Bí Ìdílé Wa Ṣe Ṣọ̀kan Padà
Gẹ́gẹ́ bí Lars àti Judith Westergaard ṣe sọ ọ́
ILÉ náà dà bí ibùgbé ọ̀kan nínú ìdílé tó láyọ̀ ní Denmark. Ibùgbé tó tura ni, wọ́n dáko kékeré kan síbẹ̀, inú abúlé kan tó tòrò ló sì wà. Fọ́tò ńlá kan wà lára ògiri nínú ilé, àwọn ọmọ tí wọ́n yà síbẹ̀ ń rẹ́rìn-ín músẹ́, ara wọ́n sì le.
Baálé ilé náà, Lars, jẹ́ alàgbà nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Judith, tí í ṣe ìyàwó rẹ̀, jẹ́ aṣáájú ọ̀nà (ajíhìnrere alákòókò kíkún). Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn méjèèjì jẹ́ aláyọ̀ báyìí, bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ̀rọ̀ rí láwọn ìgbà kan. Lars àti Judith ti ní ìṣòro àti kèéta láàárín ara wọn rí tó mú kí wọ́n kọra wọn sílẹ̀, tí ìdílé wọn sì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Ṣùgbọ́n ní báyìí, ìdílé wọ́n tún ti ṣọ̀kan padà. Èé ṣe? Àwọn fúnra wọn ni wọ́n ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀.
Lars àti Judith ò rí ohun tó burú nínú sísọ ìṣòro tí wọ́n ní nínú ìgbéyàwó wọn àti bí wọ́n ṣe wá ṣọ̀kan padà. Wọ́n ronú pé ìrírí àwọn lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́.
A Ò Níṣòro Níbẹ̀rẹ̀
Lars: Níbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé wa bí tọkọtaya ní April 1973, ayọ̀ wa kún gan-an, ó sì jọ pé nǹkan á máa ṣẹnuure fún wa títí lọ. A ò mọ Bíbélì, a ò sì mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn, ṣùgbọ́n ó dá wa lójú pé a lè mú kí ayé sunwọ̀n sí i láti gbé bí gbogbo èèyàn bá ṣiṣẹ́ kára fún ète yẹn. Ìdí nìyẹn tí a fi ń kópa nínú ètò ìṣèlú. Ayọ̀ wa pọ̀ sí i nígbà tí a bí ọmọkùnrin mẹ́ta, tára wọ́n le, tí wọ́n sì ń ta kébékébé—orúkọ wọn ni Martin, Thomas, àti Jonas.
Judith: Ọ̀gá ni mo jẹ́ lẹ́ka ilé iṣẹ́ ìjọba kan. Bákan náà, mo tún ń kópa nínú ètò ìṣèlú àti ìgbòkègbodò ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbé mi sípò aṣáájú.
Lars: Ní tèmi, ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ ńlá kan ni mo ń bá ṣiṣẹ́, mo sì dé ipò pàtàkì kan. Ọwọ́ wa bẹ̀rẹ̀ sí ròkè lẹ́nu iṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kò jọ pé ohunkóhun ń wu àlàáfíà wa léwu.
A Bẹ̀rẹ̀ Sí Jìnnà Síra Wa
Lars: Ṣùgbọ́n ṣá o, ìgbòkègbodò ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bẹ̀rẹ̀ sí gbà wá lọ́kàn gan-an débi pé a kì í lè lo àkókò púpọ̀ pẹ̀lú ara wa mọ́. Ẹgbẹ́ òṣèlú kan náà la ń bá ṣiṣẹ́ ṣùgbọ́n ẹ̀ka ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la wà. Àwọn ẹlòmíì ló ń bá wa tọ́jú àwọn ọmọ wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, yálà nílé wọn tàbí nílé ìtọ́jú ọmọdé. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀ràn ara wa ló gba àwa méjèèjì lọ́kàn, ọ̀nà ìgbésí ayé ìdílé wa dojú rú. Ìgbàkigbà táwa méjèèjì bá wà nílé, a máa ń ṣaáwọ̀ gan-an. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí fọtí pa ìrònú rẹ́.
Judith: Lóòótọ́, a ṣì fẹ́ràn ara wa àti àwọn ọmọ wa, ṣùgbọ́n a ò fìfẹ́ hàn síra wa bó ṣe yẹ ká máa ṣe; ó jọ pé ìfẹ́ táa ní síra wa ti ń tutù. Bí ìjà bí ìjà ni gbogbo ọ̀rọ̀ wa, ìyẹn sì ń pa àwọn ọmọ lára.
