ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • od orí 5 ojú ìwé 30-52
  • Àwọn Alábòójútó Tó Ń Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn Agbo

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Alábòójútó Tó Ń Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn Agbo
  • A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • OHUN TÍ ẸNI TÓ FẸ́ DI ALÁBÒÓJÚTÓ MÁA ṢE
  • ÈSO TI Ẹ̀MÍ
  • ÀWỌN ỌKÙNRIN TÓ Ń MÚ KÍ ÌṢỌ̀KAN WÀ NÍNÚ ÌJỌ
  • BÓ O ṢE LÈ SAPÁ LÁTI DI ALÀGBÀ
  • TÍ IPÒ ALÀGBÀ KAN BÁ YÍ PA DÀ
  • IṢẸ́ TÍ ÀWỌN ALÀGBÀ Ń ṢE NÍNÚ ÌJỌ
  • ÀWỌN ALÁBÒÓJÚTÓ ÀWÙJỌ
  • ÌGBÌMỌ̀ IṢẸ́ ÌSÌN ÌJỌ
  • MÁA TẸRÍ BA FÚN ÀWỌN ALÁBÒÓJÚTÓ
  • ÀWỌN IṢẸ́ MÍÌ TÁWỌN ALÁBÒÓJÚTÓ Ń ṢE NÍNÚ ÈTÒ ỌLỌ́RUN
  • ALÁBÒÓJÚTÓ ÀYÍKÁ
  • ÌGBÌMỌ̀ Ẹ̀KA
  • ÀWỌN AṢOJÚ ORÍLÉ-IṢẸ́
  • WỌ́N Ń BÓJÚ TÓ WA TÌFẸ́TÌFẸ́
  • Bí Àwọn Alábòójútó Arìnrìn Àjò Ṣe Ń Ṣiṣẹ́ Sìn Gẹ́gẹ́ Bí Olùṣòtítọ́ Ìríjú
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Àwọn Alábòójútó Arìnrìn Àjò—Àwọn Ẹ̀bùn Nínú Ènìyàn
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
od orí 5 ojú ìwé 30-52

ORÍ 5

Àwọn Alábòójútó Tó Ń Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn Agbo

NÍGBÀ tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní ayé, ó fi hàn pé “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà” ni òun. (Jòh. 10:11) Nígbà tó rí èrò rẹpẹtẹ tí wọ́n ń rọ́ tẹ̀ lé e, “àánú wọn ṣe é, torí wọ́n dà bí àgùntàn tí a bó láwọ, tí a sì fọ́n ká láìní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mát. 9:36) Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù kíyè sí i pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Ẹ ò rí bí Jésù ṣe yàtọ̀ sí àwọn èké olùṣọ́ àgùntàn ilẹ̀ Ísírẹ́lì, tí wọ́n pa agbo Ọlọ́run tì débi pé àwọn àgùntàn fọ́n ká, tí ebi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì ń pa wọ́n! (Ìsík. 34:7, 8) Àmọ́ Jésù kọ́ àwọn àgùntàn lẹ́kọ̀ọ́, ó sì ń tọ́jú wọn, kódà, ó nífẹ̀ẹ́ wọn débi pé ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wọn. Àpẹẹrẹ rẹ̀ mú kí àwọn àpọ́sítélì ran àwọn tó ní ìgbàgbọ́ lọ́wọ́ láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà tó jẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn àti alábòójútó ọkàn” wọn.​—1 Pét. 2:25.

2 Nígbà kan tí Jésù ń bá Pétérù sọ̀rọ̀, ó jẹ́ kó mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa bọ́ àwọn àgùntàn kó sì máa bójú tó wọn. (Jòh. 21:15-17) Ọ̀rọ̀ yìí wọ Pétérù lọ́kàn gan-an débi pé nígbà tó yá, ó gba àwọn alàgbà ìjọ Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tó wà níkàáwọ́ yín, kí ẹ máa ṣe alábòójútó, kì í ṣe tipátipá àmọ́ kó jẹ́ tinútinú níwájú Ọlọ́run; kó má ṣe jẹ́ nítorí èrè tí kò tọ́, àmọ́ kí ẹ máa fi ìtara ṣe é látọkàn wá; ẹ má ṣe jẹ ọ̀gá lórí àwọn tó jẹ́ ogún Ọlọ́run, àmọ́ kí ẹ jẹ́ àpẹẹrẹ fún agbo.” (1 Pét. 5:1-3) Ọ̀rọ̀ tí Pétérù sọ yìí tún kan àwọn alábòójútó tó wà nínú ìjọ lónìí. Àwọn alàgbà ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ fún agbo bí wọ́n ṣe ń sìn tinútinú, tí wọ́n ń lo ìtara, tí wọ́n sì ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.​—Héb. 13:7.

Àwọn alàgbà ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ fún agbo bí wọ́n ṣe ń sìn tinútinú, tí wọ́n ń lo ìtara, tí wọ́n sì ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà

3 Ó yẹ ká dúpẹ́ pé a ní àwọn alábòójútó tá a fi ẹ̀mí yàn nínú ìjọ. Àǹfààní púpọ̀ là ń rí bí wọ́n ṣe ń bójú tó wa. Bí àpẹẹrẹ, àwọn alábòójútó ń fún wa ní ìṣírí, wọ́n sì ń bójú tó gbogbo àwọn ará nínú ìjọ. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, wọ́n máa ń fara balẹ̀ darí àwọn ìpàdé ìjọ, èyí sì ń fún ìgbàgbọ́ àwọn ará lókun. (Róòmù 12:8) Bí àwọn alàgbà ṣe ń sapá láti dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn èèyàn búburú àtàwọn nǹkan míì tó lè pa wá lára, èyí ń mú kí ọkàn wa balẹ̀. (Àìsá. 32:2; Títù 1:9-11) Bí wọ́n ṣe ń múpò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù ń mú káwa náà máa fìtara wàásù ìhìn rere déédéé ní oṣooṣù. (Héb. 13:15-17) Jèhófà ń lo “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn” yìí láti máa gbé ìjọ ró.​—Éfé. 4:8, 11, 12.

OHUN TÍ ẸNI TÓ FẸ́ DI ALÁBÒÓJÚTÓ MÁA ṢE

4 Ká lè rí i dájú pé à ń bójú tó ìjọ bó ṣe yẹ, àwọn ọkùnrin tá a yàn sípò alábòójútó gbọ́dọ̀ kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ. Tí wọ́n bá kúnjú ìwọ̀n nìkan la tó lè sọ pé ẹ̀mí mímọ́ ló yàn wọ́n. (Ìṣe 20:28) Tí Kristẹni kan bá fẹ́ di alábòójútó, àwọn ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ pé ó gbọ́dọ̀ kúnjú ìwọ̀n rẹ̀ pọ̀ gan-an, ìdí sì ni pé iṣẹ́ alábòójútó kì í ṣe iṣẹ́ kékeré. Àmọ́ àwọn ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ yẹn kì í ṣe àléèbá fún arákùnrin tó bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú, tó sì fẹ́ kí Jèhófà lo òun. Ó yẹ kó ṣe kedere sí gbogbo èèyàn pé ẹni tó jẹ́ alábòójútó máa ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò lójoojúmọ́.

