ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Ìyọnu Mẹ́fà Tó Tẹ̀ Lé E
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Àwọn kòkòrò tó pọ̀

      Ẹ̀KỌ́ 20

      Àwọn Ìyọnu Mẹ́fà Tó Tẹ̀ Lé E

      Mósè àti Áárónì lọ jíṣẹ́ Jèhófà fún Fáráò, wọ́n sọ fún un pé: ‘Tó ò bá jẹ́ káwọn èèyàn mi lọ, màá rán àwọn eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ sí ilẹ̀ yìí.’ Àwọn eṣinṣin náà kún ilé gbogbo àwọn ọmọ Íjíbítì, àti ilé olówó àti ti tálákà. Gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì pátápátá ló kún fún àwọn eṣinṣin náà. Àmọ́ àwọn eṣinṣin yìí ò dé ilẹ̀ Góṣénì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé. Látorí ìyọnu kẹrin, àwọn ọmọ Íjíbítì nìkan ló ń jìyà àwọn ìyọnu náà. Fáráò wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé: ‘Ẹ bá mi bẹ Jèhófà pé kó mú àwọn eṣinṣin náà kúrò. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè máa lọ.’ Àmọ́, nígbà tí Jèhófà mú àwọn eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ náà kúrò tán, ńṣe ni Fáráò tún yíhùn pa dà pé òun ò ní jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ. Ṣé Fáráò tiẹ̀ kọ́gbọ́n kankan nínú àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀?

      Jèhófà sọ pé: ‘Tí Fáráò bá kọ̀, tí kò jẹ́ káwọn èèyàn mi lọ, gbogbo ẹranko àwọn ọmọ Íjíbítì máa ṣàìsàn, wọ́n á sì kú.’ Lọ́jọ́ kejì, àwọn ẹranko náà bẹ̀rẹ̀ sí í kú. Ṣùgbọ́n kò sóhun tó ṣe àwọn ẹranko àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Síbẹ̀, Fáráò ń ṣe agídí, kò sì gbà káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.

      Jèhófà wá ní kí Mósè pa dà lọ sọ́dọ̀ Fáráò, kó sì da eérú sínú afẹ́fẹ́. Eérú náà wá di eruku, ó sì dà pọ̀ mọ́ afẹ́fẹ́. Eruku náà wá bo gbogbo àwọn ọmọ Íjíbítì. Ó sì fa eéwo tó ń dunni gan-an sára àwọn àtàwọn ẹranko wọn. Síbẹ̀, Fáráò yarí kanlẹ̀ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ní lọ.

      Ìyọnu kẹrin sí ìkẹfà: eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀, ikú àwọn ẹranko, eéwo

      Jèhófà tún rán Mósè lọ sọ́dọ̀ Fáráò pé: ‘Kí ló dé tó ò jẹ́ káwọn èèyàn mi lọ? Tó bá dọ̀la, òjò yìnyín máa rọ̀ sórí ilẹ̀ náà.’ Lọ́jọ́ kejì, Jèhófà mú kí òjò yìnyín rọ̀, ó mú kí àrá máa sán, ó sì mú kí iná sọ̀ kalẹ̀. Àwọn ọmọ Íjíbítì ò rí irú òjò tó le tó báyìí rí. Ọ̀pọ̀ igi ló wó, àwọn nǹkan ọ̀gbìn sì bà jẹ́. Ṣùgbọ́n kò sóhun tó ṣẹlẹ̀ nílẹ̀ Góṣénì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé. Fáráò tún pe Mósè, ó sì sọ fún un pé: ‘Bá wa bẹ Jèhófà pé kó dáwọ́ òjò náà dúró.’ Ó tiẹ̀ tún sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè máa lọ. Àmọ́ lẹ́yìn tí òjò yìnyín náà dáwọ́ dúró, Fáráò tún yarí, kò sì jẹ́ kí wọ́n lọ mọ́.

      Lẹ́yìn náà, Mósè sọ pé: ‘Ní báyìí, àwọn kòkòrò eéṣú máa jẹ ohun tó bá ṣẹ́ kù nínú nǹkan ọ̀gbìn tí òjò yìnyín náà ò bà jẹ́.’ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ kòkòrò ya dé, wọ́n sì jẹ gbogbo nǹkan tó ṣẹ́ kù lórí àwọn igi àti ní ilẹ̀ náà run. Fáráò tún wá pe Mósè, ó sì ní kó bẹ Jèhófà pé kó lé àwọn kòkòrò náà dà nù. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí Jèhófà mú káwọn kòkòrò náà lọ, Fáráò kò tún gbà káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.

      Jèhófà tún wá sọ fún Mósè pé: ‘Na ọwọ́ rẹ sí ojú ọ̀run.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ojú ọ̀run dúdú. Fún odindi ọjọ́ mẹ́ta, àwọn ọmọ Íjíbítì ò rí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni. Ṣùgbọ́n ìmọ́lẹ̀ wà níbi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé.