Lars: Nínú ìgbìyànjú láti mú kí ìdílé wá tòrò, mo pinnu láti fi iṣẹ́ sílẹ̀. Lọ́dún 1985, a kúrò láàárín ìlú lọ sí abúlé kan tí a ń gbé nísinsìnyí. Nǹkan yí padà fúngbà díẹ̀, ṣùgbọ́n èmi àti ìyàwó mi ṣì ń gbájú mọ́ ohun tó jẹ olúkúlùkù wa lógún. Níkẹyìn, ní February 1989, a kọ ara wa sílẹ̀, ìgbéyàwó wa tó ti pé ọdún mẹ́rìndínlógún sì dópin. Ìdílé wa forí ṣánpọ́n.
Judith: Ìbànújẹ́ gbáà ló jẹ́ fún wa láti rí i tí ìdílé wa pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ àti láti rí i bí ìyà ṣe ń jẹ àwọn ọmọ wa. A kórìíra ara wa gan-an débi pé a ò gbà láti jọ máa pín àwọn ọmọ wa tọ́, nítorí náà, èmi ni mo gba ẹ̀tọ́ títọ́ àwọn ọmọ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.
Lars: Èmi àti Judith gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan láti mú kí ìdílé wa tó ti tú ká tún ṣọ̀kan ṣùgbọ́n kò yọrí sí rere. A tiẹ̀ gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n ohun tí a mọ̀ nípa Ọlọ́run ò jù bíńtín lọ.
Judith: Àwọn àdúrà tí a ń gbà mú ká ronú pé Ọlọ́run kò gbọ́ wa. A dúpẹ́ pé láti ìgbà náà wá, a ti wá rí i pé Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà.
Lars: A ò mọ̀ pé àwa fúnra wa ní láti sapá, ká sì ṣe àwọn ìyípadà. Nítorí náà, kíkọ̀ tí a kọra wa sílẹ̀ fa ìbànújẹ́ gbáà.
Lars Yí Padà Láìròtẹ́lẹ̀
Lars: Nígbà tí mo ń dá gbé, ipò nǹkan yí padà fún mi pátápátá lọ́nà tí mi ò rò tẹ́lẹ̀. Lọ́jọ́ kan, mo gba ìwé ìròyìn méjì lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣáájú ìgbà yẹn, n kì í gba àwọn Ẹlẹ́rìí láyè rárá. Ṣùgbọ́n nígbà tí mo ka àwọn ìwé ìròyìn yẹn, mo rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí gba Ọlọ́run àti Jésù Kristi gbọ́ ní ti gidi. Ìyàlẹ́nu gbáà nìyẹn jẹ́ fún mi. Mi ò mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé Kristẹni ni wọ́n.
Kò pẹ́ sí ìgbà yẹn, tí mo kó lọ bá obìnrin kan tí mo pàdé nígbà kan rí. Mo wá rí i pé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni tẹ́lẹ̀. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí béèrè ìbéèrè, ó fi hàn mí nínú Bíbélì pé Jèhófà lorúkọ Ọlọ́run. Nítorí náà, “Ẹlẹ́rìí Jèhófà” túmọ̀ sí “Ẹlẹ́rìí Ọlọ́run”!
Obìnrin náà ṣètò fún mi láti lọ gbọ́ àsọyé fún gbogbo ènìyàn ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ohun tí mo rí níbẹ̀ ru ìfẹ́ mi sókè gan-an. Mo lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ládùúgbò kí n lè mọ̀ sí i, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò pẹ́ púpọ̀ tí mo fi mọ̀ pé ọ̀nà ìgbésí ayé tí mo ń gbé ò dáa, ìdí nìyẹn tí mo fi kó kúrò lọ́dọ̀ obìnrin ojúlùmọ̀ mi yẹn, mo sì lọ ń dá gbé ní ìlú mi. Mo fà sẹ́yìn fúngbà díẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tó yá, mo kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbẹ̀ mo sì ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi lọ.
