22 Nígbà tí wọ́n gòkè lọ sí Négébù, wọ́n dé Hébúrónì.+ Ibẹ̀ ni Áhímánì, Ṣéṣáì àti Tálímáì,+ tí wọ́n jẹ́ Ánákímù+ ń gbé. Ó ṣẹlẹ̀ pé, ọdún méje ni wọ́n ti kọ́ Hébúrónì ṣáájú Sóánì ti ilẹ̀ Íjíbítì.
21 Ìgbà yẹn ni Jóṣúà pa àwọn Ánákímù+ run kúrò ní agbègbè olókè, ní Hébúrónì, Débírì, Ánábù àti gbogbo agbègbè olókè Júdà àti gbogbo agbègbè olókè Ísírẹ́lì. Jóṣúà pa àwọn àtàwọn ìlú wọn run.+