Jónátánì—“Bá Ọlọ́run Ṣiṣẹ́ Pọ̀”
ỌMỌ ọba àkọ́kọ́ lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lọ sọ́dọ̀ ìsáǹsá kan níbi tó sá pa mọ́ sí. Ó sọ fún ìsáǹsá náà pé: “Má fòyà; nítorí ọwọ́ Sọ́ọ̀lù baba mi kì yóò tẹ̀ ọ́, ìwọ ni yóò sì jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì, èmi ni yóò sì di igbá-kejì rẹ; Sọ́ọ̀lù baba mi sì mọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”—1 Sámúẹ́lì 23:17.
Jónátánì lẹni tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, Dáfídì sì ni ìsáǹsá yẹn. Ká ní kì í ṣe pé Jónátánì kú láìpẹ́ lẹ́yìn náà ni, ó ṣeé ṣe kó dẹni tí Dáfídì fọkàn tán jù lọ.
Ọ̀rẹ́ tí Jónátánì àti Dáfídì ń bára wọn ṣe ṣàrà ọ̀tọ̀. Jónátánì fúnra rẹ̀ jẹ́ ẹnì kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Àwọn tó mọ̀ ọ́n nígbà ayé ẹ̀ gbà pé òótọ́ lèyí, nítorí ohun tí wọ́n sọ nípa rẹ̀ ni pé: “Ó bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ pọ̀.” (1 Sámúẹ́lì 14:45) Kí ló mú kí wọ́n sọ bẹ́ẹ̀? Àwọn ànímọ́ wo ni Jónátánì ní? Báwo sì ni ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe lè ṣe ọ́ láǹfààní?
Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì “Wà Nínú Hílàhílo”
Nígbà tí Bíbélì kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa Jónátánì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì “wà nínú hílàhílo.” Àwọn Filísínì ti wá kó wọn lẹ́rù lọ, wọ́n sì ṣe ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò fi ní lè dojú ìjà kọ wọ́n.—1 Sámúẹ́lì 13:5, 6, 17-19.
Àmọ́ Jèhófà sọ pé òun ò ní fàwọn èèyàn òun sílẹ̀, Jónátánì sì nígbàgbọ́ pé bí yóò ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn. Bàbá Jónátánì, ìyẹn Sọ́ọ̀lù, ni Jèhófà ń sọ nípa rẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Òun yóò sì gba àwọn ènìyàn mi là kúrò lọ́wọ́ àwọn Filísínì.” Jónátánì gbà pé ohun tí Ọlọ́run sọ yìí yóò rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́. Òun fúnra rẹ̀ ti ṣáájú ẹgbẹ̀rún kan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ní nǹkan ìjà lọ́wọ́ síbẹ̀ tí wọ́n ṣẹ́gun àwọn Filísínì. Àkókò tó báyìí tó fẹ́ fòpin sí ẹ̀rù táwọn Filísínì ń dá bà wọ́n.—1 Sámúẹ́lì 9:16; 12:22; 13:2, 3, 22.
Àwọn Ọmọ Ogun Méjì Tí Wọ́n Gbójúgbóyà
Jónátánì fẹ́ lọ gbéjà ko àwọn ọmọ ogun Filísínì tó wà lẹ́yìn ibùdó nítòsí ọ̀nà àfonífojì tóóró tó wà ní Míkímáṣì. (1 Sámúẹ́lì 13:23) Kó tó lè débẹ̀, ó ní láti pọ́nkè, “ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀” ni yóò sì fi “rá gòkè” náà. Àmọ́ ìyẹn ò dá a dúró. Jónátánì pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé òun àtẹni tó ń ru ìhámọ́ra òun nìkan làwọn yóò jọ lọ gbéjà kò wọ́n. Ó sọ fẹ́ni tó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé: “Bóyá Jèhófà yóò ṣiṣẹ́ fún wa, nítorí kò sí ìdílọ́wọ́ fún Jèhófà láti fi púpọ̀ tàbí díẹ̀ gbà là.”—1 Sámúẹ́lì 14:6, 13.