Síbẹ̀síbẹ̀, mo ṣì ń ṣiyè méjì. Ṣé èèyàn Ọlọ́run làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóòótọ́? Gbogbo ohun tí mo kọ́ nígbà tí mo wà lọ́mọdé ńkọ́? Nítorí pé inú ìjọ Seventh-Day Adventist ni wọ́n bí mi sí, mo bá gba ọ̀dọ̀ àlùfáà ìjọ Adventist kan lọ. Ó gbà láti máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ lọ́jọ́ Wednesday, nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ lọ́jọ́ Monday. Ohun tí mo ń wá lọ́dọ̀ àwọn ẹ̀sìn méjèèjì ni pé kí wọ́n fún mi ní ìdáhùn tó ṣe kedere lórí àwọn kókó pàtó mẹ́rin kan, àwọn kókó náà ni: ìpadàbọ̀ Kristi, àjíǹde, ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan, àti ọ̀nà tó yẹ láti gbà ṣètò ìjọ. Oṣù mélòó kan péré ló gbà mí láti mú gbogbo iyèméjì ọkàn mi kúrò. Nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kókó mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yẹn—àti nínú gbogbo ohun mìíràn—ìgbàgbọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ló dá lórí Bíbélì látòkè délẹ̀. Ó wá já sí pé mo bẹ̀rẹ̀ sí fìdùnnú kópa nínú gbogbo ìgbòkègbodò nínú ìjọ, kò sì pẹ́ tí mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà. Ní May 1990, mo ṣèrìbọmi.
Judith Wá Ńkọ́ O?
Judith: Nígbà tí gbọ́nmisi-omi-ò-to tó ṣẹlẹ̀ nínú ìgbéyàwó wa bẹ̀rẹ̀ sí le gan-an, mo tún ti bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Nígbà tí mo gbọ́ pé Lars ti fẹ́ di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, inú mi ò dùn rárá. Jonas, ọmọ wa tó kéré jù, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá máa ń lọ kí bàbá rẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ṣùgbọ́n mo kìlọ̀ fún Lars pé kò gbọ́dọ̀ mú Jonas lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí rárá. Lars pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ, ṣùgbọ́n ohun tí mo fẹ́ ní wọ́n fọwọ́ sí.
Nígbà yẹn, mo ti bá ọkùnrin míì pàdé. Bákan náà, mo tún ti kira bọ ọ̀ràn ìṣèlú àti onírúurú iṣẹ́ ìlú gan-an. Nítorí náà, ká ní ẹnikẹ́ni bá mi sọ̀rọ̀ nípa pé ìdílé wa lè tún ṣọ̀kan padà nígbà yẹn, ńṣe ni ì bá jọ bí àlá tí ò lè ṣẹ.
Nígbà tí mo ń wá ohun tí màá fi gbógun ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo lọ bá àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì wa, ó sọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé òun ò mọ nǹkan kan nípa àwọn Ẹlẹ́rìí àti pé òun ò ní ìwé kankan tó ń sọ nípa wọn. Ohun tó kàn sọ ni pé kí ń sáà yẹra fún wọn. Bó ti wù kó rí, ìyẹn ò yí èrò òdì tí mo ní nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà padà. Ṣùgbọ́n, ohun kan mú kí n pàdé wọn lọ́ràn-anyàn lọ́nà tí mi ò rò tẹ́lẹ̀.
Àbúrò mi tó ń gbé Sweden ti di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì pè mí síbi ìgbéyàwó ẹ̀ tí wọ́n ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kan! Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ohun tí mo rí lọ́hùn-ún yí èrò mi nípa àwọn Ẹlẹ́rìí padà. Ó yà mí lẹ́nu pé wọn kì í ṣe sùẹ̀gbẹ̀ èèyàn tí mo máa ń ronú pé wọ́n jẹ́. Onínúure àti aláyọ̀ ni wọ́n, kódà, wọ́n máa ń ṣàwàdà.
Bí gbogbo èyí ṣe ń ṣẹlẹ̀, Lars, ọkọ mi àtijọ́, ti yí padà pátápátá. Ó ti wá ní láárí sí i, ó máa ń lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ, ó jẹ́ onínúure, ó sì máa ń ṣọ́ ọ̀rọ̀ tó ń sọ, kì í sì í mutí lámuyó mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀. Ìwà ẹ̀ wá fani mọ́ra gan-an! Nígbà yẹn, ó ti wá di irú ọkùnrin tí mo ń fẹ́ kó jẹ́. Inú mi máa ń bà jẹ́ gan-an tí mo bá ronú pé n kì í ṣe ìyàwó ẹ̀ mọ́ àti pé bóyá lọ́jọ́ kan á lọ́ fẹ́ obìnrin míì!