Ká lè rí i dájú pé à ń bójú tó ìjọ bó ṣe yẹ, àwọn ọkùnrin tá a yàn sípò alábòójútó gbọ́dọ̀ kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ

5 Nínú lẹ́tà àkọ́kọ́ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì àti èyí tó kọ sí Títù, ó sọ àwọn ohun tí ẹni tó fẹ́ di alábòójútó gbọ́dọ̀ kúnjú ìwọ̀n rẹ̀. Ìwé 1 Tímótì 3:1-7 sọ pé: “Tí ọkùnrin kan bá ń sapá láti di alábòójútó, iṣẹ́ rere ló fẹ́ ṣe. Nítorí náà, alábòójútó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí kò lẹ́gàn, tí kò ní ju ìyàwó kan lọ, tí kì í ṣe àṣejù, tó ní àròjinlẹ̀, tó wà létòlétò, tó ń ṣe aájò àlejò, tó kúnjú ìwọ̀n láti kọ́ni, kì í ṣe ọ̀mùtí, kì í ṣe oníwà ipá, àmọ́ kó máa fòye báni lò, kì í ṣe oníjà, kì í ṣe ẹni tó fẹ́ràn owó, kó jẹ́ ọkùnrin tó ń bójú tó ilé rẹ̀ dáadáa, tí àwọn ọmọ rẹ̀ máa ń tẹrí ba, tí wọ́n sì jẹ́ onígbọràn (torí tí ọkùnrin kan ò bá mọ bó ṣe máa bójú tó ilé ara rẹ̀, báwo ló ṣe máa bójú tó ìjọ Ọlọ́run?), kì í ṣe ẹni tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yí lọ́kàn pa dà, torí ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbéraga, kó sì ṣubú sínú ìdájọ́ tí a ṣe fún Èṣù. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ kí àwọn tó wà níta máa sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa kó má bàa ṣubú sínú ẹ̀gàn àti pańpẹ́ Èṣù.”

6 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Títù pé: “Mo fi ọ́ sílẹ̀ ní Kírétè, kí o lè ṣe àtúnṣe àwọn ohun tí kò tọ́, kí o sì lè yan àwọn alàgbà láti ìlú dé ìlú, bí mo ṣe sọ fún ọ pé kí o ṣe: bí ọkùnrin èyíkéyìí bá wà tí kò ní ẹ̀sùn lọ́rùn, tí kò ní ju ìyàwó kan lọ, tí àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ onígbàgbọ́ tí wọn kò sì ní ẹ̀sùn lọ́rùn pé wọ́n jẹ́ oníwà pálapàla tàbí ọlọ̀tẹ̀. Torí pé alábòójútó jẹ́ ìríjú Ọlọ́run, kò gbọ́dọ̀ ní ẹ̀sùn lọ́rùn, kó má ṣe jẹ́ ẹni tó ń ṣe tinú ara rẹ̀, kó má ṣe jẹ́ ẹni tó ń tètè bínú, kó má ṣe jẹ́ ọ̀mùtípara, kó má ṣe jẹ́ oníwà ipá, kó má sì jẹ́ ẹni tó máa ń wá èrè tí kò tọ́, àmọ́ kó jẹ́ ẹni tó ń ṣe aájò àlejò, tó nífẹ̀ẹ́ ohun rere, tó ní àròjinlẹ̀, tó jẹ́ olódodo, olóòótọ́, tó máa ń kó ara rẹ̀ níjàánu, ẹni tó ń di ọ̀rọ̀ òtítọ́ mú ṣinṣin nínú ọ̀nà tó ń gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, kó lè fi ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní gbani níyànjú kó sì bá àwọn tó ń ṣàtakò wí.”​—Títù 1:5-9.

7 Lóòótọ́, àwọn ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ pé ẹni tó fẹ́ di alábòójútó gbọ́dọ̀ kúnjú ìwọ̀n rẹ̀ lè dà bí ohun tó kani láyà, àmọ́ kò yẹ kí àwọn arákùnrin torí ìyẹn fà sẹ́yìn. Tí àwọn arákùnrin bá ní àwọn ànímọ́ tó yẹ kí alábòójútó ní, àwọn ará ìjọ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Pọ́ọ̀lù sọ pé Ọlọ́run fún wa ní “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn” yìí kí wọ́n lè máa “tọ́ àwọn ẹni mímọ́ sọ́nà, fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, láti gbé ara Kristi ró, títí gbogbo wa á fi ṣọ̀kan nínú ìgbàgbọ́ àti nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọmọ Ọlọ́run, tí a ó fi di géńdé ọkùnrin, tí a ó sì dàgbà dé ìwọ̀n kíkún ti Kristi.”​—Éfé. 4:8, 12, 13.

8 Àwọn alábòójútó kì í ṣe ọmọdé tàbí àwọn ọkùnrin tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yí lọ́kàn pa dà. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ti ní ìrírí nípa bó ṣe yẹ kí Kristẹni máa gbé ìgbé ayé rẹ̀, wọ́n ní ìmọ̀ Bíbélì dáadáa, wọ́n ní òye tó jinlẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́, wọ́n sì tún ní ìfẹ́ àtọkànwá fún ìjọ. Wọn kì í bẹ̀rù láti bá ẹni tó hùwà àìtọ́ nínú ìjọ sọ̀rọ̀ kí wọ́n sì tọ́ onítọ̀hún sọ́nà, wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ dáàbò bo àwọn ará ìjọ lọ́wọ́ ẹni tó fẹ́ rẹ́ wọn jẹ. (Àìsá. 32:2) Àwọn ará ìjọ gbà pé àwọn alábòójútó jẹ́ ẹni tẹ̀mí, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ agbo Ọlọ́run dénúdénú.

9 Àwọn tó kúnjú ìwọ̀n láti di alábòójútó ní láti máa gbé ìgbésí ayé wọn lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu. Tí alábòójútó bá ti ní ìyàwó, ó gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì nípa ìgbéyàwó, ìyẹn ni pé kò gbọ́dọ̀ ní ju ìyàwó kan lọ, ó sì gbọ́dọ̀ máa bójú tó ilé rẹ̀ dáadáa. Tí àwọn ọmọ rẹ̀ bá jẹ́ onígbàgbọ́, tí wọ́n ń tẹrí ba, tí wọ́n jẹ́ onígbọràn, tí wọn kò sì ní ẹ̀sùn lọ́rùn pé wọ́n jẹ́ oníwà pálapàla tàbí ọlọ̀tẹ̀, á yá àwọn ará ìjọ lára láti lọ bá alábòójútó náà pé kó fún àwọn nímọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ ìdílé àti ìgbésí ayé. Alábòójútó tún ní láti jẹ́ ẹni tí kò lẹ́gàn, tí kò ní ẹ̀sùn lọ́rùn, tí àwọn tó wà níta pàápàá ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa. Kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí wọ́n fi ẹ̀sùn tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ kàn pé ó hu ìwàkiwà tó lè kó ẹ̀gàn bá ìjọ. Kò yẹ kó jẹ́ ẹni tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fún ní ìbáwí lórí ìwà àìtọ́ tó burú jáì. Àwọn ará ìjọ á fẹ́ láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere rẹ̀, inú wọn á sì dùn pé kó máa tọ́ àwọn sọ́nà nínú ìjọsìn Ọlọ́run.​—1 Kọ́r. 11:1; 16:15, 16.

