ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Wọ́n Kọ́ Tẹ́ńpìlì fún Jèhófà
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Iná wá látọ̀dọ̀ Jèhófà, ó sì jó gbogbo ẹbọ tí wọ́n kó sórí pẹpẹ

      Ẹ̀KỌ́ 44

      Wọ́n Kọ́ Tẹ́ńpìlì fún Jèhófà

      Ọba Sólómọ́nì ń gbàdúrà

      Lẹ́yìn tí Sólómọ́nì di ọba Ísírẹ́lì, Jèhófà béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ pé: ‘Kí lo fẹ́ kí n fún ẹ?’ Sólómọ́nì sọ pé: ‘Ọmọdé ni mí, torí náà mi ò gbọ́n. Jọ̀ọ́, fún mi ní ọgbọ́n tí màá lè fi bójú tó àwọn èèyàn ẹ.’ Jèhófà dáhùn pé: ‘Torí pé ọgbọ́n lo béèrè, màá sọ ẹ́ dẹni tó gbọ́n jù láyé. Màá sì jẹ́ kó o lówó gan-an. Tó o bá ṣe ohun tí mo fẹ́, wàá pẹ́ láyé.’

      Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ tẹ́ńpìlì, ó lo àwọn nǹkan tó dáa gan-an láti fi kọ́ tẹ́ńpìlì náà, irú bíi wúrà, fàdákà, igi àti òkúta. Àìmọye èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló pawọ́ pọ̀ kọ́ tẹ́ńpìlì náà. Ọdún méje (7) ni wọ́n fi kọ́ ọ, lẹ́yìn náà wọ́n yà á sí mímọ́ fún Jèhófà. Pẹpẹ tí wọ́n kọ́ sínú ẹ̀ ni wọ́n ti máa ń rúbọ. Sólómọ́nì kúnlẹ̀ síwájú pẹpẹ náà, ó sì gbàdúrà pé: ‘Jèhófà, tẹ́ńpìlì yìí tóbi lóòótọ́, ó sì rẹwà, àmọ́ kò lè gbà ọ́. Mo bẹ̀ ọ́, máa gbọ́ àdúrà wa, kínú ẹ sì dùn sí ìjọsìn wa.’ Ṣé inú Jèhófà dùn sí tẹ́ńpìlì yẹn, ṣé ó sì gbọ́ àdúrà Sólómọ́nì? Bẹ́ẹ̀ ni. Torí pé kò pẹ́ tí Sólómọ́nì gba àdúrà náà tán ni iná wá láti ọ̀run, ó sì jó gbogbo ẹbọ tí wọ́n kó sórí pẹpẹ. Ìyẹn fi hàn pé inú Jèhófà dùn sí tẹ́ńpìlì náà. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, inú wọn dùn gan-an.

      Iná wá látọ̀dọ̀ Jèhófà, ó sì jó gbogbo ẹbọ tí wọ́n kó sórí pẹpẹ

      Ibi gbogbo làwọn èèyàn ti ń gbọ́ pé Ọba Sólómọ́nì gbọ́n gan-an, kì í ṣe nílẹ̀ Ísírẹ́lì nìkan. Torí náà, àwọn èèyàn máa ń gbé ìṣòro wọn wá sọ́dọ̀ ẹ̀ pé kó bá wọn yanjú ẹ̀. Ọbabìnrin ilẹ̀ Ṣébà tiẹ̀ béèrè àwọn ìbéèrè tó ta kókó lọ́wọ́ Sólómọ́nì. Ṣùgbọ́n nígbà tó rí bí Sólómọ́nì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè ẹ̀, ó sọ pé: ‘Mi ò kọ́kọ́ gba ohun táwọn èèyàn sọ nípa ẹ gbọ́, àmọ́ èmi fúnra mi ti wá rí i pé ọgbọ́n ẹ kọjá ohun táwọn èèyàn sọ. Jèhófà Ọlọ́run tó ò ń sìn ti bù kún ẹ gan-an.’ Lásìkò yẹn, nǹkan ń lọ dáadáa nílẹ̀ Ísírẹ́lì, inú àwọn èèyàn sì ń dùn. Àmọ́, nǹkan máa tó yí pa dà.

      “Ẹ wò ó! ohun kan tó ju Sólómọ́nì lọ wà níbí.”​—Mátíù 12:42

      Ìbéèrè: Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí Sólómọ́nì gbọ́n gan-an? Kí ni Jèhófà ṣe táwọn èèyàn fi mọ̀ pé inú rẹ̀ dùn sí tẹ́ńpìlì náà?

