Orin 82
Jẹ́ Onínú Tútù Bíi Kristi
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jésù Kristi Olúwa ló lọ́lá jù;
Àmọ́ kò lépa ipò gíga rárá.
Ó kópa ńlá kífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run lè ṣẹ;
Síbẹ̀ ẹni rírẹlẹ̀ lọ́kàn ló jẹ́.
2. Gbogbo ẹ̀yin tí làálàá ti wọ̀ lọ́rùn,
Ó ní kẹ́ẹ wá sábẹ́ àjàgà tòun.
Bẹ́ẹ bá ńwá Ìjọba náà, ẹóò rítura.
Kristi nínú tútù, ó fẹ́ oń’rẹ̀lẹ̀.
3. Jésù Olúwa sọ pé ará la jẹ́.
Má ṣe wá ipò ńlá; sin àwọn ará.
Ọlọ́run ka onínú tútù sí gan-an;
Ó ṣèlérí pé wọn yóò jogún ayé.
(Tún wo Mát. 5:5; 23:8; Òwe 3:34; Róòmù 12:16.)