10 Irú àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n yìí á lè ṣiṣẹ́ nínú ìjọ Kristẹni bíi ti àwọn àgbààgbà ilẹ̀ Ísírẹ́lì tí Bíbélì sọ pé wọ́n jẹ́ “ọlọ́gbọ́n àti olóye àti onírìírí.” (Diu. 1:13) Àwọn alàgbà ìjọ Kristẹni kì í ṣe ẹni tí kò lè dẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ará ìjọ àtàwọn ará àdúgbò mọ̀ pé wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin, wọ́n ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, wọ́n sì ti fi hàn pé ìlànà Ọlọ́run ni wọ́n máa ń tẹ̀ lé nínú ìgbésí ayé wọn. Torí pé wọ́n jẹ́ aláìlẹ́bi, wọ́n lẹ́nu ọ̀rọ̀ nínú ìjọ.​—Róòmù 3:23.

11 Àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n láti di alábòójútó kì í ṣe àṣejù nínú ìwà àti nínú àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn èèyàn. Wọ́n máa ń wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn fi hàn pé wọn kì í kọjá ààyè wọn, wọ́n sì ń kó ara wọn níjàánu. Yálà wọ́n ń jẹ tàbí wọ́n ń mu, wọ́n ń ṣeré ìtura tàbí wọ́n ń ṣeré ìnàjú, wọ́n kì í ṣàṣejù. Wọn kì í ṣe àṣejù nídìí ọtí kí wọ́n má bàa di ẹni tá a fẹ̀sùn kàn pé ó jẹ́ ọ̀mùtí. Ẹni tí ọtí ti pa níyè kò ní lè kó ara rẹ̀ níjàánu, kò sì ní lè bójú tó àwọn nǹkan tó máa gbé ìgbàgbọ́ àwọn ará ìjọ ró.

12 Kí ọkùnrin kan tó lè bójú tó ìjọ, ó ní láti jẹ́ ẹni tó wà létòletò dé ìwọ̀n tó yẹ. Bó ṣe wà létòlétò yìí máa hàn nínú ìrísí rẹ̀, ilé rẹ̀ àti nínú ohun tó ń ṣe lójoojúmọ́. Irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ kì í fòní dónìí fọ̀la dọ́la, ó mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe, á sì pinnu ọ̀nà tó máa gbà ṣe é. Ìlànà Ọlọ́run ló máa ń tẹ̀ lé.

13 Alábòójútó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó máa ń fòye báni lò. Ó gbọ́dọ̀ mọ béèyàn ṣe ń ṣiṣẹ́ níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn alàgbà yòókù, kó sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn. Kò gbọ́dọ̀ jọ ara rẹ̀ lójú, kò sì gbọ́dọ̀ máa retí pé kí àwọn èèyàn ṣe kọjá agbára wọn. Torí pé alábòójútó jẹ́ afòyebánilò, kì í rin kinkin mọ́ èrò tara rẹ̀, kó máa rò pé èrò tòun ló dáa ju tàwọn alàgbà yòókù lọ. Àwọn míì lè ní àwọn ànímọ́ tí kò ní tàbí kí wọ́n lè ṣe àwọn nǹkan tí kò lè ṣe. Alàgbà kan máa fi hàn pé òun jẹ́ afòyebánilò tó bá ń ṣe àwọn ìpinnu tó bá Ìwé Mímọ́ mu tó sì ń sapá láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi. (Fílí. 2:2-8) Kò yẹ kí alàgbà jẹ́ oníjà tàbí oníwà ipá, ó gbọ́dọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn èèyàn, kó sì gbà pé àwọn míì sàn ju òun lọ. Kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ń ṣe tinú ara rẹ̀, tó ń fi dandan lé e pé káwọn èèyàn gba èrò òun tàbí kí wọ́n ṣe nǹkan lọ́nà tí òun ń gbà ṣe é. Kì í ṣe ẹni tó máa ń tètè bínú ṣùgbọ́n ó máa ń wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn.

14 Bákan náà, ẹni tó kúnjú ìwọ̀n láti di alábòójútó nínú ìjọ gbọ́dọ̀ ní àròjinlẹ̀. Èyí túmọ̀ sí pé ó jẹ́ onílàákàyè, tí kì í kánjú ṣe ìpinnu. Ó lóye àwọn ìlànà Jèhófà dáadáa ó sì mọ bó ṣe lè lò wọ́n. Ẹni tó bá ń ronú jinlẹ̀ máa ń gba ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà. Kì í ṣe alágàbàgebè.

15 Pọ́ọ̀lù rán Títù létí pé alábòójútó ní láti jẹ́ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ ohun rere. Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ olódodo àti olóòótọ́. Àwọn ànímọ́ yìí máa hàn tí nǹkan bá da òun àtàwọn ẹlòmíì pọ̀ àti nínú ọwọ́ tó fi ń mú ohun tó tọ́ àti ohun rere. Ó ń sin Jèhófà láìyẹsẹ̀, ó sì ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo nínú gbogbo ohun tó bá ń ṣe. Ó máa ń pa ọ̀rọ̀ àṣírí mọ́. Ó tún máa ń ṣe aájò àlejò tinútinú, ó máa ń yọ̀ǹda ara rẹ̀ àtàwọn nǹkan ìní rẹ̀ fún àwọn èèyàn.​—Ìṣe 20:33-35.

16 Kí alábòójútó tó lè ṣe iṣẹ́ rẹ̀ bí iṣẹ́, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó kúnjú ìwọ̀n láti kọ́ni. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ fún Títù, alábòójútó gbọ́dọ̀ jẹ́ “ẹni tó ń di ọ̀rọ̀ òtítọ́ mú ṣinṣin nínú ọ̀nà tó ń gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, kó lè fi ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní gbani níyànjú kó sì bá àwọn tó ń ṣàtakò wí.” (Títù 1:9) Ó mọ bó ṣe lè fèrò wérò kó sì fi ẹ̀rí ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn, ó lè borí àtakò, ó sì lè lo Ìwé Mímọ́ láti yí àwọn èèyàn lérò pa dà kó sì fún ìgbàgbọ́ wọn lókun. Alábòójútó máa ń lo àwọn ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí nígbà tó rọrùn àti nígbà tí kò rọrùn. (2 Tím. 4:2) Ó máa ń mú sùúrù kó lè fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá ẹni tó ṣàṣìṣe wí. Ó sì lè ran ẹni tó ń ṣiyè méjì lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ lè sún un láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Tí alábòójútó kan bá kúnjú ìwọ̀n láti kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn tàbí ẹnì kan ṣoṣo lẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn fi hàn pé ó kúnjú ìwọ̀n apá pàtàkì yìí tá à ń béèrè lọ́wọ́ àwọn alábòójútó.

17 Ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn alàgbà máa fì ìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù. Ó tún gbọ́dọ̀ ṣe kedere pé wọ́n ń sapá láti fara wé Jésù tó fi iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere sí ipò àkọ́kọ́. Jésù fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun jẹ òun lọ́kàn, ó ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ajíhìnrere tó já fáfá. (Máàkù 1:38; Lúùkù 8:1) Bí àwọn alàgbà ṣe ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù láìka bí ọwọ́ wọn ṣe dí tó máa ń mú kí gbogbo ará ìjọ pẹ̀lú máa fìtara wàásù. Tí àwọn alàgbà bá sì ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí pẹ̀lú àwọn tó wà nínú ìdílé wọn àti àwọn míì nínú ìjọ, wọ́n á lè ‘jọ máa fún ara wọn ní ìṣírí.’​—Róòmù 1:11, 12.

