ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwbr25 September ojú ìwé 1-13
  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú “Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú “Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni”
  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé—2025
  • Ìsọ̀rí
  • SEPTEMBER 1-7
  • SEPTEMBER 8-14
  • SEPTEMBER 15-21
  • SEPTEMBER 22-28
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
  • SEPTEMBER 29–OCTOBER 5
  • OCTOBER 6-12
  • OCTOBER 13-19
  • OCTOBER 20-26
  • OCTOBER 27–NOVEMBER 2
Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé—2025
mwbr25 September ojú ìwé 1-13

Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni

© 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania

SEPTEMBER 1-7

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 29

Má Ṣe Lọ́wọ́ sí Àwọn Àṣà Tí Kò Bá Bíbélì Mu

wp16.06 6, àpótí

Àwọn Ìran Tó Sọ Àwọn Tó ń gbé Ní Ọ̀run

Bí ọ̀daràn tí wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ de ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ pa, bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ àwọn èèyàn tó ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ohun asán ṣe rí. Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló ń bẹ̀rù àwọn ẹ̀mí èṣù. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi gbọ́kàn lé oríṣiríṣi oògùn ìṣọ́ra bíi, ìfúnpá, ońdè àti tírà, láti dáàbò bo ara wọn. Kò sídìí fún ẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Ní ti Jèhófà, ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíróníkà 16:9) Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ lágbára ju Sátánì lọ fíìfíì, ó sì máa dáàbò bò ẹ́ tó o bá gbẹ́kẹ̀ lé E.

Tó o bá fẹ́ kí Jèhófà dáàbò bò ẹ́, o gbọ́dọ̀ mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́, kó o sì máa ṣe é. Bí àpẹẹrẹ, ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn Kristẹni ní ìlú Éfésù kó gbogbo àwọn ìwé ìbẹ́mìílò wọn jáde, wọ́n sì dáná sun wọ́n. (Ìṣe 19:19, 20) Bákan náà, tó o bá fẹ́ kí Ọlọ́run máa dáàbò bò ẹ́, o gbọ́dọ̀ da gbogbo oògùn ìṣọ́ra nù àti ìgbàdí, ońdè, tírà, ìwé idán, àwọn okùn “ààbò,” pẹ̀lú gbogbo ohun tó bá ní ín ṣe pẹ̀lú agbára òkùnkùn.

w19.04 17 ¶13

Rọ̀ Mọ́ Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ipò Táwọn Òkú Wà

13 Tí o kò bá mọ̀ bóyá àṣà kan bá Bíbélì mu tàbí kò bá a mu, gbàdúrà sí Jèhófà, kó o bẹ̀ ẹ́ pé kó fún ẹ lọ́gbọ́n láti ṣèpinnu tó tọ́. (Ka Jémíìsì 1:5.) Lẹ́yìn náà, ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa. O sì lè kàn sáwọn alàgbà ìjọ rẹ. Fi sọ́kàn pé wọn ò ní ṣèpinnu fún ẹ, àmọ́ wọ́n lè tọ́ka sáwọn ìlànà Bíbélì tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́, bí irú èyí tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí. Tó o bá ṣe àwọn nǹkan yìí, ṣe lò ń kọ́ “agbára ìfòyemọ̀” rẹ, èyí á sì jẹ́ kó o lè “fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”—Héb. 5:14.

w18.11 11 ¶12

“Èmi Yóò Máa Rìn Nínú Òtítọ́ Rẹ”

12 Àwọn àṣà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Àwọn mọ̀lẹ́bí wa, àwọn ọmọ iléèwé wa àtàwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ lè fẹ́ ká jọ máa ṣe àwọn ayẹyẹ kan. Kí ló yẹ ká ṣe tá ò bá fẹ́ lọ́wọ́ sí àwọn àṣà àtàwọn àjọ̀dún tí inú Jèhófà ò dùn sí? Ohun tá a lè ṣe ni pé ká máa ronú nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀. A lè ṣe ìwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa nípa ibi tí irú àwọn àjọ̀dún bẹ́ẹ̀ ti ṣẹ̀ wá. Tá a bá ń rántí ìdí tí àwọn àjọ̀dún yẹn ò fi bá Ìwé Mímọ́ mu, á dá wa lójú pé a ṣì ń rìn lójú ọ̀nà “tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa.” (Éfé. 5:10) Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tá a sì gbà pé òótọ́ lohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, a ò ní ‘wárìrì nítorí ènìyàn.’—Òwe 29:25.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

w17.10 9 ¶11

“Kí A Nífẹ̀ẹ́ . . . ní Ìṣe àti Òtítọ́”

11 Máa gbóríyìn fáwọn ará látọkàn wá. Ó yẹ ká máa gbóríyìn fáwọn ará torí pé irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń gbéni ró. (Éfé. 4:29) Àmọ́, a gbọ́dọ̀ rí i pé a gbóríyìn fún wọn látọkàn wá. Tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ṣe là ń gbé wọn gẹṣin aáyán, ìyẹn ò sì ní jẹ́ ká fún wọn nímọ̀ràn tó máa ṣe wọ́n láǹfààní. (Òwe 29:5) Tá a bá ń gbóríyìn fún ẹnì kan níṣojú rẹ̀ àmọ́ tá a wá ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ láìdáa lẹ́yìn, ìwà àgàbàgebè là ń hù. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀, ó gbóríyìn fáwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì nígbà tí wọ́n ṣe ohun tó dáa. (1 Kọ́r. 11:2) Àmọ́ nígbà tí wọ́n ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó, ó fara balẹ̀ ṣàlàyé ìdí tí ohun tí wọ́n ṣe ò fi dáa, kò sì kàn wọ́n lábùkù.—1 Kọ́r. 11:20-22.

SEPTEMBER 8-14

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 30

“Má Ṣe Fún Mi Ní Òṣì Tàbí Ọrọ̀”

w18.01 24-25 ¶10-12

Ìfẹ́ Wo Ló Ń Mú Kéèyàn Ní Ojúlówó Ayọ̀?

10 Gbogbo wa la nílò owó, torí pé ó máa ń dáàbò boni déwọ̀n àyè kan. (Oníw. 7:12) Àmọ́ ṣé èèyàn á láyọ̀ lóòótọ́ tó bá jẹ́ pé ìwọ̀nba owó táá fi gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ nìkan ló ní? Bẹ́è ni! (Ka Oníwàásù 5:12.) Ágúrì ọmọkùnrin Jákè sọ pé: “Má ṣe fún mi ní ipò òṣì tàbí ti ọrọ̀. Jẹ́ kí n jẹ ìwọ̀n oúnjẹ tí ó jẹ́ ìpín tèmi.” A lóye ìdí tó fi bẹ Jèhófà pé kó má jẹ́ kóun tòṣì. Ó sọ síwájú sí i pé òun ò fẹ́ jalè torí pé ìyẹn máa tàbùkù sí orúkọ Ọlọ́run. Àmọ́ kí nìdí tó fi gbàdúrà pé kí Ọlọ́run má ṣe fún òun ní ọrọ̀? Ó ní: “Kí n má bàa yó tán kí n sì sẹ́ ọ ní ti tòótọ́, kí n sì wí pé: ‘Ta ni Jèhófà?’ ” (Òwe 30:8, 9) Ó ṣeé ṣe kíwọ náà mọ àwọn kan tó gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ dípò Ọlọ́run.

11 Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ owó ò lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Jésù sọ pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì; nítorí yálà òun yóò kórìíra ọ̀kan, kí ó sì nífẹ̀ẹ́ èkejì, tàbí òun yóò fà mọ́ ọ̀kan, kí ó sì tẹ́ńbẹ́lú èkejì. Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.” Ó ti kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ kan ṣáájú èyí, ó ní: “Ẹ dẹ́kun títo àwọn ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín lórí ilẹ̀ ayé, níbi tí òólá àti ìpẹtà ti ń jẹ nǹkan run, àti níbi tí àwọn olè ti ń fọ́lé, tí wọ́n sì ń jalè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run, níbi tí òólá tàbí ìpẹtà kò lè jẹ nǹkan run, àti níbi tí àwọn olè kò lè fọ́lé, kí wọ́n sì jalè.”—Mát. 6:19, 20, 24.

