ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jónátánì Nígboyà, Ó sì Jẹ́ Adúrótini
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Jónátánì àti ẹni tó máa ń kó ohun ìjà ogun ẹ̀ dání

      Ẹ̀KỌ́ 42

      Jónátánì Nígboyà, Ó sì Jẹ́ Adúrótini

      Jónátánì lorúkọ ọmọkùnrin tí Ọba Sọ́ọ̀lù kọ́kọ́ bí. Jagunjagun tó lákíkanjú ni, kì í bẹ̀rù. Dáfídì tiẹ̀ sọ pé Jónátánì yára ju ẹyẹ idì lọ, ó sì lágbára ju kìnnìún lọ. Lọ́jọ́ kan, Jónátánì ráwọn ọmọ ogun Filísínì tí wọ́n tó ogún (20) lórí òkè kan. Ó wá sọ fún ẹni tó máa ń ràn án lọ́wọ́ pé: ‘Tí Jèhófà bá fún wa ní àmì nìkan la máa lọ bá wọn jà. Táwọn ọmọ ogun yẹn bá sọ pé ká máa bọ̀, a máa lọ bá wọn jà.’ Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀? Àwọn ọmọ ogun Filísínì sọ fún wọn pé: ‘Ẹ máa gòkè bọ̀, ká jọ jà!’ Bí Jónátánì àti ìkejì ẹ̀ ṣe lọ bá wọn nìyẹn, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun náà.

      Jónátánì fún Dáfídì ní díẹ̀ lára ohun tó ní

      Torí pé Jónátánì ni àkọ́bí lára àwọn ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù, òun ló yẹ kó jọba lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù. Ṣùgbọ́n Jónátánì mọ̀ pé Jèhófà ti yan Dáfídì láti jẹ́ ọba Ísírẹ́lì, kò sì bínú sí i. Ńṣe lòun àti Dáfídì di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Àwọn méjèèjì ṣèlérí pé àwọn á máa ti ara wọn lẹ́yìn, àwọn ò sì ní fi ara wọn sílẹ̀. Jónátánì wá bọ́ ẹ̀wù ẹ̀ ó sì fún Dáfídì, ó tún fún un ní idà, ọrun àti bẹ́líìtì ẹ̀ kí Dáfídì lè mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀.

      Nígbà tí Dáfídì sá lọ torí Sọ́ọ̀lù, Jónátánì lọ bá Dáfídì níbi tó wà, ó sì sọ fún un pé: ‘Má bẹ̀rù, ṣó o gbọ́? Ìwọ ni Jèhófà yàn láti jẹ́ ọba. Bàbá mi náà sì mọ̀ bẹ́ẹ̀.’ Ṣé ìwọ náà fẹ́ ní ọ̀rẹ́ tó dà bíi Jónátánì?

      Àwọn ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Jónátánì fi ẹ̀mí ara ẹ̀ wewu torí Dáfídì. Ó mọ̀ pé bàbá òun fẹ́ pa Dáfídì, ó wá sọ fún bàbá ẹ̀ pé: ‘Inú Ọlọ́run ò ní dùn tẹ́ ẹ bá pa Dáfídì; kò hùwà burúkú kankan.’ Ṣé Sọ́ọ̀lù wá gbọ́rọ̀ sí ọmọ ẹ̀ lẹ́nu? Rárá o, ṣe ló bínú gan-an sí Jónátánì. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì kú sójú ogun lọ́jọ́ kan náà.

      Lẹ́yìn tí Jónátánì kú, Dáfídì lọ wá ọmọ Jónátánì tó ń jẹ́ Méfíbóṣétì. Nígbà tí Dáfídì rí Méfíbóṣétì, ó sọ fún un pé: ‘Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni èmi àti bàbá rẹ, torí náà màá tọ́jú ẹ. Wàá máa gbé nínú ààfin mi, wàá sì máa jẹun lọ́dọ̀ mi.’ Ó dájú pé Dáfídì ò gbàgbé Jónátánì ọ̀rẹ́ rẹ̀.

      “Ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín. Kò sí ẹni tí ìfẹ́ rẹ̀ ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.”​—Jòhánù 15:12, 13

      Ìbéèrè: Kí ni Jónátánì ṣe tó fi hàn pé ó nígboyà? Báwo ni Jónátánì ṣe dúró ti Dáfídì?