18 Ó lè dà bíi pé gbogbo nǹkan tá à ń retí pé kí alábòójútó kúnjú ìwọ̀n rẹ̀ ti pọ̀ jù. Ó dájú pé kò sí alábòójútó kankan tó lè kúnjú ìwọ̀n àwọn ìlànà gíga tó wà nínú Bíbélì lọ́nà tó pé pérépéré, ṣùgbọ́n kò yẹ kí alàgbà èyíkéyìí tá a yàn sípò nínú ìjọ ṣaláìní àwọn ànímọ́ yìí débi tí yóò fi wá di àbùkù rẹ̀. Alàgbà kan lè ní àwọn ànímọ́ kan tó ta yọ, àwọn míì sì lè ní àwọn apá ibòmíì tí wọ́n dáa sí. Ohun tí èyí máa yọrí sí ni pé ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà á ní gbogbo ànímọ́ rere tí wọ́n nílò láti bójú tó ìjọ Ọlọ́run bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.

19 Tí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà bá ń dábàá àwọn ọkùnrin tí wọ́n máa yàn sípò alábòójútó, á dáa kí wọ́n máa rántí ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Mo sọ fún gbogbo ẹni tó wà láàárín yín níbẹ̀ pé kó má ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, àmọ́ kó máa ronú lọ́nà tó fi hàn pé ó láròjinlẹ̀, bí Ọlọ́run ṣe fún kálukú ní ìwọ̀n ìgbàgbọ́.” (Róòmù 12:3) Alàgbà kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ gbà pé òun rẹlẹ̀ sí àwọn yòókù. Kó yẹ kí ẹnikẹ́ni nínú wọn “ṣe òdodo àṣelékè” nígbà tí wọ́n bá ń gbé ẹnì kan yẹ̀ wò. (Oníw. 7:16) Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ lóye ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ pé kí ẹni tó fẹ́ di alábòójútó kúnjú ìwọ̀n rẹ̀, lẹ́yìn náà kí wọ́n pinnu bóyá arákùnrin kan dójú ìlà dé ìwọ̀n tó bọ́gbọ́n mu. Tí àwọn alàgbà bá fi sọ́kàn pé kò sẹ́ni tó pé, tí wọn ò sì fàyè gba ojúsàájú àti àgàbàgebè, wọ́n á lè dábàá àwọn tá a fẹ́ yàn sípò nínú ìjọ lọ́nà tó bá ìlànà òdodo Jèhófà mu, tó sì máa ṣe ìjọ láǹfààní. Wọ́n á gbàdúrà nípa ẹnì kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fẹ́ dámọ̀ràn, wọ́n á sì jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run darí àwọn. Ọ̀kan lára iṣẹ́ ńlá tí wọ́n ń ṣe nìyí, wọ́n sì gbọ́dọ̀ fi ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún wọn sọ́kàn pé kí wọ́n “má fi ìkánjú gbé ọwọ́ lé ọkùnrin èyíkéyìí láé.”​—1 Tím. 5:21, 22.

ÈSO TI Ẹ̀MÍ

20 Àwọn ọkùnrin tó bá kúnjú ìwọ̀n ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ máa ń fi hàn pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń darí àwọn, wọ́n sì máa ń fi èso ti ẹ̀mí ṣèwà hù. Pọ́ọ̀lù wá sọ apá mẹ́sàn-án tí èso ti ẹ̀mí pín sí, àwọn ni “ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, sùúrù, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.” (Gál. 5:22, 23) Irú àwọn alábòójútó bẹ́ẹ̀ máa ń mára tu àwọn ará, wọ́n sì máa ń mú kí ìjọ wà ní ìṣọ̀kan bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́. Ìwà wọn àti àṣeyọrí wọn ń fi hàn pé ẹ̀mí mímọ́ ló yàn wọ́n.​—Ìṣe 20:28.

ÀWỌN ỌKÙNRIN TÓ Ń MÚ KÍ ÌṢỌ̀KAN WÀ NÍNÚ ÌJỌ

21 Ó ṣe pàtàkì pé káwọn alàgbà fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti mú kí ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ. Ìwà wọn lè yàtọ̀ síra gan-an, síbẹ̀ tí wọ́n bá ń bọ̀wọ̀ fúnra wọn, tí wọ́n sì ń fetí sílẹ̀ síra wọn, ìyẹn á mú kí ìṣọ̀kan túbọ̀ wà láàárín wọn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé èrò wọn lè yàtọ̀ síra lórí àwọn ọ̀rọ̀ kan. Bí ìpinnu wọn kò bá ti ta ko ìlànà Bíbélì èyíkéyìí, kálukú wọn gbọ́dọ̀ ṣe tán láti fara mọ́ ìpinnu tí ìgbìmọ̀ alàgbà bá ṣe. Ẹni tó ṣe tán láti fara mọ́ èrò àwọn ẹlòmíì ń fi hàn pé “ọgbọ́n tó wá láti òkè” tó “lẹ́mìí àlàáfíà” tó sì “ń fòye báni lò,” ló ń dárí òun. (Jém. 3:17, 18) Alàgbà kankan ò gbọ́dọ̀ ka ara rẹ̀ sí ẹni tó ṣe pàtàkì ju àwọn yòókù lọ, alàgbà kankan kò sì gbọ́dọ̀ máa pàṣẹ lé àwọn yòókù lórí. Táwọn alàgbà bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nínú ìgbìmọ̀ wọn torí àtiṣe ìjọ láǹfààní, ṣe ni wọ́n ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Jèhófà.​—1 Kọ́r., orí 12; Kól. 2:19.

BÓ O ṢE LÈ SAPÁ LÁTI DI ALÀGBÀ

22 Ó yẹ kí àwọn arákùnrin tó dàgbà nípa tẹ̀mí sapá láti di alábòójútó. (1 Tím. 3:1) Àmọ́, ẹni tó bá fẹ́ di alàgbà gbọ́dọ̀ ṣe tán láti ṣiṣẹ́ kó sì lo ara rẹ̀ fáwọn ẹlòmíì. Ìyẹn ni pé kó máa yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti ran àwọn ará lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Ẹni tó ń sapá láti di alábòójútó gbọ́dọ̀ máa tiraka kó lè kúnjú ìwọ̀n ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́.

TÍ IPÒ ALÀGBÀ KAN BÁ YÍ PA DÀ

23 Arákùnrin kan tó ti jẹ́ alábòójútó fún ọ̀pọ̀ ọdún lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn tàbí kí àwọn nǹkan míì mú kó má lè bójú tó iṣẹ́ rẹ̀. Bóyá ọjọ́ ogbó ò jẹ́ kó lè ṣe iṣẹ́ alábòójútó mọ́. Síbẹ̀, ó yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fún un torí pé alàgbà ṣì ni. Kò sí ìdí fún un láti fi ipò alàgbà sílẹ̀ bí ò tiẹ̀ lè ṣe nǹkan púpọ̀ mọ́. Ọlá ìlọ́po méjì tá à ń fún àwọn alàgbà tó ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti máa bójú tó agbo Ọlọ́run náà ló yẹ ká fún irú alàgbà bẹ́ẹ̀.