12 Ọ̀pọ̀ ló ti rí i pé àwọn ń láyọ̀ àwọn sì túbọ̀ ń ráyè sin Jèhófà báwọn ṣe jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ àwọn lọ́rùn. Arákùnrin Jack tó ń gbé ní Amẹ́ríkà ta ilé àti ilé iṣẹ́ rẹ̀ kó lè ráyè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà bíi ti ìyàwó rẹ̀. Ó sọ pé: “Kò rọrùn fún wa láti dórí ìpinnu pé ká ta ilé wa torí pé àwòṣífìlà nilé ọ̀hún, ó sì wà lágbègbè tó fini lọ́kàn balẹ̀. Pẹ̀lú gbogbo ẹ̀ náà, ọ̀pọ̀ ọdún ló jẹ́ pé inú mi kì í dùn tí mo bá dé láti ibi iṣẹ́, nítorí àwọn ìṣòro tí mo máa ń kojú níbẹ̀. Àmọ́ ṣe ni inú ìyàwó mi tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé máa ń dùn ní tiẹ̀. Ó máa ń sọ fún mi pé, ‘Ọ̀gá tó dáa jù lọ ni mò ń bá ṣiṣẹ́!’ Ní báyìí témi náà ti di aṣáájú-ọ̀nà, a ti jọ wà lábẹ́ Ọ̀gá kan náà, ìyẹn Jèhófà.”

w17.05 26 ¶15-17

“Ìwọ Ha Nífẹ̀ẹ́ Mi Ju Ìwọ̀nyí Lọ Bí?”

15 Lóde òní, ohun tó jẹ ọ̀pọ̀ èèyàn lógún ni àwọn nǹkan tó lòde, bí aṣọ, fóònù, àtàwọn nǹkan míì. Torí náà, ó ṣe pàtàkì kẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa ṣàyẹ̀wò ọkàn rẹ̀, ká bi ara wa pé: ‘Ṣé kì í ṣe bí mo ṣe máa ní ọkọ̀ tó le ńlẹ̀ àtàwọn aṣọ tó lòde ni mò ń rò ṣáá tí mo sì ń wá kiri débi pé mi ò ń ráyè múra ìpàdé? Ṣé àwọn nǹkan tara tí mò ń ṣe lójoojúmọ́ ló ń gba gbogbo àkókò mi tí mi ò fi ń ráyè gbàdúrà tàbí ka Bíbélì?’ Tá a bá kíyè sí i pé ìfẹ́ tá a ní fáwọn nǹkan tara ti ń mú kí ìfẹ́ tá a ní fún Kristi jó rẹ̀yìn, á dáa ká ronú lórí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, pé: “Ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò.” (Lúùkù 12:15) Kí nìdí tí Jésù fi ṣe ìkìlọ̀ tó lágbára bẹ́ẹ̀?

16 Jésù sọ pé “kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì.” Ó tún sọ pé: “Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.” Ìdí sì ni pé àwọn “ọ̀gá” méjèèjì yìí fẹ́ kéèyàn fi gbogbo ọkàn sin àwọn. Jésù wá sọ pé, èèyàn máa ní láti “kórìíra ọ̀kan, kí ó sì nífẹ̀ẹ́ èkejì” tàbí kéèyàn “fà mọ́ ọ̀kan, kí ó sì tẹ́ńbẹ́lú èkejì.” (Mát. 6:24) Torí pé a jẹ́ aláìpé, a gbọ́dọ̀ máa sapá kí “àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara wa” má bàa borí wa, títí kan àwọn nǹkan tara.—Éfé. 2:3.

17 Àwọn tó fẹ́ràn nǹkan tara kì í ro nǹkan míì ju bí wọ́n ṣe máa ní tibí ní tọ̀hún. Ìdí sì ni pé èrò wọn ò bá ti Ọlọ́run mu. (Ka 1 Kọ́ríńtì 2:14.) Torí pé agbára ìwòye wọn kò já geere, ó ṣòro fún wọn láti fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. (Héb. 5:11-14) Ìyẹn ló fà á tó fi jẹ́ pé àwọn nǹkan tara ni wọ́n máa ń lé ṣáá, síbẹ̀ wọn kì í ní ìtẹ́lọ́rùn. (Oníw. 5:10) Àmọ́ o, ṣíṣe kù, téèyàn ò bá fẹ́ kí àwọn ohun ìní tara gba òun lọ́kàn jù, ó ṣe pàtàkì kó máa ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. (1 Pét. 2:2) Torí pé Jésù máa ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó ṣeé ṣe fún un láti borí ìdẹwò. Táwa náà bá ń fàwọn ìlànà Jèhófà sílò, a ò ní máa lépa àwọn nǹkan ìní tara. (Mát. 4:8-10) Nípa bẹ́ẹ̀, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jésù ju àwọn nǹkan ìní tara lọ.

w11 6/1 10 ¶3

Ṣe Bó O Ti Mọ—Bí O Ṣe Lè Ṣe É

Tọ́jú owó pa mọ́ fún nǹkan tó o fẹ́ rà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé títọ́jú owó pa mọ́ fún nǹkan téèyàn fẹ́ rà lè jọ àṣà ayé àtijọ́, òun ni ọ̀nà tó bọ́gbọ́n mu jù lọ téèyàn lè gbà yẹra fún gbèsè. Ṣíṣe èyí ti gba ọ̀pọ̀ èèyàn nínú gbèsè àti àìbalẹ̀ ọkàn téèyàn máa ń ní, nítorí owó èlé gegere tó má ń wà lórí nǹkan téèyàn rà láwìn. Bíbélì ṣàpèjúwe eèrà pé ó ní “ọgbọ́n” nítorí ó máa ń kó “àwọn ìpèsè oúnjẹ rẹ̀ jọ àní nígbà ìkórè” fún ìlò ọjọ́ iwájú.—Òwe 6:6-8; 30:24, 25.

w24.06 13 ¶18

Má Kúrò Nínú Ilé Jèhófà Láé!

18 Ó ṣe pàtàkì ká bi ara wa láwọn ìbéèrè kan ká lè mọ ojú tá a fi ń wo owó. Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé gbogbo ìgbà ni mo máa ń ronú nípa owó àtàwọn nǹkan tí mo fẹ́ fi owó rà? Tí mo bá yáwó, ṣé mo máa ń tètè san án pa dà àbí ṣe ni mo máa ń rò pé ẹni tó yá mi lówó náà lówó lọ́wọ́ torí náà kò pọn dandan kí n dá a pa dà? Ṣé owó tí mo ní máa ń jẹ́ kí n ronú pé mo dáa ju àwọn míì lọ, ṣé ó sì máa ń ṣòro fún mi láti lawọ́ sáwọn èèyàn? Ṣé mi kì í fẹ̀sùn kan àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mi pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ owó torí pé wọ́n lówó lọ́wọ́? Ṣé àwọn tó lówó nìkan ni mo máa ń mú lọ́rẹ̀ẹ́, bẹ́ẹ̀ sì rèé, mi ò fi bẹ́ẹ̀ gba tàwọn tálákà?’ Àǹfààní ńlá la ní pé a jẹ́ àlejò nínú àgọ́ Jèhófà. Torí náà, a lè fi hàn pé a mọyì àǹfààní yìí tá a bá ń sá fún ìfẹ́ owó. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀ láé!—Ka Hébérù 13:5.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

w09 4/15 17 ¶11-13

Àwọn Ìṣẹ̀dá Jèhófà Ń Fi Ọgbọ́n Rẹ̀ Hàn

11 Ẹranko kan tó ń jẹ́ gara orí àpáta tún jẹ́ ẹ̀dá míì tó kéré díẹ̀, àmọ́ tó lè kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì. (Ka Òwe 30:26.) Ó fẹ́ jọ ehoro ńlá, àmọ́ ẹsẹ̀ tiẹ̀ kúrú, róbótó ni etí tiẹ̀ rí, kò gún tó ti ehoro. Ibi àpáta ni ẹranko kékeré yìí máa ń gbé. Ojú rẹ̀ tó máa ń ríran gan-an yẹn ló fi ń dáàbò bo ara rẹ̀, inú ihò àti pàlàpálá àpáta tó fi ṣelé ló sì máa ń tètè sá wọ̀ kọ́wọ́ ohun tó bá fẹ́ pa á jẹ má bàa tẹ̀ ẹ́. Bí ọ̀pọ̀ àwọn gara orí àpáta tún ṣe máa ń gbé pa pọ̀ tí wọ́n sì máa ń wà pọ̀ tímọ́tímọ́ tún máa ń jẹ́ kára tù wọ́n, ààbò lèyí jẹ́ fún wọn, kì í sì í jẹ́ kí òtútù lù wọ́n pa nígbà òtútù.

12 Kí la lè rí kọ́ lára gara orí àpáta? Kọ́kọ́ kíyè sí i pé ẹranko yìí kì í wà níbi tí ọwọ́ ọ̀tá ti lè tó o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń lo àǹfààní ojú rẹ̀ tó máa ń ríran gan-an láti rí ohun tó bá fẹ́ pa á jẹ látọ̀ọ́kán, kì í sì í jìnnà sétí ihò àti pàlàpálá àpáta táá lè sá wọ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ káwa náà wà lójúfò, ká lè tètè fòye mọ àwọn ewu tó fara sin sínú ayé Sátánì yìí. Àpọ́sítélì Pétérù gba àwa Kristẹni nímọ̀ràn pé: “Ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyè sára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” (1 Pét. 5:8) Nígbà tí Jésù wà láyé, kò fìgbà kankan gbàgbéra, ó wà lójúfò sí gbogbo ọgbọ́n tí Sátánì ń ta láti ba ìgbàgbọ́ rẹ̀ jẹ́. (Mát. 4:1-11) Àpẹẹrẹ rere mà ni Jésù fi lélẹ̀ fáwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀ o!

