, 4) Tó o bá sì ti bímọ, bi ara ẹ pé: ‘Ṣé mò ń kọ́ àwọn ọmọ mi pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ kára?’ (Oníw. 3:12, 13) ‘Ṣé mò ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe kí n lè dáàbò bo àwọn ọmọ mi lọ́wọ́ ewu àti èròkerò tó kúnnú ayé Sátánì yìí?’ (Òwe 22:3) Kò ṣeé ṣe láti gba àwọn ọmọ lọ́wọ́ gbogbo ìṣòro tí wọ́n máa kojú. Àmọ́ o lè fìfẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń dàgbà láti máa fi ìlànà Ọlọ́run sílò tí wọ́n bá kojú ìṣòro, torí kò sí bí wọn ò ṣe ní níṣòro. (Ka Òwe 2:1-6.) Bí àpẹẹrẹ, bí mọ̀lẹ́bí yín kan bá fi òtítọ́ sílẹ̀, lo Bíbélì láti jẹ́ káwọn ọmọ rẹ mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. (Sm. 31:23) Tó bá sì jẹ́ pé ẹnì kan ló kú, ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó máa tu àwọn ọmọ rẹ nínú fún wọn, tó sì máa jẹ́ kí ọkàn wọn balẹ̀.—2 Kọ́r. 1:3, 4; 2 Tím. 3:16.
Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
17 Àtikékeré ni kó o ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọ rẹ. Ó ṣe pàtàkì káwọn òbí tètè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọ wọn kó tó pẹ́ jù. (Òwe 22:6) Ronú nípa àpẹẹrẹ Tímótì tó láǹfààní láti bá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò nígbà tó dàgbà. Ohun tó ràn án lọ́wọ́ ni pé láti “kékeré jòjòló” ni ìyá rẹ̀ Yùníìsì àti Lọ́ìsì ìyá rẹ̀ àgbà ti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.—2 Tím. 1:5; 3:15.
18 Orílẹ̀-èdè Côte d’Ivoire ni tọkọtaya míì tó ń jẹ́ Jean-Claude àti Peace ń gbé, wọ́n sapá gan-an débi pé àwọn ọmọ wọn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ló ń sin Jèhófà. Báwo ni wọ́n ṣe ṣe é? Àpẹẹrẹ Yùníìsì àti Lọ́ìsì ni wọ́n tẹ̀ lé. Wọ́n sọ pé: “Àtikékeré la ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọ wa ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kódà a ò jẹ́ kó pẹ́ sígbà tá a bí wọn.”—Diu. 6:6, 7.
19 Báwo lẹ̀yin òbí ṣe lè “kọ́ àwọn ọmọ” yín ní Ọ̀rọ̀ Jèhófà “léraléra”? Ìyẹn gba pé kẹ́ ẹ máa rán wọn létí ìlànà Ọlọ́run lásọtúnsọ láìjẹ́ kó sú yín. Kó lè ṣeé ṣe, ó ṣe pàtàkì kẹ́ ẹ máa lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ yín, kẹ́ ẹ sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé. Ó máa ń sú èèyàn tó bá di pé kéèyàn máa sọ ọ̀rọ̀ kan náà ṣáá. Àmọ́, á dáa kẹ́yin òbí wò ó bí ọ̀nà kan tẹ́ ẹ lè gbà gbin ẹ̀kọ́ òtítọ́ sọ́kàn àwọn ọmọ yín, táá sì jẹ́ kí wọ́n fi ẹ̀kọ́ náà sílò.
Ẹ̀yin Òbí Ẹ Jẹ́ Àpẹẹrẹ Rere Fáwọn Ọmọ Yín
Lóòótọ́, ọmọdé lọmọ́dé á máa jẹ́, àwọn ọmọ kan sì máa ń ya olórí kunkun, kódà àwọn kan máa ń ya pòkíì. (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Kí làwọn òbí lè ṣe tí wọ́n bá nírú ọmọ bẹ́ẹ̀? Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà ọmọdékùnrin ni ìwà òmùgọ̀ dì sí; ọ̀pá ìbáwí ni yóò mú un jìnnà réré sí i.” (Òwe 22:15) Ìwà òǹrorò làwọn kan ka nína ọmọ sí, wọ́n sì ní kò bóde mu mọ́. Ká sòótọ́ o, Bíbélì kò fára mọ́ kéèyàn máa sọ̀rọ̀ burúkú sí ọmọ tàbí kéèyàn máa lu ọmọ nílùkulù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà míì “ọ̀pá ìbáwí” máa ń túmọ̀ sí kéèyàn na ọmọ, àmọ́ àṣẹ táwọn òbí ní lórí ọmọ ló dìídì túmọ̀ sí. Èyí jẹ́ àṣẹ tí wọ́n ń lò láìgba gbẹ̀rẹ́, àmọ́ lọ́nà tó fi ìfẹ́ hàn tó sì bójú mu kó lè dára fáwọn ọmọ náà títí ayé.—Hébérù 12:7-11.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Jẹ́ Kí Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Tó O Ní Máa Múnú Rẹ Dùn
11 Bíi ti ẹrú kejì yẹn, àwa náà lè túbọ̀ láyọ̀ tá a bá sa gbogbo ipá wa lẹ́nu iṣẹ́ tá à ń ṣe báyìí nínú ìjọsìn Jèhófà. Jẹ́ kí ‘ọwọ́ rẹ dí gan-an’ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, kó o sì máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe nínú ìjọ. (Ìṣe 18:5; Héb. 10:24, 25) Rí i pé ò ń múra ìpàdé sílẹ̀ dáadáa, kó o lè dáhùn lọ́nà tó máa gbé àwọn ará ró. Fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ tí wọ́n bá fún ẹ nípàdé àárín ọ̀sẹ̀. Tí wọ́n bá gbé iṣẹ́ èyíkéyìí fún ẹ nínú ìjọ, rí i pé o tètè ṣe é, kó o sì jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán. Má fojú kéré ohunkóhun tí wọ́n bá fún ẹ nínú ìjọ. Ṣe ni kó o máa sapá láti sunwọ̀n sí i. (Òwe 22:29) Bó o bá ṣe ń sapá tó, bẹ́ẹ̀ ni wàá ṣe túbọ̀ máa tẹ̀ síwájú, ayọ̀ ẹ á sì máa pọ̀ sí i. (Gál. 6:4) Yàtọ̀ síyẹn, táwọn míì bá ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó wù ẹ́, á rọrùn fún ẹ láti bá wọn yọ̀.—Róòmù 12:15; Gál. 5: 26.