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì méjèèjì yìí wá àmì kan lọ́dọ̀ Jèhófà. Wọ́n ní àwọn yóò fara han àwọn ọkùnrin tí wọ́n wà lẹ́yìn ibùdó náà. Táwọn Filísínì náà bá sọ pé: “Ẹ dúró jẹ́ẹ́ títí a ó fi kàn yín lára!” Jónátánì àtẹni tó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ kò ní gòkè lọ bá wọn. Àmọ́ táwọn ọ̀tá náà bá sọ pé: “Ẹ gòkè wá gbéjà kò wá!” ó túmọ̀ sí pé Jèhófà yóò mú kí Jónátánì àtẹni tó ń ru ìhámọ́ra rẹ̀ ṣẹ́gun wọn. Ó dá Jónátánì lójú pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn òun, ìdí nìyẹn tó fi fẹ́ lọ sẹ́yìn ibùdó náà láti lọ jà.—1 Sámúẹ́lì 14:8-10.
Kí lọkùnrin méjì péré fẹ́ ṣe lẹ́gbẹ̀ẹ́ gbogbo ọmọ ogun ẹ̀yìn ibùdó? Ó dáa, ǹjẹ́ Jèhófà kò ran Éhúdù Onídàájọ́ lọ́wọ́ nígbà tó ṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti bá àwọn ará Móábù jà? Ǹjẹ́ Ọlọ́run kò wà pẹ̀lú Ṣámúgárì, tó fi ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù pa ẹgbẹ̀ta [600] Filísínì? Sámúsìnì ńkọ́, ǹjẹ́ Jèhófà kò fún òun náà lágbára, tóun nìkan fi ṣẹ́gun àwọn Filísínì? Jónátánì nígbàgbọ́ pé Ọlọ́run yóò ran òun náà lọ́wọ́.—Àwọn Onídàájọ́ 3:12-31; 15:6-8, 15; 16:29, 30.
Báwọn Filísínì ṣe rí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì méjèèjì yìí, wọ́n pariwo pé: “Ẹ gòkè tọ̀ wá wá, dájúdájú, àwa yóò sì fojú yín rí nǹkan!” Ni Jónátánì àti arùhámọ́ra rẹ̀ bá gòkè lọ bá wọn. Wọ́n kọjú ìjà sáwọn ọmọ ogun ọ̀tá náà tìgboyàtìgboyà wọ́n sì pa nǹkan bí ogún lára wọn, bí wọ́n ṣe kó ṣìbáṣìbo bá gbogbo àwọn ọmọ ogun ẹ̀yìn ibùdó náà nìyẹn. Bóyá èrò àwọn Filísínì náà ni pé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì ń tẹ̀ lé Jónátánì àtẹni tó ru ìhámọ́ra rẹ̀. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Ìwárìrì ṣẹlẹ̀ . . . láàárín gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà lára ọ̀wọ́ ọmọ ogun ẹ̀yìn ibùdó . . . ilẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí mì tìtì, ó sì di ìwárìrì láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Nítorí ìmìtìtì tí Ọlọ́run mú kó ṣẹlẹ̀ yìí, ṣìbáṣìbo bá àwọn Filísínì débi pé ‘idà olúkúlùkù dojú kọ ọmọnìkejì rẹ̀.’ Nígbà táwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì rí èyí, ọkàn wọn le. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ti lọ sá pa mọ́ àtàwọn tó ti lọ fara mọ́ àwọn Filísínì sì wá dára pọ̀ mọ́ wọn, “wọ́n sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣá àwọn Filísínì balẹ̀ láti Míkímáṣì títí dé Áíjálónì.”—1 Sámúẹ́lì 14:11-23, 31.
Àwọn Èèyàn Tún Un Rà Padà
Láìronújinlẹ̀, Sọ́ọ̀lù Ọba fi ọmọ ogun èyíkéyìí tó bá jẹun kó tó di pé àwọn ṣẹ́gun gégùn-ún. Àmọ́ fún ìdí kan, Jónátánì ò mọ̀ pé Sọ́ọ̀lù gégùn-ún rárá. Ó ti ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ bọnú afárá oyin ó sì lá díẹ̀. Ó jọ pé èyí jẹ́ kó lágbára láti parí ìjà náà.—1 Sámúẹ́lì 14:24-27.