13 Ọ̀nà kan tá a lè gbà wà lójúfò ni pé ká má ṣe kúrò lábẹ́ ààbò Jèhófà. A gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti lílọ sípàdé déédéé. (Lúùkù 4:4; Héb. 10:24, 25) Bákan náà, ńṣe ni ara máa ń tu gara orí àpáta nígbà tó bá wà láàárín àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ wà pọ̀ tímọ́tímọ́. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe yẹ káwa náà máa sún mọ́ àwọn ará wa ká bàa lè jọ máa fún ara wa ní “pàṣípààrọ̀ ìṣírí.” (Róòmù 1:12) Tá a bá fi ara wa sábẹ́ ààbò Jèhófà, à ń fi hàn pé a fara mọ́ ohun tí Dáfídì onísáàmù náà sọ nìyẹn, pé: “Jèhófà ni àpáta gàǹgà mi àti odi agbára mi àti Olùpèsè àsálà fún mi. Ọlọ́run mi ni àpáta mi. Èmi yóò sá di í.”—Sm. 18:2.

SEPTEMBER 15-21

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 31

Ohun Tá A Kọ́ Látinú Ìmọ̀ràn Onífẹ̀ẹ́ Tí Ìyá Kan Fún Ọmọ Ẹ̀

w11 2/1 19 ¶7-8

Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ ní Ohun Tó Tọ́ Nípa Ìbálòpọ̀

Kọ́ wọn ní gbogbo ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa ìbálòpọ̀. Ó yẹ kó o kìlọ̀ fún wọn. (1 Kọ́ríńtì 6:18; Jákọ́bù 1:14, 15) Àmọ́, Bíbélì fi hàn pé ìbálòpọ̀ jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kì í ṣe páńpẹ́ Sátánì. (Òwe 5:18, 19; Orin Sólómọ́nì 1:2) Tó bá jẹ́ pé ewu tó wà nínú ìbálòpọ̀ nìkan lò ń sọ fún àwọn ọmọ rẹ tí kò tíì pé ogún ọdún, èyí lè mú kí wọ́n ní èrò tí kò tọ́ nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀ràn náà. Ọ̀dọ́bìnrin kan láti ilẹ̀ Faransé tó ń jẹ́ Corrina sọ pé: “Ọ̀rọ̀ pé ìbálòpọ̀ kò dáa làwọn òbí mi máa ń ránnu mọ́ ṣáá, èyí sì mú kí n máa fojú burúkú wo ìbálòpọ̀.”

Rí i dájú pé àwọn ọmọ rẹ mọ gbogbo òtítọ́ nípa ìbálòpọ̀. Ìyá kan nílẹ̀ Mẹ́síkò tó ń jẹ́ Nadia sọ pé: “Ohun tí mo máa ń fi yé àwọn ọmọ mi ni pé ìbálòpọ̀ dára, kò sì lòdì sí ìwà ẹ̀dá àti pé Jèhófà Ọlọ́run fi fún àwọn èèyàn láti gbádùn rẹ̀ ni. Àmọ́, àwọn tó ti ṣègbéyàwó ló wà fún. Ìbálòpọ̀ lè mú ká láyọ̀ tàbí kí ó kó ìpọ́njú bá wa, ìyẹn sì wà lọ́wọ́ bí a bá ṣe lò ó.”

ijwhf àpilẹ̀kọ 4 ¶11-13

Bó O Ṣe Lè Bá Ọmọ Ẹ Sọ̀rọ̀ Nípa Ọtí

Ìwọ ni kó o dá ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀. Mark, tó jẹ́ bàbá ọlọ́mọ nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé, “Ọ̀rọ̀ ọtí kì í sábà yé àwọn ọmọdé. Mo bi ọmọkùnrin mi ọlọ́dún mẹ́jọ bóyá ó dáa kéèyàn mu ọtí àbí kò dáa. Mo rí i pé mo fi í lára balẹ̀, mi ò sì mú ọ̀rọ̀ náà le, èyí jẹ́ kó lè sọ bó ṣe rí lára ẹ̀ láìbẹ̀rù.”

Tó o bá ń dá ọ̀rọ̀ nípa ọtí sílẹ̀ léraléra, ohun tó o bá sọ á túbọ̀ wọ àwọn ọmọ ẹ lọ́kàn. Bí ọmọ ẹ bá ṣe dàgbà tó, ó lè mú àwọn ọ̀rọ̀ míì mọ́ ọn tẹ́ ẹ bá ń sọ̀rọ̀ nípa ọtí, irú bí ọ̀rọ̀ sísọdá títì àti ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀.

Fi àpẹẹrẹ lélẹ̀. Bíi tìmùtìmù làwọn ọmọdé rí, ohun tí wọ́n ń rí láyìíká wọn máa ń tètè ràn wọ́n, bí ìgbà tí tìmùtìmù bá fa omi. Ìwádìí sì fi hàn pé àwọn òbí ló máa ń nípa tó pọ̀ jù lórí àwọn ọmọ wọn. Ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé, tó bá jẹ́ pé ọtí lo fi máa ń tura ṣáá tó bá ti rẹ̀ ẹ́, ohun tó ò ń dọ́gbọ́n sọ fún ọmọ ẹ ni pé ọtí lèèyàn fi ń yanjú ìṣòro láyé yìí. Torí náà, àpẹẹrẹ rere ni kó o jẹ́. Rí i pé ò ń hùwà ọmọlúàbí tó bá dọ̀rọ̀ ọtí mímu.

g17.6 9 ¶5

Bó O Ṣe Lè Kọ́ Ọmọ Rẹ Ní Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀

Kọ́ ọmọ rẹ láti jẹ́ ọ̀làwọ́. Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ̀ pé “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Báwo lo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ẹ lè jọ kọ orúkọ àwọn kan sílẹ̀ tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́, bóyá tẹ́ ẹ lè lọ bá ra nǹkan lọ́jà, tẹ́ ẹ lè lọ fi ọkọ̀ gbé tàbí tẹ́ ẹ lè bá tún àwọn nǹkan tó bà jẹ́ ṣe. Kó o sì mú ọmọ rẹ dání nígbà tó o bá fẹ́ lọ ran àwọn ẹni náà lọ́wọ́. Jẹ́ kí ọmọ rẹ rí i pé inú ìwọ òbí rẹ̀ ń dùn, ọkàn rẹ sì balẹ̀ bó o ṣe ń ran àwọn míì lọ́wọ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lò ń kọ́ ọmọ rẹ ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ lọ́nà tó dáa jù lọ, ìyẹn nípa àpẹẹrẹ ìwọ fúnra rẹ.—Ìlànà Bíbélì: Lúùkù 6:38.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

w25.01 13 ¶16

Ẹ̀yin Ọkọ, Ẹ Máa Bọlá fún Ìyàwó Yín

16 Sọ fún un pé o mọyì ẹ̀ gan-an. Ọkọ tó ń bọlá fún ìyàwó ẹ̀ máa ń fún un níṣìírí, ó sì máa ń jẹ́ kórí ẹ̀ wú. Ó máa ń rántí láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ìyàwó ẹ̀ torí gbogbo ohun tó ń ṣe láti tì í lẹ́yìn. (Kól. 3:15) Tí ọkọ bá ń yin ìyàwó ẹ̀ látọkàn wá, ó máa múnú ìyàwó ẹ̀ dùn gan-an. Ọkàn ìyàwó ẹ̀ á balẹ̀, á mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ òun, ó sì ń bọlá fóun.—Òwe 31:28.

SEPTEMBER 22-28

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ONÍWÀÁSÙ 1-2

Ẹ Túbọ̀ Máa Dá Àwọn Ìran Tó Ń Bọ̀ Lẹ́kọ̀ọ́

w17.01 27-28 ¶3-4

Fi ‘Nǹkan Wọ̀nyí Lé Àwọn Olùṣòtítọ́ Lọ́wọ́’

3 Ọ̀pọ̀ wa ló fẹ́ràn iṣẹ́ tá à ń ṣe, ó sì wù wá pé ká máa ṣe iṣẹ́ náà lọ. Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé láti ìgbà ayé Ádámù ni nǹkan ti yí bìrí, tó wá di pé bí ìran kan ṣe ń darúgbó ni ìran míì ń bọ́ sójú ọpọ́n. (Oníw. 1:4) Torí èyí, àwọn ìpèníjà kan ti yọjú láàárín àwa èèyàn Jèhófà lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Bí àpẹẹrẹ, iṣẹ́ táwa èèyàn Jèhófà ń ṣe túbọ̀ ń tẹ̀ síwájú lójoojúmọ́, ó sì ń gbòòrò sí i. Bá a ṣe ń ṣe àwọn nǹkan tuntun, bẹ́ẹ̀ là ń rí àwọn ọ̀nà tuntun tá a lè gbà ṣe wọ́n, kódà ó lè gba pé ká lo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé nígbà míì. Torí náà, kì í rọrùn fáwọn tó ti dàgbà láti bójú tó àwọn iṣẹ́ tuntun tó ń yọjú yìí. (Lúùkù 5:39) Ká tiẹ̀ sọ pé àwọn àgbàlagbà yìí lè ṣe àwọn iṣẹ́ náà, àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ dàgbà tó wọn lọ́jọ́ orí ṣì lágbára àti okun jù wọ́n lọ. (Òwe 20:29) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé káwọn àgbàlagbà dá àwọn tí kò tó wọn lọ́jọ́ orí lẹ́kọ̀ọ́ láti bójú tó àwọn ojúṣe pàtàkì nínú ètò Ọlọ́run.—Ka Sáàmù 71:18.