24 Ṣùgbọ́n tí arákùnrin kan bá rí i pé ohun tó máa dáa jù ni pé kí òun fi ipò alàgbà sílẹ̀ torí pé ipò òun tó yí pa dà kò ní jẹ́ kí òun lè fi bẹ́ẹ̀ sìn mọ́, ó lè ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Pét. 5:2) Ó yẹ ká ṣì máa bọ̀wọ̀ fún un. Ó ṣì wúlò púpọ̀ fún ìjọ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé a kò fún un ní àwọn iṣẹ́ tá a máa ń fún àwọn alàgbà.

IṢẸ́ TÍ ÀWỌN ALÀGBÀ Ń ṢE NÍNÚ ÌJỌ

25 Onírúurú iṣẹ́ làwọn alàgbà ń ṣe nínú ìjọ. Ìjọ kọ̀ọ̀kan máa ń ní olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà, akọ̀wé, alábòójútó iṣẹ́ ìsìn, olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ àti alábòójútó Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Ọ̀pọ̀ alàgbà ló jẹ́ alábòójútó àwùjọ. A kì í sábà yí àwọn alàgbà yìí pa dà kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn. Àmọ́, tí alàgbà kan bá kó lọ sí ìjọ míì tàbí tí kò lè ṣe iṣẹ́ rẹ̀ mọ́ nítorí àìlera, tàbí kò lè sìn mọ́ torí pé kò kúnjú ìwọ̀n ohun tá a béèrè nínú Ìwé Mímọ́ mọ́, a máa gbé iṣẹ́ rẹ̀ fún alàgbà míì. Ní àwọn ìjọ tí àwọn alábòójútó kò bá ti pọ̀ tó, ó lè pọn dandan pé kí alàgbà kan máa ṣe ju iṣẹ́ kan lọ títí wọ́n á fi yan àwọn arákùnrin míì tó kúnjú ìwọ̀n sípò alàgbà.

26 Olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ló máa ń ṣe alága tí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà bá ń ṣèpàdé. Ó máa ń fi ìrẹ̀lẹ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà tó kù láti bójú tó agbo Ọlọ́run. (Róòmù 12:10; 1 Pét. 5:2, 3) Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó máa ń ṣe nǹkan létòlétò, tó sì lè bójú tó nǹkan lọ́nà tó já fáfá.​—Róòmù 12:8.

27 Akọ̀wé ló ń tọ́jú àwọn àkọsílẹ̀ ìjọ, òun ló sì máa ń fi àwọn ìsọfúnni pàtàkì tó àwọn alàgbà létí. Bó bá pọn dandan, a lè yan alàgbà míì tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tó dáńgájíá pé kó máa ràn án lọ́wọ́.

28 Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ló máa ń ṣètò iṣẹ́ ìsìn pápá àtàwọn nǹkan míì tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Ó máa ń ṣètò ìbẹ̀wò déédéé sí àwùjọ kọ̀ọ̀kan, tó fi jẹ́ pé ó máa ń lo òpin ọ̀sẹ̀ kan lóṣooṣù láti bẹ àwùjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wò. Ní ìjọ kékeré tí kò ní àwùjọ tó pọ̀, ó lè bẹ àwùjọ kan wò lẹ́ẹ̀méjì lọ́dún. Nígbà ìbẹ̀wò rẹ̀, òun ló máa darí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá, á bá àwùjọ náà ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, á sì ran àwọn akéde lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

ÀWỌN ALÁBÒÓJÚTÓ ÀWÙJỌ

29 Ọ̀kan lára àwọn àǹfààní pàtàkì tí alàgbà kan lè ní nínú ìjọ ni pé kó máa ṣe alábòójútó àwùjọ. Lára àwọn iṣẹ́ alábòójútó àwùjọ ni pé (1) kó máa ran ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú àwùjọ rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ lágbára nípa tẹ̀mí; (2) kó máa ran ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú àwùjọ rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa wàásù déédéé, lọ́nà tó nítumọ̀, kí wọ́n sì máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ náà; àti pé (3) kó máa ran àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó wà ní àwùjọ rẹ̀ lọ́wọ́, kó sì máa dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa sapá kọ́wọ́ wọn lè tẹ àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ló máa pinnu àwọn arákùnrin tó kúnjú ìwọ̀n jù lọ tó máa lè bójú tó àwọn apá tí iṣẹ́ yìí pín sí.

30 Nítorí bí iṣẹ́ náà ṣe rí, tó bá ṣeé ṣe alàgbà ni kó jẹ́ alábòójútó àwùjọ. Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tó dáńgájíá sì lè máa ṣe iṣẹ́ náà títí dìgbà tá a máa rí alàgbà tó lè ṣe é. Ìránṣẹ́ àwùjọ la ó máa pe ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó bá ń ṣe iṣẹ́ yìí, torí pé kì í ṣe alábòójútó nínú ìjọ. Torí náà, àwọn alàgbà ni yóò máa darí rẹ̀ nínú iṣẹ́ tó ń ṣe.

31 Iṣẹ́ pàtàkì kan lára iṣẹ́ alábòójútó àwùjọ ni pé kó máa mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù. Bó ṣe ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù déédéé, tó ń lo ìtara, tó sì ń ṣe ọ̀yàyà máa fún àwọn tó wà ní àwùjọ rẹ̀ níṣìírí. Torí pé àwọn akéde máa ń rí ìṣírí àti ìrànlọ́wọ́ gbà nígbà tí wọ́n bá wà pa pọ̀, á dáa kí alábòójútó náà ṣètò àwọn ìgbà tí àwùjọ rẹ̀ á jọ máa lọ wàásù, kó sì jẹ́ àsìkò tó rọ ọ̀pọ̀ lọ́rùn. (Lúùkù 10:1-16) Alábòójútó àwùjọ gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ìpínlẹ̀ ìwàásù tó pọ̀ tó máa ń wà fún àwọn tó bá jáde. Òun ló sábà máa ń darí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá táá sì ṣètò àwọn ará fún iṣẹ́ ọjọ́ yẹn. Tí kò bá lè wá, kó ṣètò pé kí alàgbà míì tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan bá òun ṣe iṣẹ́ náà. Bí kò bá sì rí àwọn yẹn, ó lè ní kí akéde kan tó kúnjú ìwọ̀n bá òun ṣe iṣẹ́ náà kí àwọn ará lè rí ẹni darí wọn.

32 Kí alábòójútó àwùjọ múra sílẹ̀ de ìbẹ̀wò alábòójútó iṣẹ́ ìsìn, kó sọ fún àwùjọ rẹ̀ nípa ìbẹ̀wò náà, kó sì mú kí wọ́n máa wọ̀nà fún àǹfààní tí ìbẹ̀wò náà máa ṣe wọ́n. Tí gbogbo àwọn tó wà ní àwùjọ bá mọ̀ nípa ìbẹ̀wò náà, wọ́n á lè fi ìtara kọ́wọ́ tì í.

