ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 9/15 ojú ìwé 14-17
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Hóséà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Hóséà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “MÚ ÀGBÈRÈ AYA . . . FÚN ARA RẸ”
  • (Hóséà 1:1–3:5)
  • “JÈHÓFÀ NÍ ẸJỌ́ KAN”
  • (Hóséà 4:1–13:16)
  • “ÀWỌN Ọ̀NÀ JÈHÓFÀ DÚRÓ ṢÁNṢÁN”
  • (Hóséà 14:1-9)
  • Àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà Ń fún Wa Níṣìírí Láti Bá Ọlọ́run Rìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Bá Ọlọ́run Rìn Kó O Lè Kórè Ohun Tó Dára
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Wòlíì—Hóséà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • “Àwọn Ọ̀nà Jèhófà Dúró Ṣánṣán”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 9/15 ojú ìwé 14-17

Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Hóséà

ÌJỌSÌN tòótọ́ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pòórá tán pátápátá ní ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ti àríwá Ísírẹ́lì. Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lọ́rọ̀ gan-an lákòókò tí Jèróbóámù Kejì ń ṣàkóso wọn, àmọ́ láìpẹ́ lẹ́yìn ikú Jèróbóámù, orílẹ̀-èdè náà di èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ lọ́rọ̀ mọ́. Ẹ̀yìn ìyẹn ló wá di pé ìlú ò tòrò mọ́, tí rògbòdìyàn lórí ọ̀ràn ìṣèlú sì gbòde kan. Wọ́n pa mẹ́rin nínú àwọn ọba mẹ́fà tó jẹ lẹ́yìn Jèróbóámù. (2 Àwọn Ọba 14:29; 15:8-30; 17:1-6) Ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́ta tí Hóséà fi sọ àsọtẹ́lẹ̀, èyí tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 804 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, dé àkókò rúkèrúdò yìí.

A rí ojú tí Jèhófà fi wo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó jẹ́ oníwàkiwà yìí kedere nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé Hóséà. Àṣírí ìṣìnà Ísírẹ́lì àti àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí Jèhófà ṣe máa dá Ísírẹ́lì àti ìjọba Júdà lẹ́jọ́ ni olórí ohun tí ọ̀rọ̀ Hóséà dá lé. Hóséà sì kọ gbogbo èyí sínú ìwé kan tá a fi orúkọ rẹ̀ pè, ó lo àwọn ọ̀rọ̀ tó tuni lára tó sì gba ọgbọ́n, ó tún lo èdè tó lágbára tó sì fi bí nǹkan ṣe rí gẹ́lẹ́ hàn. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yè ó sì ń sa agbára níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ara Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí ni.—Hébérù 4:12.

“MÚ ÀGBÈRÈ AYA . . . FÚN ARA RẸ”

(Hóséà 1:1–3:5)

Jèhófà sọ fún Hóséà pé: “Lọ, mú àgbèrè aya . . . fún ara rẹ.” (Hóséà 1:2) Hóséà ṣe bí Ọlọ́run ti wí, ó fẹ́ Gómérì, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún un. Àmọ́, ọkùnrin mìíràn ni Gómérì bí àwọn ọmọ méjì tó bí lẹ́yìn ìyẹn fún. Ìtumọ̀ orúkọ wọn, ìyẹn Lo-rúhámà àti Lo-ámì, tọ́ka sí bí Jèhófà ṣe fa ọwọ́ àánú rẹ̀ sẹ́yìn kúrò ní Ísírẹ́lì tó sì kọ àwọn èèyàn rẹ̀ tó jẹ́ aláìṣòótọ́ sílẹ̀.