JULY 21-27
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 23
Àwọn Ìlànà Tó Kan Ọ̀rọ̀ Ọtí Mímu
Ṣọ́ra Fún Ọtí Àmujù
5 Tẹ́nì kan bá wá ń mu ọtí bí ẹní mumi àmọ́ tí ò hàn lójú ẹ̀ tàbí kó máa ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ ńkọ́? Àwọn kan wà tó jẹ́ pé bí wọ́n tilẹ̀ mu odidi àgbá pàápàá, kò ní hàn lójú wọn. Ṣùgbọ́n, tẹ́nì kan bá rò pé òun lé máa hu irú ìwà yẹn kóun sì mú un jẹ, ńṣe lonítọ̀hún ń tan ara rẹ̀. (Jeremáyà 17:9) Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọtí mímu á di bárakú sí i lára, á sì di “ẹrú fún ọ̀pọ̀ wáìnì.” (Títù 2:3) Nígbà tí òǹkọ̀wé nì, Caroline Knapp ń sọ̀rọ̀ nípa béèyàn ṣe ń di ọ̀mùtí, ó ní: “Ọjọ́ kan kọ́ lèèyàn ń di ọ̀mùtí, díẹ̀díẹ̀ ló máa ń bẹ̀rẹ̀, èèyàn ò sì ní mọ̀gbà tó máa wọ̀ ọ́ lẹ́wù.” Ọ̀fìn gbáà ni ọtí àmujù!
6 Tún wo ìkìlọ̀ Jésù, ó ní: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn. Nítorí yóò dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Lúùkù 21:34, 35) Kò dìgbà tẹ́nì kan bá ń mutí yó pàápàá kí ọtí tó sọ onítọ̀hún di ọ̀lẹ àti ẹni tó ń tòògbé nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Tí ọjọ́ Jèhófà bá wá lọ dé bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ nírú ipò yẹn ńkọ́?
Ṣé Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ọtí Lo Fi Ń Wò?
Àmọ́, Jèhófà Ẹlẹ́dàá ti fún àwa Kristẹni ní ìtọ́sọ́nà torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Bí àpẹẹrẹ, ó jẹ́ ká mọ̀ pé ọtí àmujù lè ba ayé wa jẹ́. Àwa náà lè ti ka àlàyé tí Òwe 23:29-35 ṣe nípa ẹni tó mutí yó àti àjálù tó máa ń fà. Daniel, alàgbà kan tó ń gbé nílẹ̀ Yúróòpù rántí ìgbésí ayé tó ń gbé kó tó di Kristẹni, ó ní: “Mo máa ń mutí lámujù, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí n ṣe àwọn ìpinnu tí kò dáa. Torí bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan burúkú ṣẹlẹ̀ sí mi, inú mi sì máa ń bà jẹ́ gan-an tí mo bá ń rántí wọn.”
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Bí àpẹẹrẹ, sísanra jọ̀kọ̀tọ̀ lè jẹ́ àmì àjẹkì, àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìgbà lọ̀rọ̀ rí bẹ́ẹ̀. Àìsàn lè mú kí ẹnì kan sanra gan-an. Àbùdá ẹnì kan sì tún lè fà á. Bákan náà, ó tún yẹ ká fi sọ́kàn pé bí ara ẹnì kan ṣe rí ni ọ̀rọ̀ sísanra jọ̀kọ̀tọ̀ nígbà tí àjẹkì jẹ́ ìwà téèyàn ń hù. Ohun tí ìwé àtúmọ̀ èdè kan tumọ̀ sísanra jọ̀kọ̀tọ̀ sí ni “níní àpọ̀jù ọ̀rá nínú ara” nígbà tó túmọ̀ jíjẹ àjẹkì sí “fífi ìwọra jẹun tàbí jíjẹ oúnjẹ ní àjẹjù.” Nípa bẹ́ẹ̀, bí ẹnì kan ṣe tóbi sí kọ́ la fi ń mọ ẹni tó ń jẹ àjẹkì bí kò ṣe bó ṣe máa ń ṣe tọ́rọ̀ oúnjẹ bá délẹ̀. Ẹnì kan lè máà tóbi, kódà ó tiẹ̀ lè tín-ín-rín pàápàá, síbẹ̀ kó jẹ́ alájẹkì. Síwájú sí i, ojú tí wọ́n fi ń wo kéèyàn sanra tàbí kéèyàn pẹ́lẹ́ńgẹ́ yàtọ̀ síra gan-an láti ibi kan sí òmíràn.