Ni mo bá dọ́gbọ́n “àyínìke” kan. Nígbà kan tí Jonas wà lọ́dọ̀ bàbá ẹ̀, mo ṣètò kí èmi àti méjì lára àwọn àbúrò mi obìnrin lọ wo Jonas àti Lars, ṣùgbọ́n kó dà bíi pé ńṣe làwọn àǹtí ọmọ mi méjèèjì náà wá wo ọmọ ẹ̀gbọ́n wọn. A pàdé ní ọgbà ìṣiré kan. Nígbà tí àwọn àǹtí ọmọ mi ń bá a ṣeré, èmi àti Lars wá orí bẹ́ǹṣì kan jókòó sí.
Ó yà mí lẹ́nu pé gbàrà tí mo gbẹ́nu lé ọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la wa, ńṣe ni Lars fa ìwé kan yọ nínú àpò ẹ̀. Orúkọ ìwé náà ni Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ.a Ó mú ìwé náà fún mi, ó sì dábàá pé kí n ka àwọn àkòrí tó sọ nípa ipa ọkọ àti ìyàwó nínú ìdílé. Ó gbà mí nímọ̀ràn gidigidi pé kí n ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n tọ́ka sí níbẹ̀.
Lẹ́yìn náà, nígbà tí èmi ati Lars dìde lórí bẹ́ǹṣì, mo fẹ́ dì í lápá mú, ṣùgbọ́n ó fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ kọ̀. Lars kò tún fẹ́ bẹ̀rẹ̀ àjọṣepọ̀ pẹ̀lú mi nígbà tí kò tíì mọ èrò mi nípa ẹ̀sìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà. Ìyẹn bí mi nínú díẹ̀, ṣùgbọ́n mo wá rí i pé ohun tó ṣe yẹn mọ́gbọ́n dání, àti pé fún àǹfààní tèmi náà ló máa jẹ́ bó bá tún padà di ọkọ mi.
Gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí mú kí n túbọ̀ máa tọ pinpin ju tìgbàkigbà rí lọ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lọ́jọ́ kejì, mo ké sí obìnrin kan tí mo mọ̀ pé ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí, a sì ṣètò pé kí òun àti ọkọ ẹ̀ wá ṣàlàyé àwọn ohun tí mo fẹ́ mọ̀ nípa ẹ̀sìn wọn fún mi. Wọ́n fi Bíbélì dáhùn gbogbo ìbéèrè mi. Mo wá rí i pé ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi kọ́ni dá lórí Bíbélì gan-an. Mo gbà pé òtítọ́ ni gbogbo ohun tí a jíròrò.
Lákòókò yẹn, mo kọ̀wé fi Ìjọ Ajíhìnrere ti Luther sílẹ̀, mo sì jáwọ́ nínú ọ̀ràn ìṣèlú. Mo tiẹ̀ jáwọ́ mímú sìgá pàápàá. Ìyẹn ló ṣì le jù nínú gbogbo ìgbésẹ̀ tí mo gbé. Mo bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi ní August 1990, nígbà tó sì di April 1991, mo ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Ìgbéyàwó Wọn Ẹlẹ́ẹ̀kejì
Judith: Ní báyìí, àwa méjèèjì ti di Ẹlẹ́rìí tó ti ṣèrìbọmi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa méjèèjì ti forí lé ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, a ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn ẹ̀kọ́ dáadáa inú rẹ̀, a ti yàtọ̀ sí ohun tí a jẹ́ tẹ́lẹ̀. A ṣì bìkítà fún ara wa, bóyá lọ́nà tó tiẹ̀ jinlẹ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ pàápàá. Tóò, àǹfààní tún ṣí sílẹ̀ fún wa láti fẹ́ ara wa lẹ́ẹ̀kan sí i—ohun tí a sì ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn o. A tún jẹ́jẹ̀ẹ́ fúnra wa lẹ́ẹ̀kejì, ṣùgbọ́n lọ́tẹ̀ yìí, Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ti ṣe é.
Lars: Nǹkan ìyanu ńlá ṣẹlẹ̀—ìdílé wá mà tún ṣọ̀kan padà o! Ńṣe ni inú wa ń dùn ṣìnkìn nísinsìnyí!