Ojú wo ni Jèhófà fi wo àwọn èèyàn rẹ̀ tó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ yìí? Ó sọ fún Hóséà pé: “Lọ lẹ́ẹ̀kan sí i, nífẹ̀ẹ́ obìnrin kan tí alábàákẹ́gbẹ́ kan nífẹ̀ẹ́, tí ó sì ń ṣe panṣágà, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ti ìfẹ́ Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n yí padà sí àwọn ọlọ́run mìíràn.”—Hóséà 3:1.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:

1:1—Kí nìdí tí Hóséà fi dárúkọ gbogbo ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó jẹ lórí Júdà lákòókò tó ń ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún un àmọ́ tó jẹ́ pé ẹyọ kan ṣoṣo ló dárúkọ lára àwọn ọba Ísírẹ́lì? Ìdí ni pé kìkì àwọn ọba tó wá láti ìlà ìdílé Dáfídì nìkan ni wọ́n gbà pé ó lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ alákòóso lórí àwọn èèyàn tí Ọlọ́run yàn. Àwọn ọba tó jẹ lórí ìjọba àríwá kò wá láti ìlà ìdílé Dáfídì, àmọ́ ìlà ìdílé Dáfídì làwọn tó jẹ lórí Júdà ti wá.

1:2-9—Ṣé lóòótọ́ ni Hóséà mú aya àgbèrè? Bẹ́ẹ̀ ni, Hóséà fẹ́ obìnrin kan tó wá di panṣágà nígbà tó yá. Wòlíì náà ò sì sọ ohunkóhun tó fi hàn pé ohun tó sọ nípa ìdílé rẹ̀ yìí jẹ́ àlá tàbí ìran kan lásán.

1:7—Ìgbà wo ni Jèhófà fi àánú hàn sí ilé Júdà tó sì gbà wọ́n là? Èyí nímùúṣẹ lọ́dún 732 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà ayé Hesekáyà Ọba. Àkókò yẹn ni Jèhófà fòpin sí gbogbo báwọn ará Ásíríà ṣe ń halẹ̀ mọ́ Jerúsálẹ́mù. Ó mú kí áńgẹ́lì kan ṣoṣo pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀rún márùn-ún [185,000] lára àwọn ọmọ ogun ọ̀tá náà lóru ọjọ́ kan ṣoṣo. (2 Àwọn Ọba 19:34, 35) Bí Jèhófà ṣe gba Júdà là nìyẹn, àmọ́ kì í ṣe “nípasẹ̀ ọrun tàbí nípasẹ̀ idà tàbí nípasẹ̀ ogun, nípasẹ̀ àwọn ẹṣin tàbí àwọn ẹlẹ́ṣin,” bí kò ṣe nípasẹ̀ áńgẹ́lì kan ṣoṣo.

1:10, 11—Níwọ̀n bí ìjọba àríwá Ísírẹ́lì ti ṣubú lọ́dún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, báwo la ṣe wá “kó” àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn ọmọ Júdà “jọpọ̀ sínú ìṣọ̀kan”? Ọ̀pọ̀ lára àwọn ará ìjọba àríwá ti wá sílẹ̀ Júdà kó tó di pé wọ́n kó àwọn tó ń gbé nílẹ̀ Júdà lọ sígbèkùn Bábílónì lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (2 Kíróníkà 11:13-17; 30:6-12, 18-20, 25) Nígbà táwọn Júù tó wà nígbèkùn padà sílùú wọn lọ́dún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ àwọn tó wá láti ìjọba àríwá Ísírẹ́lì wà lára àwọn tó padà nígbà náà.—Ẹ́sírà 2:70.

2:21-23—Kí ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ pé: “Dájúdájú, èmi yóò sì fọ́n [Jésíréélì] bí irúgbìn fún ara mi ní ilẹ̀ ayé, èmi yóò sì fi àánú hàn sí [i],” ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀? Orúkọ ọmọkùnrin tó jẹ́ àkọ́bí Hóséà, èyí tí Gómérì bí fún un ni Jésíréélì. (Hóséà 1:2-4) Orúkọ yẹn túmọ̀ sí, “Ọlọ́run Yóò Fọ́n Irúgbìn,” èyí sì jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí Jèhófà ṣe kó àwọn olóòótọ́ tó ṣẹ́ kù jọ lọ́dún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni tó sì gbìn wọ́n bí irúgbìn ní Júdà. Ilẹ̀ tó ti di ahoro fún àádọ́rin ọdún yóò wá di èyí tó máa mú ọkà, wáìnì dídùn, àti òróró jáde báyìí. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí wá sọ lọ́nà ewì pé àwọn ohun rere wọ̀nyí yóò bẹ ilẹ̀ ayé pé kó mú àwọn èròjà aṣaralóore rẹ̀ jáde, ayé náà yóò bẹ ọ̀run pé kó rọ òjò. Ọ̀run náà yóò wá bẹ Jèhófà pé kó pèsè kùrukùru òjò. Gbogbo èyí yóò ṣẹlẹ̀ kí àwọn yòókù tó padà wá lè rí ọ̀pọ̀ yanturu nǹkan gbọ́ bùkátà ara wọn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Pétérù lo ọ̀rọ̀ inú Hóséà 2:23 fún kíkó tí wọ́n máa kó àwọn tó ṣẹ́ kù lára Ísírẹ́lì tẹ̀mí jọ.—Róòmù 9:25, 26; 1 Pétérù 2:10.

Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:

1:2-9; 3:1, 2. Nǹkan ńlá ni Hóséà ṣe yìí o, ìyẹn bó ṣe ṣègbọràn sí Ọlọ́run tí kò kọ aya rẹ̀ sílẹ̀! Nígbà tọ́rọ̀ bá kan ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, báwo la ṣe máa ń múra tán láti yááfì àwọn ohun tó wù wá?

1:6-9. Jèhófà kórìíra panṣágà tẹ̀mí bó ṣe kórìíra panṣágà ti ara.

1:7, 10, 11; 2:14-23. Àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà sọ nípa Ísírẹ́lì àti Júdà nímùúṣẹ. Gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà ló máa ń ṣẹ.

2:16, 19, 21-23; 3:1-4. Jèhófà ṣe tán láti dárí ji àwọn tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn. (Nehemáyà 9:17) Àwa náà gbọ́dọ̀ ṣe bíi ti Jèhófà, ká jẹ́ oníyọ̀ọ́nú ká sì máa ṣàánú ọmọnìkejì wa.

“JÈHÓFÀ NÍ ẸJỌ́ KAN”

(Hóséà 4:1–13:16)

“Jèhófà ní ẹjọ́ kan pẹ̀lú àwọn olùgbé ilẹ̀ náà.” Kí nìdí? Ìdí ni pé “kò sí òtítọ́ tàbí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tàbí ìmọ̀ nípa Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà.” (Hóséà 4:1) Àwọn ọ̀dàlẹ̀ èèyàn Ísírẹ́lì ń lu jìbìtì, wọ́n ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì ń ṣàgbèrè nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Dípò kí wọ́n máa wojú Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́, “wọ́n . . . pe Íjíbítì; wọ́n [tún] lọ sí Ásíríà.”—Hóséà 7:11.

Jèhófà wá polongo ìdájọ rẹ̀ lórí wọn, ó ní: “Ísírẹ́lì ni a óò gbé mì gbìnrín.” (Hóséà 8:8) Ìjọba Júdà náà kò bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀bi yìí. Hóséà 12:2 sọ pé: “Jèhófà sì ní ẹjọ́ láti bá Júdà ṣe, àní láti béèrè fún ìjíhìn lọ́wọ́ Jékọ́bù gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀nà rẹ̀; òun yóò san án padà fún un gẹ́gẹ́ bí àwọn ìbánilò rẹ̀.” Àmọ́, ó dájú pé ìmúpadàbọ́sípò máa wà, nítorí Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Èmi yóò tún wọn rà padà láti ọwọ́ Ṣìọ́ọ̀lù; èmi yóò mú wọn padà láti inú ikú.”—Hóséà 13:14.