33 A dìídì ṣètò pé kí iye àwọn ará tó máa wà ní àwùjọ kọ̀ọ̀kan kéré. Èyí á jẹ́ kí alábòójútó àwùjọ lè mọ gbogbo àwọn tó wà ní àwùjọ náà dáadáa. Nítorí pé ó jẹ́ alábòójútó tó nífẹ̀ẹ́, ọ̀rọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan tó wà nínú àwùjọ náà máa ń jẹ ẹ́ lọ́kàn. Ó máa ń ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́, ó sì máa ń fún wọn níṣìírí láti máa wàásù kí wọ́n sì máa lọ sáwọn ìpàdé ìjọ. Ó tún máa ń sapá láti ṣe ohun tó bá yẹ kó lè ran ẹnì kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ kí wọ́n lè lágbára nípa tẹ̀mí. Àwọn tó bá ń ṣàìsàn tàbí àwọn tí ọkàn wọn rẹ̀wẹ̀sì máa jàǹfààní nínú ìbẹ̀wò tí alábòójútó náà bá ṣe sọ́dọ̀ wọn. Ọ̀rọ̀ ìṣírí tàbí ìmọ̀ràn tó ń gbéni ró tó ń fún wọn lè mú kí àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í sapá kí wọ́n lè ní àfikún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ kí wọ́n sì túbọ̀ máa ran àwọn ará lọ́wọ́. Àwọn tó wà nínú àwùjọ rẹ̀ ni alábòójútó àwùjọ kan sábà máa ń ràn lọ́wọ́ lákọ̀ọ́kọ́. Àmọ́, nítorí pé ó jẹ́ alàgbà àti olùṣọ́ àgùntàn, ọ̀rọ̀ gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ máa ń jẹ ẹ́ lọ́kàn, ó sì ṣe tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́.​—Ìṣe 20:17, 28.

34 Ara iṣẹ́ alábòójútó àwùjọ ni pé kó gba ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá àwọn tó wà ní àwùjọ rẹ̀. Á wá kó àwọn ìròyìn náà fún akọ̀wé. Táwọn akéde bá ń tètè fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn sílẹ̀, wọ́n á mú kí iṣẹ́ alábòójútó àwùjọ rọrùn. Wọ́n sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ tí wọ́n bá ń fi ìròyìn wọn lé alábòójútó àwùjọ lọ́wọ́ níparí oṣù tàbí tí wọ́n fi sínú àpótí tá à ń kó ìròyìn sí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.

ÌGBÌMỌ̀ IṢẸ́ ÌSÌN ÌJỌ

35 Àwọn iṣẹ́ kan wà tí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ máa ń bójú tó, àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ náà ni olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà, akọ̀wé àti alábòójútó iṣẹ́ ìsìn. Bí àpẹẹrẹ, ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn ló ń fọwọ́ sí lílo Gbọ̀ngàn Ìjọba fún ìgbéyàwó àti ọ̀rọ̀ ìsìnkú, ìgbìmọ̀ náà ló sì tún máa ń pín àwọn akéde sí àwùjọ. Ìgbìmọ̀ yìí ló tún ń fọwọ́ sí ìwé ìwọṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé àti ti aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ àtàwọn fọ́ọ̀mù tó wà fún àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn míì. Ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn wà lábẹ́ ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà.

36 Ẹ̀ka ọ́fíísì máa ń sọ iṣẹ́ tí àwọn arákùnrin yìí ń ṣe, títí kan iṣẹ́ olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, alábòójútó Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ àti ti àwọn míì nínú ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà.

37 Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan máa ń pàdé pọ̀ látìgbàdégbà láti jíròrò bí ìjọ ṣe lè máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Yàtọ̀ sí ìpàdé táwọn alàgbà máa ń ṣe nígbà ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, wọ́n tún máa ń ṣe ìpàdé míì ní nǹkan bí oṣù mẹ́ta lẹ́yìn ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká. Àmọ́, àwọn alàgbà lè ṣètò ìpàdé míì nígbàkigbà tí ipò àwọn nǹkan bá gbà pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.

MÁA TẸRÍ BA FÚN ÀWỌN ALÁBÒÓJÚTÓ

38 Aláìpé ni àwọn alábòójútó, síbẹ̀ a gba gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ níyànjú pé kí wọ́n máa tẹrí ba fún wọn torí pé Jèhófà ló ṣètò wọn. Àwọn alábòójútó máa jíhìn fún Ọlọ́run. Jèhófà àti àkóso rẹ̀ ni wọ́n ń ṣojú fún. Ìwé Hébérù 13:17 sọ pé: “Ẹ máa ṣègbọràn sí àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì máa tẹrí ba, torí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí yín bí àwọn tó máa jíhìn, kí wọ́n lè ṣe é tayọ̀tayọ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn, torí èyí máa pa yín lára.” Bí Jèhófà ṣe fi ẹ̀mí mímọ́ yan ọkùnrin kan sípò, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe lè fi ẹ̀mí mímọ́ yọ ọ́ kúrò nípò alábòójútó tí kò bá fi èso tẹ̀mí hàn nínú ìgbésí ayé rẹ̀ mọ́, tí ìwà rẹ̀ kò sì bá ìlànà Ìwé Mímọ́ mu mọ́.

39 Ó dájú pé a mọyì iṣẹ́ ribiribi tí àwọn alábòójútó nínú ìjọ ń ṣe àti àpẹẹrẹ àtàtà tí wọ́n ń fi lélẹ̀. Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará ìjọ Tẹsalóníkà pé: “Ẹ̀yin ará, a fẹ́ kí ẹ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ kára láàárín yín, tí wọ́n ń ṣe àbójútó yín nínú Olúwa, tí wọ́n sì ń gbà yín níyànjú; ẹ máa kà wọ́n sí lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ nínú ìfẹ́ nítorí iṣẹ́ wọn.” (1 Tẹs. 5:12, 13) Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àṣekára tí àwọn alábòójútó ìjọ ń ṣe ń mú kí iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run túbọ̀ rọrùn, ká sì túbọ̀ gbádùn ẹ̀. Bákan náà, nínú lẹ́tà àkọ́kọ́ tí Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì, ó mẹ́nu kan bó ṣe yẹ káwọn ará nínú ìjọ máa ṣe sí àwọn alábòójútó. Ó ní: “Ó yẹ ká fún àwọn alàgbà tó ń ṣe àbójútó lọ́nà tó dáa ní ọlá ìlọ́po méjì, pàápàá àwọn tó ń ṣiṣẹ́ kára nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni.”​—1 Tím. 5:17.

ÀWỌN IṢẸ́ MÍÌ TÁWỌN ALÁBÒÓJÚTÓ Ń ṢE NÍNÚ ÈTÒ ỌLỌ́RUN

40 Nígbà míì, a máa ń yan àwọn alàgbà kan láti sìn nínú Àwùjọ Tó Ń Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò. Àwọn alàgbà míì ń sìn nínú Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn, wọ́n sì máa ń ṣèbẹ̀wò sí àwọn ilé ìwòsàn àti sọ́dọ̀ àwọn dókítà kí wọ́n lè gbà wọ́n níyànjú láti máa tọ́jú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láì fa ẹ̀jẹ̀ sí wa lára. Àwọn alábòójútó míì máa ń kọ́wọ́ ti iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run nípa kíkọ́ àti bíbójútó àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ, wọ́n sì lè jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Àpéjọ Agbègbè. Gbogbo wa nínú ètò Ọlọ́run la mọrírì iṣẹ́ àṣekára tí àwọn arákùnrin yìí ń ṣe àti bí wọ́n ṣe ń lo ara wọn tinútinú. Ká sòótọ́, a “ka irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ sí ẹni ọ̀wọ́n.”​—Fílí. 2:29.

