Ǹjẹ́ o Mọ̀?
(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 27. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìtẹ̀jáde “Insight on the Scriptures,” tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.)
1. Ọ̀nà wo ni Jésù sọ fún obìnrin ará Samáríà náà pé a gbọ́dọ̀ gbà jọ́sìn Ọlọ́run? (Jòhánù 4:24)
2. Kí ni Ọlọ́run ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́, kí wọ́n baà lè fara da pákáǹleke àti inúnibíni? (2 Kọ́ríńtì 4:7-10)
3. Ta ni ó kéré jù lọ lára àwọn ọmọkùnrin Gídéónì Onídàájọ́, ọ̀kan ṣoṣo tó yè bọ́ lára àádọ́rin ọmọkùnrin rẹ̀ nígbà tí Ábímélékì ọmọ bàbá rẹ̀ pa wọ́n? (Àwọn Onídàájọ́ 9:5)
4. Orúkọ wo ni a fún ọdún àádọ́ta lẹ́yìn tí Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, nígbà tí wọ́n gbọ́dọ̀ pòkìkí ìdásílẹ̀ lómìnira ní gbogbo ilẹ̀ náà? (Léfítíkù 25:10)
5. Láti ọwọ́ ìjọba kékeré wo ni àwọn ọmọ Ámónì ti háyà ẹgbẹ̀rún méjìlá ọkùnrin tí ń jà láti lò wọ́n fún bíbá Dáfídì jà? (2 Sámúẹ́lì 10:6)
6. Kí ni Nebukadinésárì Ọba Bábílónì rí nínú àlá kan tó dà á láàmú gidigidi ní ọdún kejì ìṣàkóso rẹ̀? (Dáníẹ́lì 2:1, 31)
7. Kí ni Sámúsìnì fọwọ́ lásán fà ya sí méjì nínú àkọsílẹ̀ nípa bó ṣe kọ́kọ́ lo agbára tí Ọlọ́run fi fún un? (Àwọn Onídàájọ́ 14:5, 6)
8. Ẹran wo ni Ábúráhámù rí tí ìwo rẹ̀ há sínú ìgbòrò tí ó sì lò láti fi rúbọ dípò Ísákì? (Jẹ́nẹ́sísì 22:13)
9. Kí ni Sọ́ọ̀lù Ọba ṣe tó fi ré àṣẹ Jèhófà kọjá nínú ogun tí ó bá àwọn ọmọ Ámálékì jà? (1 Sámúẹ́lì 15:3-9)
10. Orúkọ wo ni wọ́n fún Étánímù, tí í ṣe oṣù àkọ́kọ́ nínú kàlẹ́ńdà àwọn Júù, lẹ́yìn tí Bábílónì kó wọn nígbèkùn?
11. Ibo ni àwọn òbí Jésù ti rí ọmọkùnrin wọn ọlọ́dún méjìlá lẹ́yìn tí wọ́n ti wá a kiri fún ọjọ́ mẹ́ta? (Lúùkù 2:46)
12. Ta ni a sọ fún lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ pé kí ó yọ̀ látàrí wíwọlé tí Jésù wọlé pẹ̀lú ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́? (Sekaráyà 9:9)
13. Èé ṣe tí Jésù fi pèsè àmọ̀ràn náà pé kí á ‘to ìṣúra jọ pa mọ́ ní ọ̀run’? (Mátíù 6:20)
14. Kí ni Jèhófà ṣe láti fi ìbínú rẹ̀ hàn sí Sólómọ́nì nígbà tí Sólómọ́nì yí padà, tó lọ ń rúbọ sí àwọn ọlọ́run mìíràn nígbà tó darúgbó? (1 Àwọn Ọba 11:14, 23-26)
15. Kí ni Ìwé Mímọ́ gbà wá nímọ̀ràn láti ṣọ́ ju ohunkóhun mìíràn lọ? (Òwe 4:23)
16. Kí ni Jèhóákímù Ọba ṣe nígbà tí wọ́n ka àkájọ ìwé náà fún un tí ó ní ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ lòdì sí Ísírẹ́lì nínú? (Jeremáyà 36:23)
17. Kí ni Jékọ́bù rò pé ó pa Jósẹ́fù ọmọkùnrin òun? (Jẹ́nẹ́sísì 37:33)
18. Ìlú wo ni a mọ̀ látayébáyé gẹ́gẹ́ bí “ìlú ńlá àwọn igi ọ̀pẹ”? (Diutarónómì 34:3)
Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. “Ní ẹ̀mí àti òtítọ́”
2. “Agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá”
3. Jótámù
4. Júbílì
5. Íṣítóbù
6. Ère arabaríbí kan ní àwòrán ènìyàn, tí a fi oríṣiríṣi mẹ́táàlì ṣe àwọn ẹ̀ya ara rẹ̀
7. Ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ kan
8. Àgbò
9. Ó dá Ágágì, ọba wọn sí, bákan náà ló tún dá èyí tó dára jù lọ nínú agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran wọn sí
10. Tíṣírì
11. Nínú tẹ́ńpìlì
12. “Ọmọbìnrin Síónì”
13. Àwọn ìṣúra ti ara lè bà jẹ́, wọn kì í sì í fúnni láǹfààní kankan lọ́dọ̀ Ọlọ́run
14. Ó fawọ́ ìbùkún rẹ̀ sẹ́yìn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn alátakò dìde sí Sólómọ́nì
15. Ọkàn àyà ìṣàpẹẹrẹ
16. Ó ya á sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, ó sì sọ ọ́ sínú iná
17. “Ẹranko ẹhànnà abèṣe”
18. Jẹ́ríkò