4 Ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fáwọn tó ń múpò iwájú láti gbé lára iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe fáwọn tí kò tó wọn lọ́jọ́ orí. Ìdí sì ni pé inú àwọn kan kì í dùn tó bá di pé kí wọ́n gbéṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe fáwọn míì. Ó máa ń ká àwọn míì lára pé àwọn ò ní lè bójú tó àwọn ojúṣe kan mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò dá wọn lójú pé àwọn tí kò tó wọn lọ́jọ́ orí á lè ṣe iṣẹ́ náà dáadáa. Àwọn kan sì lè ronú pé àwọn ò lè ráyè dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. Bó ti wù kó rí, kò yẹ káwọn tí kò tó àwọn àgbàlagbà lọ́jọ́ orí bínú bí wọn ò bá fún wọn láfikún iṣẹ́, ṣe ló yẹ kí wọ́n ṣe sùúrù.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

lff ẹ̀kọ́ 37 kókó 1

Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Iṣẹ́ àti Owó

1. Kí ni Bíbélì sọ nípa iṣẹ́?

Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbádùn iṣẹ́ wa. Bíbélì sọ pé: “Kò sóhun tó dáa fún èèyàn ju pé kó . . . gbádùn iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.” (Oníwàásù 2:24) Òṣìṣẹ́ kára ni Jèhófà. Táwa náà bá ń ṣiṣẹ́ kára bíi ti Jèhófà, a máa múnú ẹ̀ dùn, inú tiwa náà á sì máa dùn.

Iṣẹ́ ṣe pàtàkì gan-an. Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí iṣẹ́ ṣe pàtàkì sí wa débi tá ò fi ní ráyè máa sin Jèhófà bó ṣe yẹ. (Jòhánù 6:27) Jèhófà ṣèlérí pé tá a bá ń fi ìjọsìn òun sí ipò àkọ́kọ́, òun á máa tọ́jú wa.

SEPTEMBER 29–OCTOBER 5

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ONÍWÀÁSÙ 3-4

Ẹ̀yin Tọkọtaya, Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Kí Okùn Onífọ́nrán Mẹ́ta Yín Já

ijwhf àpilẹ̀kọ 10 ¶2-8

Bó Ò Ṣe Ní Jẹ́ Kí Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Gbà Ẹ́ Lọ́kàn

● Ẹ̀rọ ìgbàlódé lè ṣe àwọn tọkọtaya láǹfààní tí wọ́n bá fọgbọ́n lò ó. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tọkọtaya kan máa ń lò ó láti bára wọn sọ̀rọ̀ nígbà tí wọn ò bá sí pa pọ̀.

“Tó o bá tẹ àtẹ̀jíṣẹ́ pé ‘Mo nífẹ̀ẹ́ ẹ’ tàbí ‘Ọkàn mi fà sí ẹ’ lè mú kí àárín yín gún régé.”—Jonathan.

● Tèèyàn ò bá fọgbọ́n lo ẹ̀rọ ìgbàlódé, ó lè ṣàkóbá fún ìgbéyàwó. Bí àpẹẹrẹ, gbogbo ìgbà làwọn kan máa ń lo fóònù tàbí tábúlẹ́ẹ̀tì wọn, ó sì máa ń gba gbogbo àkókò tó yẹ kí wọ́n lò pẹ̀lú ọkọ tàbí ìyàwó wọn wọn.

“Lọ́pọ̀ ìgbà, mo mọ̀ pé ó máa ń wu ọkọ mi láti bá mi sọ̀rọ̀, àmọ́ fóònù tí mò ń tẹ̀ kò jẹ́ ká fẹ́ sọ̀rọ̀.”—Julissa.

● Àwọn kan sọ pé àwọn lè máa bá ọkọ tàbí aya àwọn sọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì káwọn sì máa lo fóònù wọn lásìkò kan náà. Sherry Turkle tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá sọ pé “àlá tí kò lè ṣẹ ni tẹ́nì kan bá rò pé òun lè ṣe nǹkan méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà.” Kódà, ó ní kì í ṣe ìwà ọmọlúwàbí. Ó tún sọ pé, “òótọ́ kan ni pé kò sí bá a ṣe lè gbìyànjú láti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ́ẹ̀kan náà tí àwọn nǹkan ọ̀hún sì máa dáa.”

“Mo máa ń gbádùn àkókò témi àtọkọ mi fi máa ń sọ̀rọ̀ gan-an, àmọ́ kì í ṣègbà tó bá ń ṣe nǹkan méjì tàbí mẹ́ta lẹ́ẹ̀kan náà. Tó bá ti ń ṣe nǹkan méjì tàbí mẹ́tà lẹ́ẹ̀kan náà, ó máa ń ṣe mí bíi pé ohun tó ń ṣe yẹn ló jẹ ẹ́ lógún jù, kò sì fẹ́ mọ̀ bóyá mo wà pẹ̀lú òun tàbí mi ò sí.”—Sarah.

Kókó ibẹ̀: Bó o ṣe ń lo ẹ̀rọ ìgbàlódé lè ṣe ìgbéyàwó rẹ láǹfààní tàbí kó ṣàkóbá fún un.

w23.05 23-24 ¶12-14

Ẹ̀yin Tọkọtaya, Ẹ Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Yín Dà Bí “Ọwọ́ Iná Jáà”

12 Báwo lẹ̀yin tọkọtaya ṣe lè fara wé Ákúílà àti Pírísílà? Ronú nípa ọ̀pọ̀ nǹkan tí ẹ̀yin méjèèjì fẹ́ ṣe. Ṣé ẹ lè jọ ṣe díẹ̀ lára ẹ̀ dípò kí ìwọ nìkan dá ṣe gbogbo ẹ̀? Bí àpẹẹrẹ, Ákúílà àti Pírísílà jọ máa ń wàásù. Ṣé ẹ̀yin náà máa ń ṣètò àkókò yín kẹ́ ẹ lè jọ máa wàásù? Yàtọ̀ síyẹn, Ákúílà àti Pírísílà jọ máa ń ṣiṣẹ́. Iṣẹ́ tí ẹ̀yin méjèèjì ń ṣe lè yàtọ̀ síra, àmọ́ ṣé ẹ lè jọ máa ṣiṣẹ́ ilé pa pọ̀? (Oníw. 4:9) Tí ẹ bá ń ṣe àwọn iṣẹ́ kan pa pọ̀, ìyẹn máa jẹ́ kẹ́ ẹ túbọ̀ ṣe ara yín lọ́kan, ẹ̀ẹ́ sì tún láǹfààní láti jọ sọ̀rọ̀. Robert àti Linda ti ṣègbéyàwó ní ohun tó lé ní àádọ́ta (50) ọdún. Robert sọ pé: “Kí n sòótọ́, a kì í fi bẹ́ẹ̀ ráyè jọ ṣeré jáde. Àmọ́ tí mo bá ń fọ abọ́, tí ìyàwó mi sì ń nù ún tàbí tí mo bá ń gé koríko níta, tí ìyàwó mi sì wá ràn mí lọ́wọ́, inú mi máa ń dùn gan-an. Bá a ṣe jọ ń ṣe nǹkan pa pọ̀ ń mú ká túbọ̀ fà mọ́ra wa. Ìyẹn sì ti jẹ́ kí ìfẹ́ wa lágbára gan-an.”

13 Ẹ máa rántí pé tí ọkọ àti ìyàwó kan bá tiẹ̀ wà pa pọ̀, kò túmọ̀ sí pé wọ́n ń ṣe ara wọn lọ́kan. Ìyàwó kan lórílẹ̀-èdè Brazil sọ pé: “Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń fa ìpínyà ọkàn. Torí náà, téèyàn ò bá ṣọ́ra, ó lè máa ronú pé òun ń lo àkókò pẹ̀lú ẹnì kejì òun, ó ṣe tán inú ilé kan náà làwọn ń gbé. Mo ti rí i pé kì í ṣe ká kàn jọ wà pa pọ̀ nìkan, àmọ́ ó tún yẹ ká jọ gbádùn àkókò yẹn.” Ẹ jẹ́ ká wo bí Bruno àti ìyàwó ẹ̀ Tays ṣe ń rí i pé àwọn wáyè fún ara àwọn. Bruno sọ pé: “Tá a bá wà pa pọ̀ láwọn ìgbà tí ọwọ́ wa dilẹ̀, a máa ń gbé fóònù wa jù sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, àá sì jọ gbádùn àkókò yẹn.”

