ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 2/8 ojú ìwé 25-28
  • Ìrètí Ló Ń fún Mi Lókun Láti Fara Da Àwọn Àdánwò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìrètí Ló Ń fún Mi Lókun Láti Fara Da Àwọn Àdánwò
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbẹ̀rẹ̀ Àwọn Àdánwò Wa
  • Mo Lọ Ń Gbé Lọ́dọ̀ Àwọn Òbí Mi
  • Ìrètí Ló fún Mi Lókun
  • Orísun Ayọ̀ Làwọn Ọmọ Mi Jẹ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún Wa
  • Ọ̀pọ̀ Ìbùkún Ń fún Wa Lókun
  • Jèhófà Máa Ń Fa Àwọn Onírẹ̀lẹ̀ Wá Sínú Òtítọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Kò Rọrùn Láti Tọ́ Ọmọ Mẹ́jọ Ní Ọ̀nà Jèhófà, Àmọ́ Ó Máyọ̀ Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Jèhófà Ti Mẹ́sẹ̀ Mi Dúró ní Gbogbo Ọjọ́ Ayé Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • “Wàá Kàn Kú Dànù Ni!”
    Jí!—2000
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 2/8 ojú ìwé 25-28

Ìrètí Ló Ń fún Mi Lókun Láti Fara Da Àwọn Àdánwò

GẸ́GẸ́ BÍ MICHIKO OGAWA TI SỌ Ọ́

Ní April 29, 1969, àwọn ọlọ́pàá tẹ̀ mí láago. Wọ́n sọ pé Seikichi, ọkọ mi, fara pa nínú jàǹbá ọkọ̀, ó sì wà nílé ìwòsàn. Mo kó àwọn ọmọ mi kékeré méjèèjì ti ọ̀rẹ́ mi kan, mo sì sáré gbọ̀nà ilé ìwòsàn lọ. Látìgbà yẹn ni Seikichi ti di alárùn ẹ̀gbà, ó sì dákú lọ gbári látìgbà yẹn, kò sì tíì jí sáyé títí di báa ti ń wí yìí. Ẹ jẹ́ kí n sọ fún yín nípa ìdílé wa àti báa ṣe ń yí i mọ́ ọn látìgbà yẹn wá.

OṢÙ February ọdún 1940 ni wọ́n bí mi nílùú Sanda, nítòsí Kobe, Japan. Látìgbà témi àti Seikichi ti ń lọ síléèwé jẹ́lé-ó-sinmi la ti mọra wa. February 16, 1964 la ṣègbéyàwó. Ọkọ mi ò lágbaja ọ̀rọ̀ sísọ, àmọ́ ó fẹ́ràn ọmọdé. Kò pẹ́ táa fi bí ọmọkùnrin méjì, orúkọ wọn ni Ryusuke àti Kohei.

Iléeṣẹ́ ìkọ́lé kan ní Tokyo ni Seikichi ti ń ṣiṣẹ́, a sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé nítòsí ibẹ̀ lẹ́yìn ìgbéyàwó. Ní October 1967, ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan wá sílé mi, ó sì sọ pé òun ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Èsì tí mo fún un nìyí: “Ẹ dákun, ẹ yọ̀ǹda mi. Mo ní Bíbélì tèmi.”

Obìnrin náà béèrè pé: “Ṣé mo lè rí Bíbélì ọ̀hún?”

Mo fa Bíbélì náà yọ látibi táa ń kówèé sí—ti Seikichi ni—mo sì fi hàn án. Ó fi orúkọ Jèhófà hàn mí nínú rẹ̀. Mi ò mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé orúkọ Ọlọ́run nìyẹn. Nígbà tóbìnrin náà ṣàkíyèsí àwọn ọmọ mi kékeré méjèèjì, ó ṣí Bíbélì, ó sì ka ibì kan tó sọ pé: “Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀; nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kì yóò yà kúrò nínú rẹ̀.” (Òwe 22:6) Mo kúkú ti ń ronú tẹ́lẹ̀ nípa bí màá ṣe tọ́ àwọn ọmọ mi ní àtọ́yanjú. Nítorí náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Mo ní kí obìnrin náà wọlé wá sínú iyàrá, a sì bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nínú ìwé pẹlẹbẹ náà “Sawo o! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” Mo wá ń sọ lọ́kàn mi pé, ‘Ì bá mà dáa o, ká ní gbogbo ìdílé wa lè jùmọ̀ máa gbádùn ìgbésí ayé aláyọ̀!’ Nígbà tí Seikichi wọlé dé, mo sọ fún un pé: “Mo fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

