ORIN 120
Jẹ́ Oníwà Tútù Bíi Kristi
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jésù lẹni tó tóbi jù lọ láyé.
Ìgbéraga kò sí nínú ìwà rẹ̀.
Ipò ńlá ni Jèhófà fi Jésù sí.
Síbẹ̀, onírẹ̀lẹ̀ ni látọkàn wá.
2. Gbogbo àwọn tó ní ìdààmú ọkàn,
3. Jésù sọ pé ará ni gbogbo wa jẹ́.
Òun ni Orí wa, àṣẹ rẹ̀ là ń tẹ̀ lé.
Jésù ṣe tán láti bá wọn gbẹ́rù wọn.
Àwọn oníwà tútù yóò rítura
Bí wọ́n ṣe ń wá ire Ìjọba ọ̀run.
Ọlọ́run mọyì àwọn onírẹ̀lẹ̀.
Ó ṣèlérí pé wọ́n máa jogún ayé.
(Tún wo Òwe 3:34; Mát. 5:5; 23:8; Róòmù 12:16.)