14 Ká sọ pé ẹ̀yin méjèèjì kì í gbádùn àkókò tẹ́ ẹ jọ máa ń lò ńkọ́? Ó lè jẹ́ pé ohun tẹ́ ẹ nífẹ̀ẹ́ sí yàtọ̀ síra, ó sì lè jẹ́ pé ẹnì kejì ẹ láwọn ìwà kan tó máa ń múnú bí ẹ. Kí lo lè ṣe? Ẹ jẹ́ ká tún wo àpẹẹrẹ iná igi tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan. Kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni iná náà máa ràn, táá sì máa jó lala. Ó máa gba pé ká kọ́kọ́ máa ki àwọn igi kéékèèké sínú ẹ̀, lẹ́yìn ìyẹn, a lè wá máa ki igi ńláńlá sínú ẹ̀. Lọ́nà kan náà, ẹ ò ṣe máa lo àkókò díẹ̀ pa pọ̀ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan? Ẹ rí i pé nǹkan tẹ́yin méjèèjì nífẹ̀ẹ́ sí lẹ jọ ń ṣe, kì í ṣe nǹkan tó máa fa èdèkòyédè láàárín yín. (Jém. 3:18) Tẹ́ ẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí í lo àkókò díẹ̀díẹ̀ pa pọ̀, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìfẹ́ tẹ́ ẹ ní síra yín á túbọ̀ jinlẹ̀.

w23.05 20 ¶3

Ẹ̀yin Tọkọtaya, Ẹ Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Yín Dà Bí “Ọwọ́ Iná Jáà”

3 Kí “ọwọ́ iná Jáà” tó lè máa jó láàárín yín, ẹ̀yin tọkọtaya gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára kí àjọṣe yín pẹ̀lú Jèhófà lè lágbára. Báwo nìyẹn ṣe máa mú kí ìfẹ́ tó wà láàárín yín túbọ̀ lágbára? Tí tọkọtaya kan bá mọyì àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà, á rọrùn fún wọn láti máa fi ìmọ̀ràn ẹ̀ sílò, wọn ò ní máa ṣe ohun táá fa ìṣòro, tí ìṣòro bá sì dé, wọ́n á ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti borí ẹ̀ kí ìfẹ́ wọn má bàa di tútù. (Ka Oníwàásù 4:12.) Ó yẹ káwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn náà sapá láti fara wé Jèhófà, kí wọ́n láwọn ìwà tí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká ní bí inúure àti sùúrù, kí wọ́n sì máa dárí ji ara wọn. (Éfé. 4:32–5:1) Ó máa rọrùn fáwọn tọkọtaya tó bá ní àwọn ànímọ́ yìí láti fìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn síra wọn. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Lena, tó sì ti ṣègbéyàwó ní ohun tó lé lọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) sọ pé: “Ó máa ń rọrùn láti nífẹ̀ẹ́ ẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, kéèyàn sì bọ̀wọ̀ fún un.”

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

w22.12 4 ¶7

Jèhófà Fẹ́ Ká Wà Láàyè Títí Láé

7 Jèhófà tún dá wa lọ́nà tó fi jẹ́ pé kì í wù wá pé ká kú. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ti “fi ayérayé sí [wa] lọ́kàn.” (Oníw. 3:11) Ìdí nìyẹn tá a fi gbà pé ọ̀tá wa ni ikú. (1 Kọ́r. 15:26) Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń ṣàìsàn kan tó le, ṣé àá máa wo ara wa níran títí tá a fi máa kú? Rárá. Ó dájú pé a máa lọ sọ́dọ̀ àwọn dókítà, àá sì lo àwọn oògùn tí wọ́n bá fún wa kí àìsàn náà lè lọ. Kódà, gbogbo nǹkan tó bá gbà la máa ṣe ká má bàa kú. Tẹ́nì kan tá a fẹ́ràn bá sì kú, bóyá ọmọdé ni tàbí àgbàlagbà, ó ṣì máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa fún ọ̀pọ̀ ọdún. (Jòh. 11:32, 33) Ó dájú pé Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ ò ní fi sí wa lọ́kàn pé ká wà láàyè títí láé tóun fúnra ẹ̀ ò bá fẹ́ ká wà láàyè títí láé. Àmọ́ àwọn ẹ̀rí míì wà tó jẹ́ ká gbà pé a lè wà láàyè títí láé. Torí náà ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe nígbà àtijọ́ àtàwọn ohun tó ń ṣe báyìí tó fi hàn pé ó ṣì fẹ́ káwa èèyàn wà láàyè títí láé.

OCTOBER 6-12

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ONÍWÀÁSÙ 5-6

Bá A Ṣe Lè Máa Bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Wa Atóbilọ́lá

w08 8/15 15-16 ¶17-18

Máa Ṣe Ohun Tó Ń gbé Iyì Jèhófà Yọ

17 A gbọ́dọ̀ rí i pé a kì í ṣe ohun tó lè tàbùkù sí Jèhófà nígbà ìjọsìn. Oníwàásù 5:1 sọ pé: “Ṣọ́ ẹsẹ̀ rẹ nígbàkigbà tí o bá ń lọ sí ilé Ọlọ́run tòótọ́.” Bí Ọlọ́run ṣe pàṣẹ fún Mósè nígbà kan ló ṣe pàṣẹ fún Jóṣúà náà pé kó bọ́ sálúbàtà rẹ̀ nígbà tó wà ní ibi mímọ́. (Ẹ́kís. 3:5; Jóṣ. 5:15) Àwọn méjèèjì ní láti ṣe bẹ́ẹ̀ láti fi hàn pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run. Ọlọ́run pa á láṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ àlùfáà pé kí wọ́n máa wọ ṣòkòtò tá a fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe “láti [fi] bo ara tí ó wà ní ìhòòhò.” (Ẹ́kís. 28:42, 43) Èyí kò ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni rí ìhòòhò wọn nígbà tí wọ́n bá wà lẹ́nu iṣẹ́ wọn nídìí pẹpẹ. Gbogbo ìdílé àlùfáà pẹ̀lú ló gbọ́dọ̀ máa hùwà tí kò ní tàbùkù sí Ọlọ́run.

18 Èyí fi hàn pé ìjọsìn tó bá máa gbé iyì Ọlọ́run yọ ní láti jẹ́ èyí tá a ṣe tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, láìṣe ohunkóhun tó lè tàbùkù sí Ọlọ́run. Ká tó lè jẹ́ ẹni táwọn èèyàn ń buyì kún tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún, a ní láti yẹra fún ìwà àbùkù. Kò yẹ ká máa fi ẹnu lásán sọ pé a ń hùwà tó buyì kúnni tàbí ká máa ṣe ojú ayé. Ó ní láti wá látinú ọkàn wa lọ́hùn-ún, níbi téèyàn ò lè rí àfi Ọlọ́run. (1 Sám. 16:7; Òwe 21:2) Ó yẹ kí híhùwà tó buyì kúnni mọ́ wa lára, kó máa hàn nínú ìṣe wa àti àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn èèyàn, àní títí kan èrò tá à ń ní nípa ara wa àti irú ojú tá a fi ń wo ara wa pàápàá. Láìsí àní-àní, gbogbo ìgbà ló yẹ ká máa yàgò fún ohun àbùkù, yálà nínú ìṣe wa tàbí ọ̀rọ̀ ẹnu wa. Ní ti ìwà, ìṣe àti ìmúra wa, ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yìí ló yẹ kó máa ró lọ́kàn wa, ó ní: “Kò sí ọ̀nà kankan tí àwa gbà jẹ́ okùnfà èyíkéyìí fún ìkọ̀sẹ̀, kí a má bàa rí àléébù sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa; ṣùgbọ́n lọ́nà gbogbo, a ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run.” (2 Kọ́r. 6:3, 4) Ńṣe ni ká máa “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, lọ́ṣọ̀ọ́ nínú ohun gbogbo.”—Títù 2:10.

w09 11/15 11 ¶21

Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Láti Mú Kí Àdúrà Rẹ Sunwọ̀n Sí I

