ORIN 27
Ọlọ́run Máa Ṣí Àwọn Ọmọ Rẹ̀ Payá
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jáà ti yan àwọn ọmọ rẹ̀.
Ó máa ṣí wọn payá.
Wọ́n máa jọba pẹ̀lú Kristi.
Ẹ̀dá ẹ̀mí ni wọ́n.
(ÈGBÈ)
Jáà ṣí àwọn ‘mọ rẹ̀ payá
Pẹ̀lú Jésù Kristi.
Wọ́n máa jagun, wọ́n máa ṣẹ́gun.
Jáà yóò san wọ́n lẹ́san.
2. Láìpẹ́, àwọn tó bá ṣẹ́ kù
Máa gbọ́ ìpè ‘kẹyìn.
Olúwa àwọn olúwa
Yóò gbà wọ́n sọ́dọ̀ rẹ̀.
(ÈGBÈ)
Jáà ṣí àwọn ‘mọ rẹ̀ payá
Pẹ̀lú Jésù Kristi.
Wọ́n máa jagun, wọ́n máa ṣẹ́gun.
Jáà yóò san wọ́n lẹ́san.
(ÀSOPỌ̀)
Kristi àtàwọn ọmọ Jáà
Máa jagun ìkẹyìn.
’Gbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn
Máa wà títí ayé.
(ÈGBÈ)
Jáà ṣí àwọn ‘mọ rẹ̀ payá
Pẹ̀lú Jésù Kristi.
Wọ́n máa jagun, wọ́n máa ṣẹ́gun.
Jáà yóò san wọ́n lẹ́san.