JULY 28–AUGUST 3
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 24
Gbára Dì fún Àkókò Wàhálà
“Ẹ Dúró Gbọn-in, Ẹ Má Yẹsẹ̀”
15 Máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó o sì máa ṣàṣàrò. Igi kan máa lágbára tí gbòǹgbò ẹ̀ bá fìdí múlẹ̀. Lọ́nà kan náà, ìgbàgbọ́ wa máa lágbára tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí igi náà bá ṣe ń dàgbà, bẹ́ẹ̀ náà ni gbòǹgbò ẹ̀ á máa fìdí múlẹ̀, táá sì máa tóbi sí i. Táwa náà bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì ń ṣàṣàrò, ìgbàgbọ́ wa á máa lágbára sí i, á sì túbọ̀ dá wa lójú pé àwọn ìlànà Ọlọ́run ló dáa jù lọ. (Kól. 2:6, 7) Máa ronú nípa bí ìtọ́sọ́nà, ìmọ̀ràn àti ààbò Jèhófà ṣe ran àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́wọ́ nígbà àtijọ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ìsíkíẹ́lì rí ìran, ó rí áńgẹ́lì kan tó ń wọn tẹ́ńpìlì, ó sì fọkàn sí gbogbo àlàyé tí áńgẹ́lì náà ṣe. Ìran yìí fún Ìsíkíẹ́lì lókun, ó sì jẹ́ káwa náà mọ bá a ṣe lè tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà nínú ìjọsìn mímọ́. (Ìsík. 40:1-4; 43:10-12) Àwa náà máa jàǹfààní tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì ń ṣàṣàrò nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀.
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìṣòro Ba Ayọ̀ Rẹ Jẹ́
12 Òwe 24:10 sọ pé: “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.” Òwe míì tún sọ pé: “Nítorí ìrora ọkàn-àyà, ìdààmú máa ń bá ẹ̀mí.” (Òwe 15:13) Ìrẹ̀wẹ̀sì ti mú àwọn Kristẹni kan débi tí wọ́n fi ṣíwọ́ kíka Bíbélì àti ṣíṣàṣàrò lórí rẹ̀. Àdúrà wọn kò ti ọkàn wọn wá mọ́, wọ́n sì lè máa yẹra fún àwọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà. Ó ṣe kedere pé ewu wà nínú kéèyàn jẹ́ kí ìbànújẹ́ pẹ́ lọ́kàn òun.—Òwe 18:1, 14.
13 Àmọ́ tá a bá ní èrò pé nǹkan á dáa, ó máa jẹ́ ká lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn apá ibi tó ń fúnni ní ayọ̀ àti ìdùnnú nínú ìgbésí ayé wa. Dáfídì sọ pé: “Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí.” (Sm. 40:8) Tí nǹkan ò bá lọ fún wa bó ṣe yẹ kó lọ, a ò gbọ́dọ̀ ṣíwọ́ ṣíṣe àwọn ohun tá à ń ṣe láti jọ́sìn Ọlọ́run. Àní, ohun tá a fi lè borí ìbànújẹ́ ni pé ká máa lọ́wọ́ nínu ìgbòkègbodò tó ń fúnni láyọ̀. Jèhófà sọ fún wa pé tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ òun déédéé, tá a sì ń ronú lórí ohun tá a kà nínú rẹ̀, a ó máa rí ìdùnnú àti ayọ̀. (Sm. 1:1, 2; Ják. 1:25) “Àwọn àsọjáde dídùnmọ́ni” tó ń gbé wa ró tó sì ń jẹ́ kí ọkàn wa yọ̀ là ń rí gbà látinú Bíbélì àti láwọn ìpàdé.—Òwe 12:25; 16:24
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Òwe 24:16 sọ pé: “Olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje, á sì tún dìde.” Ṣé ohun tí ẹsẹ yìí ń sọ ni pé èèyàn lè máa dẹ́ṣẹ̀ léraléra kí Ọlọ́run sì máa dárí jì í?
Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, kì í ṣe ohun tí ẹsẹ Bíbélì náà ń sọ nìyẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni pé èèyàn lè ṣubú ní ti pé ó ń tinú ìṣòro kan bọ́ sínú òmíì. Láìka tàwọn ìṣòro tó ní sí, ó ń dìde tó túmọ̀ sí pé ó ń fara dà á.
