-
Diutarónómì 1:27, 28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Ẹ̀ ń ráhùn ṣáá nínú àwọn àgọ́ yín, ẹ sì ń sọ pé, ‘Torí Jèhófà kórìíra wa ló ṣe mú wa kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì láti fi wá lé àwọn Ámórì lọ́wọ́, kí wọ́n lè pa wá run. 28 Báwo ni ibi tí à ń lọ ṣe rí? Àwọn arákùnrin wa mú kí ẹ̀rù bà wá,*+ wọ́n sọ pé: “Àwọn èèyàn náà lágbára, wọ́n sì ga jù wá lọ, àwọn ìlú wọn tóbi, wọ́n sì mọ odi rẹ̀ kan ọ̀run,*+ a sì rí àwọn ọmọ Ánákímù+ níbẹ̀.”’
-