ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Amí Méjìlá
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ ṣe amí ilẹ̀ Kénáánì

      Ẹ̀KỌ́ 26

      Àwọn Amí Méjìlá

      Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Òkè Sínáì, wọ́n rin ìrìn àjò gba àwọn aṣálẹ̀ Páránì lọ sí ibì kan tó ń jẹ́ Kádéṣì. Níbẹ̀, Jèhófà sọ fún Mósè pé: ‘Rán ọkùnrin méjìlá (12) látinú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan láti lọ ṣe amí ilẹ̀ Kénáánì, ilẹ̀ yìí ni màá fún ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì.’ Torí náà, Mósè yan ọkùnrin méjìlá (12), ó sì sọ fún wọn pé: ‘Ẹ lọ yẹ ilẹ̀ Kénáánì wò bóyá ó dáa fun iṣé àgbẹ̀. Kẹ́ ẹ sì wo báwọn èèyàn ibẹ̀ ṣe lágbára tó, bóyá inú àgọ́ ni wọ́n ń gbé tàbí ìlú ńlá.’ Jóṣúà àti Kélẹ́bù wà lára àwọn amí méjìlá náà, gbogbo wọn sì gba ilẹ̀ Kénáánì lọ.

      Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ráhùn, wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì

      Àwọn amí yìí pa dà lẹ́yìn ogójì (40) ọjọ́, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀tọ́, pómégíránétì àti èso àjàrà wálé. Wọ́n sọ pé: ‘Ilẹ̀ náà dáa, àmọ́ àwọn èèyàn ibẹ̀ lágbára gan-an, ògiri wọn sì tún ga gìrìwò.’ Kélẹ́bù wá sọ pé: ‘A lè ṣẹ́gun wọn. Ẹ jẹ́ ká lọ mú wọn balẹ̀ báyìí!’ Ṣé o mọ ìdí tí Kélẹ́bù fi sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé òun àti Jóṣúà gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Àmọ́ àwọn amí mẹ́wàá tó kù sọ pé: ‘Rárá! Àwa ò ní tẹ̀ lé yín lọ síbì kankan. Àwọn ará ìlú yẹn ga gan-an, wọ́n sì lágbára! Ńṣe la dà bíi kòkòrò kékeré lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn.’

      Inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bà jẹ́. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn, wọ́n sì ń sọ fún ara wọn pé: ‘Ẹ jẹ́ ká yan ẹlòmíì táá máa darí wa, ká sì pa dà sí Íjíbítì. Kí ló dé tá a fi máa gba ilẹ̀ Kénáánì lọ kí wọ́n lè pa wá dà nù?’ Jóṣúà àti Kélẹ́bù sọ pé: ‘Ẹ má ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ẹ má sì bẹ̀rù rárá. Jèhófà máa dáàbò bò wá.’ Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò gbọ́. Àní wọ́n tiẹ̀ fẹ́ pa Jóṣúà àti Kélẹ́bù!

      Kí ni Jèhófà wá ṣe? Ó sọ fún Mósè pé: ‘Pẹ̀lú gbogbo ohun tí mo ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, síbẹ̀ wọn ò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. Torí ohun tí wọ́n ṣe yìí, wọn ò ní kúrò nínú aṣálẹ̀ yìí fún ogójì (40) ọdún, ibẹ̀ ni wọ́n sì máa kú sí. Àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú Jóṣúà àti Kélẹ́bù ló máa gba ilẹ̀ tí mo ṣèlérí pé màá fún un yín.’

      “Kí ló dé tí ẹ̀rù ń bà yín tó báyìí, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré?”​—Mátíù 8:26

      Ìbéèrè: Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn amí méjìlá (12) náà pa dà dé láti ilẹ̀ Kénáánì? Báwo ni Jóṣúà àti Kélẹ́bù ṣe fi hàn pé àwọn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?