Torí náà, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹni tó ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ ni Òwe 24:16 ń sọ nípa ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹni tó ṣubú sínú ìṣòro tàbí tó ń tinú ìṣòro kan bọ́ sí òmíì ló ń sọ. Nínú ayé burúkú tá à ń gbé yìí, olódodo lè ṣàìsàn tàbí kó láwọn ìṣòro míì. Kódà, ìjọba lè ṣenúnibíni sí i nítorí ohun tó gbà gbọ́. Bó ti wù kó rí, ọkàn ẹ̀ balẹ̀ pé Ọlọ́run máa ti òun lẹ́yìn, á sì fún òun lókun láti fara dà á. Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti rí i pé Ọlọ́run máa ń dúró ti àwọn èèyàn ẹ̀, wọn kì í sì í bọ́hùn. Kí nìdí? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi dá wa lójú pé, “Jèhófà ń gbé gbogbo àwọn tó ti fẹ́ ṣubú ró, ó sì ń gbé gbogbo àwọn tó dorí kodò dìde.”—Sm. 41:1-3; 145:14-19
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, bí ọkùnrin kan bá fẹ́ “gbé agbo ilé [rẹ̀] ró,” ìyẹn ni pé tó bá fẹ́ gbéyàwó kó sì ní ìdílé tirẹ̀, ó yẹ kó bi ara rẹ̀ pé, ‘Ṣé mo ti ṣe tán láti bójú tó aya àtàwọn ọmọ tá a bá bí kí n sì máa gbọ́ bùkátà wọn?’ Kó tó ní ìdílé, ó ní láti ṣiṣẹ́, kó bójú tó oko rẹ̀, tàbí irè oko rẹ̀. Nítorí náà, bí gbólóhùn náà ṣe kà kedere nínú Bíbélì Today’s English Version ní èdè Gẹ̀ẹ́sì rèé: “O kò gbọ́dọ̀ tíì kọ́ ilé rẹ tàbí kó o fìdí ilé rẹ múlẹ̀ títí dìgbà tí irè oko rẹ á fi jáde, tó sì dá ọ lójú pé o lè rí nǹkan mú relé láti ibẹ̀.” Ǹjẹ́ ìlànà kan náà ṣeé lò lóde òní?
Bẹ́ẹ̀ ni. Ọkùnrin kan tó fẹ́ ṣègbéyàwó ní láti múra sílẹ̀ dáadáa láti ṣe ojúṣe rẹ̀. Tí ara rẹ̀ bá le ó ní láti ṣiṣẹ́. Àmọ́, iṣẹ́ àṣekára tí ọkùnrin ní láti ṣe kó tó lè bójú tó ìdílé rẹ̀ kò mọ sórí pípèsè nǹkan tara nìkan. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé ọkùnrin tí kì í bá bójú tó nǹkan tara tí ìdílé rẹ̀ nílò, tí kì í sì í bójú tó ẹ̀dùn ọkàn wọn àti ohun tí wọ́n nílò nípa tẹ̀mí, ó burú ju aláìgbàgbọ́ lọ. (1 Tím. 5:8) Nítorí náà, ó yẹ kí ọmọkùnrin tó ń gbèrò àtigbéyàwó kó sì bímọ bi ara rẹ̀ láwọn ìbéèrè bí: ‘Ǹjẹ́ mo ti múra sílẹ̀ débi tó lápẹẹrẹ láti pèsè nǹkan ti ara fún ìdílé tí mo máa ní? Ṣé mo ti múra tán láti di olórí ìdílé tá a máa múpò iwájú nínú ìjọsìn? Ǹjẹ́ màá lè máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ìyàwó àtàwọn ọmọ mi déédéé?’ Ó dájú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tẹnu mọ́ àwọn iṣẹ́ pàtàkì wọ̀nyẹn.—Diu. 6:6-8; Éfé. 6:4.
Nítorí náà, ọ̀dọ́kùnrin tó ń wá ìyàwó ní láti ronú dáadáa nípa ìlànà tó wà nínú Òwe 24:27. Bákan náà, ọ̀dọ́bìnrin ní láti béèrè lọ́wọ́ ara rẹ̀ bóyá òun ti múra láti ṣe ojúṣe ìyàwó àti ìyá. Tọkọtaya tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó tí wọ́n sì ń gbèrò àtibímọ tàbí àwọn méjì tí wọ́n ń fẹ́ra wọn sọ́nà ní láti bi ara wọn ní irú àwọn ìbéèrè yẹn. (Lúùkù 14:28) Táwọn èèyàn Ọlọ́run bá ń tẹ̀ lé amọ̀nà tí Ọlọ́run mí sí yìí, wọ́n á yẹra fún ọ̀pọ̀ ìrora ọkàn, wọ́n á sì gbádùn ìgbé ayé ìdílé tó ń mérè wá.