Nígbà tí Sọ́ọ̀lù gbọ́ pé Jónátánì jẹun, ó pàṣẹ pé ó ní láti kú. Àmọ́ ẹ̀rù ikú kò ba Jónátánì. Ó ní: “Èmi nìyí! Jẹ́ kí n kú!” “Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: ‘Jónátánì yóò ha kú, tí ó ti mú ìgbàlà ńláǹlà yìí ṣe ní Ísírẹ́lì? Kò ṣeé ronú kàn! Bí Jèhófà ti ń bẹ láàyè, ẹyọ kan nínú irun orí rẹ̀ kì yóò bọ́ sí ilẹ̀; nítorí ó bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ pọ̀ lónìí yìí.’ Pẹ̀lú ìyẹn, àwọn ènìyàn tún Jónátánì rà padà, kò sì kú.”—1 Sámúẹ́lì 14:38-45.
Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní kì í lọ jagun, àmọ́ àwọn ìgbà kan lè wà nígbèésí ayé rẹ tí wàá ní láti fi hàn pé o ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà. Ó lè má rọrùn fún ọ láti ṣe ohun tó tọ́ bó bá jẹ́ pé ohun tí kò tọ́ ni gbogbo àwọn tó wà láyìíká rẹ ń ṣe. Àmọ́ Jèhófà yóò fún ọ lókun, á sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó wù ọ́ lọ́kàn, ìyẹn ni láti rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà òdodo rẹ̀. Ó lè gba pé kó o nígboyà kó o bàa lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìsìn kan nínú ètò Jèhófà, irú bíi títẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ, títẹ́wọ́gba àfikún iṣẹ́ ìsìn, tàbí ṣíṣí lọ síbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run lójú méjèèjì. O lè máa wò ó pé bóyá lo kúnjú ìwọ̀n láti ṣe iṣẹ́ náà. Àmọ́ jẹ́ kó dá ọ lójú pé ohun tó dára gan-an lo ṣe bó o bá yọ̀ǹda ara rẹ kí Jèhófà lè lò ọ́ lọ́nà tó tọ́ lójú rẹ̀. Má ṣàì rántí Jónátánì! “Ó bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ pọ̀.”
Jónátánì àti Dáfídì
Ní nǹkan bí ogún ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, Gòláyátì tó jẹ́ ọ̀gágun àwọn Filísínì ṣáátá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ísírẹ́lì, àmọ́ Dáfídì pa á. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kó tó ọgbọ̀n ọdún tí Jónátánì fi ju Dáfídì lọ, wọ́n fi ọ̀pọ̀ nǹkan jọra.a Ó hàn gbangba pé Dáfídì náà ní irú ìgboyà tí Jónátánì fi hàn ní Míkímáṣì. Ọ̀nà tó tayọ jù lọ tí wọ́n gbà jọra ni pé, bíi ti Jónátánì, Dáfídì nígbàgbọ́ pé Jèhófà lágbára láti gbani là, èyí tó mú kó lè kojú Gòláyátì láìbẹ̀rù nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù sá sẹ́yìn. Ìdí rèé tí “ọkàn Jónátánì pàápàá wá fà mọ́ ọkàn Dáfídì, Jónátánì sì bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkàn òun tìkára rẹ̀.”—1 Sámúẹ́lì 17:1–18:4.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé jíjẹ́ tí Dáfídì jẹ́ akọni mú kí Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í kà á sí ọ̀tá, Jónátánì kò jowú Dáfídì rárá. Ńṣe lòun àti Dáfídì di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n jọ ń sọ̀rọ̀ àṣírí, Dáfídì á ti sọ fún Jónátánì pé Ọlọ́run ti fàmì òróró yan òun láti di ọba Ísírẹ́lì lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù bá kú. Jónátánì fara mọ́ ìpinnu Ọlọ́run.