Ó sọ fún mi pé: “Olùfẹ́, kò sídìí fún irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀. Màá kọ́ ẹ ní ohunkóhun tóo bá fẹ́ mọ̀.” Síbẹ̀síbẹ̀, mo gba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyè, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, kò sì pẹ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ sí lọ sípàdé wọn.

Ìbẹ̀rẹ̀ Àwọn Àdánwò Wa

Nígbà tí mo dé ilé ìwòsàn tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè lálẹ́ ọjọ́ yẹn ní April 1969, ṣe lòtútù dà bò mí nígbà tí mo gbọ́ pé ọ̀rẹ́ Seikichi kan, ìyẹn ọkọ obìnrin tí mo kó àwọn ọmọ mi tì, wà nínú ọkọ̀ takisí náà pẹ̀lú rẹ̀ nígbà tí jàǹbá náà ṣẹlẹ̀. Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà ni ọ̀rẹ́ ọkọ mi yìí kú.

Lóru yẹn, àwọn ọ̀ṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn sọ pé kí n tètè sọ fún gbogbo ẹni tí mo bá mọ̀ pé ó yẹ kó wá rí Seikichi, nítorí wọn ò rò pé á yè é. Egungun tó wà nísàlẹ̀ agbárí rẹ̀ ti fọ́, ọ̀kan lára iṣan ọpọlọ rẹ̀ sì ti bà jẹ́. Ọjọ́ kejì làwọn ẹbí wa sáré dé sílé ìwòsàn láti àgbègbè Kobe.

Ohùn kan ń dún fatafata lórí ẹ̀rọ gbohùngbohùn ilé ìwòsàn náà pé: “Gbogbo ẹ̀yin ẹbí Seikichi Ogawa, ẹ jọ̀ọ́, ẹ tètè wá wò ó.” Ṣe ni a rọ́ gìrìgìrì lọ sí wọ́ọ̀dù ìtọ́jú àkànṣe, tí a lọ ń kí i lọ́kọ̀ọ̀kan pé ó dìgbà o. Ṣùgbọ́n oṣù kan gbáko ló fi wà ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan sàréè. Àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe gbẹ̀yìn fi hàn pé ó máa wà ní ipò yìí fún àkókò gígùn.

Fún ìdí yìí, wọ́n fi ọkọ̀ tí wọ́n fi ń gbé aláìsàn gbé Seikichi láti Tokyo lọ sí Kobe, ó jẹ́ ìrìn ẹgbẹ̀ta kìlómítà ó lé àádọ́ta. Mo bá a dédìí ọkọ̀ kí n tó wá wọ ọkọ̀ ojú irin ayára-bí-àṣá padà wálé, tí mo ń gbàdúrà pé kí ọkọ mi máà kú. Inú mi dùn yàtọ̀ lálẹ́ ọjọ́ yẹn nígbà tí mo rí i láàyè ní ilé ìwòsàn kan ní Kobe. Mo wá rọra sọ fún un kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé, ‘Olùfẹ́, o ti bọ́ nínú eléyìí ná!’