21 Jésù gbàdúrà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tó kún rẹ́rẹ́. Bí àpẹẹrẹ, kí Jésù tó jí Lásárù dìde, ó “gbé ojú rẹ̀ sókè sí ọ̀run, ó sì wí pé: ‘Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé o ti gbọ́ tèmi. Lóòótọ́, èmi mọ̀ pé ìwọ ń gbọ́ tèmi nígbà gbogbo.’ ” (Jòh. 11:41, 42) Ṣé àdúrà tìrẹ náà máa ń fi irú ọ̀wọ̀ àti ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ hàn? Fara balẹ̀ ka àdúrà àwòkọ́ṣe tí Jésù gbà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, wàá rí i pé àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú àdúrà yẹn ni kí orúkọ Jèhófà di mímọ́, kí Ìjọba rẹ̀ dé, kí ìfẹ́ rẹ̀ sì di ṣíṣe. (Mát. 6:9, 10) Ronú nípa àdúrà tìrẹ náà. Ṣó máa ń fi hàn pé dídé Ìjọba Jèhófà, bí ìfẹ́ rẹ̀ yóò ṣe di ṣíṣe àti bí orúkọ rẹ̀ yóò ṣe di mímọ́ ṣe pàtàkì lọ́kàn rẹ? Bó ṣe yẹ kó rí nìyẹn.

w17.04 6 ¶12

“Ohun Tí O Jẹ́jẹ̀ẹ́, San Án”

12 Àmọ́ o, ìbẹ̀rẹ̀ lásán ni ìrìbọmi jẹ́. Lẹ́yìn ìrìbọmi, ó yẹ ká máa gbé ìgbé ayé wa níbàámu pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa bá a ṣe ń fòótọ́ inú sin Ọlọ́run. Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé mò ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run látìgbà tí mo ti ṣèrìbọmi? Ṣé tọkàntọkàn ni mo fi ń sin Jèhófà? (Kól. 3:23) Ṣé mo máa ń gbàdúrà, ṣé mo sì ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Ṣé mo máa ń lọ sípàdé déédéé, ṣé mo sì máa ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù déédéé? Àbí mo ti ń dẹwọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò yìí?’ Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé téèyàn ò bá fẹ́ di aláìṣiṣẹ́mọ́ nínú ìjọsìn Ọlọ́run, ó gbọ́dọ̀ máa fi ìmọ̀, ìfaradà àti ìfọkànsìn Ọlọ́run kún ìgbàgbọ́ tó ní.—Ka 2 Pétérù 1:5-8.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

w20.09 31 ¶3-5

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Oníwàásù 5:8 ń sọ̀rọ̀ nípa alákòóso kan tó ń ni àwọn aláìní lára, tó sì ń fi ìdájọ́ òdodo dù wọ́n. Ó yẹ kí alákòóso bẹ́ẹ̀ máa rántí pé ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan tó ga ju òun lọ tàbí tó wà nípò àṣẹ tó ju tòun lọ rí òun. Kókó ibẹ̀ ni pé àwọn míì tó wà nípò tó jù bẹ́ẹ̀ lọ tún lè máa wo onítọ̀hún. Ó bani nínú jẹ́ pé bóyá la rí ẹnì kan tó san ju òmíì lọ nínú àwọn alákòóso èèyàn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wọn ni jẹgúdújẹrá. Torí náà, ó di dandan pé káwọn tó wà lábẹ́ wọn máa rọ́jú.

Síbẹ̀, bó ti wù kí nǹkan burú tó, ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà ń ‘ṣọ́ àwọn tó wà nípò gíga’ nínú ìjọba èèyàn. Torí náà, a lè bẹ Jèhófà pé kó gbà wá lọ́wọ́ wọn, ká sì fọ̀rọ̀ wa lé e lọ́wọ́. (Sm. 55:22; Fílí. 4:6, 7) A mọ̀ pé “ojú Jèhófà ń lọ káàkiri gbogbo ayé láti fi agbára rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín.”—2 Kíró. 16:9.

Torí náà, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an nínú ìjọba èèyàn ni Oníwàásù 5:8 sọ nípa ẹ̀, pé ẹnì kan wà nípò àṣẹ tó ju tiwọn lọ. Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ni pé Jèhófà ga ju gbogbo wọn lọ, kódà òun ni Aláṣẹ Gíga Jù Lọ. Jèhófà ti ń ṣàkóso báyìí nípasẹ̀ Jésù Kristi. Torí náà, ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà tó ń rí ohun gbogbo jẹ́ onídàájọ́ òdodo, bí Jésù Ọmọ ẹ̀ náà sì ṣe rí nìyẹn.

OCTOBER 13-19

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ONÍWÀÁSÙ 7-8

“Lọ sí Ilé Ọ̀fọ̀”

w17.07 14 ¶12

‘Ẹ Máa Sunkún Pẹ̀lú Àwọn Tí Ń Sunkún’

12 Àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ tún lè rí ìtùnú nínú ìjọ Kristẹni. (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:11.) Kí la lè ṣe láti tu àwọn “tí ìdààmú bá” nínú, ká sì gbé wọn ró? (Òwe 17:22) Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀” wà. (Oníw. 3:7) Arábìnrin Dalene tọ́kọ rẹ̀ ti kú sọ pé: “Àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ máa ń fẹ́ tú gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wọn jáde. Torí náà, ohun tó dáa jù téèyàn lè ṣe fún àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ ni pé kéèyàn tẹ́tí sí wọn dáadáa, kó má sì dá ọ̀rọ̀ mọ́ wọn lẹ́nu.” Arábìnrin Junia tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin pa ara rẹ̀ sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí bó o ṣe lè lóye bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn gan-an, ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kó o gbìyànjú láti fi ara rẹ sí ipò wọn.”

w19.06 23 ¶15

Máa Ṣèrànwọ́ Fáwọn Tó Ní Ìdààmú Ọkàn

15 Arákùnrin William tí ìyàwó ẹ̀ kú lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn sọ pé: “Inú mi máa ń dùn táwọn míì bá ń sọ ohun tó dáa nípa ìyàwó mi, ìyẹn máa ń jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀ pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún un. Ohun tí wọ́n ń ṣe yìí máa ń mú kára tù mí gan-an, kínú mi sì dùn torí pé mo nífẹ̀ẹ́ ìyàwó mi gan-an, òun sì ni igi lẹ́yìn ọgbà mi.” Arábìnrin Bianca tí ọkọ rẹ̀ ti kú sọ pé: “Ara máa ń tù mí táwọn míì bá gbàdúrà pẹ̀lú mi tí wọ́n sì ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí méjì fún mi. Ó máa ń wú mi lórí tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa ọkọ mi tí wọ́n sì tẹ́tí sílẹ̀ tí mo bá ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.”

w17.07 16 ¶16

‘Ẹ Máa Sunkún Pẹ̀lú Àwọn Tí Ń Sunkún’

16 Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ máa mọrírì rẹ̀ gan-an tó o bá gbàdúrà fún un tàbí tẹ́ ẹ jọ gbàdúrà. O lè má mọ ohun tó o máa sọ nínú àdúrà náà, àmọ́ ara lè tu ẹni náà bó ṣe ń gbọ́ tó ò ń gbàdúrà àtọkànwá, bóyá tí omijé tiẹ̀ ń dà lójú rẹ, tí ohùn rẹ sì ń gbọ̀n. Arábìnrin Dalene sọ pé: “Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan táwọn arábìnrin bá wá kí mi, mo máa ń sọ pé kí wọ́n gbàdúrà fún mi. Níbẹ̀rẹ̀, wọn kì í mọ ohun tí wọ́n máa sọ, àmọ́ bí wọ́n ṣe ń bá àdúrà náà lọ, ọ̀rọ̀ wọn máa ń sọjú abẹ níkòó, ó sì máa ń jẹ́ àtọkànwá. Ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní àti bí wọ́n ṣe fìfẹ́ hàn sí mi máa ń mára tù mí, ó sì máa ń fún mi lókun.”

w17.07 16 ¶17-19

‘Ẹ Máa Sunkún Pẹ̀lú Àwọn Tí Ń Sunkún’

17 Àkókò tó máa ń gbà kí ẹ̀dùn ọkàn tó lọ lára ẹnì kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra. Torí náà, ká má ṣe fi lílọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ mọ sígbà tí àjálù náà ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀, táwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ wà pẹ̀lú wọn, àmọ́ ká tún máa bẹ̀ wọ́n wò kódà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù tí tẹbítọ̀rẹ́ ti pa dà sílé wọn. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17) Orísun ìtùnú làwa Kristẹni gbọ́dọ̀ jẹ́ fún àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ títí dìgbà tí wọ́n á gbé e kúrò lára.—Ka 1 Tẹsalóníkà 3:7.

18 Ká rántí pé àròkàn ní í fa ẹkún àsun-ùndá. Torí náà, déètì kan nínú ọdún lè mú kẹ́ni téèyàn rẹ̀ kú rántí ọ̀fọ̀ tó ṣẹ̀ ẹ́, ó sì lè jẹ́ orin kan tẹ́ni náà fẹ́ràn tàbí fọ́tò rẹ̀, kódà ó lè jẹ́ òórùn lásán tàbí àwọn nǹkan míì. Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn méjèèjì ti jọ ń ṣe pa pọ̀, àmọ́ ní báyìí tó ku òun nìkan, ó lè ṣòro fún un láti ṣe àwọn nǹkan kan, bíi lílọ sí àpéjọ tàbí Ìrántí Ikú Kristi. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan sọ pé: “Mo mọ̀ pé tó bá máa di déètì ọjọ́ tá a ṣègbéyàwó, kò sí bí mi ò ṣe ní rántí ìyàwó mi tó kú, ó sì dájú pé ọkàn mi máa gbọgbẹ́ gan-an. Kò rọrùn fún mi lọ́jọ́ yẹn, àmọ́ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ṣètò àpèjẹ ráńpẹ́ kan, wọ́n sì pe àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ kí n má bàa dá nìkan wà.”