AUGUST 4-10
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 25
Àwọn Ìlànà Tó Kan Ọ̀rọ̀ Ẹnu Wa
Máa Fi Ahọ́n Rẹ Sọ̀rọ̀ Tó Ń Gbéni Ró
6 Ìwé Òwe 25:11 sọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká mọ ìgbà tó tọ́ láti sọ̀rọ̀. Ó ní: “Bí àwọn èso ápù ti wúrà nínú àwọn ohun gbígbẹ́ tí a fi fàdákà ṣe ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́.” Ápù aláwọ̀ wúrà máa lẹ́wà gan-an lóòótọ́. Tá a bá tún wá gbé e sínú abọ́ fàdákà, ńṣe nìyẹn tún máa bu ẹwà kún un. Bákan náà, tá a bá fòye mọ ìgbà tó tọ́ láti sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ wa á tu àwọn èèyàn lára á sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Àmọ́, báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀
7 Ó lè jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tá a sọ fẹ́nì kan ló máa ràn án lọ́wọ́, àmọ́ tá ò bá fòye mọ àkókò tó dáa jù láti sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ wa ò ní wọ̀ ọ́ lọ́kàn. (Ka Òwe 15:23.) Bí àpẹẹrẹ, lóṣù March ọdún 2011, ìsẹ̀lẹ̀ tó lágbára kan mú kí omi òkun ya wọ inú àwọn ìlú tó wà ní ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Japan, ó sì run ọ̀pọ̀ ìlú tó wà níbẹ̀. Àwọn tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15,000] lọ ló pàdánù ẹ̀mí wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àjálù yìí ò yọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ sílẹ̀, wọ́n lo gbogbo àǹfààní tí wọ́n ní láti sọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì fún àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀. Ẹlẹ́sìn Búdà ni ọ̀pọ̀ àwọn tó wà níbẹ̀, wọn ò sì mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Àwọn ará wa fòye mọ̀ pé kò ní dáa kó jẹ́ pé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn àjálù náà làwọn á máa wàásù ìrètí àjíǹde fáwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ náà. Ńṣe ni wọ́n lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ tí wọ́n ní láti tu àwọn èèyàn nínú, wọ́n sì lo Bíbélì láti fi ṣàlàyé ìdí tí irú àwọn nǹkan burúkú bẹ́ẹ̀ fi ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀
Máa Fi Ahọ́n Rẹ Sọ̀rọ̀ Tó Ń Gbéni Ró
15 Ohun tá a sọ àti bá a ṣe sọ ọ́ ṣe pàtàkì. Nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nínú sínágọ́gù nípa ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀, ìyẹn Násárétì, ẹnu yà àwọn èèyàn náà “nítorí àwọn ọ̀rọ̀ alárinrin tí ń jáde láti ẹnu rẹ̀.” (Lúùkù 4:22) Tá a bá ń fi ohùn pẹ̀lẹ́ bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, wọ́n á tẹ́tí sí wa, ọ̀rọ̀ wa á sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn. (Òwe 25:15) Tá a bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn, tá a sì ń gba tiwọn rò, á rọrùn fún wa láti bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́. Ohun tí Jésù ṣe nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó rí làálàá táwọn ogunlọ́gọ̀ kan ṣe torí kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àánú wọn ṣe é, ó sì “bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.” (Máàkù 6:34) Kódà, nígbà táwọn kan bú Jésù, kò bú wọn pa dà.—1 Pét. 2:23.
16 Ó lè ṣòro fún wa láti lo òye ká sì fi ohùn pẹ̀lẹ́ sọ̀rọ̀ pàápàá tó bá jẹ́ pé ẹni tó sún mọ́ wa dáadáa là ń bá sọ̀rọ̀. A lè máa rò ó pé a lè bá àwọn mẹ́ńbà ìdílé wa tàbí ọ̀rẹ́ wa nínú ìjọ sọ̀rọ̀ bó ṣe wù wá. Àmọ́, ṣé Jésù sọ̀rọ̀ sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bó ṣe wù ú torí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́? Rárá o! Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń jiyàn nípa ẹni tó lọ́lá jù láàárín wọn, Jésù fi ohùn pẹ̀lẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì fi ọmọ kékeré kan ṣàpèjúwe fún wọn. (Máàkù 9:33-37) Àwọn alàgbà náà lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, kí wọ́n máa gbani nímọ̀ràn pẹ̀lú “ẹ̀mí ìwà tútù.”—Gál. 6:1.
Ẹ Máa Ru Ara Yín Lọ́kàn Sókè Sí Ìfẹ́ àti Sí Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà—Báwo?
8 Ní ṣíṣiṣẹ́sin Ọlọrun wa, gbogbo wa lè ru ara wa lọ́kàn sókè lẹ́nìkínní kejì nípa fífi àpẹẹrẹ lélẹ̀. Dájúdájú Jesu ru àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lọ́kàn sókè. Ó nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ Kristian ó sì gbé iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà ga. Ó sọ pé ó dàbí oúnjẹ fún òun. (Johannu 4:34; Romu 11:13) Irú ìtara ọkàn bẹ́ẹ̀ máa ń ranni. Ìwọ bákan náà ha lè jẹ́ kí ìdùnnú-ayọ̀ rẹ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ di mímọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn bí? Bí o ti ń fi tìṣọ́ratìṣọ́ra yẹra fún ọ̀rọ̀ ìṣògo, ṣàjọpín àwọn ìrírí dáradára tí o ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ. Nígbà tí o bá késí àwọn ẹlòmíràn láti bá ọ ṣiṣẹ́, ṣàkíyèsí bí o bá lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ojúlówó ìgbádùn nínú bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa, Jehofa.—Owe 25:25.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Sùúrù
OHUN TÓ O LÈ ṢE: Máa ṣe sùúrù, kí ìbínú má bàa sọ ẹ́ di ẹrú. Àwọn kan máa ń wo ẹni tó ń bínú sódì bí alágbára èèyàn, àmọ́ ká sòótọ́, àbùkù ló jẹ́ fún ẹni tí kò bá lè kápá ìbínú rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Bí ìlú tí a ya wọ̀, tí kò ní ògiri, ni ẹni tí kò lè kápá ìbínú rẹ̀.” (Òwe 25:28) Ọ̀nà kan tó dáa tá a lè gbà kápá ìbínú wa ni pé ká máa gbìyànjú láti mọ ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ká tó dá sí i. “Ìjìnlẹ̀ òye tí èèyàn ní ló máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀.” (Òwe 19:11) Tọ́rọ̀ bá ṣẹlẹ̀, ó ṣe pàtàkì ká fetí sílẹ̀ dáadáa, ká sì gbọ́ tọ̀tún-tòsì lágbọ̀ọ́yé ká tó ṣe ohunkóhun, ìyẹn ni ò ní jẹ́ ká ṣi ọ̀rọ̀ sọ tàbí ká ṣìwà hù.