ALÁBÒÓJÚTÓ ÀYÍKÁ

41 Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló ń ṣètò bí wọ́n ṣe máa ń yan àwọn alàgbà tó kúnjú ìwọ̀n láti jẹ́ alábòójútó àyíká. Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń ṣètò wọn láti bẹ àwọn ìjọ tó wà nínú àyíká kan wò, wọ́n sì sábà máa ń bẹ àwọn ìjọ wò lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún. Wọ́n tún máa ń ṣèbẹ̀wò látìgbàdégbà sọ́dọ̀ àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó ń sìn láwọn ìpínlẹ̀ àdádó. Wọ́n máa ń ṣètò ìgbà tí wọ́n máa bẹ ìjọ kọ̀ọ̀kan wò, wọ́n á sì fi tó àwọn ìjọ náà létí tipẹ́ kí ìbẹ̀wò náà tó dé, káwọn ará lè jàǹfààní dáadáa.

42 Olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ló máa ń mú ipò iwájú láti ṣètò àwọn nǹkan kí ìbẹ̀wò náà lè tu gbogbo ará ìjọ lára. (Róòmù 1:11, 12) Gbàrà tí olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà bá ti gba ìwé ìbẹ̀wò, tó sì ti mọ àwọn nǹkan tí alábòójútó àyíká àti ìyàwó rẹ̀ máa nílò (ìyẹn tó bá ní ìyàwó), òun àtàwọn arákùnrin míì á ṣètò ibi tí alábòójútó àyíká máa dé sí àtàwọn nǹkan míì tó yẹ. Á rí i dájú pé àwọn ará ìjọ àti alábòójútó àyíká mọ ètò táwọn ti ṣe.

43 Alábòójútó àyíká máa kàn sí olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà láti mọ ètò tí wọ́n ṣe fún àwọn ìpàdé, títí kan ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá. Tí wọ́n bá ń ṣe àwọn ètò náà, kí wọ́n tẹ̀ lé ìtọ́ni tí ẹ̀ka ọ́fíìsì fún wọn àtohun tí alábòójútó àyíká bá dábàá. Ṣáájú ìbẹ̀wò náà ló ti yẹ kí àwọn ará ìjọ mọ àkókò àti ibi tí wọ́n ti máa ṣe ìpàdé ìjọ, ìpàdé àwọn aṣáájú-ọ̀nà àti ìpàdé àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, wọ́n sì gbọ́dọ̀ mọ àkókò àti ibi tí wọ́n ti máa pàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá.

44 Ọ̀sán ọjọ́ Tuesday ni alábòójútó àyíká máa ń ṣàyẹ̀wò Àkọsílẹ̀ Akéde Ìjọ (Congregation’s Publisher Record), àkọsílẹ̀ iye àwọn tó ń wá sí ìpàdé, àkọsílẹ̀ ìpínlẹ̀ ìwàásù àti àkọsílẹ̀ ìnáwó. Èyí á jẹ́ kó lè rí ibi tí ìjọ ti nílò ìrànlọ́wọ́, á sì lè ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ń bójú tó àwọn àkọsílẹ̀ náà. Kí olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà rí i dájú pé òun ti ṣètò àwọn àkọsílẹ̀ náà sílẹ̀ kí alábòójútó àyíká tó dé.

45 Nígbà tí alábòójútó àyíká bá ń bẹ ìjọ wò, ó máa fara balẹ̀ bá àwọn akéde sọ̀rọ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan bó bá ṣe rí àyè tó, ó lè jẹ́ ní ìpàdé, lóde ẹ̀rí, nígbà tí wọ́n bá ń ṣe é lálejò tàbí láwọn ìgbà míì. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń bá àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ṣèpàdé, ó máa fún wọn ní ìmọ̀ràn, àbá àti ọ̀rọ̀ ìyànjú tó bá yẹ látinú Ìwé Mímọ́, èyí tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo tí wọ́n ń bójú tó. (Òwe 27:23; Ìṣe 20:26-32; 1 Tím. 4:11-16) Ó tún máa ń bá àwọn aṣáájú-ọ̀nà ṣèpàdé kó lè fún wọn ní ìṣírí kó sì ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́ lórí ìṣòro èyíkéyìí tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

46 Tí àwọn ọ̀rọ̀ míì bá wà tó ń fẹ́ àbójútó, alábòójútó àyíká máa ràn wọ́n lọ́wọ́ débi tó bá ṣeé ṣe dé ní ọ̀sẹ̀ náà. Tí ọ̀rọ̀ náà ò bá yanjú lọ́sẹ̀ yẹn, ó lè ran àwọn alàgbà tàbí àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn lọ́wọ́ láti ṣe ìwádìí kí wọ́n lè mọ ìlànà Ìwé Mímọ́ tí wọ́n á lò. Tó bá yẹ kí ẹ̀ka ọ́fíìsì gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ náà, òun àtàwọn alàgbà máa kọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ọ̀rọ̀ náà ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì.

47 Tí alábòójútó àyíká bá ń bẹ ìjọ wò, ó máa ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ará ní àwọn ìpàdé. Látìgbàdégbà, ẹ̀ka ọ́fíìsì lè fún yín ní ìtọ́ni nípa bí àwọn ìpàdé náà ṣe máa lọ. Alábòójútó àyíká máa sọ àwọn àsọyé láti gba ìjọ níyànjú, láti ta wọ́n jí, láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, kó sì fún wọn lókun. Ó máa ń sapá láti mú kí àwọn ará nínú ìjọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, Jésù Kristi àti ètò Ọlọ́run.

48 Ọ̀kan lára ìdí tí alábòójútó àyíká fi ń bẹ ìjọ wò ni láti fún àwọn ará ní ìṣírí kí wọ́n lè máa fi ìtara wàásù, á sì fún wọn ní àwọn àbá tó wúlò. Ọ̀pọ̀ àwọn ará máa ṣètò àkókò wọn kí wọ́n lè lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù dáadáa lọ́sẹ̀ yẹn, bóyá kí wọ́n ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù tí ìbẹ̀wò náà bọ́ sí. Àwọn tó bá fẹ́ bá alábòójútó àyíká tàbí ìyàwó rẹ̀ ṣiṣẹ́ máa ń forúkọ sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa rí tá a bá mú alábòójútó àyíká tàbí ìyàwó rẹ̀ lọ síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ìpadàbẹ̀wò wa. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé a mọrírì bó o ṣe sapá gan-an láti kọ́wọ́ ti iṣẹ́ ìwàásù lọ́sẹ̀ ìbẹ̀wò.​—Òwe 27:17.

