ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 13
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Nọ́ńbà

      • Wọ́n rán amí 12 lọ sí Kénáánì (1-24)

      • Amí mẹ́wàá mú ìròyìn tí kò dáa wá (25-33)

Nọ́ńbà 13:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ṣàyẹ̀wò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 18:25; Di 1:15
  • +Di 1:22, 23

Nọ́ńbà 13:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 12:16; Di 1:19

Nọ́ńbà 13:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 13:30; 14:30, 38; 34:18, 19; 1Kr 4:15

Nọ́ńbà 13:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 11:28; 13:16; 14:30; 34:17

Nọ́ńbà 13:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 48:5
  • +Jẹ 48:17, 19

Nọ́ńbà 13:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Jèhóṣúà,” ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ìgbàlà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 17:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2002, ojú ìwé 11

Nọ́ńbà 13:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 1:7

Nọ́ńbà 13:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 3:8; Di 8:7

Nọ́ńbà 13:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “lọ́ràá.”

  • *

    Ní Héb., “kò lọ́ràá.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 9:25; Isk 20:6
  • +Di 31:6; Joṣ 1:6, 9
  • +Nọ 13:23

Nọ́ńbà 13:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àbáwọlé Hámátì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 34:2, 3; Joṣ 15:1
  • +2Sa 10:6, 8
  • +Nọ 34:8

Nọ́ńbà 13:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 13:18; Joṣ 15:13; 21:11, 12
  • +Ond 1:10
  • +Di 9:1, 2; Joṣ 11:21

Nọ́ńbà 13:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 32:9
  • +Di 1:25; 8:7-9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2006, ojú ìwé 16

Nọ́ńbà 13:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Òṣùṣù Èso Àjàrà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 1:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2006, ojú ìwé 16

Nọ́ńbà 13:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 14:33, 34

Nọ́ńbà 13:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 1:19

Nọ́ńbà 13:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 3:8; Le 20:24
  • +Di 1:25

Nọ́ńbà 13:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 13:22, 33; Di 1:27, 28

Nọ́ńbà 13:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 36:12; Ẹk 17:8; 1Sa 15:3
  • +Nọ 13:17
  • +Ond 1:21; 2Sa 5:6, 7
  • +Jẹ 10:15, 16
  • +Ẹk 23:23; Di 7:1; 20:17
  • +Jẹ 10:19

Nọ́ńbà 13:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 14:7, 8

Nọ́ńbà 13:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 32:9

Nọ́ńbà 13:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 14:36
  • +Emọ 2:9

Nọ́ńbà 13:33

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “wá láti ara.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 1:28; 9:1, 2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    7/15/2011, ojú ìwé 10-11

    10/1/2006, ojú ìwé 16-17

Àwọn míì

Nọ́ń. 13:2Ẹk 18:25; Di 1:15
Nọ́ń. 13:2Di 1:22, 23
Nọ́ń. 13:3Nọ 12:16; Di 1:19
Nọ́ń. 13:6Nọ 13:30; 14:30, 38; 34:18, 19; 1Kr 4:15
Nọ́ń. 13:8Nọ 11:28; 13:16; 14:30; 34:17
Nọ́ń. 13:11Jẹ 48:5
Nọ́ń. 13:11Jẹ 48:17, 19
Nọ́ń. 13:16Ẹk 17:9
Nọ́ń. 13:17Di 1:7
Nọ́ń. 13:18Ẹk 3:8; Di 8:7
Nọ́ń. 13:20Ne 9:25; Isk 20:6
Nọ́ń. 13:20Di 31:6; Joṣ 1:6, 9
Nọ́ń. 13:20Nọ 13:23
Nọ́ń. 13:21Nọ 34:2, 3; Joṣ 15:1
Nọ́ń. 13:212Sa 10:6, 8
Nọ́ń. 13:21Nọ 34:8
Nọ́ń. 13:22Jẹ 13:18; Joṣ 15:13; 21:11, 12
Nọ́ń. 13:22Ond 1:10
Nọ́ń. 13:22Di 9:1, 2; Joṣ 11:21
Nọ́ń. 13:23Nọ 32:9
Nọ́ń. 13:23Di 1:25; 8:7-9
Nọ́ń. 13:24Di 1:24
Nọ́ń. 13:25Nọ 14:33, 34
Nọ́ń. 13:26Di 1:19
Nọ́ń. 13:27Ẹk 3:8; Le 20:24
Nọ́ń. 13:27Di 1:25
Nọ́ń. 13:28Nọ 13:22, 33; Di 1:27, 28
Nọ́ń. 13:29Jẹ 36:12; Ẹk 17:8; 1Sa 15:3
Nọ́ń. 13:29Nọ 13:17
Nọ́ń. 13:29Ond 1:21; 2Sa 5:6, 7
Nọ́ń. 13:29Jẹ 10:15, 16
Nọ́ń. 13:29Ẹk 23:23; Di 7:1; 20:17
Nọ́ń. 13:29Jẹ 10:19
Nọ́ń. 13:30Joṣ 14:7, 8
Nọ́ń. 13:31Nọ 32:9
Nọ́ń. 13:32Nọ 14:36
Nọ́ń. 13:32Emọ 2:9
Nọ́ń. 13:33Di 1:28; 9:1, 2
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Nọ́ńbà 13:1-33