Mo Lọ Ń Gbé Lọ́dọ̀ Àwọn Òbí Mi

Èmi àtàwọn ọmọ mi padà sílé àwọn òbí mi ní Sanda, níbẹ̀ làwọn ọmọ ti bẹ̀rẹ̀ iléèwé jẹ́lé-ó-sinmi. Mo san àsansílẹ̀ owó ọkọ̀ ojú irin táa máa gbé mi lọ, gbé mi bọ̀ láti Kobe, ìlú tó jẹ́ bí ogójì kìlómítà síbi tí mò ń gbé, tí mo bá lọ sí ilé ìwòsàn náà lónìí, ìyá ọkọ mi á lọ lọ́la, báa ṣe ń ṣe lójoojúmọ́ nìyẹn fọ́dún kan gbáko. Ohun tí mo máa ń rò lọ́kàn ni pé, ‘Ta ní mọ̀ bóyá òní ni Seikichi máa jí sáyé? Kí ló máa kọ́kọ́ sọ fún mi? Èsì wo ni màá fún un ná?’ Ìgbàkigbà tí mo bá rí ìdílé aláyọ̀ kan ni mo tún máa ń sọ lọ́kàn ara mi pé, ‘Ká ní ara Seikichi le ni, ṣebí àwọn ọmọ tàwa náà ì bá máa gbádùn báyìí.’ Omi á wá lé ròrò sí mi lójú.

Ní àwọn ọdún wọ̀nyẹn tí gbogbo rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, tí mo bá kà á nínú ìwé ìròyìn pé ẹnì kan ti jí sáyé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù tó fi dákú lọ gbári, èmi náà á wá bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé Seikichi pẹ̀lú mà lè jí. Nítorí náà, mo sọ fún ẹ̀gbọ́n ọkọ mi pé: “Mo fẹ́ gbé ọkọ mi lọ sílé ìwòsàn tó wà ní Honshu, níhà ìlà oòrùn àríwá.” Ṣùgbọ́n ó sọ fún mi pé àìsàn yìí ò gbóògùn, ó sì dá a lábàá pé kí n máa fi owó táa bá ní tọ́jú àwọn mẹ́ńbà ìdílé wa yòókù.

Kristẹni kan tó jẹ́ alàgbà nínú ọ̀kan lára ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Kobe ń gbé nítòsí ilé ìwòsàn náà, mo sì máa ń yà sílé rẹ̀ kí n tó lọ sọ́dọ̀ Seikichi. Ìyàwó rẹ̀ máa ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Àwọn ọmọ wọn méjèèjì sì máa ń wá sí iyàrá wa nílé ìwòsàn láti wá fún wa ní kásẹ́ẹ̀tì tí wọ́n ká gbogbo ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ nínú ìpàdé ìjọ wọn sí. Ìdílé yìí fún mi níṣìírí, wọ́n sì tù mí nínú lọ́pọ̀lọpọ̀.

Ìrètí Ló fún Mi Lókun

Lọ́jọ́ kan, alábòójútó arìnrìn-àjò kan tó ń bẹ ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wò, bẹ̀ wá wò nílé ìwòsàn, ó sì ka ìwé Róòmù 8:18-25 sí mi létí. Apá kan rẹ̀ kà pé: “Mo ṣírò rẹ̀ pé àwọn ìjìyà àsìkò ìsinsìnyí kò jámọ́ ohunkóhun ní ìfiwéra pẹ̀lú ògo tí a óò ṣí payá nínú wa. . . . Nítorí àwa mọ̀ pé gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí. . . . Nígbà tí ẹnì kan bá rí ohun kan, ó ha máa ń retí rẹ̀ bí? Ṣùgbọ́n bí a bá ń retí ohun tí a kò rí, a óò máa bá a nìṣó ní dídúró dè é pẹ̀lú ìfaradà.”

Ìjíròrò náà nípa ìrètí táwa Kristẹni ní, rán mi létí pé kékeré ni gbogbo nǹkan tí à ń jìyà rẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́, táa bá fi wé ohun ayọ̀ tí Jésù ṣèlérí—ìyẹn ni ìyè nínú Párádísè tí ń bọ̀ wá sórí ilẹ̀ ayé. (Lúùkù 23:43) Ìjíròrò náà ràn mí lọ́wọ́ láti rántí pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojú ogun le, ìrètí ńbẹ, ó sì ràn mí lọ́wọ́ láti tẹjú mọ́ àwọn ìbùkún tó dájú pé yóò dé lọ́jọ́ iwájú nínú ayé tuntun.—2 Kọ́ríńtì 4:17, 18; Ìṣípayá 21:3, 4.