      Nọ́ńbà 13:1–14:38; Diutarónómì 1:22-33; Sáàmù 78:22; Hébérù 3:17-19

  • Wọ́n Ta Ko Jèhófà
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Kórà àtàwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ̀ dúró síwájú Mósè àti Áárónì

      Ẹ̀KỌ́ 27

      Wọ́n Ta Ko Jèhófà

      Láàárín àsìkò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà ní aginjù, Kórà, Dátánì, Ábírámù, àtàwọn ọgọ́rùn-ún méjì àti àádọ́ta (250) ọkùnrin míì ta ko Mósè. Wọ́n sọ fún un pé: ‘Ọ̀rọ̀ ẹ ti sú wa! Kí ló dé tó ò ń ṣe bí ọ̀gá lé wa lórí, tí Áárónì náà sì tún sọ ara ẹ̀ di àlùfáà àgbà? Ìwọ àti Áárónì nìkan kọ́ ni Jèhófà lè lò, Jèhófà wà pẹ̀lú àwa náà.’ Inú bí Jèhófà sí ohun tí wọ́n sọ yìí. Lójú Jèhófà, ńṣe ló dà bíi pé òun làwọn èèyàn náà ń ta kò!

      Mósè wá sọ fún Kórà àtàwọn èèyàn ẹ̀ tó kù pé: ‘Ẹ wá sí àgọ́ ìjọsìn lọ́la, kẹ́ ẹ sì fi tùràrí sórí ìkóná yín. Jèhófà máa jẹ́ ká mọ ẹni tóun yàn.’

      Lọ́jọ́ kejì, Kórà àtàwọn ọgọ́rùn-ún méjì àti àádọ́ta (250) ọkùnrin náà lọ pàdé Mósè ní àgọ́ ìjọsìn. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sun tùràrí bíi pé àlùfáà ni wọ́n. Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé: ‘Ẹ kúrò lọ́dọ̀ Kórà àtàwọn èèyàn ẹ̀.’

      Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Kórà lọ pàdé Mósè ní àgọ́ ìjọsìn, Dátánì, Ábírámù, àti ìdílé wọn ò lọ. Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n kúrò láyìíká ibi tí Kórà, Dátánì, àti Ábírámù pàgọ́ sí. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Dátánì, Ábírámù, àti gbogbo ìdílé wọn wá dúró síwájú àgọ́ wọn. Lójijì, ilẹ̀ lanu ó sì gbé wọn mì! Ní àgọ́ ìjọsìn, iná yọ látọ̀run, ó sì jó Kórà àtàwọn ọgọ́rùn-ún méjì àti àádọ́ta (250) ọkùnrin náà run.

      Ilẹ̀ lanu, ó sì gbé Dátánì, Ábírámù àti ìdílé wọn mì

      Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: ‘Gba ọ̀pá kan lọ́wọ́ olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, kó o sì kọ orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sára ọ̀pá tiẹ̀. Ṣùgbọ́n orúkọ Áárónì ni kó o kọ sára ọ̀pá ti ẹ̀yà Léfì. Kó àwọn ọ̀pá yìí sínú àgọ́ ìjọsìn, ọ̀pá ẹni tí mo bá sì yàn máa yọ òdòdó.’

      Lọ́jọ́ kejì, Mósè kó àwọn ọ̀pá náà jáde láti fi han àwọn olórí náà. Ọ̀pá Áárónì ló yọ òdòdó, ó sì tún ní èso álímọ́ńdì tó ti pọ́n. Jèhófà tipa báyìí fi dá wọn lójú pé Áárónì lòún yàn láti jẹ́ àlùfáà àgbà.

      “Ẹ máa ṣègbọràn sí àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì máa tẹrí ba.”​—Hébérù 13:17

      Ìbéèrè: Kí nìdí tí Kórà àtàwọn èèyàn ẹ̀ fi ta ko Mósè? Báwo la ṣe mọ̀ pé Áárónì ni Jèhófà yàn láti jẹ́ àlùfáà àgbà?

      Nọ́ńbà 16:1–17:13; 26:9-11; Sáàmù 106:16-18

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́