HÓSÍÀ OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ 1 Ìyàwó Hósíà àti àwọn ọmọ tó bí (1-9) Jésírẹ́lì (4), Lo-ruhámà (6), àti Lo-ámì (9) Ìmúbọ̀sípò àti ìṣọ̀kan ń bọ̀ (10, 11) 2 Ọlọ́run fìyà jẹ Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ (1-13) Ó pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà ọkọ rẹ̀ (14-23) “Ọkọ Mi ni wàá máa pè mí” (16) 3 Hósíà gba ìyàwó rẹ̀ alágbèrè pa dà (1-3) Ísírẹ́lì máa pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà (4, 5) 4 Jèhófà pe Ísírẹ́lì lẹ́jọ́ (1-8) Kò sí ìmọ̀ Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà (1) Ísírẹ́lì bọ̀rìṣà, ó sì ṣe ìṣekúṣe (9-19) Ẹ̀mí ìṣekúṣe mú kí wọ́n ṣìnà (12) 5 Éfúrémù àti Júdà gba ìdájọ́ (1-15) 6 Ẹ jẹ́ ká pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà (1-3) Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí àwọn èèyàn náà ní tètè ń pòórá (4-6) Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sàn ju ẹbọ lọ (6) Ìwà àìnítìjú tí àwọn èèyàn náà hù (7-11) 7 Àpèjúwe nípa ìwà ibi Éfúrémù (1-16) Kò sí ọ̀nà àbáyọ nínú àwọ̀n Ọlọ́run (12) 8 Wọ́n jìyà torí pé wọ́n bọ̀rìṣà (1-14) Wọ́n gbin afẹ́fẹ́, wọ́n sì ká ìjì (7) Ísírẹ́lì ti gbàgbé Ẹni tó dá a (14) 9 Ẹ̀ṣẹ̀ Éfúrémù mú kí Ọlọ́run kọ̀ ọ́ (1-17) Wọ́n fi ara wọn fún ọlọ́run tó ń tini lójú (10) 10 Ísírẹ́lì jẹ́ igi àjàrà tí kò dáa, ó máa pa run (1-15) Fífúnrúgbìn àti kíkórè (12, 13) 11 Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí Ísírẹ́lì láti ìgbà tó wà lọ́mọdé (1-12) ‘Láti Íjíbítì ni mo ti pe ọmọkùnrin mi’ (1) 12 Éfúrémù ní láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà (1-14) Jékọ́bù bá Ọlọ́run jà (3) Jékọ́bù sunkún kó lè rí ojú rere Ọlọ́run (4) 13 Éfúrémù abọ̀rìṣà gbàgbé Jèhófà (1-16) “Ìwọ Ikú, oró rẹ dà?” (14) 14 Hósíà bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà (1-3) Ẹ fi ètè rú ẹbọ ìyìn (2) Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ máa gba ìwòsàn (4-9)