Ní June 1970, wọ́n gbé Seikichi wá sílé ìwòsàn kan ní Sanda, níbi tí èmi àtàwọn òbí mi ń gbé. Ní January ọdún tó tẹ̀ lé e, nígbà tí mo gba ìwé tí agbẹjọ́rò wa kọ, tó fi kéde pé jàǹbá náà ti sọ ọkọ mi di aláìlètapútú, inú mi bà jẹ́ gan-an, mo kàn bẹ̀rẹ̀ sí sunkún ni. Ìyá ọkọ mi á máa sọ fún mi pé: “Pẹ̀lẹ́, Michiko, ojú rẹ ti rí nǹkan gan-an nítorí ọmọ mi.” Ó tún máa ń sọ pé: “Ì bá ṣe pé mo lè fi ara mi dí Seikichi ni, inú mi ì bá dùn.” A óò tún jọ bẹ̀rẹ̀ sí sunkún.

Bàbá mi máa ń sọ pé kí n lọ wáṣẹ́ tí yóò gbà mí ní gbogbo ọjọ́, àmọ́ ohun tó wà ní góńgó ẹ̀mí mi ni láti tọ́jú Seikichi. Bó tilẹ̀ dà bíi pé kò mọ ohun tó ń lọ, síbẹ̀ ó máa ń mọ ooru àti òtútù lára, bí wọ́n ṣe ń tọ́jú rẹ̀ sì máa ń nípa lórí rẹ̀. Bàbá mi fẹ́ kí n lọ fẹ́ ẹlòmíì, ṣùgbọ́n lójú tèmi, ìyẹn ò bójú mu rárá, torí pé ọkọ mi ṣì ń bẹ láàyè. (Róòmù 7:2) Lẹ́yìn ìyẹn, tí bàbá mi bá mutí yó tán, á wá máa sọ pé: “Bí mo bá kú, àtèmi àti Seikichi, a jọ ń lọ ni.”

Inú mi dùn gan-an nígbà tí wọ́n dá ìjọ sílẹ̀ ní Sanda lọ́dún 1971. Nígbà tó wá di July 28, 1973, mo ṣèrìbọmi láti fi hàn pé mo ti ṣe ìyàsímímọ́ sí Jèhófà. Èyí jẹ́ nígbà àpéjọpọ̀ àgbáyé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní Ibi Ìpàtẹ Osaka.

Lẹ́yìn náà ní 1973, ṣe ni kíndìnrín Kohei ọmọ mi ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí wú, ó sì wà nílé ìwòsàn fún oṣù márùn-ún. Bàbá mi pẹ̀lú wà nílé ìwòsàn nítorí ikọ́ ẹ̀gbẹ. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé, ní January 1, 1974, ilé ìwòsàn mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo ń yà kiri láti lọ wo bàbá mi, ọkọ mi, àti ọmọ mi. Ní ọjọọjọ́ Sunday nígbà tí èmi àti Ryusuke, àkọ́bí mi, bá lọ wo Kohei, mo máa ń fi ìwé Fifetisilẹ si Olukọ Nla Na bá òun àti Kohei ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Ẹ̀yìn ìyẹn ni èmi àti Ryusuke á wá lọ sípàdé ní Kobe, tí a ó sì darí wálé tìdùnnú-tìdùnnú.

Ìgbà gbogbo ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó ń bá mi tọ́jú Seikichi. Mo rí i dájú pé mo ń ṣàjọpín ìmọ̀ Bíbélì pẹ̀lú wọn. Nígbà tí àbúrò ọ̀kan lára àwọn tó ń tọ́jú rẹ̀ kú nínú jàǹbá iná, mo sọ fún un nípa àgbàyanu ìrètí àjíǹde tí Bíbélì ṣèlérí, ó sì tújú ká. (Jóòbù 14:13-15; Jòhánù 5:28, 29) A bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀ nílé ìwòsàn náà, àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó ṣèrìbọmi ní àpéjọpọ̀ kan lọ́dún 1978.