Nọ́ńbà

13 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 2 “Rán àwọn ọkùnrin lọ ṣe amí* ilẹ̀ Kénáánì tí mo fẹ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Kí ẹ rán ọkùnrin kan látinú ẹ̀yà baba ńlá wọn kọ̀ọ̀kan, kí ọ̀kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìjòyè+ láàárín wọn.”+

3 Torí náà, Mósè rán wọn jáde láti aginjù Páránì+ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ. Gbogbo àwọn ọkùnrin náà jẹ́ olórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 4 Orúkọ wọn nìyí: Nínú ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Ṣámúà ọmọ Sákúrì; 5 nínú ẹ̀yà Síméónì, Ṣáfátì ọmọ Hórì; 6 nínú ẹ̀yà Júdà, Kélẹ́bù+ ọmọ Jéfúnè; 7 nínú ẹ̀yà Ísákà, Ígálì ọmọ Jósẹ́fù; 8 nínú ẹ̀yà Éfúrémù, Hóṣéà+ ọmọ Núnì; 9 nínú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, Pálítì ọmọ Ráfù; 10 nínú ẹ̀yà Sébúlúnì, Gádíélì ọmọ Sódì; 11 nínú ẹ̀yà Jósẹ́fù,+ fún ẹ̀yà Mánásè,+ Gádáì ọmọ Súsì; 12 nínú ẹ̀yà Dánì, Ámíélì ọmọ Gémálì; 13 nínú ẹ̀yà Áṣérì, Sẹ́túrì ọmọ Máíkẹ́lì; 14 nínú ẹ̀yà Náfútálì, Náhíbì ọmọ Fófísì; 15 nínú ẹ̀yà Gádì, Géúélì ọmọ Mákì. 16 Èyí ni orúkọ àwọn ọkùnrin tí Mósè rán láti ṣe amí ilẹ̀ náà. Mósè wá sọ Hóṣéà ọmọ Núnì ní Jóṣúà.*+

17 Nígbà tí Mósè ń rán wọn lọ ṣe amí ilẹ̀ Kénáánì, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ gòkè lọ sí Négébù, kí ẹ sì lọ sí agbègbè olókè.+ 18 Kí ẹ lọ wo irú ilẹ̀ tó jẹ́,+ kí ẹ sì wò ó bóyá àwọn tó ń gbé ibẹ̀ lágbára tàbí wọn ò lágbára, bóyá wọ́n pọ̀ tàbí wọn ò pọ̀, 19 kí ẹ wò ó bóyá ilẹ̀ náà dáa tàbí kò dáa, bóyá inú àgọ́ làwọn èèyàn ilẹ̀ náà ń gbé àbí àwọn ìlú wọn ní ààbò. 20 Kí ẹ wádìí bóyá ilẹ̀ náà lọ́rọ̀* àbí kò lọ́rọ̀,*+ bóyá igi wà níbẹ̀ àbí kò sí. Ẹ jẹ́ onígboyà,+ kí ẹ sì mú lára èso ilẹ̀ náà bọ̀.” Ó ṣẹlẹ̀ pé àkókò yẹn ni àkọ́pọ́n èso àjàrà+ máa ń jáde.