19 Àmọ́ o, kì í ṣe irú àwọn àsìkò báyìí nìkan làwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nílò ìṣírí. Arábìnrin Junia sọ pé: “Ó máa ń ṣèrànwọ́ gan-an táwọn èèyàn bá wà pẹ̀lú wa láwọn àsìkò míì, yàtọ̀ sí àwọn ọjọ́ pàtàkì nìkan. Ó máa ń tù wá lára táwọn ará bá bẹ̀ wá wò láwọn ìgbà tá ò retí.” Ká sòótọ́, kò sóhun tá a ṣe tó lè mú káwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ gbàgbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn pátápátá, bẹ́ẹ̀ sì ni ojú olójú kò lè dà bí ojú ẹni. Àmọ́, a lè tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú tá a bá ṣe àwọn nǹkan pàtó fún wọn. (1 Jòh. 3:18) Arábìnrin Gaby sọ pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún wa láwọn alàgbà tí wọ́n ràn mí lọ́wọ́ ní gbogbo àsìkò tí nǹkan le gan-an fún mi. Ó jẹ́ kí n rí i pé lóòótọ́ ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi.”

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

w23.03 31 ¶18

“Èyí Ni Gbogbo Èèyàn Máa Fi Mọ̀ Pé Ọmọ Ẹ̀yìn Mi Ni Yín”

18 Nígbà míì, ó yẹ ká lọ bá ẹni tá a jọ ń sin Jèhófà tó ṣẹ̀ wá, ká lè yanjú ọ̀rọ̀ náà. Àmọ́ ká tó ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká kọ́kọ́ bi ara wa láwọn ìbéèrè bíi: ‘Ṣé mo mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó mú kó hùwà yẹn sí mi?’ (Òwe 18:13) ‘Ṣé ó lè jẹ́ pé kò mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó ṣe?’ (Oníw. 7:20) ‘Ṣé èmi náà ti hu irú ìwà yẹn rí?’ (Oníw. 7:21, 22) ‘Tí mo bá lọ bá ẹni yẹn, ṣéyẹn máa yanjú ọ̀rọ̀ náà àbí ṣe ló máa dá kún un?’ (Ka Òwe 26:20.) Tá a bá ronú lórí àwọn ìbéèrè yẹn dáadáa, a lè wá rí i pé ìfẹ́ tá a ní fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa máa mú ká gbójú fo ọ̀rọ̀ náà.

OCTOBER 20-26

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ONÍWÀÁSÙ 9-10

Ní Èrò Tó Dáa Tó O Bá Tiẹ̀ Níṣòro

w13 8/15 14 ¶20-21

Má Ṣe “Kún Fún Ìhónú Sí Jèhófà”

20 Ẹ má ṣe jẹ́ ká máa dá Ọlọrun lẹ́bi. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa dá Ọlọ́run lẹ́bi? Ó lè jẹ́ pé àwa fúnra wa la fa àwọn ìṣòro kan tó ń bá wa fínra. Tó bá jẹ́ pé àfọwọ́fà tiwa ni lóòótọ́, a gbọ́dọ̀ gbà bẹ́ẹ̀. (Gál. 6:7) Má ṣe máa dá Jèhófà lẹ́bi pé òun ló fa ìṣòro rẹ. Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu pé ká dá Jèhófà lẹ́bi? Wo àpẹẹrẹ yìí ná: Ká sọ pé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan lè sáré gan-an. Àmọ́, tó bá ṣẹlẹ̀ pé awakọ̀ náà sá eré àsápajúdé wọ kọ́nà, tí jàǹbá wá ṣẹlẹ̀, ṣé ẹni tó ṣe ọkọ̀ náà la máa dá lẹ́bi? Rárá o! Bákan náà, ńṣe ni Jèhófà dá wa pẹ̀lú òmìnira láti ṣe ohun tó wù wá. Àmọ́, ó tún fún wa ní àwọn ìlànà tó máa jẹ́ ká lè ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Torí náà, kí nìdí tá a fi wá ń dá Ẹlẹ́dàá wa lẹ́bi pé òun ló fa àwọn àṣìṣe wa?

21 Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo ìgbà náà ló jẹ́ pé àwọn àṣìṣe wa tàbí ìwà tí kò dára tá a hù ló fa àwọn ìṣòro wa. Àwọn nǹkan kan máa ń wáyé nítorí “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀.” (Oníw. 9:11) Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé pé Sátánì Èṣù gan-an ló pilẹ̀ àwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ láyé. (1 Jòh. 5:19; Ìṣí. 12:9) Òun ni ọ̀tá wa, kì í ṣe Jèhófà!—1 Pét. 5:8.

w19.09 4 ¶10

Jèhófà Mọyì Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Tó Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀

10 Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń jẹ́ kí nǹkan túbọ̀ rọrùn fún wa. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, nígbà míì nǹkan kì í lọ bá a ṣe fẹ́, wọ́n sì lè fi ohun tó tọ́ sí wa dù wá. Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì sọ pé: “Mo ti rí àwọn ìránṣẹ́ tó ń gun ẹṣin àmọ́ tí àwọn olórí ń fẹsẹ̀ rìn bí ìránṣẹ́.” (Oníw. 10:7) Nígbà míì, àwọn tó ṣiṣẹ́ kára tàbí tó lẹ́bùn tó ta yọ kì í gbayì lójú àwọn èèyàn. Àmọ́ àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ lẹ́bùn làwọn èèyàn máa ń gbé gẹ̀gẹ̀. Síbẹ̀, Sólómọ́nì sọ pé á dáa ká má ṣe yọ ara wa lẹ́nu nípa ohun tá ò lè ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀. (Oníw. 6:9) Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a ò ní máa da ara wa láàmú táwọn nǹkan tá ò retí bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé wa.

w11 10/15 8 ¶1-2

Ṣé Eré Ìtura Tó O Yàn Máa Ṣe Ẹ́ Láǹfààní?

ÀWỌN ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé Jèhófà fẹ́ ká máa wà láàyè ká sì tún máa gbádùn ìgbésí ayé wa fara hàn léraléra nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, Sáàmù 104:14, 15 sọ pé Jèhófà ń mú kí “oúnjẹ jáde wá láti inú ilẹ̀, àti wáìnì tí ń mú kí ọkàn-àyà ẹni kíkú máa yọ̀, láti mú kí òróró máa mú ojú dán, àti oúnjẹ tí ń gbé ọkàn-àyà ẹni kíkú ró.” Dájúdájú, Jèhófà ń mú kí àwọn irúgbìn dàgbà kí wọ́n lè mú ọkà, òróró àti wáìnì jáde fún ìlò wa. Àmọ́, wáìnì tún máa ‘ń mú ọkàn-àyà yọ̀.’ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò pọn dandan ká mu wáìnì ká tó lè máa wà láàyè, ó máa ń fi kún ayọ̀ wa. (Oníw. 9:7; 10:19) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà fẹ́ ká máa láyọ̀, kí ọkàn-àyà wa sì kún fún “ìmóríyágágá.”—Ìṣe 14:16, 17.