Orísun Ayọ̀ Làwọn Ọmọ Mi Jẹ́

Dídánìkan tọ́ àwọn ọmọ mi láìsí ìrànlọ́wọ́ ọkọ mi kò rọrùn rárá, àmọ́ mo ti rí èrè púpọ̀ nídìí ẹ̀! Mo kọ́ wọn ní ìwà ọmọlúwàbí àti gbígba tàwọn ẹlòmíì rò. Nígbà tí Ryusuke kò tíì ju ọmọ ọdún mẹ́ta péré lọ ló ti mọ̀ pé èèyàn gbọ́dọ̀ tọrọ àforíjì tó bá ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó, á sọ pé: “Màmá, ẹ máà bínú.” Kohei ní tiẹ̀ ya ìpáǹle díẹ̀, ńṣe ló máa bínú rangbandan nígbà míì tí mo bá ń bá a wí. Nígbà kan, ṣe ló tiẹ̀ ń sunkún, tó ń gbára yílẹ̀ níwájú ilé ìtajà kan nígbà tó ń fẹ́ nǹkan kan. Àmọ́ mo máa ń fọgbọ́n tún ojú ìwòye rẹ̀ ṣe, pẹ̀lú ìfẹ́ àti sùúrù. Nígbà tó wá yá, ó di elétí ọmọ, ọmọ dáadáa. Èyí ló mú un dá mi lójú gbangba pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì lóòótọ́.—2 Tímótì 3:15-17.

Nígbà tí Ryusuke wọ iléèwé girama ọlọ́dún mẹ́ta àkọ́kọ́, ó ṣàlàyé fáwọn olùkọ́ nípa ìdí tóun ò fi ní bá wọn kọ́ ẹ̀kọ́ ìgbèjà ara ẹni. (Aísáyà 2:4) Lọ́jọ́ kan, ó ti iléèwé dé tayọ̀tayọ̀ nítorí pé ó dáhùn àwọn ìbéèrè táwọn olùkọ́ bi í níbi ìpàdé kan tí wọ́n pè.

Ìbákẹ́gbẹ́ tó gbámúṣé nínú ìjọ ran àwọn ọmọ mi lọ́wọ́ gan-an. Àwọn Kristẹni alàgbà máa ń pè wọ́n lọ jàsè nílé wọn, wọ́n sì máa ń ké sí wọn nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé wọn àti nígbà eré ìnàjú. Àwọn àǹfààní tún wà fún ìbákẹ́gbẹ́ alárinrin, títí kan jíjùmọ̀ ṣe onírúurú eré ìmárale. Ryusuke fẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ fún Jèhófà hàn nígbà tó ṣe ìrìbọmi lọ́dún 1979, Kohei náà sì ṣèrìbọmi tiẹ̀ ní ọdún tó tẹ̀ lé e.

Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún Wa

Nígbà kan tí alábòójútó arìnrìn-àjò bẹ̀ wá wò, mo sọ fún un pé mo fẹ́ di aṣáájú ọ̀nà, èyíinì ni òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nítorí pé ipò tí mo wà nígbà yẹn ò ní jẹ́ kó dà bí ìgbésẹ̀ tó mọ́gbọ́n dání, ó rọra fi sùúrù rán mi létí ìjẹ́pàtàkì fífi òtítọ́ Bíbélì tọ́ àwọn ọmọ mi lọ́nà tó fẹsẹ̀ múlẹ̀. Ó sọ pé: “Ohun tó ṣe pàtàkì ni láti ní ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà.” Nítorí náà, èmi àtàwọn ọmọ mi máa ń ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá gba ìsinmi ní iléèwé. Iṣẹ́ yìí ràn mí lọ́wọ́ gan-an láti ní ayọ̀ àti àlàáfíà ọkàn bí mo ṣe ń tọ́jú Seikichi.