AUGUST 11-17
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 26
Má Ṣe Bá “Òmùgọ̀” Da Nǹkan Pọ̀
it-2 729 ¶6
Òjò
Àwọn àsìkò. Ní Ilẹ̀ Ìlérí, wọ́n máa ń ní àsìkò ẹ̀rùn àti àsìkò òjò. (Fi wé Sm 32:4; Sol 2:11, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) Ìwọ̀nba òjò díẹ̀ ló máa ń rọ̀ láti nǹkan bí ìlàjì oṣù April sí ìlàjì oṣù October. Àsìkò yìí náà ni wọ́n máa ń kórè àwọn irè oko wọn. Òwe 26:1 jẹ́ ká rí i pé ó ṣàjèjì kí òjò rọ̀ lásìkò ìkórè. (Fi wé 1Sa 12:17-19.) Tó bá di àsìkò òjò, kì í ṣe gbogbo ìgbà lòjò máa ń rọ̀; láwọn ọjọ́ kan á rọ̀, àmọ́ láwọn ọjọ́ míì kò ní rọ̀. Bákan náà, torí pé ojú ọjọ́ máa ń tutù lásìkò yìí, òtútù lè mú ẹni tó bá wọnú òjò. (Ẹsr 10:9, 13) Torí náà, wọ́n máa ń mọyì ẹ̀ tí wọ́n bá rí ilé tó tura.—Ais 4:6; 25:4; 32:2; Job 24:8.
w87 10/1 19 ¶12
Ìbáwí Máa Ńmú Èso Tí Ńwá Alaafia Wá
12 Pẹlu awọn eniyan kan awọn ìgbéṣẹ̀ tí ó tubọ lekoko sí i lè pọ̀ndandan gẹgẹ bí Owe 26:3 ti tọ́kafihàn: “Pàṣán wà fun ẹṣin, ìjánu wà fun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ọ̀pá sì wà fun ẹ̀hìn awọn arìndìn eniyan.” Ní awọn ìgbà miiran Jehofah jẹ́ kí a tẹ̀ Israel orilẹ-ede rẹ̀ ba nipasẹ awọn ìjọ̀gbọ̀n tí wọn fà wá sórí araawọn: “Wọn ti hùwà ọ̀tẹ̀ lòdìsí awọn àwípé-ọ̀rọ̀ Ọlọrun; ati pé ìmọ̀ràn Ọ̀gá-Ògo Julọ ni wọn ti ṣàìbọ̀wọ̀ fun. Nitori bẹẹ pẹlu ìjọ̀gbọ̀n ni oun tẹ̀síwájú lati tẹ̀ ọkàn-àyà wọn ba; wọn kọsẹ̀, tí kò sì sí ẹni tí ó ńṣèrànlọ́wọ́. Wọn sí bẹ̀rẹ̀síí képe Jehofah fun ìrànlọ́wọ́ ninu ìdààmú wọn; lati inu awọn pákáǹleke tí ó wà lórí wọn ni oun ti gbà wọn là bí ó ti sábà máa ńrí.” (Psalm 107:11-13, NW ) Awọn arìndìn kan, bí ó ti wù kí ó rí, ti mú araawọn yigbì rékọjá àrọwọ́tó irú ìbáwí amúniláradá eyikeyi: “Eniyan kan tí a ńfìbáwí-tọ́sọ́nà léraléra ṣugbọn tí ó mú ọrùn rẹ̀ le yoo ṣẹ́ lójijì, tí kì yoo sì sí ìmúláradá.”—Owe 29:1, NW.
it-2 191 ¶4
Arọ
Àkànlò èdè. Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì sọ pé: “Bí ẹni tó dá ara rẹ̀ lẹ́sẹ̀ [èyí táá sọ ọ́ di arọ], tó sì ṣe ara rẹ̀ léṣe ni ẹni tó fa ọ̀ràn lé òmùgọ̀ lọ́wọ́.” Ká sòótọ́, ẹni tó bá gbé iṣẹ́ èyíkéyìí fún òmùgọ̀ pé kó bá òun ṣe dà bí ẹni tó fẹ́ ṣe ara ẹ̀ léṣe. Ó dájú pé gbogbo iṣẹ́ náà ló máa forí ṣánpọ́n, á sì pàdánù ohun ìní rẹ̀.—Owe 26:6.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Tó O Bá Ní Ìwà Tútù, Wàá Di Alágbára
18 Òótọ́ kan ni pé kì í ṣe gbogbo èèyàn tá a fara balẹ̀ ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́ fún ló máa gba ohun tá a sọ. Àmọ́ tá a bá fọgbọ́n ṣàlàyé lọ́nà pẹ̀lẹ́, àá lè ràn wọ́n lọ́wọ́. (Ka Kólósè 4:6.) A lè fi bá a ṣe ń ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́ wé bí ẹnì kan ṣe ń ju bọ́ọ̀lù sí ẹlòmíì. A lè rọra ju bọ́ọ̀lù náà, a sì lè fagbára jù ú. Tá a bá rọra jù ú, ó ṣeé ṣe kẹ́ni tá a jù ú sí rí i mú, ká sì jọ máa gbádùn eré náà lọ. Lọ́nà kan náà, tá a bá fọgbọ́n ṣàlàyé lọ́nà pẹ̀lẹ́, ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn gbọ́ wa, kí wọ́n sì fẹ́ ká máa bá ìjíròrò náà lọ. Àmọ́ ṣá o, tá a bá rí i pé ẹnì kan ń bá wa jiyàn tàbí pé ó ń ta ko ohun tá a gbà gbọ́, kò pọn dandan ká máa bá ìjíròrò náà lọ. (Òwe 26:4) Àmọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ò wọ́pọ̀ torí ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa fetí sí wa.
