Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Wòlíì—Hóséà
1. Ìbéèrè wo ló ṣeé ṣe kó o ti bi ara rẹ?
1 ‘Àwọn nǹkan wo ni mo máa fẹ́ yááfì nítorí Jèhófà?’ Ó ṣeé ṣe kó o ti bi ara rẹ ní ìbéèrè yìí nígbà tó ò ń ṣàṣàrò lórí bí oore àti àánú Ọlọ́run ṣe pọ̀ tó. (Sm. 103:2-4; 116:12) Tọkàntọkàn ni Hóséà fi ṣe ohun tí Jèhófà ní kó ṣe, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní láti yááfì àwọn nǹkan kan. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Hóséà?
2. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àtàtà tí Hóséà fi lélẹ̀ fún wa ní ti bó ṣe lo ìfaradà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
2 Wàásù Ní Àsìkò Tí Kò Rọgbọ: Àwọn ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì ni Ọlọ́run dìídì ní kí Hóséà lọ jẹ́ ìhìn iṣẹ́ rẹ̀ fún, èyí sì jẹ́ lákòókò tí wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa ìjọsìn tòótọ́ rẹ́ ráúráú. Ọba Jèróbóámù Kejì ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, ó sì gbé ìjọsìn ère ọmọ màlúù tí Jèróbóámù Kínní bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lárugẹ. (2 Ọba 14:23, 24) Àwọn ọba tó sì jẹ tẹ̀ lé e túbọ̀ mú kí ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá náà jìnnà sí Ọlọ́run títí tí orílẹ̀-èdè náà fi pa run ní ọdún 740 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Síbẹ̀, láìka bí ìsìn èké ṣe gbilẹ̀ tó, Hóséà ń bá a nìṣó láti jẹ́ wòlíì olóòótọ́ fún ó kéré tán ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́ta [59]. Ṣé àwa náà ti pinnu pé a ò ní yéé wàásù láti ọdún dé ọdún, kódà táwọn èèyàn ò bá fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa tàbí tí wọ́n ta kò wá?—2 Tím. 4:2.
3. Báwo ni ohun tí Hóséà fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé aláàánú ni Jèhófà?
3 Jẹ́ Kí Àánú Jèhófà Ṣe Pàtàkì sí Ẹ: Jèhófà sọ pé kí Hóséà fẹ́ “àgbèrè aya.” (Hós. 1:2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Gómérì, ìyàwó rẹ̀ bí ọmọkùnrin kan fún un, ó tún lọ bí ọmọ méjì míì síta. Bí Hóséà ṣe fínnúfíndọ̀ dárí ji ìyàwó rẹ̀ ṣàpẹẹrẹ àánú ńlá tí Jèhófà fi hàn sí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì oníwàkiwà nígbà tí wọ́n ronú pìwà dà. (Hós. 3:1; Róòmù 9:22-26) Ṣé àwa náà múra tán láti pa ohun tó wù wá tì ká bàa lè jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jèhófà ń fi àánú hàn sí gbogbo èèyàn?—1 Kọ́r. 9:19-23.
4. Àwọn nǹkan wo la lè yááfì nítorí Jèhófà?
4 Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan ti yááfì iṣẹ́ tí ì bá máa mówó gọbọi wọlé torí kí wọ́n lè máa lo àkókò púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn kan ti yàn pé àwọn kò ní lọ́kọ tàbí láya tàbí pé àwọn kò ní bímọ nítorí kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Tá a bá ronú nípa ohun tí Hóséà ṣe, a lè sọ pé, ‘Èmi ò lè ṣe ohun tó ṣe yẹn o.’ Àmọ́, bí a ṣe túbọ̀ ń mọrírì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Jèhófà fi hàn sí wa, tá a sì ń gbára lé ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti fún wa lókun, Jèhófà lè lò wá láti ṣe ohun tá a ti rò pé kò ṣeé ṣe, bó ṣe lo Hóséà.—Mát. 19:26; Fílí. 2:13.