Orin151
Ọlọ́run Máa Ṣí Àwọn Ọmọ Rẹ̀ Payá
Bíi Ti Orí Ìwé
Jáà ti yan àwọn ọmọ rẹ̀
Ó máa ṣí wọn payá.
Wọ́n máa jọba pẹ̀lú Kristi
Ẹ̀dá ẹ̀mí ni wọ́n.
(ÈGBÈ)
Jáà ṣí àwọn ‘mọ rẹ̀ payá
Kristi l’Olúwa wọn.
Wọ́n máa ṣẹ́gun pẹ̀lú Kristi
Wọ́n máa jọ gba èrè.
Láìpẹ́ àwọn ìyókù wọn
Máa gbọ́ ohùn ìpè.
Jésù Ọba àwọn ọba
Máa kó gbogbo wọn jọ.
(Ègbè)
Jáà ṣí àwọn ‘mọ rẹ̀ payá
Kristi l’Olúwa wọn.
Wọ́n máa ṣẹ́gun pẹ̀lú Kristi
Wọ́n máa jọ gba èrè.
(ÌSOPỌ̀)
Kristi àti àwọn ‘mọ Jáà
Máa jagun ìkẹyìn.
’Gbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn
Máa wà pẹ́ títí láé.
(Ègbè)
Jáà ṣí àwọn ‘mọ rẹ̀ payá
Kristi l’Olúwa wọn.
Wọ́n máa ṣẹ́gun pẹ̀lú Kristi
Wọ́n máa jọ gba èrè.