AUGUST 18-24
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 27
Bí Àwọn Ọ̀rẹ́ Tòótọ́ Ṣe Ń Ṣe Wá Láǹfààní
Jèhófà Mọyì Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Tó Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀
12 Ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń mọyì ìbáwí tí wọ́n bá fún un. Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí: Ká sọ pé o ti kí ọ̀pọ̀ àwọn ará lẹ́yìn ìpàdé, lẹnì kan bá fà ẹ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ó sì rọra sọ fún ẹ pé oúnjẹ ti há sí ẹ léyín. Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ? Ó dájú pé ojú máa tì ẹ́, ó tiẹ̀ lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ó yẹ kẹ́nì kan ti sọ fún ẹ tẹ́lẹ̀. Síbẹ̀, ṣé inú ẹ ò ní dùn pé ẹni náà sọ fún ẹ? Lọ́nà kan náà, ṣé kò yẹ ká mọyì ẹni tó lo ìgboyà, tó sì bá wa wí lásìkò tó tọ́. Ṣe ló yẹ ká mú irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́, dípò ká sọ ọ́ di ọ̀tá.—Ka Òwe 27:5, 6; Gál. 4:16.
it-2 491 ¶3
Aládùúgbò
Nígbà tí Òwe ń gbà wá níyànjú pé ká fọkàn tán ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, ká sì kàn sí i nígbà ìṣòro, ó sọ pé: “Má fi ọ̀rẹ́ rẹ tàbí ọ̀rẹ́ bàbá rẹ sílẹ̀, má sì wọ ilé ọmọ ìyá rẹ ní ọjọ́ àjálù rẹ; aládùúgbò [sha·khenʹ] tó wà nítòsí sàn ju ọmọ ìyá tó jìnnà réré.” (Owe 27:10) Ohun tí ẹni tó kọ òwe yìí ń sọ ni pé ó sàn kéèyàn kàn sí ọ̀rẹ́ tó wà nítòsí nígbà ìṣòro ju kéèyàn kàn sí mọ̀lẹ́bí tí ọ̀nà ẹ̀ jìn. Torí pé ọ̀rọ̀ náà lè bá a lójijì, kó má sì lè tètè gbé ìgbésẹ̀ tàbí kó má rọrùn fún un láti ṣèrànwọ́ ní àkókò yẹn.
Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Báwo Lẹ Ṣe Fẹ́ Káyé Yín Rí?
7 Ohun tá a rí kọ́ nínú ìpinnu tí ò dáa tí Jèhóáṣì ṣe ni pé ó yẹ ká yan àwọn ọ̀rẹ́ táá jẹ́ ká níwà rere, ìyẹn àwọn ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì ń múnú ẹ̀ dùn. Kì í ṣe àwọn tá a jọ jẹ́ ẹgbẹ́ nìkan la lè yàn lọ́rẹ̀ẹ́, a tún lè yan àwọn tó dàgbà jù wá lọ tàbí àwọn tó kéré sí wa. Ẹ má gbàgbé pé Jèhóáṣì kéré gan-an sí ọ̀rẹ́ rẹ̀ Jèhóádà. Tó o bá fẹ́ yan ọ̀rẹ́, bi ara ẹ láwọn ìbéèrè yìí: ‘Ṣé àwọn tí mo fẹ́ yàn lọ́rẹ̀ẹ́ yìí máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ mi nínú Jèhófà túbọ̀ lágbára? Ṣé wọ́n á jẹ́ kí n máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run? Ṣé wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àti òtítọ́ tó ń kọ́ wa? Ṣé wọ́n máa ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run? Ṣé wọ́n máa ń bá mi sòótọ́ ọ̀rọ̀ tí mo bá ṣohun tí ò dáa àbí ńṣe ni wọ́n máa ń sọ pé ohun tí mo ṣe dáa?’ (Òwe 27:5, 6, 17) Ká sòótọ́, táwọn ọ̀rẹ́ ẹ ò bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kò yẹ kó o máa bá wọn rìn. Àmọ́ tó o bá láwọn ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àwọn ọ̀rẹ́ gidi nìyẹn. Má fi wọ́n sílẹ̀ o!—Òwe 13:20
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Òwe
27:21. Ìyìn lè fi irú ẹni tá a jẹ́ hàn. Tá a bá fi ọpẹ́ àṣeyọrí wa fún Jèhófà nígbà táwọn èèyàn bá yìn wá, tí ìyìn yẹn sì mú ká máa bá a lọ láti sin Jèhófà, a jẹ́ pé onírẹ̀lẹ̀ ni wá. Ṣùgbọ́n tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́ńbẹ́lú àwọn míì nítorí pé àwọn èèyàn ń yìn wá, ńṣe nìyẹn máa fi hàn pé agbéraga ni wá.
AUGUST 25-31
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 28
Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Ẹni Burúkú àti Olódodo
Iwọ Ha Ń Tọ Jehofa Lẹhin Lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ Bi?