Níkẹyìn, nígbà tó di September 1979, ni mo dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé. Ní May 1984, nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn tí Ryusuke jáde iléèwé girama, òun náà forúkọ sílẹ̀ fún iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Kohei dara pọ̀ mọ́ ọn nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní September 1984. Nípa bẹ́ẹ̀, àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta la ti gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún yìí. Bí mo ti bojú wẹ̀yìn, tí mo wo ohun tó lé ní ogún ọdún tí mo ti fi ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, nínú èyí tí mo ti láǹfààní láti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti sin Jèhófà, mo mọ̀ pé iṣẹ́ yìí ti fún mi lókun láti kojú àwọn àdánwò mi.

Ryusuke yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún iṣẹ́ kíkọ́ ilé kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò, tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó wà ní Kansai. Lẹ́yìn náà, ó wá fi ọdún méje sìn gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú Gbọ̀ngàn Àpéjọ ti Hyogo. Nísinsìnyí, Kristẹni alàgbà ni nínú ìjọ kan nítòsí, ní Kobe, òun ló sì ń tọ́jú mi. Láti 1985 ni Kohei ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ebina.

Ọ̀pọ̀ Ìbùkún Ń fún Wa Lókun

Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi ń lọ sílé ìwòsàn lọ́pọ̀ ìgbà lọ́sẹ̀, tí mo lọ ń bẹ Seikichi wò, tí mo sì ń wẹ̀ fún un. Mo ń ṣe ìtọ́jú yìí ní àfikún sí ìtọ́jú tí olùtọ́jú ń ṣe déédéé. Ní September 1996, lẹ́yìn ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n tí Seikichi fi wà nílé ìwòsàn, a gbé e padà wálé láti wá máa gbé nílé, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ olùtọ́jú kan. Ọ̀pá oníhò kan tí wọ́n tì bọ imú rẹ̀ ni wọ́n fi ń fa oúnjẹ olómi sí i lára. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì lajú, ó máa ń ṣe bí ẹní gbọ́ wa nígbà táa bá ń bá a sọ̀rọ̀. Ó ń dùn mí gan-an bí mo ṣe ń rí Seikichi ní ipò tó wà yìí, àmọ́ ìrètí àgbàyanu tí ń bẹ níwájú ló ń fún mi lókun.

Ní gẹ́rẹ́ ká tó gbé Seikichi padà wálé, mo ní kí alábòójútó àyíká kan àtìyàwó rẹ̀ máa dé sọ́dọ̀ wa, fún ìdí yìí, ọdún kan làwa márùn-ún fi ń gbé pa pọ̀ nínú ilé wa kékeré. Mi ò mọ̀ pé ó lè ṣeé ṣe láyé, láti tún jùmọ̀ gbé pẹ̀lú Seikichi, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún èyí. Fún ọ̀pọ̀ ọdún ni mo ń yán hànhàn pé kí Seikichi tiẹ̀ lajú, àmọ́ kí ìfẹ́ Jèhófà di ṣíṣe ló kù tó jẹ mí lógún báyìí.

Mo lè sọ tòótọ́-tòótọ́ pé: “Ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.” (Òwe 10:22) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àkókò ráńpẹ́ lèmi àti Seikichi fi wà pa pọ̀ ní àlàáfíà ara, Ẹlẹ́dàá ti fi ọmọ méjì jíǹkí mi, àwọn ọmọ tó rántí ‘Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá.’ Èyí tọ́pẹ́, ó ju ọpẹ́ lọ!—Oníwàásù 12:1.

Ní báyìí ná, mo fẹ́ máa ṣe aṣáájú ọ̀nà nìṣó—kí n lè máa bá a lọ ní ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti rí “ìyè tòótọ́”—lẹ́sẹ̀ kan náà, kí n sì máa fi ìfẹ́ tọ́jú Seikichi. (1 Tímótì 6:19) Ìrírí mi ti jẹ́ kí n mọ̀ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí onísáàmù náà sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.”—Sáàmù 55:22.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Èmi àti ọkọ mi pẹ̀lú Ryusuke

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Seikichi àtàwọn ọmọ wa méjèèjì, lóṣù mẹ́fà ṣáájú jàǹbá náà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Ẹlẹ́dàá fi ọmọkùnrin méjì yìí, Ryusuke àti Kohei (lókè), jíǹkí wa, àwọn ọmọ tó ‘rántí Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá’

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́