ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt ojú ìwé 1766-1767
  • B1 Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • B1 Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lẹ́yìn 4026 Ṣ.S.K.
  • 1943 Ṣ.S.K.
  • Lẹ́yìn 1070 Ṣ.S.K.
  • 29 S.K.
  • 33 S.K.
  • Nǹkan Bíi 1914 S.K.
  • Ọjọ́ Iwájú
  • Bí Àsọtẹ́lẹ̀ Kan Tó Ti Pẹ́ Ṣe Kàn Ẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Jèhófà Ṣí Ète Rẹ̀ Payá
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Irú Ọmọ Ejò náà—Báwo ni A Ṣe Tú u Fó?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìlérí tí Ọlọ́run Ṣe Láti Ẹnu Àwọn Wòlíì
    Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀
Àwọn Míì
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
B1 Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì

B1

Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì

Bíi Ti Orí Ìwé

Jèhófà Ọlọ́run ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso. Ọ̀nà tó ń gbà ṣàkóso ló dára jù lọ. Ohun tó ní lọ́kàn fún ayé yìí àti aráyé máa ṣẹ.

Ejò wà nítòsí Ádámù àti Éfà nínú ọgbà Édẹ́nì

Lẹ́yìn 4026 Ṣ.S.K.

Ohun tí “ejò” náà ń sọ ni pé Jèhófà kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso àti pé ọ̀nà tó ń gbà ṣàkóso kò dára. Jèhófà ṣèlérí pé òun á gbé “ọmọ,” tàbí “èso” kan dìde tó máa tẹ ejò yẹn, ìyẹn Sátánì, rẹ́ níkẹyìn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5,15, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Àmọ́, Jèhófà fàyè gba àwọn èèyàn láti máa ṣàkóso ara wọn bí ejò náà ṣe ń darí wọn.

Ábúráhámù ń gbọ́ ìlérí tí Ọlọ́run ń ṣe fún un

1943 Ṣ.S.K.

Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé “ọmọ” tí òun ṣèlérí náà yóò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 22:18.

Ọba Dáfídì

Lẹ́yìn 1070 Ṣ.S.K.

Jèhófà mú un dá Ọba Dáfídì àti Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ lójú pé “ọmọ” tí òun ṣèlérí náà yóò wá láti ìlà ìdílé wọn.—2 Sámúẹ́lì 7:12, 16; 1 Àwọn Ọba 9:3-5; Àìsáyà 9:6, 7.

Nígbà tí Jésù ṣe ìrìbọmi

29 S.K.

Jèhófà jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jésù ni “ọmọ” tí òun ṣèlérí tó jẹ́ Ajogún ìtẹ́ Dáfídì.—Gálátíà 3:16; Lúùkù 1:31-33; 3:21, 22.

Nígbà tí wọ́n pa Jésù

33 S.K.

Ejò náà, ìyẹn Sátánì dí “ọmọ” ìlérí náà lọ́wọ́ nígbà tó pa Jésù. Jèhófà gbé Jésù dìde sí ìyè ti ọ̀run, ó sì tẹ́wọ́ gba ìtóye ìwàláàyè pípé tí Jésù fi rúbọ, ó tipa bẹ́ẹ̀ mú kó ṣeé ṣe fún àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù láti rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà kí Ọlọ́run sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Jẹ́nẹ́sísì 3:15; Ìṣe 2:32-36; 1 Kọ́ríńtì 15:21, 22.

Jésù fi ejò náà, ìyẹn Sátánì, sọ̀kò sí ayé gẹ́gẹ́ bí ìlérí tó wà nínú ìwé Ìfihàn

Nǹkan Bíi 1914 S.K.

Jésù ju ejò náà, Sátánì sí ayé, ó sì sé e mọ́ ibẹ̀ fún àkókò kúkúrú.—Ìfihàn 12:7-9, 12.

Jésù ń ṣàkóso lórí ayé látorí ìtẹ́ rẹ lọ́run gẹ́gẹ́ bí ìlérí tó wà nínú ìwé Ìfihàn

Ọjọ́ Iwájú

Ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún ni Jésù á fi ti Sátánì mọ́ ẹ̀wọ̀n, lẹ́yìn náà ó máa pa á run, tó túmọ̀ sí pé á fọ́ ọ lórí. Ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀ fún ayé yìí àti aráyé máa ṣẹ, á mú gbogbo ẹ̀gàn kúrò lórí orúkọ rẹ̀, á sì dá ọ̀nà tó ń gbà ṣàkóso láre.—Ìfihàn 20:1-3, 10; 21:3, 4.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́