“OLÓDODO láyà bi kinniun.” (Owe 28:1) Wọn ń lo igbagbọ, wọn ń fi igbọkanle gbarale Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, wọn sì ń fi ìgboyà lọ siwaju ninu iṣẹ-isin Jehofa ni oju ewu eyikeyii.
it-2 1139 ¶3
Òye
Àwọn tó kọ ọgbọ́n Ọlọ́run. Tẹ́nì kan bá bẹ̀rẹ̀ sí í mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀, ìyẹn fi hàn pé kò ka Ọlọ́run sí mọ́, kódà kì í ronú nípa ohun tí Jèhófà fẹ́ kó tó ṣèpinnu. (Job 34:27) Irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń tan ara ẹ̀ jẹ pé kò sóhun tó burú nínú nǹkan tóun ń ṣe, kò sì ní lè ronú lọ́nà tó tọ́. (Sm 36:1-4) Ó lè sọ pé òun ń jọ́sìn Ọlọ́run, àmọ́ ó ka ọgbọ́n èèyàn sí ju ti Ọlọ́run lọ. (Ais 29:13, 14) Tó bá ń hùwàkiwà, ó máa ń ronú pé “eré” lásán lòun ń ṣe (Owe 10:23) ìyẹn máa ń jẹ́ kó hùwà àìnítìjú, ìwà ipá, kó sì máa ronú bí òmùgọ̀ débi táá fi máa rò pé Ọlọ́run ò rí àwọn nǹkan tóun ń ṣe. (Sm 94:4-10; Ais 29:15, 16; Jer 10:21) Àwọn nǹkan tó ń ṣe àti bó ṣe ń gbé ìgbésí ayé ẹ̀ fi hàn pé kò gbà pé Jèhófà wà, (Sm 14:1-3) kì í sì í rí ti Jèhófà rò tó bá fẹ́ ṣèpinnu. Torí pé kì í tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà, kì í lóye ọ̀rọ̀ dáadáa, kò lè ronú lọ́nà tó tọ́, kò sì lè ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání.—Owe 28:5.
it-1 1211 ¶4
Ìwà Títọ́
Tẹ́nì kan bá fẹ́ pa ìwà títọ́ mọ́, kò ní gbára lé agbára ẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ó gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀, kó sì gbà pé Jèhófà lágbára láti gba òun là. (Sm 25:21) Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa jẹ́ “apata” àti “ibi ààbò,” fún àwọn tó ń rìn nínú ìwà títọ́. (Owe 2:6-8; 10:29; Sm 41:12) Torí pé bí wọ́n ṣe máa rí ojú rere Ọlọ́run ló jẹ wọ́n lógún, ìgbésí ayé wọn máa ń nítumọ̀, ohun tí wọ́n dáwọ́ lé sì máa ń yọrí sí rere. (Sm 26:1-3; Owe 11:5; 28:18) Jóòbù kíyè sí pé àwọn aláìlẹ́bi máa ń jìyà tí àwọn ẹni burúkú bá ń ṣàkóso, nígbà míì wọ́n sì máa ń kú pẹ̀lú àwọn èèyàn burúkú. Àmọ́ Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ pé òun mọ ohun táwọn aláìlẹ́bi ń bá yí, ó fi dá wọn lójú pé ogún wọn máa wà títí láé, wọ́n máa gbádùn àlàáfíà lọ́jọ́ iwájú, wọ́n sì máa ní àwọn ohun rere. (Job 9:20-22; Sm 37:18, 19, 37; 84:11; Owe 28:10) Bó ṣe rí lọ́rọ̀ ti Jóòbù, kì í ṣe bí ẹnì kan ṣe lówó tó ló máa mú kó níyì lójú Jèhófà bí kò ṣe bó ṣe pa ìwà títọ́ mọ́. (Owe 19:1; 28:6) Tí òbí kan bá ń pa ìwà títọ́ mọ́, àwọn ọmọ ẹ̀ máa láyọ̀ (Owe 20:7), wọ́n á ní àpẹẹrẹ tó dáa láti tẹ̀ lé, àwọn èèyàn á sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn torí orúkọ rere tí òbí wọn ní.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
O Lè Yẹra fún Àrùn Ọkàn Nípa Tẹ̀mí
Dídá ara ẹni lójú jù. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí àrùn ọkàn kọlù ló gbà pé kokooko lara àwọn le, kó tó di pé àrùn ọkàn kọlù wọ́n. Wọn kì í sábàá lọ fún àyẹ̀wò lọ́dọ̀ dókítà, wọ́n tilẹ̀ lè sọ pé ìranù ni. Bákan náà, àwọn kan lè máa fọwọ́ sọ̀yà pé níwọ̀n bí ọjọ́ ti pẹ́ táwọn ti ń bá a bọ̀ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, mìmì kan ò lè mi àwọn. Wọ́n lè dágunlá sí lílọ fún àyẹ̀wò nípa tẹ̀mí, títí wàhálà á fi dé. Ó ṣe pàtàkì láti rántí ìmọ̀ràn rere tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnni nípa ṣíṣàì dá ara ẹni lójú jù. Ó sọ pé: “Kí ẹni tí ó bá rò pé òun dúró kíyè sára kí ó má bàa ṣubú.” Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká fi sọ́kàn pé ẹ̀dá aláìpé ni wá, ká sì máa yẹ ara wa wò lóòrèkóòrè.—1 Kọ́ríńtì 10:12; Òwe 28:14