      1 Sámúẹ́lì 14:1-23; 18:1-4; 19:1-6; 20:32-42; 23:16-18; 31:1-7; 2 Sámúẹ́lì 1:23; 9:1-13

  • Ọba Dáfídì Dẹ́ṣẹ̀
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Wòlí ì Nátánì ń bá Ọba Dáfídì wí

      Ẹ̀KỌ́ 43

      Ọba Dáfídì Dẹ́ṣẹ̀

      Lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù kú, Dáfídì di ọba. Ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún ni nígbà yẹn. Lẹ́yìn ọdún mélòó kan tó di ọba, ohun kan ṣẹlẹ̀. Lálẹ́ ọjọ́ kan, ó wà lórí òkè ààfin ẹ̀, ó sì rí obìnrin kan tó rẹwà. Dáfídì wádìí nípa obìnrin yẹn, wọ́n sì sọ fún un pé Bátí-ṣébà lorúkọ ẹ̀ àti pé ọmọ ogun kan tó ń jẹ́ Ùráyà lọkọ ẹ̀. Dáfídì ní kí wọ́n bá òun pe Bátí-ṣébà wá. Dáfídì bá obìnrin náà sùn, obìnrin náà sì lóyún. Torí pé Dáfídì ò fẹ́ kí àṣírí òun tú, ó sọ fún ọ̀gá àwọn ọmọ ogun ẹ̀ pé kí wọ́n fi Ùráyà síwájú ogun, kí wọ́n sì pa dà lẹ́yìn ẹ̀. Bó ṣe di pé Ùráyà kú sójú ogun nìyẹn, Dáfídì sì fi Bátí-ṣébà ṣe aya.

      Ọba Dáfídì ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó dárí ji òun

      Àmọ́ Jèhófà rí gbogbo ìwà búburú tí Dáfídì hù. Kí wá ni Jèhófà ṣe? Jèhófà rán wòlíì Nátánì sí Dáfídì. Nátánì sọ fún Dáfídì pé: ‘Ọkùnrin olówó kan ní àgùntàn tó pọ̀ gan-an, tálákà kan sì ní ọmọ àgùntàn kan ṣoṣo, ó sì máa ń tọ́jú ẹ̀ gan-an. Àmọ́, ṣe ni olówó yẹn gba ọmọ àgùntàn kan ṣoṣo tí tálákà náà ní.’ Nígbà tí Dáfídì gbọ́, inú bí i, ó sì sọ pé: ‘Ṣe ló yẹ ká pa ọkùnrin olówó yẹn!’ Nátánì wá sọ fún Dáfídì pé: ‘Ìwọ gan-an ni ọkùnrin yẹn!’ Inú Dáfídì bà jẹ́, ó sì jẹ́wọ́ fún Nátánì pé: ‘Mo ti ṣẹ Jèhófà.’ Ẹ̀ṣẹ̀ tí Dáfídì dá yẹn mú wàhálà bá òun àtàwọn ará ilé ẹ̀. Jèhófà fìyà jẹ Dáfídì, àmọ́ Jèhófà ò jẹ́ kó kú torí pé Dáfídì jẹ́ olóòótọ́, ó sì rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀.

      Ó wu Dáfídì láti kọ́ tẹ́ńpìlì fún Jèhófà, àmọ́ Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì ni Jèhófà yàn pé kó kọ́ tẹ́ńpìlì fóun. Síbẹ̀, Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn nǹkan jọ fún Sólómọ́nì. Dáfídì wá sọ pé: ‘Tẹ́ńpìlì Jèhófà máa tóbi, ó sì máa lẹ́wà gan-an. Àmọ́ Sólómọ́nì ọmọ mi ṣì kéré, torí náà mo ti kó àwọn nǹkan tó máa lò sílẹ̀ fún un.’ Dáfídì kó owó rẹpẹtẹ sílẹ̀ kí wọ́n lè fi kọ́ ilé náà. Ó wá àwọn òṣìṣẹ́ tó mọṣẹ́ dáadáa. Ó kó àwọn nǹkan míì jọ, bíi wúrà àti fàdákà, ó sì kó àwọn igi kédárì wá láti ìlú Tírè àti Sídónì. Nígbà tó kù díẹ̀ kí Dáfídì kú, ó fún Sólómọ́nì ní ìwé tí wọ́n ya àwòrán tẹ́ńpìlì náà sí. Ó wá sọ fún un pé: ‘Jèhófà ló ní kí n ya àwòrán yìí sílẹ̀ fún ẹ. Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Má bẹ̀rù, ṣe bí ọkùnrin, kó o sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà.’

      Dáfídì ń fi àwòrán tẹ́ńpìlì hàn Sólómọ́nì

      “Ẹni tó bá ń bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kò ní ṣàṣeyọrí, àmọ́ ẹni tó bá jẹ́wọ́, tó sì fi wọ́n sílẹ̀ la ó fi àánú hàn sí.”​—Òwe 28:13

      Ìbéèrè: Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni Dáfídì dá? Kí ni Dáfídì fún Sólómọ́nì pé kó fi kọ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run?

      2 Sámúẹ́lì 5:3, 4, 10; 7:1-16; 8:1-14; 11:1–12:14; 1 Kíróníkà 22:1-19; 28:11-21; Sáàmù 51:1-19

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́