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:

6:1-3—Ta ló ń sọ pé: “Ẹ wá, ẹ̀yin ènìyàn, ẹ sì jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Jèhófà”? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n di aláìṣòótọ́ ló ń gba ara wọn níyànjú pé káwọn padà sọ́dọ̀ Jèhófà. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n wulẹ̀ ń díbọ́n pé àwọn ti ronú pìwà dà. Inúrere wọn onífẹ̀ẹ́ kò tó nǹkan, kò sì ní pẹ́ pòórá bí “àwọsánmà òwúrọ̀ àti . . . ìrì tí ń tètè lọ.” (Hóséà 6:4) Ó sì tún lè jẹ́ pé Hóséà lẹni tó ń sọ̀rọ̀ yẹn, tó ń bẹ àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n padà sọ́dọ̀ Jèhófà. Ohun yòówù kó jẹ́, àwọn oníwàkiwà tí wọ́n wà ní ẹ̀yà mẹ́wàá ìjọba Ísírẹ́lì ní láti ronú pìwà dà tọkàntọkàn kí wọ́n sì padà sọ́dọ̀ Jèhófà ní ti gidi.

7:4—Ọ̀nà wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì onípanṣágà yìí gbà dà bí ‘ìléru tí a dá kí ó máa jó’? Àfiwé yìí jẹ́ ká rí i bí èrò ibi inú ọkàn wọn ṣe pọ̀ tó.

Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:

4:1, 6. Tá a bá fẹ́ máa rí ojú rere Jèhófà títí lọ, a gbọ́dọ̀ máa gba ìmọ̀ rẹ̀ ká sì máa fi àwọn ohun tá à ń kọ́ sílò.

4:9-13. Àwọn tó ń ṣèṣekúṣe tí wọ́n sì ń lọ́wọ́ nínú ìjọsìn tí kò mọ́ yóò jíhìn fún Jèhófà.—Hóséà 1:4.

5:1. Àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run kò gbọ́dọ̀ bá àwọn apẹ̀yìndà da ohunkóhun pọ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọ́n lè mú káwọn kan lọ́wọ́ nínú ìjọsìn èké, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ di ‘pańpẹ́ àti àwọ̀n’ fún wọn.

6:1-4; 7:14, 16. Ẹni tó bá ronú pìwà dà lọ́rọ̀ ẹnu lásán kàn ń ṣojú ayé ni, ìyẹn ò sì wúlò rárá. Kí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó lè rí àánú Ọlọ́run gbà, ó ní láti ronú pìwà dà tọkàntọkàn, kó sì fi èyí hàn nípa pípadà sí ohun kan “tí ó ga sí i,” ìyẹn ni pé kó padà sínú ìjọsìn tí a gbé ga. Ìṣe rẹ̀ gbọ́dọ̀ wà níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà tó dára gan-an tí Ọlọ́run fi lélẹ̀.—Hóséà 7:16.

6:6. Téèyàn bá sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà, a jẹ́ pé ìfẹ́ Ọlọ́run ò jinlẹ̀ lọ́kàn onítọ̀hún. Kò sí bí ẹbọ tẹ̀mí tá a rú ṣe lè pọ̀ tó tó máa rọ́pò irú àbùkù bẹ́ẹ̀.

8:7, 13; 10:13. Ìlànà tó ṣẹ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì abọ̀rìṣà lára ni èyí tó sọ pé “ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.”—Gálátíà 6:7.

8:8; 9:17; 13:16. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìjọba àríwá nímùúṣẹ nígbà táwọn ará Ásíríà ṣẹ́gun Samáríà tó jẹ́ olú ìlú wọn. (2 Àwọn Ọba 17:3-6) Ó dá wa lójú pé Ọlọ́run yóò ṣe ohun tó ti sọ, yóò sì mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ.—Númérì 23:19.

8:14. Jèhófà tipasẹ̀ àwọn ará Bábílónì rán “iná sínú àwọn ìlú ńlá [Júdà]” lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, bí àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ pé Jerúsálẹ́mù àti ilẹ̀ Júdà máa di ahoro ṣe nímùúṣẹ nìyẹn. (2 Kíróníkà 36:19) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò lè kùnà láé.—Jóṣúà 23:14.

9:10. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run tòótọ́, síbẹ̀ wọ́n “wọlé tọ Báálì ti Péórù, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti ya ara wọn sí mímọ́ fún ohun tí ń tini lójú.” Ọlọgbọ́n la jẹ́ tá a bá fi ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn kọ́gbọ́n, tá ò jẹ́ kí ohunkóhun ba ìyàsímímọ́ wa sí Jèhófà jẹ́.—1 Kọ́ríńtì 10:11.