21 Torí náà, wọ́n gòkè lọ, wọ́n sì ṣe amí ilẹ̀ náà láti aginjù Síínì+ dé Réhóbù+ ní tòsí Lebo-hámátì.*+ 22 Nígbà tí wọ́n gòkè lọ sí Négébù, wọ́n dé Hébúrónì.+ Ibẹ̀ ni Áhímánì, Ṣéṣáì àti Tálímáì,+ tí wọ́n jẹ́ Ánákímù+ ń gbé. Ó ṣẹlẹ̀ pé, ọdún méje ni wọ́n ti kọ́ Hébúrónì ṣáájú Sóánì ti ilẹ̀ Íjíbítì. 23 Nígbà tí wọ́n dé Àfonífojì Éṣíkólì,+ wọ́n gé ẹ̀ka àjàrà tó ní òṣùṣù èso àjàrà kan, méjì lára àwọn ọkùnrin náà sì fi ọ̀pá gbọọrọ kan gbé e, pẹ̀lú pómégíránétì díẹ̀ àti èso ọ̀pọ̀tọ́+ díẹ̀. 24 Wọ́n pe ibẹ̀ ní Àfonífojì Éṣíkólì,*+ torí òṣùṣù èso tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gé níbẹ̀.

25 Lẹ́yìn ogójì (40) ọjọ́,+ wọ́n pa dà láti ilẹ̀ tí wọ́n ti lọ ṣe amí. 26 Wọ́n sì pa dà sọ́dọ̀ Mósè àti Áárónì àti gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní aginjù Páránì, ní Kádéṣì.+ Wọ́n jábọ̀ fún gbogbo àpéjọ náà, wọ́n sì fi àwọn èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n. 27 Ohun tí wọ́n ròyìn fún Mósè ni pé: “A dé ilẹ̀ tí o rán wa lọ, wàrà àti oyin+ sì ń ṣàn níbẹ̀ lóòótọ́, àwọn èso+ ibẹ̀ nìyí. 28 Àmọ́, àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà lágbára, àwọn ìlú olódi náà sì tóbi gan-an. A tún rí àwọn Ánákímù níbẹ̀.+ 29 Àwọn ọmọ Ámálékì+ ń gbé ilẹ̀ Négébù,+ àwọn ọmọ Hétì, àwọn ará Jébúsì+ àti àwọn Ámórì+ ń gbé ní agbègbè olókè, àwọn ọmọ Kénáánì+ sì ń gbé létí òkun+ àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì.”

30 Kélẹ́bù wá gbìyànjú láti fi àwọn èèyàn náà lọ́kàn balẹ̀ bí wọ́n ṣe dúró níwájú Mósè, ó sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká gòkè lọ láìjáfara, ó dájú pé a máa gba ilẹ̀ náà, torí ó dájú pé a máa borí wọn.”+ 31 Àmọ́ àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ lọ sọ pé: “A ò lè lọ bá àwọn èèyàn náà jà, torí wọ́n lágbára jù wá lọ.”+ 32 Wọ́n sì ń ròyìn ohun tí kò dáa+ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ilẹ̀ tí wọ́n lọ ṣe amí rẹ̀, wọ́n ní: “Ilẹ̀ tó ń jẹ àwọn tó ń gbé inú rẹ̀ run ni ilẹ̀ tí a lọ ṣe amí rẹ̀, gbogbo àwọn èèyàn tí a sì rí níbẹ̀ ló tóbi yàtọ̀.+ 33 A rí àwọn Néfílímù níbẹ̀, àwọn ọmọ Ánákì,+ tí wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ* àwọn Néfílímù. Lójú wọn, ṣe la dà bíi tata, bẹ́ẹ̀ náà ló sì rí lójú tiwa.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́