49 Lọ́dọọdún, àyíká kọ̀ọ̀kan máa ń ṣe àpéjọ àyíká méjì. Alábòójútó àyíká ló máa ṣètò bí nǹkan ṣe máa lọ dáadáa ní àwọn àpéjọ náà. Alábòójútó àyíká máa yan alábòójútó àpéjọ àti olùrànlọ́wọ́ alábòójútó àpéjọ. Àwọn arákùnrin yìí máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú alábòójútó àyíká láti bójú tó ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ àpéjọ. Èyí á jẹ́ kí alábòójútó àyíká lè pọkàn pọ̀ sórí àsọyé, ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àtàwọn apá míì tó máa wáyé ní àpéjọ náà. Alábòójútó àyíká tún máa ń yan àwọn arákùnrin míì tó dáńgájíá láti máa bójú tó àwọn ẹ̀ka míì ní àpéjọ. Ó tún máa ń ṣètò pé kí ẹnì kan ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ ìnáwó àyíká lẹ́yìn àpéjọ kọ̀ọ̀kan. Nínú ọ̀kan lára àwọn àpéjọ àyíká méjì tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún, ẹ̀ka ọ́fíìsì máa rán aṣojú kan wá tó máa jẹ́ àlejò olùbánisọ̀rọ̀. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ibi tí àwọn ará ń gbé jìnnà sí gbọ̀ngàn àpéjọ tàbí gbọ̀ngàn náà kéré láti gba àwọn ará lẹ́ẹ̀kan náà, a máa ń pín àwọn àyíká kan sí apá mélòó kan tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn á sì ṣe àpéjọ àyíká tirẹ̀.

50 Alábòójútó àyíká máa ń fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá rẹ̀ ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ní ìparí oṣù. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ìjọ tó bẹ̀ wò kò lè fún un ní ìwọ̀nba owó tó ná lórí ìrìn àjò, oúnjẹ, ilé gbígbé àtàwọn ìnáwó míì tó pọn dandan láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, ó lè fi àkọsílẹ̀ ìnáwó náà ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Ó dá àwọn aṣojú tó ń rìnrìn àjò lójú pé táwọn bá fi ire Ìjọba Jèhófà sí ipò àkọ́kọ́, àwọn á rí ohun tí àwọn nílò nípa tara bí Jésù ti ṣèlérí. (Lúùkù 12:31) Ó yẹ kí àwọn ìjọ fi sọ́kàn pé àǹfààní ló jẹ́ fún àwọn láti máa lawọ́ sí àwọn alàgbà tó ń ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn nítorí wọn.​—3 Jòh. 5-8.

ÌGBÌMỌ̀ Ẹ̀KA

51 Ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé, a máa ń yan àwọn arákùnrin mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n kúnjú ìwọ̀n tí wọ́n sì dàgbà nípa tẹ̀mí láti jẹ́ Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka kí wọ́n lè máa bójú tó iṣẹ́ ìwàásù ní orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà tàbí ní àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ àbójútó wọn. Ọ̀kan lára àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ náà máa jẹ́ olùṣekòkáárí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka.

52 Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka máa ń bójú tó ohun tó kan gbogbo ìjọ tó wà lábẹ́ àbójútó wọn. Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka máa ń rí sí i pé a wàásù ìhìn rere Ìjọba náà jákèjádò ibi tó wà lábẹ́ ẹ̀ka wọn, wọ́n sì máa ń ṣètò àwọn ìjọ àtàwọn àyíká kí wọ́n lè bójú tó àwọn nǹkan tí àwọn ará nílò. Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka tún máa ń bójú tó iṣẹ́ àwọn míṣọ́nnárì, àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, aṣáájú-ọ̀nà déédéé àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka máa ń ṣe àwọn ètò tó bá yẹ fún àpéjọ àyíká àti ti agbègbè, wọ́n á sì yan iṣẹ́ fún àwọn tó bá yẹ kí ohun gbogbo lè “ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó bójú mu àti létòlétò.”​—1 Kọ́r. 14:40.

53 A máa ń yan Ìgbìmọ̀ Orílẹ̀-Èdè láwọn orílẹ̀-èdè kan, wọ́n sì máa ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ àbójútó Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka tó wà ní orílẹ̀-èdè míì. Èyí á mú ká túbọ̀ mọ bí iṣẹ́ wa ṣe ń lọ sí níbi tí Ìgbìmọ̀ Orílẹ̀-Èdè wà. Ìgbìmọ̀ yìí ló ń bójú tó àwọn iṣẹ́ tá à ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì, ó tún ń bójú tó àwọn lẹ́tà àti ìròyìn, títí kan gbogbo iṣẹ́ ìsìn táwọn ará ń ṣe lórílẹ̀-èdè yẹn. Ìgbìmọ̀ Orílẹ̀-Èdè máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka kí iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lè máa tẹ̀ síwájú.

54 Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló máa ń yan àwọn tó ń sìn nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka àti Ìgbìmọ̀ Orílẹ̀-Èdè.

ÀWỌN AṢOJÚ ORÍLÉ-IṢẸ́

55 Látìgbàdégbà, Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń ṣètò pé kí àwọn arákùnrin tó kúnjú ìwọ̀n lọ bẹ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa wò kárí ayé. Arákùnrin tí wọ́n bá yàn láti ṣe iṣẹ́ yìí là ń pè ní aṣojú orílé-iṣẹ́. Lájorí iṣẹ́ rẹ̀ ni pé kó fún ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní ìṣírí, kó sì ran Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lọ́wọ́ lórí àwọn ìṣòro tí wọ́n ń kojú tàbí kó dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọ́n ní nípa iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Arákùnrin yìí á ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn alábòójútó àyíká kan, ó sì tún lè ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn míṣọ́nnárì tó wà ní pápá. Ó máa ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro wọn tàbí àwọn ohun tó ń fẹ́ àbójútó, á fún wọn ní ìṣírí tó yẹ nípa iṣẹ́ wọn tó ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn.

56 Aṣojú orílé-iṣẹ́ máa ń fẹ́ láti mọ ohun tá à ń gbé ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti àwọn iṣẹ́ míì nínú ìjọ. Tí àkókò bá wà, ó tún lè bẹ àwọn ọ́fíìsì atúmọ̀ èdè wò. Tí aṣojú orílé-iṣẹ́ bá bẹ ẹ̀ka ọ́fíìsì kan wò, á lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tó bá ṣe lè ṣeé ṣe fún un tó.

Bá a ṣe ń tẹrí ba fún àwọn alábòójútó tí Ọlọ́run yàn láti máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo rẹ̀, à ń wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù tó jẹ́ Orí ìjọ

WỌ́N Ń BÓJÚ TÓ WA TÌFẸ́TÌFẸ́

57 À ń jàǹfààní gan-an látinú iṣẹ́ àṣekára tí àwọn ọkùnrin tó dàgbà nípa tẹ̀mí ń ṣe àti bí wọ́n ṣe ń fìfẹ́ bójú tó wa. Bá a ṣe ń tẹrí ba fún àwọn alábòójútó tí Ọlọ́run yàn láti máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo rẹ̀, à ń wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù tó jẹ́ Orí ìjọ. (1 Kọ́r. 16:15-18; Éfé. 1:22, 23) Nítorí náà, ẹ̀mí Ọlọ́run ń ṣiṣẹ́ láwọn ìjọ tó wà kárí ayé, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì ń tọ́ wa sọ́nà láti máa ṣe iṣẹ́ náà níbi gbogbo láyé.​—Sm. 119:105.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́