2 Torí náà, kò sí ìdí tó fi yẹ ká máa dá ara wa lẹ́bi tá a bá ń wáyè lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti “fi tọkàntara ṣàkíyèsí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run” àti “àwọn òdòdó lílì pápá” tàbí ká lè ṣe àwọn nǹkan míì tó máa mára tù wá tó sì máa mú kára wá jí pépé. (Mát. 6:26, 28; Sm. 8:3, 4) Ìgbésí ayé tó gbámúṣé jẹ́ “ẹ̀bùn Ọlọ́run.” (Oníw. 3:12, 13) Bá a bá wo àkókò tí ọwọ́ wa dilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí apá kan lára ẹ̀bùn yẹn, a ó lè lò ó lọ́nà tó máa mú inú Ọlọ́run tó fún wa lẹ́bùn náà dùn.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

lv 137 ¶11, 12

Ẹ Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ẹnu Yín “Dára fún Gbígbéniró”

11 Òfófó tí ń pani lára, ìbanilórúkọjẹ́. Béèyàn bá ń yọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ sọ létí ẹlòmíì, òfófó ló ń ṣe yẹn. Ṣé gbogbo òfófó ló burú ni? Rárá o, pàápàá jù lọ bí ohun tá à ń sọ nípa onítọ̀hún bá jẹ́ àwọn ohun tó yẹ káwọn ẹlòmíì mọ̀, irú bí ọ̀rọ̀ nípa ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi tàbí ẹni tó yẹ ká gbà níyànjú. Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní kì í fọ̀rọ̀ ara wọn ṣeré, wọ́n sì máa ń sọ ọ̀rọ̀ tó bá yẹ kí wọ́n sọ nípa àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn fáwọn ẹlòmíì. (Éfésù 6:21, 22; Kólósè 4:8, 9) Àmọ́ ṣá o, òfófó lè burú tó bá lọ jẹ́ pé irọ́ là ń tàn kálẹ̀ nípa onítọ̀hún tàbí kó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ àṣírí ẹni náà la tú síta. Ohun tó burú jù nínú ẹ̀ ni pé, ó lè yọrí sí ìbanilórúkọjẹ́ èyí tó máa ń pani lára ní gbogbo ìgbà. Ìbanilórúkọjẹ́ ni “fífi ẹ̀sùn èké kanni, èyí tó lè buni kù tó sì ń sọni dèèyàn burúkú.” Bí àpẹẹrẹ, àwọn Farisí gbìdánwò láti fi ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ba Jésù lórúkọ jẹ́. (Mátíù 9:32-34; 12:22-24) Ìbanilórúkọjẹ́ sábà máa ń yọrí sí asọ̀.—Òwe 26:20.

12 Jèhófà kì í fojú tó dáa wo àwọn tó ń fi ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ ba àwọn ẹlòmíì lórúkọ jẹ́ tàbí tí wọ́n fi ń fa ìpínyà. Ó sì kórìíra àwọn tó bá ń dá “asọ̀ sílẹ̀ láàárín àwọn arákùnrin.” (Òwe 6:16-19) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà di·aʹbo·los, la tú sí afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, ọ̀kan lára àwọn orúkọ Sátánì sì ni. Òun ni “Èṣù,” ẹni ibi tó fọ̀rọ̀ èké ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́. (Ìṣípayá 12:9, 10) Ó dájú pé a ò ní fẹ́ sọ ohunkóhun tó máa mú ká fìwà jọ èṣù. A ò fàyè gba ẹnikẹ́ni láti fọ̀rọ̀ èké bani lórúkọ jẹ́ nínú ìjọ torí ìyẹn ló máa ń fa àwọn iṣẹ́ ti ara bí “asọ̀” àti “ìpínyà.” (Gálátíà 5:19-21) Nítorí náà, kó o tó sọ ohunkóhun nípa ẹnikẹ́ni, kọ́kọ́ bi ara rẹ pé: ‘Ṣé òótọ́ ọ̀rọ̀ ni? Ṣó máa dáa kí n tan ọ̀rọ̀ náà kálẹ̀? Ṣó pọn dandan tàbí kẹ̀, ṣó tiẹ̀ bọ́gbọ́n mu pé kí n sọ ọ̀rọ̀ náà fáwọn ẹlòmíì?’—Ka 1 Tẹsalóníkà 4:11.

OCTOBER 27–NOVEMBER 2

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ONÍWÀÁSÙ 11-12

Ohun Tó Máa Jẹ́ Kó O Láyọ̀, Kó O sì Ní Ìlera Tó Dáa

w23.03 25 ¶16

Máa Fi Àwọn Nǹkan Tí Jèhófà Dá Kọ́ Ọmọ Rẹ

16 Tẹ́yin ìdílé bá ń lo ohun tí Jèhófà dá láti gbádùn ara yín lásìkò ìsinmi, á jẹ́ kẹ́ ẹ túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara yín. Bíbélì sọ pé “ìgbà rírẹ́rìn-ín” wà àti ìgbà “títa pọ́n-ún pọ́n-ún kiri.” (Oníw. 3:1, 4, àlàyé ìsàlẹ̀) Jèhófà ti pèsè ọ̀pọ̀ ibi tó rẹwà gan-an tá a ti lè lọ gbádùn ara wa. Ọ̀pọ̀ ìdílé gbádùn kí wọ́n jọ máa lọ sí ọgbà ìgbafẹ́, ìgbèríko, orí òkè àti etíkun. Àwọn ọmọ kan fẹ́ràn kí wọ́n máa sáré kiri nínú ọgbà ìgbafẹ́ tàbí kí wọ́n máa wo àwọn ẹranko. Àwọn ọmọ míì sì gbádùn kí wọ́n máa lúwẹ̀ẹ́ nínú odò tàbí létíkun. Ẹ ò rí i pé a láǹfààní tó pọ̀ gan-an láti gbádùn ara wa tá a bá jáde lọ wo àwọn ohun tí Jèhófà dá!

w23.02 21 ¶6-7

Bó O Ṣe Lè Mọyì Ìwàláàyè Tí Ọlọ́run Fún Ẹ

6 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé ìṣègùn tàbí ìwé tó ń sọ nípa ohun tá a máa jẹ àtohun tá ò ní jẹ, ó jẹ́ ká mọ irú ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn nǹkan yìí. Bí àpẹẹrẹ, ó gbà wá níyànjú pé ká ‘sá fún àwọn ohun tó lè ṣe wá léṣe.’ (Oníw. 11:10) Bíbélì sọ fún wa pé àjẹkì àti ọtí àmujù ò dáa, àwọn nǹkan yìí sì lè dá àìsàn sí wa lára tàbí kí wọ́n ṣekú pa wá. (Òwe 23:20) Jèhófà fẹ́ ká kó ara wa níjàánu tó bá kan irú oúnjẹ tá a fẹ́ jẹ àtohun tá a fẹ́ mu àti bó ṣe máa pọ̀ tó.—1 Kọ́r. 6:12; 9:25.

7 Tá a bá ń lo làákàyè, àwọn ìpinnu tá a bá ń ṣe máa fi hàn pé a mọyì ìwàláàyè tí Ọlọ́run fún wa. (Sm. 119:99, 100; ka Òwe 2:11.) Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ ká máa ṣọ́ra tá a bá fẹ́ pinnu ohun tá a máa jẹ. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ oúnjẹ kan àmọ́ tá a mọ̀ pé kò bá wa lára mu, làákàyè wa máa sọ fún wa pé kò yẹ ká jẹ oúnjẹ náà mọ́. Bákan náà, tá a bá ní ìfòyemọ̀, àá máa sùn dáadáa, àá máa ṣeré ìmárale déédéé, àá máa tọ́jú ara wa dáadáa, àá sì máa bójú tó ilé wa kó lè mọ́ tónítóní.

w24.09 2 ¶2-3

“Ẹ Máa Ṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Náà Sọ”

2 Kí nìdí táwa ìránṣẹ́ Jèhófà fi máa ń láyọ̀? Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń jẹ́ ká láyọ̀, àmọ́ èyí tó ṣe pàtàkì jù lára ẹ̀ ni pé a máa ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, a sì máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fi ohun tá a kọ́ sílò.—Ka Jémíìsì 1:22-25.

3 Ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa rí tá a bá ń “ṣe ohun tí ọ̀rọ̀ náà sọ.” Bí àpẹẹrẹ, a mọ̀ pé tá a bá ń ṣe ohun tá a kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, inú Jèhófà máa dùn sí wa, ìyẹn sì máa jẹ́ ká láyọ̀. (Oníw. 12:13) Bákan náà, ó máa jẹ́ kí àwa àtàwọn tá a jọ wà nínú ìdílé túbọ̀ sún mọ́ra, ó sì máa jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ará nínú ìjọ. Ó ṣeé ṣe kíwọ náà gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn. Yàtọ̀ síyẹn, a máa ń sá fáwọn nǹkan tó lè mú ká kó síṣòro táwọn tí ò tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà máa ń ní. Lẹ́yìn tí Ọba Dáfídì mẹ́nu ba àwọn òfin Jèhófà, àwọn ìlànà àtàwọn ìdájọ́ ẹ̀ nínú orin tó kọ, ohun tó fi parí ẹ̀ ni pé: “Èrè ńlá wà nínú pípa wọ́n mọ́,” àwa náà sì gbà pé òótọ́ ló sọ.—Sm. 19:7-11.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

lff ẹ̀kọ́ 3 kókó 1

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Gbára Lé Bíbélì?

1. Ṣé òótọ́ lohun tó wà nínú Bíbélì àbí ìtàn àròsọ lásán ni?

“Àwọn ọ̀rọ̀ tó péye tó sì jẹ́ òtítọ́” ló wà nínú Bíbélì. (Oníwàásù 12:10) Ìtàn àwọn èèyàn ẹlẹ́ran ara bíi ti wa ló wà nínú ẹ̀, àwọn nǹkan tó sọ nípa wọn sì ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. (Ka Lúùkù 1:3; 3:1, 2.) Àwọn òpìtàn àtàwọn awalẹ̀pìtàn jẹ́rìí sí i pé àwọn déètì, àwọn èèyàn, orúkọ àwọn ìlú àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì péye, ó sì jóòótọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́