Nígbà tí Sọ́ọ̀lù Ọba sọ fún Jónátánì ọmọ rẹ̀ àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé òun fẹ́ pa Dáfídì, Jónátánì sọ fún Dáfídì pé kó ṣọ́ra. Jónátánì jẹ́ kí Sọ́ọ̀lù mọ̀ pé Dáfídì kì í ṣe èèyànkéèyàn. Ó ṣe tán, Dáfídì kò ṣẹ ọba rárá! Ṣebí Dáfídì fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu láti lọ kojú Gòláyátì. Ọ̀rọ̀ tí Jónátánì sọ tìtaratìtara yìí nípa ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí Sọ́ọ̀lù kà sẹ́ni burúkú mú ọkàn Sọ́ọ̀lù rọ̀. Àmọ́ kò pẹ́ tí Sọ́ọ̀lù tún fi bẹ̀rẹ̀ sí í gbèrò ibi nípa Dáfídì tó sì tún gbìyànjú láti pa á, èyí tó mú kó di dandan fún Dáfídì láti sá lọ.—1 Sámúẹ́lì 19:1-18.
Àmọ́ Jónátánì kò fi Dáfídì sílẹ̀ o. Àwọn ọ̀rẹ́ méjèèjì pàdé pọ̀ láti ro ohun tí wọ́n máa ṣe. Jónátánì ti ọ̀rẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn, ó sì tún gbìyànjú láti ti bàbá rẹ̀ lẹ́yìn, ó sọ fún Dáfídì pé: “Kò ṣeé ronú kàn! Ìwọ kì yóò kú.” Àmọ́ Dáfídì sọ fún Jónátánì pé: “Nǹkan bí ìṣísẹ̀ kan ni ó wà láàárín èmi àti ikú!”—1 Sámúẹ́lì 20:1-3.
Jónátánì àti Dáfídì wá dá ọgbọ́n kan láti mọ ohun tó wà lọ́kàn Sọ́ọ̀lù. Bí Sọ́ọ̀lù bá mọ̀ pé Dáfídì kò wá jẹun ní tábìlì ọba, Jónátánì yóò sọ fún bàbá rẹ̀ pé Dáfídì ti tọrọ àyè pé òun kò ní lè wá nítorí pé òun fẹ́ lọ síbi ìrúbọ kan tí wọ́n fẹ́ ṣe nínú ìdílé àwọn. Bí inú bá bí Sọ́ọ̀lù, àmì nìyẹn pé inú Sọ́ọ̀lù kò dùn sí Dáfídì. Jónátánì ṣàdúrà fún Dáfídì ó sì sọ ohun kan tó fi hàn pé ó gbà pé yóò di ọba lọ́jọ́ iwájú, ó ní: “Kí Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti wà pẹ̀lú baba mi.” Àwọn méjèèjì búra pé àwọn ò ní da ara wọn, wọn sì sọ ọ̀nà tí Jónátánì yóò gbà jẹ́ kí Dáfídì mọ àbájáde ìdánwò tí wọ́n fẹ́ ṣe náà.—1 Sámúẹ́lì 20:5-24.
Nígbà tí Sọ́ọ̀lù rí i pé Dáfídì kò wá, Jónátánì ṣàlàyé pé Dáfídì ti bẹ òun pé: “Bí mo bá rí ojú rere ní ojú rẹ, jọ̀wọ́, jẹ́ kí n yọ́ lọ, kí n lè rí àwọn arákùnrin mi.” Ẹ̀rù kò ba Jónátánì láti jẹ́ kí bàbá òun mọ̀ pé òun fẹ́ràn Dáfídì. Àmọ́ inú bí ọba gan-an! Ó sọ̀rọ̀ burúkú sí Jónátánì ó sì ń pariwo pé Dáfídì kò ní jẹ́ kọ́mọ òun di ọba lẹ́yìn òun. Sọ́ọ̀lù pàṣẹ fún Jónátánì pé kó lọ mú Dáfídì wá nítorí pé ó ní láti kú. Jónátánì bá fìbínú dáhùn pé: “Èé ṣe tí a ó fi fi ikú pa á? Kí ni ohun tí ó ṣe?” Pẹ̀lú ìbínú, Sọ́ọ̀lù ju ọ̀kọ̀ lu ọmọ rẹ̀. Ọ̀kọ̀ náà ò ba Jónátánì, àmọ́ inú rẹ̀ bà jẹ́ gan-an nítorí Dáfídì.—1 Sámúẹ́lì 20:25-34.
