Ṣé Òṣùpá Ló Ń darí Ayé rẹ?
FÚN ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ni àwọn ènìyàn ti gbà gbọ́ pé òṣùpá máa ń darí àwọn apá kan nínú ayé èèyàn lórí ilẹ̀ ayé. Èrò wọn ni pé bí òṣùpá ṣe ń lọ tó sì ń bọ̀, ó ń nípa lórí irúgbìn, ẹranko, àti ènìyàn pàápàá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwádìí nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní ti jádìí àwọn èrò táwọn kan ti ní lọ́kàn tipẹ́, síbẹ̀ wọ́n ṣì gba àwọn ohun kan gbọ́ títí dòní olónìí. Kí ni àwọn ẹ̀rí tó wà fi hàn?
Ó dá àwọn kan lójú pé ìṣípòpadà òṣùpá ń kó ipa kan nínú ìdàgbàsókè àwọn irúgbìn. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń wo kàlẹ́ńdà àti àwọn ìwé tí wọ́n fi ń ṣírò àkókò láti pinnu ìgbà tó yẹ kí wọ́n gbin òdòdó, ìgbà tó yẹ kí wọ́n lo ajílẹ̀, ìgbà tó yẹ kí wọ́n pọn ọtí tàbí ìgbà tó yẹ kí wọ́n lọ èso pamọ́. Ìdí tí wọ́n fi ń ṣe èyí ni pé wọ́n gbà gbọ́ pé táwọn bá ṣe àwọn iṣẹ́ kan tí kò sì bọ́ sí àkókò ìṣípòpadà òṣùpá, ó lè ba nǹkan náà jẹ́. Ẹnì kan fún àwọn tó ń dáko nímọ̀ràn yìí pé: “Àsìkò tí òṣùpá bá yọ dáadáa ló yẹ kéèyàn já ẹ̀fọ́ tó bá fẹ́ tètè jẹ, àmọ́ nígbà tóṣùpá ò bá fi bẹ́ẹ̀ yọ ló dáa kéèyàn já èyí tó bá fẹ́ fi pamọ́.” Ǹjẹ́ ẹ̀rí kankan wà nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó gbe àṣà yìí lẹ́yìn?
Ó jọ pé àwọn ìwádìí kan fi hàn pé ìṣípòpadà òṣùpá ń kópa nínú ìdàgbàsókè irúgbìn. Bó ti wù kó rí, ìyẹn ò tíì yí ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lérò padà. Wọ́n ṣàlàyé pé lílọ bíbọ̀ òṣùpá jẹ́ nǹkan tó díjú, kì í sì í fìgbà gbogbo ṣe déédéé, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àmì kankan tí èèyàn lè fojú rí nípa wọn, nítorí náà, ó ṣòro láti tún àwọn àyẹ̀wò tí ìwádìí náà dá lé lórí ṣe.
Ṣùgbọ́n, wọ́n ti fìdí àwọn ẹ̀rí kan múlẹ̀ nípa ipa tí òṣùpá máa ń ní. Fún àpẹẹrẹ, ó hàn gbangba pé àwọn ìgbòkègbodò ọ̀pọ̀ ẹ̀dá alààyè, irú bíi jíjẹun wọn, mímú irú tiwọn jáde, àti àwọn ìyípadà wọn lọ́nà tí ẹ̀dá ní í ṣe pẹ̀lú ìlọsókè sódò omi òkun, tí agbára òòfà òṣùpá sì wá ń nípa lórí èyí ní tààràtà.
Àwọn kan sọ pé tí òṣùpá bá lè nípa lórí lílọ sókèsódò omi òkun, ó gbọ́dọ̀ nípa lórí ẹ̀dá ènìyàn bákan náà, níwọ̀n bí omi ti kó ìpín tó pọ̀ jù nínú ohun tó wà lára ẹ̀dá ènìyàn. Èwo tún ni ipa tó jọ pe lílọ àti bíbọ̀ òṣùpá kó nínú àwọn ohun bí ìdàrú ọpọlọ, ìgbà tí wọ́n bí ènìyàn, àti àkókò tí nǹkan oṣù obìnrin ń bọ́ sí, èyí tí gígùn àkókò ẹ̀ jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú ti òṣùpá?
Wọ́n tí ṣe ìwádìí ní àwọn ẹ̀ka ìtọ́jú àìsàn ọpọlọ, ẹ̀ka ìrònú òun ìhùwà, àti ẹ̀ka ìtọ́jú àìsàn ara obìnrin láti mọ òtítọ́ tó wà nídìí ọ̀ràn yìí. Àmọ́, àwọn àbájáde ẹ̀ ò múná dóko. Àwọn olùwádìí kan sọ pé àwọn rí i pé ìbáṣepọ̀ díẹ̀ wà láàárín ìgbòkègbodò ẹ̀dá ènìyàn àti lílọ bíbọ̀ òṣùpá, ṣùgbọ́n àwọn mìíràn sọ pé kò sí nǹkan tó pa wọ́n pọ̀ rárá. Wọ́n jiyàn pé, ká ní àyípoyípo òṣùpá máa ń ní àmì tó ṣeé rí lára ìbí ẹ̀dá ènìyàn ni, ìsokọ́ra náà ì bá ti hàn gbangba tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn. Láfikún sí i, kò sí ọ̀kankan nínú àwọn àbá èrò orí tí wọ́n gbé kalẹ̀ náà láti ṣàlàyé ipa tí òṣùpá ń ní lórí ènìyàn tó tíì yí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lápapọ̀ lérò padà.a
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé sáyẹ́ǹsì fi hàn kedere pé òṣùpá ń nípa díẹ̀ lórí oríṣiríṣi àwọn nǹkan ẹlẹ́mìí tó wà lórí ilẹ̀ ayé, kò rọrùn láti pinnu bí ìyẹn ṣe tó. Àgbáálá ayé wa tó ṣeé fojú rí díjú, àti pé ní báyìí ná, kò tíì sẹ́ni tó mọ púpọ̀ lára àwọn ọ̀nà àgbàyanu tó ń gbà ṣiṣẹ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Díẹ̀ lára àwọn àbá èrò orí wọ̀nyí dá lórí ìmọ́lẹ̀ òṣùpá, òòfàmọ́lẹ̀, àti ìṣiṣẹ́pọ̀ mànàmáná òun mágínẹ́ẹ̀tì.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Abo ọlọ́run Selene, èyí tí àwọn Gíríìkì àti àwọn ará Róòmù ìgbàanì ń jọ́sìn gẹ́gẹ́ bí òṣùpá tó gbáwọ̀ èèyàn wọ̀
[Credit Line]
Musei Capitolini, Roma