Judith: Lára àwọn tó wá síbi ìgbéyàwó wa ni àwọn ọmọ wa, púpọ̀ lára àwọn ẹbí wa, àti ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ wa tuntun àti àwọn táa ti ní tẹ́lẹ̀. Ìrírí àgbàyanu gbáà ló jẹ́. Àwọn kan tó mọ̀ wá nígbà táa kọ́kọ́ fẹ́ra wà lára àwọn táa pè; inú wọ́n dùn láti tún rí wa papọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹnu sì yà wọ́n láti rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ojúlówó ayọ̀ láàárín ara wọn.
Àwọn Ọmọ
Lars: Látìgbà táa ti ṣèrìbọmi, inú wá dùn láti rí i pé méjì lára àwọn ọmọ wa yàn láti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà.
Judith: Jonas ti mọyì òtítọ́ inú Bíbélì tó ti gbọ́ nípa rẹ̀ láti kékeré, nígbà tó máa ń lọ kí bàbá rẹ̀. Ọmọ ọdún mẹ́wàá péré ni nígbà tó sọ fún mi pé òun fẹ́ lọ máa gbé ọ̀dọ̀ bàbá òun, ó sì ṣàlàyé ìdí tó fi fẹ́ bẹ́ẹ̀, ó ní, “Dádì máa ń fi ohun tí Bíbélì sọ sílò.” Jonas ṣèrìbọmi nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá. Ó ti parí ẹ̀kọ́ rẹ̀, òjíṣẹ́ alákòókò kíkún sì ni nísinsìnyí.
Lars: Ọmọ wa tó dàgbà jù lọ, Martin, ti pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n nísinsìnyí. Àwọn ìyípadà tó rí pé a ṣe ń mú kó ronú gan-an. Ó filé sílẹ̀, ó sì ń lọ gbé apá ibòmíràn ní orílẹ̀-èdè náà. Ní ọdún méjì sẹ́yìn, ó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lápá ibi tó ń gbé. Lẹ́yìn oṣù márùn-ún péré, ó ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi. Ó ṣì ń wéwèé àwọn ohun tó gbámúṣé nípa ìgbésí ayé rẹ̀ ọjọ́ iwájú gẹ́gẹ́ bí Kristẹni.
Ọmọ wa kejì, Thomas, kò tíì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bó ti wù kó rí, a fẹ́ràn rẹ̀ gidigidi, àárín àwa pẹ̀lú rẹ̀ sì dán mọ́rán. Inú ẹ̀ dùn sí ìyípadà tó ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé wa. Gbogbo wa sì gbà pé àwọn ìlànà táwa òbí kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ láti inú Bíbélì ló mú kí ìdílé wa ṣọ̀kan padà. Ìbùkún ńlá ló jẹ́ fún wa pé a lè wà papọ̀ bí ìdílé lọ́pọ̀ ìgbà, àtàwa àtàwọn ọmọkùnrin wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta!
Bí Ìgbésí Ayé Wa Ṣe Rí Lónìí
Lars: A ò sọ pé a ti dẹni pípé o. Ṣùgbọ́n a ti kọ́ ohun kan—pé ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ fún tọ̀túntòsì ṣe pàtàkì gan-an nínú ìgbéyàwó aláṣeyọrí sí rere. Orí ìpìlẹ̀ táa gbé ìgbéyàwó wa kà nísinsìnyí yàtọ̀ gan-an sí ti tẹ́lẹ̀. Nísinsìnyí, àwa méjèèjì ti fara mọ́ aláṣẹ kan tó ga jù wá lọ, nítorí pé àwa méjèèjì mọ̀ pé a wà láàyè fún Jèhófà. Èmi àti Judith ti wá ṣọ̀kan lóòótọ́, a sì ń fi ìdánilójú wọ̀nà fún ọjọ́ iwájú.
Judith: Mo rò pé a jẹ́ ẹ̀rí tó ṣeé fojú rí pé Jèhófà ni olùgbani-nímọ̀ràn tó dára jù lọ nípa ìgbéyàwó àti ìdílé.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde lọ́dún 1978; ṣùgbọ́n a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Lars àti Judith nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ ṣègbéyàwó lọ́dún 1973
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn ọmọkùnrin mẹ́ta yìí pàdánù ìdílé wọn tó ṣọ̀kan, wọ́n sì tún rí i padà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Lars àti Judith lónìí, fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò ló mú wọ́n ṣọ̀kan padà