ORIN 20
O Fún Wa Ní Ọmọ Rẹ Ọ̀wọ́n
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Nígbà tó dà bíi pé
Kò sírètí fún wa,
Jèhófà fi ẹ̀jẹ̀
Ọmọ rẹ̀ rà wá!
Gbogbo ìgbé ayé
Wa lá ó máa fi sìn ọ́;
A ó sì sọ fáráyé,
Kí ìfẹ́ rẹ lè ṣẹ.
(ÈGBÈ)
Títí ayérayé,
A ó pa ohùn wa pọ̀
Láti máa kọrin ọpẹ́
pó o fún wa lọ́mọ rẹ ọ̀wọ́n.
2. Àánú rẹ, inúure,
Ń mú kí a sún mọ́ ọ.
À ń fi orúkọ rẹ
Pè wá, ó wù wá.
Ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tó ga,
Tó ṣeyebíye jù
Ni ikú Ọmọ rẹ
Tó jẹ́ ká lè ríyè.
(Ègbè)
Títí ayérayé,
A ó pa ohùn wa pọ̀
Láti máa kọrin ọpẹ́
pó o fún wa lọ́mọ rẹ ọ̀wọ́n.
(ÌLÀ ÀKỌPARÍ)
À ń fàdúrà dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Jèhófà.
O ṣeun tí o fún wa ní Ọmọ rẹ ọ̀wọ́n.
(Tún wo Jòh. 3:16; 15:13.)