Ẹ ò rí i pé ìdúróṣinṣin Jónátánì yìí le kú! Tá a bá fojú ẹ̀dá èèyàn wò ó, kò sí àǹfààní kan lọ títí tó máa rí nínú bíbá Dáfídì ṣọ̀rẹ́, ohun tó sì máa pàdánù kì í ṣe kékeré. Àmọ́ Jèhófà ti pinnu pé Dáfídì ni yóò di ọba lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù, ohun tí Ọlọ́run sì pinnu láti ṣe yìí yóò ṣe Jónátánì fúnra rẹ̀ àtàwọn mìíràn láǹfààní.
Wọ́n Fi Ẹkún Pínyà
Jónátánì lọ pàdé Dáfídì níkọ̀kọ̀ láti sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún un. Níbi tọ́rọ̀ dé yìí, ó hàn gbangba pé Dáfídì kò tún lè wọ ààfin Sọ́ọ̀lù mọ́ láé. Àwọn méjèèjì sunkún wọ́n sì dì mọ́ ara wọn. Lẹ́yìn náà ni Dáfídì lọ fara pa mọ́.—1 Sámúẹ́lì 20:35-42.
Ẹ̀ẹ̀kan péré ni Jónátánì tún fojú kan ìsáǹsá yìí, ìyẹn sì jẹ́ nígbà tí Dáfídì ń sá pa mọ́ fún Sọ́ọ̀lù “ní aginjù Sífù ní Hóréṣi.” Àkókò yẹn ni Jónátánì fún Dáfídì níṣìírí, tó sọ fún un pé: “Má fòyà; nítorí ọwọ́ Sọ́ọ̀lù baba mi kì yóò tẹ̀ ọ́, ìwọ ni yóò sì jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì, èmi ni yóò sì di igbá-kejì rẹ; Sọ́ọ̀lù baba mi sì mọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.” (1 Sámúẹ́lì 23:15-18) Kò pẹ́ sígbà yẹn ni Jónátánì àti Sọ́ọ̀lù kú nínú ogun tí wọ́n lọ bá àwọn Filísínì jà.—1 Sámúẹ́lì 31:1-4.
Ó yẹ kí gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ronú dáadáa nípa irú ìgbésí ayé tí Jónátánì gbé. Ǹjẹ́ ìwọ náà dojú kọ ìpinnu nípa tẹni tó yẹ kó o ṣe? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, rántí pé ohun tí Sọ́ọ̀lù ń fẹ́ ni pé kí Jónátánì máa lépa ìfẹ́ tara rẹ̀. Àmọ́ Jónátánì bọlá fún Jèhófà, ó fi gbogbo ọkàn fara mọ́ ìpinnu Jèhófà, ó ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún un, inú rẹ̀ sì dùn pé ẹni tí Ọlọ́run yàn ni yóò di ọba Ísírẹ́lì lẹ́yìn bàbá òun. Bẹ́ẹ̀ ni, Jónátánì ti Dáfídì lẹ́yìn ó sì tún jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.
Jónátánì ní àwọn ànímọ́ tó wuni gan-an. Gbìyànjú kó o nírú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀! Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn á lè sọ nípa rẹ bí wọ́n ṣe sọ nípa Jónátánì pé: “Ó bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ pọ̀.”—1 Sámúẹ́lì 14:45.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ó kéré tán Jónátánì á ti tó ẹni ogún ọdún nígbà tí Bíbélì kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí ogun níbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sọ́ọ̀lù, ẹni tó jọba fún ogójì ọdún. (Númérì 1:3; 1 Sámúẹ́lì 13:2) Nípa báyìí, Jónátánì á ti máa sún mọ́ ẹni ọgọ́ta ọdún nígbà tó kú ní nǹkan bí ọdún 1078 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Níwọ̀n bí Dáfídì ti jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún nígbà yẹn, ó ṣe kedere pé Jónátánì fi nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún ju Dáfídì lọ.—1 Sámúẹ́lì 31:2; 2 Sámúẹ́lì 5:4.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Jónátánì kò jowú Dáfídì