10:1, 2, 12. A gbọ́dọ̀ jọ́sìn Ọlọ́run láìṣe àgàbàgebè. Tá a bá ‘fún irúgbìn fún ara wa ní òdodo, a óò kárúgbìn ní ìbámu pẹ̀lú inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti Ọlọ́run.’

10:5. Bẹti-áfénì (tó túmọ̀ sí “Ilé Ọṣẹ́”) jẹ́ orúkọ ìṣáátá tí wọ́n máa ń pe Bẹ́tẹ́lì (tó túmọ̀ sí “Ilé Ọlọ́run”). Nígbà tí wọ́n gbé òrìṣà ọmọ màlúù ti Bẹti-áfénì lọ sígbèkùn, àwọn tó ń gbé Samáríà ṣọ̀fọ̀ nítorí pé wọ́n pàdánù ohun tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn jọ́sìn yìí. Ẹ ò rí i pé ìwà òmùgọ̀ gbáà ni kéèyàn gbẹ́kẹ̀ lé òrìṣà tí kò lẹ́mìí, tí ò tiẹ̀ lè dáàbò bo ara rẹ̀ pàápàá!—Sáàmù 135:15-18; Jeremáyà 10:3-5.

11:1-4. Jèhófà máa ń fìfẹ́ bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò. Títẹríba fún Ọlọ́run kì í ṣe ohun ìnira rárá.

11:8-11; 13:14. Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa bó ṣe máa mú àwọn èèyàn rẹ̀ padà sínú ìjọsìn tòótọ́ ‘kò padà sọ́dọ̀ rẹ̀ láìní ìmúṣẹ.’ (Aísáyà 55:11) Lọ́dún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìgbèkùn àwọn ará Bábílónì dópin, àwọn tó ṣẹ́ kù sì padà wá sí Jerúsálẹ́mù. (Ẹ́sírà 2:1; 3:1-3) Ohunkóhun tí Jèhófà ti tipasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀ sọ gbọ́dọ̀ nímùúṣẹ.

12:6. A gbọ́dọ̀ múra tán láti máa fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn, ká máa ṣe ìdájọ́ òdodo, ká sì máa ní ìrètí nínú Jèhófà nígbà gbogbo.

13:6. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì “yó, ọkàn-àyà wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ga. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi gbàgbé [Jèhófà].” A gbọ́dọ̀ yẹra fún ohunkóhun tó lè mú ká máa gbéra ga.

“ÀWỌN Ọ̀NÀ JÈHÓFÀ DÚRÓ ṢÁNṢÁN”

(Hóséà 14:1-9)

Hóséà pàrọwà pé: “Padà wá, ìwọ Ísírẹ́lì, sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nítorí ìwọ ti kọsẹ̀ nínú ìṣìnà rẹ.” Ó ń rọ àwọn èèyàn náà láti sọ fún Jèhófà pé: “Kí o dárí ìṣìnà jì; kí o sì tẹ́wọ́ gba ohun rere, àwa yóò sì fi ẹgbọrọ akọ màlúù ètè wa rúbọ ní ìdápadà.”—Hóséà 14:1, 2.

Ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà gbọ́dọ̀ wá sọ́dọ̀ Jèhófà, kó tẹ̀ lé àwọn ọ̀nà rẹ̀, kó sì rú ẹbọ ìyìn sí i. Kí nìdí? Ìdí ni pé “àwọn ọ̀nà Jèhófà dúró ṣánṣán, àwọn olódodo sì ni yóò máa rìn nínú wọn.” (Hóséà 14:9) Inú wa mà dùn gan-an o, pé dájúdájú ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì máa “fi ìgbọ̀npẹ̀pẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jèhófà àti sínú oore rẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́”!—Hóséà 3:5.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé Hóséà jẹ́ àpẹẹrẹ ọ̀nà tí Jèhófà gbà bá Ísírẹ́lì lò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ìgbà tí Samáríà pa run lọ́dún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì pòórá

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́