      1 Àwọn Ọba 2:12; 3:4-28; 4:29–5:18; 6:37, 38; 7:15–8:66; 10:1-13; 2 Kíróníkà 7:1; 9:22

  • Ìjọba Ísírẹ́lì Pín sí Méjì
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Áhíjà ya aṣọ ẹ̀ sọ́nà méjìlá níṣojú Jèróbóámù

      Ẹ̀KỌ́ 45

      Ìjọba Ísírẹ́lì Pín sí Méjì

      Àlàáfíà wà nílẹ̀ Ísírẹ́lì ní gbogbo ìgbà tí Sólómọ́nì ń sin Jèhófà tọkàntọkàn. Àmọ́ nígbà tó yá, Sólómọ́nì lọ fẹ́ ọ̀pọ̀ obìnrin àjèjì, òrìṣà làwọn obìnrin náà sì ń bọ. Bó ṣe di pé Sólómọ́nì náà bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn àwọn òrìṣà ilẹ̀ àjèjì nìyẹn. Inú bí Jèhófà gan-an. Jèhófà wá sọ fún Sólómọ́nì pé: ‘Màá gba ilẹ̀ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ ìdílé ẹ, màá sì pín in sí méjì. Màá fún ìránṣẹ́ ẹ ní apá tó tóbi jù lára ẹ̀, ìdílé ẹ á sì máa jọba ní apá kékeré tó ṣẹ́ kù.’

      Jèhófà ṣe ohun kan tó mú kí ìpinnu ẹ̀ ṣe kedere. Lọ́jọ́ kan, ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì tó ń jẹ́ Jèróbóámù ń rìnrìn àjò, ló bá pàdé wòlíì kan tó ń jẹ́ Áhíjà. Nígbà tí wọ́n pàdé, Áhíjà fa aṣọ ara ẹ̀ ya, ó sì pín in sọ́nà méjìlá, ó wá sọ fún Jèróbóámù pé: ‘Jèhófà máa gba ilẹ̀ Ísírẹ́lì kúrò lọ́wọ́ ìdílé Sólómọ́nì, ó sì máa pín in sí méjì. Torí náà, mú ẹ̀wù mẹ́wàá lára méjìlá náà, torí pé ìwọ lo máa jọba lórí ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì.’ Nígbà tí Ọba Sólómọ́nì gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá bó ṣe máa pa Jèróbóámù. Ni Jèróbóámù bá sá lọ sí Íjíbítì. Nígbà tó yá, Sólómọ́nì kú, ọmọ ẹ̀ tó ń jẹ́ Rèhóbóámù sì di ọba. Ìgbà yẹn ni Jèróbóámù tó pa dà sí Ísírẹ́lì.

      Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń rúbọ sí eré màlúù oníwúrà tí Jèróbóámù ṣe

      Àwọn àgbààgbà tó wà ní Ísírẹ́lì sọ fún Rèhóbóámù pé: ‘Tó o bá ń ṣe dáadáa sáwọn ará ìlú, wọn ò ní fi ẹ́ sílẹ̀.’ Àmọ́, àwọn ọ̀rẹ́ Rèhóbóámù tí wọ́n jọ jẹ́ ẹgbẹ́ sọ fún un pé: ‘Ṣe ni kó o túbọ̀ fìyà jẹ wọ́n dáadáa. Kó o tún fi iṣẹ́ kún iṣẹ́ wọn.’ Kàkà kí Rèhóbóámù tẹ̀ lé ìmọ̀ràn táwọn àgbààgbà fún un, ohun táwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ sọ ló ṣe. Rèhóbóámù wá bẹ̀rẹ̀ sí í fìyà jẹ àwọn ará ìlú, àwọn èèyàn náà sì pa dà lẹ́yìn ẹ̀. Wọ́n fi Jèróbóámù jọba ẹ̀yà mẹ́wàá, ẹ̀yà mẹ́wàá yìí la wá mọ̀ sí ìjọba Ísírẹ́lì. Ẹ̀yà méjì tó kù la mọ̀ sí ìjọba Júdà, àwọn ará Júdà ò sì pa dà lẹ́yìn Rèhóbóámù. Bí ẹ̀yà méjìlá Ísírẹ́lì ṣe pín sí méjì nìyẹn.

      Jèróbóámù ò fẹ́ káwọn èèyàn òun lọ máa jọ́sìn ní Jerúsálẹ́mù torí pé abẹ́ ìjọba Rèhóbóámù nibẹ̀ wà. Ṣé o mọ ìdí? Ìdí ni pé ẹ̀rù ń ba Jèróbóámù pé tí wọ́n bá ń lọ síbẹ̀, wọ́n máa pa òun tì, wọ́n á sì pa dà sọ́dọ̀ Rèhóbóámù. Ó wá gbẹ́ ère ọmọ màlúù wúrà méjì fún wọn, ó sì sọ fún wọn pé: ‘Jerúsálẹ́mù ti jìnnà jù. Ẹ máa ṣe ìjọsìn yín níbí. Báwọn èèyàn náà ṣe gbàgbé Jèhófà nìyẹn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn àwọn ère ọmọ màlúù náà.

      “Ẹ má fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́. Nítorí àjọṣe wo ni òdodo àti ìwà tí kò bófin mu ní? . . . Àbí kí ló pa onígbàgbọ́ àti aláìgbàgbọ́ pọ̀?”​—2 Kọ́ríńtì 6:14, 15

      Ìbéèrè: Kí nìdí tílẹ̀ Ísírẹ́lì fi pín sí méjì? Kí làwọn nǹkan tí kò dáa tí Ọba Rèhóbóámù àti Ọba Jèróbóámù ṣe?

      1 Àwọn Ọba 11:1-13, 26-43; 12:1-33

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́