      Ìyọnu keje sí ìkẹsàn-án: òjò yìnyín, àwọn kòkòrò, òkùnkùn

      Fáráò wá sọ fún Mósè pé: ‘Ìwọ àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè máa lọ. Ṣùgbọ́n ẹ fi àwọn ẹranko yín sílẹ̀ níbí.’ Mósè fèsì pé: ‘A gbọ́dọ̀ kó àwọn ẹranko wa dání ká lè fi wọ́n rúbọ sí Ọlọ́run wa.’ Inú bí Fáráò gan-an, ó wá pariwo pé: ‘Kóra ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi! Tí mo bá tún rí ẹ, màá pa ẹ́ ni.’

      “Ẹ ó sì tún rí ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú, láàárín ẹni tó ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.”​—Málákì 3:18

      Ìbéèrè: Àwọn ìyọnu wo ni Jèhófà tún mú wá? Báwo ni wọ́n ṣe yàtọ̀ sáwọn ìyọnu mẹ́ta àkọ́kọ́?

      Ẹ́kísódù 8:20–10:29

  • Ìyọnu Kẹwàá
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Ọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì ń fi ẹ̀jẹ̀ sàmì sí ilẹ̀kùn ẹ̀

      Ẹ̀KỌ́ 21

      Ìyọnu Kẹwàá

      Mósè ṣèlérí fún Fáráò pé òun ò ní wá sọ́dọ̀ ẹ̀ mọ́. Àmọ́ kí Mósè tó lọ, ó sọ fún Fáráò pé: ‘Tó bá di òru, gbogbo àkọ́bí ẹ̀yin ará Íjíbítì máa kú, látorí ọmọkùnrin Fáráò dórí ọmọ àwọn ẹrú.’

      Jèhófà ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì se oúnjẹ pàtàkì kan. Ó sọ fún wọn pé: ‘Ẹ pa àgbò kan tàbí òbúkọ kan tó ti pé ọdún kan, kẹ́ ẹ sì fi ẹ̀jẹ̀ ẹ̀ sàmì síbi ilẹ̀kùn ilé yín. Kẹ́ ẹ wá sun ẹran náà, kẹ́ ẹ sì fi búrẹ́dì aláìwú jẹ ẹ́. Kẹ́ ẹ wọ aṣọ àti bàtà yín, kẹ́ ẹ sì múra tán láti kúrò ní Íjíbítì. Òru yìí ni màá gbà yín lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì.’ Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? Ṣé inú wọn máa dùn àbí kò ní dùn?

      Nígbà tó di òru, áńgẹ́lì Jèhófà lọ sí gbogbo ilé tó wà ní Íjíbítì. Tó bá ti dé ilé tí wọn ò fi ẹ̀jẹ̀ sàmì sí ilẹ̀kùn ẹ̀, ó máa pa àkọ́bí wọn. Àmọ́ ó máa ré kọjá àwọn ilé tí wọ́n bá fi ẹ̀jẹ̀ sàmì sí. Gbogbo àkọ́bí àwọn ará Íjíbítì ló kú àtọmọ olówó àtọmọ tálákà. Àmọ́ kò sọ́mọ Ísírẹ́lì kankan tó kú.

      Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ọmọ Fáráò náà kú? Ìyẹn ló fà á tí ara Fáráò kò fi lè gbà á mọ́. Ló bá ránṣẹ́ pe Mósè àti Áárónì ní kíá, ó sì sọ fún wọn pé: ‘Ó yá, ó yá. Ẹ jáde kúrò nílùú wa. Ẹ lọ máa jọ́sìn Ọlọ́run yín. Ẹ kó gbogbo ẹran yín, kẹ́ ẹ máa lọ!’

      Àárín òru tí òṣùpá mọ́lẹ̀ rokoṣo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì, wọ́n ṣètò ara wọn ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, àti ní ẹbí kọ̀ọ̀kan. Iye àwọn ọkùnrin tó wà láàárín wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600,000). Àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé tó pọ̀ gan-an sì tún wà pẹ̀lú wọn. Àwọn míì tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì náà bá wọn lọ kí wọ́n lè jọ máa sin Jèhófà. Níkẹyìn, Jèhófà mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú!

      Jèhófà fẹ́ kí wọ́n máa rántí bóun ṣe dá wọn nídè, torí náà ó sọ fún wọn pé kí wọ́n máa jẹ oúnjẹ pàtàkì yẹn lọ́dọọdún. Èyí ni wọ́n ń pè ní Ìrékọjá.

      Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jáde kúrò ní Íjíbítì

      “Ìdí tí mo fi jẹ́ kí o máa wà nìṣó ni pé: kí n lè fi agbára mi hàn nípasẹ̀ rẹ àti pé kí a lè ròyìn orúkọ mi ní gbogbo ayé.”​—Róòmù 9:17

      Ìbéèrè: Kí ni ìyọnu kẹwàá? Kí ni Jèhófà ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe kí ìyọnu kẹwàá náà má bàa pa àwọn ọmọ wọn?

      Ẹ́kísódù 11:1–12:42; 13:3-10

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́