‘Ó Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Ronú Nípa Ìgbésí Ayé Mi’
OHUN tí ọmọbìnrin kan, ẹni ọdún méjìdínlógún, tó ń jẹ́ Maria, ní ìlú Cherepovets sọ nìyẹn nípa ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́. Lẹ́tà tó wà nísàlẹ̀ yìí ló kọ sí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nítòsí St. Petersburg, Rọ́ṣíà, tó jẹ́ nǹkan bí irínwó kìlómítà láti Cherepovets.
“Ìwé yìí ti ràn mí lọ́wọ́ láti ronú nípa ìgbésí ayé mi, ohun tí mo ń lépa, àti àwọn èèyàn tó wà láyìíká mi. Mo rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó ń jẹ mí lọ́kàn jù lọ. Nígbà tí mo ń ka ìwé náà, mo mọrírì rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí omijé fi ń bọ́ lójú mi.”
Maria tún sọ pé: “Ńṣe ló dà bíi pé wọ́n ṣí aṣọ lójú mi, tó sì wá là sílẹ̀ rekete bí inú mi ti ń dùn. Mi ò tíì ka ìwé tó dára tó èyí rí láyé mi. Kò láfiwé, níwọ̀n bí wọ́n ti gbé e karí Bíbélì tó sì jẹ́ pé ìmọ̀ràn Jèhófà Ọlọ́run ló dára jù.”
Bí ìwọ pẹ̀lú bá fẹ́ jàǹfààní ohun tó wà nínú ìwé náà, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, o lè rí ìsọfúnni nípa bí o ṣe lè rí ẹ̀dà kan gbà tí o bá kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kí o sì fi ránṣẹ́ sí wa tàbí kí o fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí tí a tò sójú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí mi nípa bí mo ṣe lè rí ìwé náà, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, gbà.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.